Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
6 Lákòókò yẹn, bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ń pọ̀ sí i, àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé nípa àwọn Júù tó ń sọ èdè Hébérù, nítorí pé àwọn tó ń pín nǹkan lójoojúmọ́ ń gbójú fo àwọn opó wọn.+ 2 Ni àwọn Méjìlá náà bá pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ẹ̀yìn jọ, wọ́n sì sọ pé: “Kò tọ́ kí a* fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ ká wá máa pín oúnjẹ sórí tábìlì.+ 3 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ yan àwọn ọkùnrin méje láàárín yín tí wọ́n lórúkọ rere,*+ tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n,+ kí a lè yàn wọ́n láti máa bójú tó ọ̀ràn tó pọn dandan yìí;+ 4 àmọ́, àwa á gbájú mọ́ àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.” 5 Ohun tí wọ́n sọ dùn mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà nínú, wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú Fílípì,+ Pírókórọ́sì, Níkánọ̀, Tímónì, Páménásì àti Níkóláósì tó jẹ́ aláwọ̀ṣe* ará Áńtíókù. 6 Wọ́n mú wọn wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.+
7 Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbilẹ̀ nìṣó,+ iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń pọ̀ sí i gidigidi+ ní Jerúsálẹ́mù; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba* ìgbàgbọ́ náà.+
8 Nígbà náà, Sítéfánù, tó kún fún oore Ọlọ́run àti agbára, ń ṣe àwọn ohun ìyanu* ńlá àti àwọn iṣẹ́ àmì láàárín àwọn èèyàn. 9 Àmọ́ àwọn ọkùnrin kan látinú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira wá, pẹ̀lú àwọn ará Kírénè àti àwọn ará Alẹkisáńdíríà àti lára àwọn tó wá láti Sìlíṣíà àti Éṣíà, wọ́n wá bá Sítéfánù fa ọ̀rọ̀. 10 Àmọ́ wọn ò lè dúró níwájú rẹ̀ nítorí ọgbọ́n àti ẹ̀mí tó fi ń sọ̀rọ̀.+ 11 Lẹ́yìn náà, wọ́n sún àwọn kan ní bòókẹ́lẹ́ pé kí wọ́n sọ pé: “A gbọ́ tó ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Mósè àti Ọlọ́run.” 12 Wọ́n ru àwọn èèyàn àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin sókè, wọ́n wá bá a lójijì, wọ́n fipá gbá a mú, wọ́n sì mú un lọ sí Sàhẹ́ndìrìn. 13 Wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tí wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí kò jáwọ́ nínú sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí ibi mímọ́ yìí àti sí Òfin. 14 Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ tó sọ pé Jésù ará Násárẹ́tì máa wó ibí yìí palẹ̀, á sì yí àwọn àṣà tí Mósè fi lé wa lọ́wọ́ pa dà.”
15 Bí gbogbo àwọn tó jókòó ní Sàhẹ́ndìrìn ṣe tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí i pé ojú rẹ̀ dà bí ojú áńgẹ́lì.