Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?
NÍGBÀ kan, Jésù bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Baba wo ní ń bẹ láàárín yín tí ó jẹ́ pé, bí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, bóyá tí yóò fi ejò lé e lọ́wọ́ dípò ẹja? Tàbí bí ó bá tún béèrè ẹyin, tí yóò fi àkekèé lé e lọ́wọ́?” (Lúùkù 11:11, 12) Àwọn ọmọdé tó wà nílùú Gálílì fẹ́ràn láti máa jẹ ẹyin àti ẹja, wọ́n sì dá irú oúnjẹ tí wọ́n fẹ́ mọ̀.
Jésù sọ pé ká máa bá a nìṣó láti máa béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ láìjẹ́ kó sú wa, bí ọmọ kékeré kan tébi ń pa ṣe máa ń béèrè fún oúnjẹ. (Lúùkù 11:9, 13) Tá a bá lóye ohun tí ẹ̀mí mímọ jẹ́, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ipa pàtàkì tó lè kó nígbèésí ayé wa. Torí náà, jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì kọ́ wa nípa ẹ̀mí mímọ́.
“Agbára Ẹni Gíga Jù Lọ”
Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ agbára ìṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run máa ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ń sọ fún Màríà pé ó máa bímọ ọkùnrin kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sún mọ́ ọkùnrin kankan rí, áńgẹ́lì náà sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:35) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ, ìjọra kan wà láàárín ẹ̀mí mímọ àti “agbára Ẹni Gíga Jù Lọ.”
Èrò tó jọ èyí wà níbòmíì nínú Bíbélì. Wòlíì Míkà sọ pé: “Èmi alára sì ti kún fún agbára, nípa ẹ̀mí Jèhófà.” (Míkà 3:8) Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín.” (Ìṣe 1:8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ nípa “agbára ẹ̀mí mímọ.”—Róòmù 15:13, 19.
Torí náà, kí la lè parí èrò sí látinú àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí? A rí i pé ìjọra tó pọ̀ gan-an wà láàárín ẹ̀mí mímọ́ àti agbára Ọlọ́run. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà máa ń gbà lo agbára rẹ̀. Ní kúkúrú, ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣe nǹkan tàbí ipa agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni! Agbára tí kò láfiwé ni Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run. Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, Jèhófà dábàá pé ká ronú lórí àwọn nǹkan yìí, ó ní: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—Aísáyà 40:26.
Torí náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ‘okun alágbára gíga’ tàbí agbára Ọlọ́run Olódùmárè ló jẹ́ kí ayé àti ọ̀run wà, kó sì wà létòlétò. Ó dájú pé ipa agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọ́run kò láfiwé, ipasẹ̀ rẹ̀ la sì fi wà láàyè.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, “Àwọn Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Fi Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe.”
Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ṣe ohun tó lágbára gan-an, bó ṣe lò ó láti ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run. Ó sì tún lè lò ó láti ran àwa èèyàn lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ipa agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọ́run fún lágbára wà nínú Bíbélì.
“Ẹ̀mí Jèhófà Ń Bẹ Lára Mi”
Iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù ṣe jẹ́ ká rí díẹ̀ nínú bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe lè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára. Jésù sọ fún àwọn ará Násárétì pé, “ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi.” (Lúùkù 4:18) Àṣeyọrí wo ni Jésù ṣe nípasẹ̀ “agbára ẹ̀mí”? (Lúùkù 4:14) Ó wo oríṣiríṣi àìsàn sàn, ó jẹ́ kí òkun tó ń ru gùdù rọlẹ̀, ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn pẹ̀lú ìwọ̀nba búrẹ́dì àti ẹja díẹ̀, kódà ó jí òkú dìde. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn ní gbangba . . . nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára àti àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣe 2:22.
Lónìí, Ọlọ́run kò lo ẹ̀mí mímọ́ láti ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ mọ́. Àmọ́ ó ṣì lè lò ó láti ṣe àwọn ohun ribiribi fún wa. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú, Jèhófà máa ń fínnúfíndọ̀ fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́. (Lúùkù 11:13) Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Ṣé ẹ̀mí mímọ́ lè ṣe ohun kan náà nígbèésí ayé rẹ? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa dáhùn ìbéèrè yìí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìdí Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Kì Í Fi Í Ṣe Ẹnì Kan
Bíbélì fi ẹ̀mí mímọ́ wé omi. Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣèlérí ìbùkún ọjọ́ iwájú fún àwọn èèyàn rẹ̀, ó sọ pé: “Èmi yóò da omi sára ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, àti àwọn odò kéékèèké tí ń ṣàn sórí ibi gbígbẹ. Èmi yóò da ẹ̀mí mi sára irú-ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sára àwọn ọmọ ìran rẹ.”—Aísáyà 44:3.
Nígbà tí Ọlọ́run da ẹ̀mí rẹ̀ sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n “kún fún ẹ̀mí mímọ́.” Bíbélì sọ pé Jésù, Jòhánù Oníbatisí, Pétérù, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kún fún ẹ̀mí mímọ́, bákan náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n kóra jọ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni.—Lúùkù 1:15; 4:1; Ìṣe 4:8; 9:17; 11:22, 24; 13:9.
Gbé èyí yẹ̀ wò ná: Ṣé ẹnì kan lè ‘da’ ara rẹ̀ sára ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn? Ṣó ṣeé ṣe kí ẹnì kan “kún” inú àwùjọ èèyàn? Ó dájú pé ìyẹn kò bọ́gbọ́n mu. Bíbélì sọ nípa àwọn kan pé wọ́n kún fún ọgbọ́n, òye tàbí ìmọ̀ pípéye, àmọ́ kò ṣàpèjúwe ẹnì kankan rí pé ó kún fún ẹlòmíì.—Ẹ́kísódù 28:3; 1 Àwọn Ọba 7:14; Lúùkù 2:40; Kólósè 1:9.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà Pneuʹma, ni wọ́n tú sí “ẹ̀mí,” èyí tó tún túmọ̀ sí pé nǹkan kan jẹ́ agbára tí kò ṣeé fojú rí. Bákan náà, ìwé Vine’s Expository Dictionary of New Testament Words tún sọ pé, ọ̀rọ̀ náà pneuʹma “túmọ̀ níti gidi sí afẹ́fẹ́ . . . ó tún túmọ̀ sí èémí; pàápàá jù lọ ó túmọ̀ sí ẹ̀mí, tóun náà ò ṣeé fojú rí bí afẹ́fẹ́, kò ṣeé fọwọ́ kàn, ó sì lágbára.”
Ó ṣe kedere nígbà náà pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, ka “Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́” lójú ìwé 201 sí 204 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Credit Line]
Photodisc/SuperStock