15 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀,+
Àmọ́ ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.+
2 Ahọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ lọ́nà rere,+
Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń tú ọ̀rọ̀ ẹ̀gọ̀ jáde.
3 Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo,
Ó ń ṣọ́ ẹni burúkú àti ẹni rere.+
4 Ahọ́n pẹ̀lẹ́ jẹ́ igi ìyè,+
Àmọ́ ọ̀rọ̀ békebèke máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.
5 Òmùgọ̀ kì í ka ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀ sí,+
Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gba ìbáwí.+
6 Ọ̀pọ̀ ìṣúra ló wà nínú ilé olódodo,
Àmọ́ èso ẹni burúkú máa ń fa wàhálà bá a.+
7 Ètè ọlọ́gbọ́n máa ń tan ìmọ̀ kálẹ̀,+
Àmọ́ ọkàn àwọn òmùgọ̀ kì í ṣe bẹ́ẹ̀.+
8 Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+
Àmọ́ àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú Rẹ̀ dùn.+
9 Jèhófà kórìíra ọ̀nà ẹni burúkú,+
Àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń wá òdodo.+
10 Ìbáwí dà bí ohun tí kò dára lójú ẹni tó ń ṣìnà,+
Ẹni tó bá sì kórìíra ìbáwí á kú.+
11 Isà Òkú àti ibi ìparun ṣí sílẹ̀ gbayawu lójú Jèhófà.+
Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ọkàn èèyàn!+
12 Ẹlẹ́gàn kì í fẹ́ràn ẹni tó ń tọ́ ọ sọ́nà.+
Kì í fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọlọ́gbọ́n.+
13 Inú dídùn ló ń mórí yá,
Àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.+
14 Ọkàn tó ní òye máa ń wá ìmọ̀,+
Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ ni àwọn òmùgọ̀ fi ń ṣe oúnjẹ jẹ.+
15 Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ,+
Àmọ́ ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.+
16 Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀, kó sì bẹ̀rù Jèhófà+
Ju kó ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ pẹ̀lú àníyàn.+
17 Oúnjẹ tí a fi nǹkan ọ̀gbìn sè níbi tí ìfẹ́ wà+
Sàn ju akọ màlúù àbọ́sanra níbi tí ìkórìíra wà.+
18 Onínúfùfù máa ń dá wàhálà sílẹ̀,+
Àmọ́ ẹni tí kì í tètè bínú máa ń mú kí ìjà rọlẹ̀.+
19 Ọ̀nà ọ̀lẹ dà bí igbó ẹ̀gún,+
Àmọ́ ipa ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin dà bí ọ̀nà tó tẹ́jú.+
20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ máa ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn,+
Àmọ́ òmùgọ̀ èèyàn máa ń kórìíra ìyá rẹ̀.+
21 Ẹni tí kò ní làákàyè máa ń fi ìwà òmùgọ̀ ṣayọ̀,+
Àmọ́ ẹni tó ní òye máa ń rìn lọ tààrà.+
22 Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán,
Àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.+
23 Inú èèyàn máa ń dùn tí ìdáhùn rẹ̀ bá tọ̀nà,+
Ọ̀rọ̀ tó bá sì bọ́ sí àkókò mà dára o!+
24 Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye ń tọ ọ̀nà ìyè tó lọ sókè,+
Kí ó lè yẹra fún Isà Òkú nísàlẹ̀.+
25 Jèhófà máa ya ilé àwọn agbéraga lulẹ̀,+
Àmọ́ kò ní jẹ́ kí wọ́n sún ààlà opó sẹ́yìn.+
26 Jèhófà kórìíra èrò àwọn ẹni ibi,+
Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára mọ́ lójú Rẹ̀.+
27 Ẹni tó ń jẹ èrè tí kò tọ́ ń fa wàhálà bá agbo ilé rẹ̀,+
Àmọ́ ẹni tó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò máa wà láàyè.+
28 Ọkàn olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn,+
Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú máa ń tú ọ̀rọ̀ burúkú jáde.
29 Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,
Àmọ́ ó máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olódodo.+
30 Ojú tó ń dán máa ń mú ọkàn yọ̀;
Ìròyìn tó dára máa ń mú kí egungun lágbára.+
31 Ẹni tó ń fetí sí ìbáwí tó ń fúnni ní ìyè,
Àárín àwọn ọlọ́gbọ́n ló ń gbé.+
32 Ẹni tó bá ń kọ ìbáwí kórìíra ẹ̀mí rẹ̀,+
Àmọ́ ẹni tó bá ń gba ìbáwí ní òye.+
33 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń kọ́ni lọ́gbọ́n,+
Ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń ṣáájú ògo.+