Bí Àṣà Ilẹ̀ Gíríìsì Ṣe Nípa Lórí Àwọn Tó Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni
ÈDÈ Gíríìkì lọ̀pọ̀ lára àwọn táwọn tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni wàásù fún ń sọ. Èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fi ti àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa Jésù lẹ́yìn. Èdè Gíríìkì náà lọ̀pọ̀ nínú àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fi kọ ọ́, wọ́n sì lo àwọn ọ̀rọ̀ àti àpèjúwe tó rọrùn láti lóye fáwọn tó mọ àṣà àwọn Gíríìkì. Síbẹ̀, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀, títí kan àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lára wọn, kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì. Júù ni gbogbo wọn.—Róòmù 3:1, 2.
Báwo lèdè Gíríìkì ṣe wá ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ fún títan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀? Báwo làwọn òǹkọ̀wé tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni àtàwọn míṣọ́nnárì ṣe gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ lọ́nà tó fi máa wọ àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì lọ́kàn? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sóhun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn lákòókò yẹn?
Bí Àṣà Àwọn Gíríìkì Ṣe Tàn Kálẹ̀
Ní ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ọba Páṣíà, bẹ́ẹ̀ ló sì ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lágbàáyé. Káwọn ìlú tó ti ṣẹ́gun lè máa ṣe nǹkan bákan náà, òun àtàwọn ọba tó jẹ lẹ́yìn tó kú fi dandan lé e pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn gbọ́dọ̀ kọ́ èdè àti àṣà àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì.
Kódà, nígbà tí Róòmù ṣẹ́gun Gíríìsì tó sì rọ gbogbo olóṣèlú wọn lóyè, àṣà àwọn Gíríìkì ṣì gbilẹ̀ láàárín àwọn tó yí wọn ká. Láàárín ọ̀rúndún kìíní àti ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn nílùú Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn nǹkan táwọn Gíríìkì ṣe lárugẹ, tọ̀nà ìgbàyàwòrán la fẹ́ sọ ni àbí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́lé, tọ̀nà ìgbàkọ̀wé ni àbí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú, gbogbo nǹkan wọn pátá ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ìyẹn ló sì wá jẹ́ kí akéwì kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Horace kéwì pé: “Ẹrú a máa kó ọ̀gá rẹ̀ lẹ́rú, bí Gíríìsì ṣe mú kọ́gàá rẹ̀ fẹ́ràn àwọn àṣà rẹ̀.”
Nígbà tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso, àṣà àwọn Gíríìkì ló gbilẹ̀ láwọn ìlú bí Éṣíà Kékeré, Síríà, àti Íjíbítì. Bó ṣe di pé àṣà Gíríìkì mú ọ̀làjú bá gbogbo apá ìgbésí ayé àwọn èèyàn nìyẹn, látorí àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba, títí dórí òfin, ọjà títà, àtàwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, kódà ó kan ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń múra pàápàá. Púpọ̀ lára ìlú àwọn ará Gíríìsì ló ní gbọ̀ngàn táwọn ọmọdékùnrin ti máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa fara pitú, wọ́n sì láwọn gbọ̀ngàn ìwòran níbi tí wọ́n ti máa ń lọ wo àwọn eré ìtàgé tó jẹ mọ́ àṣà àwọn ará Gíríìsì.
Ohun tí òpìtàn Emil Schürer sọ nípa ìyípadà tó wáyé rèé, ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ò kọ́kọ́ fẹ́ gba àwọn àṣà yìí, wọn ò mọ̀gbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n hùwà, wọn ò sì fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀ mọ́ nígbà tó yá.” Ìtara táwọn Júù ní fún ẹ̀sìn wọn ò kọ́kọ́ jẹ́ kí wọ́n fàyè gba ìbọ̀rìṣà tó wà lára àṣà àwọn Gíríìkì, àmọ́ nígbà tó yá, ìgbésí ayé wọn wá dọ̀rọ̀ béwé bá pẹ́ lára ọṣẹ á dọṣẹ. Ó ṣe tán, òpìtàn Schürer kíyè sí pé “àdúgbò táwọn èèyàn ti ń sọ èdè Gíríìkì tí wọ́n sì ti ń dáṣà wọn ló yí àgbègbè kékeré táwọn Júù ń gbé ká, kò sì sí bí wọ́n ṣe lè yẹra fún wọn torí pé wọ́n jọ ń rajà lọ́wọ́ ara wọn ni.”
Iṣẹ́ Bíbélì Septuagint
Bí ọ̀pọ̀ àwọn Júù ṣe ń ṣí kúrò nílẹ̀ wọn tí wọ́n sì ń tẹ̀ dó sáwọn orílẹ̀-èdè tó wà létí Òkun Mẹditaréníà, wọ́n rí i pé àárín àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì tí wọ́n sì ń dáṣà ilẹ̀ Gíríìsì ni wọ́n bára wọn. Àwọn Júù wọ̀nyí ṣì ń ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù, wọ́n ṣì máa ń wá sí Jerúsálẹ́mù fún àwọn àjọyọ̀ táwọn Júù máa ń ṣe lọ́dọọdún. Àmọ́ bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í gbàgbé èdè Hébérù.a Ìdí sì nìyẹn tó fi di dandan láti tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sédè Gíríìkì tọ́pọ̀ jù lọ wọn ń sọ. Àwọn ọ̀mọ̀wé Júù tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa gbé ní Alẹkisáńdíríà, lórílẹ̀-èdè Íjíbítì tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìlú tí àṣà àwọn Gíríìkì ti gbilẹ̀, ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtumọ̀ yìí lọ́dún 280 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìwé tí wọ́n tú ló wá di Bíbélì Septuagint báyìí.
Àwọn èèyàn sọ pé Bíbélì Septuagint wúlò gan-an. Òun ló jẹ́ káwọn tó ń gbé láyé ọ̀làjú tá a wà yìí mọ àwọn ìṣúra tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ká ní kò sí Bíbélì Septuagint ni, kò ní sí báwọn èèyàn ṣe máa mọ àjọṣe tó wà láàárín Ọlọ́run àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí ṣàṣà làwọn tó gbọ́ èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ ọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí ìhìn rere náà tàn káyé bó ṣe rí lónìí. Ká sòótọ́, Bíbélì Septuagint ló jẹ́ ká mọ ibi tọ́rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ ti bẹ̀rẹ̀, àtohun tó wà níbẹ̀, èdè tí wọ́n sì fi kọ ọ́ ló jẹ́ kó rọrùn láti tú ìmọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run fáwọn èèyàn tó wà lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé. Torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbọ́ èdè Gíríìkì, òun làwọn oníwàásù fi tan òtítọ́ nípa Ọlọ́run kálẹ̀.
Àwọn Aláwọ̀ṣe Àtàwọn Olùbẹ̀rù Ọlọ́run
Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù ti tú púpọ̀ lára àwọn ìwé wọn sí èdè Gíríìkì, èdè yẹn náà ni wọ́n sì fi ń kọ àwọn ìwé míì tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ nígbà yẹn. Èyí ló sì jẹ́ káwọn Kèfèrí wá mọ ìtàn Ísírẹ́lì àti ìjọsìn wọn dáadáa. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The History of the Jewish People in the Age of Jesus Christ ṣe ṣàlàyé, àwọn òpìtàn sọ pé lákòókò yẹn, ńṣe làwọn Kèfèrí “bẹ̀rẹ̀ sí í báwọn Júù ṣe nǹkan pa pọ̀, wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn àwọn Júù, wọ́n sì ń pa òfin àwọn Júù mọ́ bó bá ṣe yé wọn sí.”
Nígbà tó yá, àwọn Kèfèrí kan tẹ̀ síwájú débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù, wọ́n dádọ̀dọ́, wọ́n sì wá di aláwọ̀ṣe. Àwọn míì fara mọ́ apá kan lára ẹ̀sìn àwọn Júù, àmọ́ wọn ò fẹ́ yí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe pa dà. Àwọn wọ̀nyí làwọn ìwé tí wọ́n kọ lédè Gíríìkì sábà máa ń pè ní “àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run.” Bíbélì pe Kọ̀nílíù ní “olùfọkànsìn àti ẹnì kan tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàdé àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Júù ní Éṣíà Kékeré àti Gíríìsì. Bí àpẹẹrẹ, ní Áńtíókù tàwọn ará Písídíà, ó pe àwọn tó pàdé pọ̀ sí sínágọ́gù ní “ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòókù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run.”—Ìṣe 10:2; 13:16, 26; 17:4; 18:4.
Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn Júù tó wà lẹ́yìn odi Jùdíà, púpọ̀ lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn ló jẹ́ pé àṣà àwọn Gíríìkì ni wọ́n fi tọ́ wọn dàgbà. Ilẹ̀ ọlọ́ràá nirú àwọn àgbègbè wọ̀nyẹn jẹ́ fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀sìn Kristẹni. Nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn ti wá rí i pé Ọlọ́run ti ń fáwọn Kèfèrí náà nírètí láti ní ìgbàlà, ó wá yé wọn pé lójú Ọlọ́run “kò sí Júù tàbí Gíríìkì.”—Gálátíà 3:28.
Wọ́n Wàásù Fáwọn Gíríìkì
Nígbà táwọn Júù tó kọ́kọ́ di Kristẹni ronú lórí ẹ̀sìn táwọn Kèfèrí wọ̀nyẹn ń ṣe tẹ́lẹ̀ àti ìwà tí wọ́n ń hù, wọn ò fẹ́ gbà wọ́n láyè láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni. Torí náà, nígbà tó ṣe kedere sáwọn àpọ́sítélì pé Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba àwọn Kèfèrí, àwọn àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ kó yé wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, wọn ò gbọ́dọ̀ ṣàgbèrè, wọn ò sì gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà. (Ìṣe 15:29) Ó ṣe pàtàkì pé káwọn tó ti ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àṣà àwọn Gíríìkì ṣe àwọn ìyípadà wọ̀nyí nígbèésí ayé wọn, torí pé “ìbálòpọ̀ takọtabo tí ń dójú tini,” kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀, kí obìnrin sì máa bá obìnrin lò pọ̀ kì í ṣe nǹkan bàbàrà láàárín àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù. Kò sáyè fún irú àwọn ìwà pálapàla wọ̀nyẹn láàárín àwọn Kristẹni.—Róòmù 1:26, 27; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló gbajúmọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì tó wàásù láàárín àwọn Gíríìkì nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Títí di báyìí, àwọn tó bá rìnrìn àjò lọ sí Áténì, lórílẹ̀-èdè Gíríìsì ṣì máa rí wàláà tí wọ́n fi idẹ ṣe tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Áréópágù níbi tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó sí. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn wà ní orí 17 nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì. Báwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn nílùú Gíríìsì ni Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní “Ẹ̀yin ènìyàn Áténì,” ìyẹn sì jẹ́ kára tu àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ títí kan àwọn Epikúréì, ìyẹn àwọn tó nígbàgbọ́ nínú káwọn jayé òní àtàwọn Sítọ́íkì, ìyẹn àwọn ọ̀mọ̀wé tó nígbàgbọ́ nínú kádàrá. Kàkà kí Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n rí i pé ohun tí wọ́n ń ṣe ò bá òun lára mu tàbí kó máa bẹnu àtẹ́ lu ohun táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà gbọ́, ńṣe ló kọ́kọ́ ronú lórí ìfẹ́ ọkàn wọn, ó sì wá gbóríyìn fún wọn pé wọ́n fẹ́ràn ìjọsìn. Ó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kọ sórí pẹpẹ wọn, ìyẹn “Sí Ọlọ́run Àìmọ̀,” ó sì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn látorí ohun tí wọ́n fara mọ́ nípa sísọ fún wọn pé Ọlọ́run tí wọn ò mọ̀ yẹn lòun wá wàásù rẹ̀ fún wọn.—Ìṣe 17:16-23.
Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn nípa lílo àwọn àlàyé tó máa rọrùn fún wọn láti gbà. Àwọn tó nígbàgbọ́ nínú kádàrá gbà pẹ̀lú ẹ̀ pé Ọlọ́run ni Orísun ìwàláàyé aráyé, pé ibì kan náà ni gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀ wá, pé Ọlọ́run ò jìnnà sí wa, àti pé ọwọ́ Ọlọ́run ni ìwàláàyé wa wà. Pọ́ọ̀lù fi ewì Aratus (tí àkọlé ẹ̀ jẹ́ Phaenomena) àti ti Cleanthes (ìyẹn orin tó kọ sí Súúsì) ti ọ̀rọ̀ tó sọ gbẹ̀yìn lẹ́yìn. Àwọn Epikúréì náà rí i pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ò ta ko ohun táwọn gbà gbọ́; wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, ó sì ṣeé mọ̀, pé ó ní ohun gbogbo, pé kò tọrọ ohunkóhun lọ́wọ́ èèyàn, pé kò sì lè gbé nínú àwọn tẹ́ńpìlì táwọn èèyàn fọwọ́ kọ́.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò kò ṣàjèjì sáwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀. Kódà, ìwé kan jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ayé (ìyẹn kosmos),” “àtọmọdọ́mọ” àti “Olù-Wà Ọ̀run” tí Pọ́ọ̀lù lò làwọn ọ̀jọ̀gbọ̀n Gíríìkì sábà máa ń lò. (Ìṣe 17:24-29) Kì í kúkú ṣe pé Pọ́ọ̀lù fòótọ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó wá máa sọ nǹkan míì kó lè yí wọn lérò pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ gbẹ̀yìn nípa àjíǹde àti ìdájọ ò bá ìgbàgbọ́ wọn mu. Síbẹ̀ náà, ńṣe ló fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀, kó lè wọ àwọn tó lọ́pọlọ nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn.
Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù ló kọ sáwọn ìjọ táwọn Gíríìkì wà tàbí sáwọn tó wà láwọn àdúgbò tí Róòmù ń ṣàkóso, àmọ́ tí wọ́n ti kọ́ àṣà àwọn Gíríìkì. Pọ́ọ̀lù kọ àwọn lẹ́tà wọ̀nyí lọ́nà tó já geere, ó lo ògidì ọ̀rọ̀ Gíríìkì, àwọn èrò tó kọ àtàwọn àpẹẹrẹ tó lò sì bá àṣà àwọn Gíríìkì mu. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn eré ìdárayá tí wọ́n máa ń ṣe, ó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn táwọn akọni máa ń gbà, ó sọ̀rọ̀ nípa akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó tẹ̀ lé ọmọkùnrin kan lọ síléèwé, àtàwọn àpẹẹrẹ míì tó bá àṣà àwọn Gíríìkì mu. (1 Kọ́ríńtì 9:24-27; Gálátíà 3:24, 25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣe tán láti lo ọ̀rọ̀ àwọn Gíríìkì, kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn ìwà àti ìjọsìn wọn.
Ó Di Ohun Gbogbo fún Ènìyàn Gbogbo
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tóun bá fẹ́ wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, òun gbọ́dọ̀ “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” Òun fúnra ẹ̀ sọ pé “fún àwọn Júù [òun] dà bí Júù, kí [òun] lè jèrè àwọn Júù,” ó sì ṣe bíi Gíríìkì kó lè ran àwọn Gíríìkì lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Kò sí àníàní pé Pọ́ọ̀lù tóótun láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé Júù ni, àdúgbò tí àṣà àwọn Gíríìkì ti gbilẹ̀ ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Ohun tó yẹ kí gbogbo Kristẹni máa ṣe lónìí gan-an nìyẹn.—1 Kọ́ríńtì 9:20-23.
Lónìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń fìlú wọn sílẹ̀ tí wọ́n lọ ń gbé níbòmíì, àwọn míì sì ti kọ́ àṣà tó yàtọ̀ sí tiwọn. Èyí ti wá gbé ojúṣe tó lágbára lé àwọn Kristẹni lọ́wọ́, torí wọ́n ti fi wíwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ṣe olórí iṣẹ́ wọn, wọ́n sì fẹ́ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 24:14; 28:19) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti rí i pé ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an tí wọ́n bá gbọ́ ọ lédè abínibí wọn, wọ́n sì máa ń ṣàwọn ìyípadà tó bá yẹ.
Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lóṣooṣù ọgọ́rùn-ún kan àti mọ́kàndínláàádọ́rin [169] èdè la fi ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́—Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà, tá a sì ń tẹ ìwé ìròyìn Jí! ní èdè mọ́kànlélọ́gọ́rin [81] lóṣooṣù. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ti sapá gan-an láti kọ́ èdè tí kì í ṣe tiwọn, kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere fáwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Àwọn èdè míì lára àwọn èdè tí wọ́n kọ́ kì í rọrùn láti lóye, irú bí Lárúbáwá, èdè àwọn ará Ṣáínà àti èdè àwọn ará Rọ́ṣíà. Ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ò yàtọ̀ sí tàwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ rèé, ó ní: “Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là.”—1 Kọ́ríńtì 9:22.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ló gbédè Gíríìkì. Bí àpẹẹrẹ, “àwọn ọkùnrin kan dìde lára àwọn tí wọ́n wá láti inú èyí tí àwọn ènìyàn ń pè ní Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira, àti lára àwọn ará Kírénè àti àwọn ará Alẹkisáńdíríà àti lára àwọn tí wọ́n wá láti Sìlíṣíà àti Éṣíà,” ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èdè Gíríìkì ni wọ́n ń sọ.—Ìṣe 6:1, 9.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Róòmù
GÍRÍÌSÌ
Áténì
ÉṢÍÀ
Áńtíókù (ti Písídíà)
SÌLÍṢÍÀ
SÍRÍÀ
JÙDÍÀ
Jerúsálẹ́mù
ÍJÍBÍTÌ
Alẹkisáńdíríà
Kírénè
ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Bíbélì Septuagint ló jẹ́ káwọn oníwàásù lè tan ìmọ̀ nípa Jèhófà kálẹ̀ nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀
[Credit Line]
Látọwọ́ Israel Antiquities Authority
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Wàláà tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí ní Áréópágù