Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́ Agbára Tó O Nílò Nígbèésí Ayé Rẹ
“MÁ ṢE gbé mi sọnù kúrò níwájú rẹ; ẹ̀mí mímọ́ rẹ ni kí o má sì gbà kúrò lára mi.” (Sáàmù 51:11) Èyí ni àdúrà àtọkànwá tí Dáfídì Ọba gbà lẹ́yìn tó ṣe àṣìṣe kan tó lágbára.
Ó ti pẹ́ tí Dáfídì ti máa ń rí ọwọ́ agbára ẹ̀mí mímọ́ nínú ayé rẹ̀. Nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti borí Gòláyátì, ìyẹn sójà tó dà bíi pé kò ṣe é borí. (1 Sámúẹ́lì 17:45-50) Ó tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti kọ àwọn kan lára sáàmù tó mọ́gbọ́n dání jù lọ tí wọ́n tíì kọ. Dáfídì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ni ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wà lórí ahọ́n mi.”—2 Sámúẹ́lì 23:2.
Jésù Kristi alára jẹ́rìí sí i pé ẹ̀mí mímọ́ kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé Dáfídì. Nígbà kan, Jésù sọ fún àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà wí fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.”’” (Máàkù 12:36; Sáàmù 110:1) Jésù mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ ló darí Dáfídì nígbà to kọ àwọn sáàmù yẹn. Ṣé ẹ̀mí mímọ́ yẹn ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ran àwa náà lọ́wọ́?
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Bíbéèrè, A Ó sì Fi Í Fún Yín”
O lè má kọ sáàmù. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kó o ti dojú kọ òkè ìṣòro tó ń dẹ́rù bani bíi Góláyátì. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Isabel yẹ̀ wò.a Ọkọ rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó sì bá ọmọge lọ. Gbèsè ńlá ni ọkọ rẹ̀ fi sílẹ̀ fún un, kò sì fowó kankan sílẹ̀ láti máa fi gbọ́ bùkátà àwọn ọmọbìnrin méjì tí wọ́n bí. Isabel sọ pé: “Ọkọ mi dalẹ̀ mi, ó sì fẹ̀gbin lọ̀ mí. Síbẹ̀, látìgbà tó ti kọ̀ mí sílẹ̀, mo nímọ̀lára pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá ìgbésí ayé mi lọ.”
Ṣé Isabel ń retí pé òun máa rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ láìsí ìsapá kankan ni? Rárá o, ojoojúmọ́ ló máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún òun ní ẹ̀mí rẹ̀. Ó mọ̀ pé òun nílò okun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí òun tó lè dojú kọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú láìfòyà, kí òun tó lè tọ́jú àwọn ọmọ òun, kí òun sì tó lè mú èrò pé òun kò já mọ́ nǹkan kan kúrò lọ́kàn. Ó fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.”—Mátíù 7:7.
Ọ̀gbẹ́ni Roberto náà rí i pé òun nílò ẹ̀mí Ọlọ́run àmọ́ ìṣòro tiẹ̀ yàtọ̀. Sìgá àti hashish to tún lágbára ju igbó lọ ti di bárakú fún un. Odindi ọdún méjì gbáko ló fi sapá láti jáwọ́ nínú àṣà yìí, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń pa dà sídìí rẹ̀. Roberto sọ pé: “Ayé máa sú èèyàn tó bá jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Ńṣe lara á máa béèrè fún un lójoojúmọ́.”
Roberto ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àmọ́ mo ti pinnu láti yí ìgbésí ayé mi pa dà kí n bàa lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. Mo gbìyànjú láti fi àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tó wà nínú Bíbélì kún inú ọkàn mi. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbàdúrà tọkàntọkàn sí Ọlọ́run pé kó fún mi lókun kí n lè gbé ìgbésí ayé tó bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu. Mo mọ̀ pé agbára tèmi nìkan kò ká a. Mo sì rí i bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà mi, pàápàá láwọn ìgbà tí ọkàn mi bá gbọgbẹ́ torí bí mo tún ṣe pa dà sí ìwà mi àtijọ́. Mo gbà pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló sọ okun mi dọ̀tun, tí kì í bá ṣe ti ẹ̀mí yìí ni kò ní lè ṣeé ṣe fún mi láti borí àṣà tó ti di bárakú fún mi yìí.”—Fílípì 4:6-8.
Fífi “Ìyẹ́ Apá Ròkè Bí Idì”
Bíi ti Isabel àti Roberto, ọ̀kẹ́ àìmọye Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti rọ́wọ́ agbára ẹ̀mí mímọ́ nígbèésí ayé wọn. Tó o bá fẹ́, ìwọ́ náà lè rọ́wọ́ ipa agbékánkánṣiṣẹ́ Jèhófà, ìyẹn agbára tó lò nígbà tó ń ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, nígbèésí ayé rẹ. Ọlọ́run ṣe tán, ó sì wù ú láti fún ẹ ní ẹ̀mí rẹ̀ tó o bá fi tọkàntọkàn béèrè fún un. Àmọ́, kó o tó lè rí ẹ̀mí yìí gbà, ó yẹ kó o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, kó o sì fi tọkàntọkàn sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Aísáyà 55:6; Hébérù 11:6.
Tó o bá wà lábẹ́ agbára ẹ̀mí mímọ́, á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti gba okun tó máa jẹ́ kó o lè sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, kó o sì lè kojú ìṣòro èyíkéyìí nígbèésí ayé rẹ. Ohun tí Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú ni pé: “[Jèhófà] ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga. . . . Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”—Aísáyà 40:28-31.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
‘Ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbàdúrà tọkàntọkàn sí Ọlọ́run pé kó fún mi lókun. Mo mọ̀ pé agbára tèmi nìkan kò ká a. Mo sì rí i bó ṣe dáhùn àdúrà mi’
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
ÀWỌN IṢẸ́ TÍ ỌLỌ́RUN FI Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ ṢE
Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ láti ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun tó wà láyé àti ọ̀run. Onísáàmù náà sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ. Bí ìwọ bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a óò dá wọn.” —Sáàmù 104:24, 30; Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Jóòbù 33:4.
Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ darí àwọn tó kọ Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.” (2 Tímótì 3:16) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “Ọlọ́run mí sí” ní tààràtà túmọ̀ sí “Ọlọ́run mí èémí rẹ̀ sí.” Èémí Jèhófà tàbí ẹ̀mí rẹ̀ darí èrò inú àwọn tó kọ Bíbélì, ìyẹn sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti kọ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” fún wa. —1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ darí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú lọ́nà tó pé pérépéré. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé: “Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ó jáde wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí. Nítorí a kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 Pétérù 1:20, 21; Jóẹ́lì 2:28.
Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ ran Jésù àti àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Jésù sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, ó rán mi jáde láti wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú.”—Lúùkù 4:18; Mátíù 12:28.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ÀWỌN Ọ̀NÀ TÍ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ LÈ GBÀ RÀN WÁ LỌ́WỌ́
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè fún ẹ lókun tó máa jẹ́ kó o lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tó ń pani lára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè jẹ́ kó o ní àwọn ànímọ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn. Bíbélì sọ pé: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè fún ẹ lágbára tó o máa fi kojú ìdẹwò. Bíbélì sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.