Ìdí Márùn-ún Tó Fi Yẹ Kó O Bẹ̀rù Ọlọ́run Dípò Èèyàn
ÌYÀLẸ́NU gbáà ló jẹ́ fún ọmọkùnrin náà. Kò ronú pé nǹkan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ yìí lè wáyé láé. Ọ̀rọ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan bá a sọ ti jẹ́ kó mọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Ọjọ́ pẹ́ tó ti ń fẹ́ lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, àmọ́ wọ́n ti wá fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè ẹ̀ báyìí. Kò mọ̀ pé àwọn ìsọfúnni tó lè múnú èèyàn dùn tó sì ṣe pàtàkì tóyẹn wà nínú Bíbélì.
Kò pẹ́ táwọn àlejò wọ̀nyẹn lọ tán ni ìyá onílé ẹ̀ fìbínú já wọnú yàrá ẹ̀, tó sì pariwo mọ́ ọn pé, “Ta làwọn èèyàn wọ̀nyẹn?”
Torí ọmọkùnrin náà ò retí irú ìbéèrè yìí, kò mohun tí ì bá sọ.
Nígbà tọ́mọkùnrin yẹn ò dá a lóhùn, obìnrin náà pariwo pé, “Mo mọ̀ wọ́n dáadáa, ọjọ́ tó o bá sì tún gbà wọ́n lálejò lo máa kẹ́rù ẹ̀ kúrò ńlé yìí!”
Obìnrin náà fìbínú tilẹ̀kùn gbàgà, ó sì bá tiẹ̀ lọ.
Àtakò Ò Jọ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Kristi Lójú
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sọ́mọkùnrin yẹn kì í ṣe nǹkan tuntun. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Látìgbà táláyé ti dáyé làwọn èèyàn ò ti nífẹ̀ẹ́ sáwọn Kristẹni tòótọ́. Kí nìdí? Ìdí tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀ ò ṣòro ṣàlàyé, torí àpọ́sítélì Jòhánù sọ fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “A mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Bíbélì sì tún pe Sátánì Èṣù ní “kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Jòhánù 5:19; 1 Pétérù 5:8) Ìbẹ̀rù èèyàn sì wà lára irinṣẹ́ tó jẹ́ Sátánì lọ́wọ́ jù lọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni Jésù Kristi ṣe nígbà tó wà láyé tí kò sì dẹ́ṣẹ̀ kankan, àwọn èèyàn fi í ṣẹ̀sín, wọn ò sì gba tiẹ̀. Òun fúnra ẹ̀ sọ pé: “Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.” (Jòhánù 15:25) Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa á, ó jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó sọ pé: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín sọ́kàn, pé, ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.”—Jòhánù 15:18, 20.
Ọ̀pọ̀ ni ò fẹ́ láti ṣèsìn tòótọ́ nítorí ìkìlọ̀ yìí. Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó ń wá Jésù lọ́jọ́ kan rèé, ó ní: “Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹnì kan tí ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.” (Jòhánù 7:13; 12:42) Àwọn aṣáájú ìsìn ti dẹ́rù ba àwọn èèyàn nípa sísọ pé gbogbo ẹni tó bá ti gba Kristi gbọ́ làwọ́n máa lé kúrò nínú sínágọ́gù. Ìdí nìyẹn tí ìbẹ̀rù ò fi jẹ́ káwọn kan di Kristẹni.—Ìṣe 5:13.
Nígbà tó yá, lẹ́yìn tí ìjọ Kristẹni ti fìdí múlẹ̀, a kà nípa “inúnibíni ńlá” táwọn èèyàn ń ṣe sí ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 8:1) Kódà, àwọn Kristẹni dojú kọ àtakò ní gbogbo Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn nílùú Róòmù sọ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:22) Kò sí àní-àní pé, ibi gbogbo làwọn èèyàn ò ti gba tàwọn ojúlówó Kristẹni.
Kódà, Sátánì ṣì ń lo ìbẹ̀rù èèyàn láti dẹkùn mú àwọn èèyàn kan lónìí, kí wọ́n má bàa di ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi. Àwọn èèyàn máa ń fàwọn olóòótọ́ èèyàn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́ níléèwé, níbi iṣẹ́, ládùúgbò tàbí nígbà tí wọ́n bá wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́. Àwọn olóòótọ́ èèyàn wọ̀nyí lè máà fẹ́ káwọn èèyàn máa kàn wọ́n lábùkù, wọ́n lè máà fẹ́ pàdánù àwọn ọ̀rẹ́ wọn tàbí ìrànlọ́wọ́ nípa tara látọ̀dọ̀ àwọn kan. Láwọn abúlé kan, àwọn àgbẹ̀ máa ń bẹ̀rù pé àwọn aládùúgbò lè máà fẹ́ ran àwọn lọ́wọ́ tó bá dìgbà ìkórè, wọ́n sì lè máà fẹ́ báwọn bójú tó àwọn nǹkan ọ̀sìn àwọn. Láìka irú àwọn ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ sí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fara wé Jésù Kristi nípa jíjẹ́ kí ìgbésí ayé wọn bá ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Jèhófà sì ti bù kún wọn, nítorí ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí.
Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Ọlọ́run Dípò Èèyàn
Bíbélì gbà wá níyànjú láti bẹ̀rù Ọlọ́run dípò èèyàn, ó ní: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.” (Sáàmù 111:10) Ìbẹ̀rù tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ kì í ṣe ìbẹ̀rù oníjìnnìjìnnì, àmọ́ ìbẹ̀rù tó máa jẹ́ ká ronú jinlẹ̀ tá ò fi ní fẹ́ ṣẹ Olùfúnni Ní Ìwàláàyè wa. Ìbẹ̀rù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run. Kí wá nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù Ọlọ́run dípò èèyàn? Jẹ́ ká gbé ìdí márùn-ún yẹ̀ wò.
1 Kò sẹ́lẹgbẹ́ Jèhófà. Jèhófà lágbára ju ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì. Tá a bá níbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá mọ́ Ọlọ́run Olódùmarè, ẹni tó jẹ́ pé lójú ẹ̀, “àwọn orílẹ̀-èdè [ò ju] ẹ̀kán omi kan láti inú korobá” lọ. (Aísáyà 40:15) Ọlọ́run lágbára láti ṣẹ́gun “ohun ìjà yòówù [táwọn èèyàn] bá ṣe” sáwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí i, nítorí pé òun ni Olódùmarè, kò sì sẹ́lẹgbẹ́ ẹ̀. (Aísáyà 54:17) Nígbà tó sì jẹ́ pé òun ló máa pinnu ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti wà láàyè títí láé, ó bọ́gbọ́n mu pé ká máà jẹ́ kí nǹkan kan dí wa lọ́wọ́ mímọ Ọlọ́run àti kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ rẹ̀.—Ìṣípayá 14:6, 7.
2 Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́, ó sì máa dáàbò bò wá. Bíbélì sọ nínú ìwé Òwe 29:25 pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.” Ìdẹkùn ni ìbẹ̀rù èèyàn, nítorí pé kì í jẹ́ ká lè fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ọlọ́run sì ti jẹ́ kó dá wa lójú pé òun lágbára láti gbà wá, ó ní: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 41:10.
3 Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó sún mọ́ ọn. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ rèé, ó ní: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:37-39) Tá a bá kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tá a sì ń ṣègbọ́ràn sí i, a máa jàǹfààní látinú àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú aláṣẹ́ láyé àtọ̀run nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. O ò rí i pé àǹfààní ńlá lèyí!
4 A mọyì gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa. Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, tí kì í bá ṣòun ni à bá tí wà láàyè. Yàtọ̀ síyẹn, ó ti pèsè gbogbo ohun tó máa jẹ́ ká máa wà láàyè nìṣó, títí kan àwọn nǹkan tó máa mú ká gbádùn ayé wa, kó sì dùn mọ́ wa. Ká sòótọ́, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀bùn rere ti wá. (Jákọ́bù 1:17) Dáfídì, ọkùnrin olóòótọ́ kan tó mọyì inúure Ọlọ́run kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa . . . Wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.”—Sáàmù 40:5.
5 Àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàtakò sí wa lè yí pa dà. O lè ran àwọn tó ń ṣenúnibíni sí ẹ lọ́wọ́ tó ò bá dáwọ́ sínsin Ọlọ́run dúró àmọ́ tó ò ń bá a nìṣó láti bẹ̀rù Ọlọ́run tó o sì ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. O lè fi tàwọn ìbátan Jésù ṣàríkọ́gbọ́n. Wọn ò kọ́kọ́ nígbàgbọ́ nínú Jésù, wọ́n sọ pé: “Orí rẹ̀ ti yí.” (Máàkù 3:21; Jòhánù 7:5) Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn ló di onígbàgbọ́ lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde. Kódà, Jákọ́bù àti Júúdà tí wọ́n jẹ́ iyèkan Jésù wà lára àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́. Àpẹẹrẹ míì tún ni ti Sọ́ọ̀lù tó gba wèrè mẹ́sìn débi tó fi ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Òun ló wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Torí náà, tá a bá ń fìgboyà bá a nìṣó láti jólóòótọ́, àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàtakò sí wa báyìí lè wá lóye pé àwa gan-an la lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.—1 Tímótì 1:13.
Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Aberash, nílẹ̀ Áfíríkà, ti ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kóun mọ òtítọ́. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ àtàwọn olórí ìsìn fojú ẹ̀ rí màbo. Àwọn kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀, táwọn náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn mú wọn dáwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dúró. Àmọ́, Aberash gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun ní okun àti ìgboyà, ó sì ti wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi báyìí. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ohun tó ṣe yìí fún ìgbàgbọ́ àwọn mẹ́jọ lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ lókun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà, wọ́n sì ti ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn.
O Lè Borí Ìbẹ̀rù Èèyàn
Tó ò bá fẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn borí ẹ, àfi kó o ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti mú kí ìfẹ́ ẹ fún Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀. Láti ṣèyẹn, o ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì máa ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì bí irú èyí tó wà nínú Hébérù 13:6 tó sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?” Má gbàgbé àwọn ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o máa bẹ̀rù Ọlọ́run dípò èèyàn.
Tún máa rántí àwọn àǹfààní tó o máa rí tó o bá ń fàwọn nǹkan tó o ti kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù. Wàá ráwọn ìdáhùn tó máa tẹ́ ẹ lọ́rùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹ̀dá. Wàá lọ́gbọ́n tó o lè fi bójú tó àwọn ìṣòro tó wà láyé lónìí. Báyé yìí ò tiẹ̀ fara rọ, wàá nírètí pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Wàá sì láǹfààní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run olódùmarè nígbàkugbà.
Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká pinnu pé a ò ní kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa ṣe ohun gbogbo pẹ̀lú ìbẹ̀rù ẹ̀ lọ́kàn wa. Kàkà kó o jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn sọ ìgbàgbọ́ ẹ dakúrẹtẹ̀, á dáa kó o máa ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún wa nínú Ìwé Mímọ́, ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Àǹfààní ńlá mà lèyí o!
Má gbàgbé pé kò séèyàn kankan tó lè fún ẹ lóhun tí Ọlọ́run máa fún gbogbo àwọn tó bá ń bẹ̀rù rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Nítorí ìgboyà tí Aberash ní, mẹ́jọ lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ló ti ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí