Ohun Tá A Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù
Nípa Ìgbésí Ayé Ìdílé
Irú èrò wo nípa ìgbéyàwó ló lè mú kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀?
Ohun mímọ́ tó ń so tọkọtaya pọ̀ ni ìgbéyàwó jẹ́. Nígbà tí àwọn èèyàn bi Jésù bóyá Ọlọ́run fọwọ́ sí ìkọ̀sílẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀. . . . Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 19:4-6, 9) Nígbà tí tọkọtaya bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ni ọkàn wọn máa balẹ̀ tí wọ́n á sì máa láyọ̀.
Kí nìdí tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi máa ń jẹ́ kí ìdílé láyọ̀?
Jésù sọ pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.” Kí ni àṣẹ kejì tó tóbi jù? Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ [títí kan àwọn tí wọ́n sún mọ́ ẹ jù lọ, ìyẹn ìdílé rẹ] gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:37-39) Torí náà, ohun tó lè mú kí ìdílé láyọ̀ ni pé kí èèyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, torí pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run máa ń mú kí èèyàn nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì.
Báwo ni tọkọtaya ṣe lè máa mú inú ara wọn dùn?
Àwọn ọkọ máa mú inú àwọn aya wọn dùn tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ó kú ikú ìrúbọ torí ìfẹ́ tó ní sí aya rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ìjọ Ọlọ́run. (Éfésù 5:25) Jésù sọ pé: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́.” (Mátíù 20:28) Jésù kò fìgbà kan rí jẹ́ apàṣẹwàá tàbí kó máa hùwà òǹrorò sí àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ara máa ń tù wọ́n lọ́dọ̀ rẹ̀. (Mátíù 11:28) Nítorí náà, àwọn ọkọ ní láti máa lo àṣẹ tí wọ́n ní lọ́nà tó máa ṣe gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé ní àǹfààní.
Àwọn aya náà lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Jésù. Bíbélì sọ pé: “Orí Kristi ni Ọlọ́run.” Ó tún sọ pé, “orí obìnrin ni ọkùnrin.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Jésù kò ronú pé òun ti ga ju ẹni tó yẹ kó wà lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run. Ó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Baba rẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:29) Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí aya kan ní fún Ọlọ́run ló mú kó máa tẹrí ba fún àṣẹ ọkọ rẹ̀, iṣẹ́ kékeré kọ́ ló ń ṣe láti fi kún ayọ̀ ìdílé rẹ̀.
Kí ni àwọn òbí lè rí kọ́ nípa ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọdé?
Jésù máa ń wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé, ohun tí wọ́n ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn sì jẹ ẹ́ lógún gan-an ni. Bíbélì sọ pé: “Jésù pe àwọn ọmọ kéékèèké náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó wí pé: ‘Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi.’” (Lúùkù 18:15, 16) Lọ́jọ́ kan, àwọ́n èèyàn jágbe mọ́ àwọn ọmọkùnrin kan tí wọ́n ń sọ nípa ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jésù. Àmọ́, Jésù gbóríyìn fún àwọn ọmọ náà, ó sì sọ fún àwọn tó ń jágbe mọ́ wọn pé: “Ṣé ẹ kò tíì ka èyí rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde’?”—Mátíù 21:15, 16.
Kí ni àwọn ọmọdé lè rí kọ́ lára Jésù?
Jésù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọmọdé nípa bí wọ́n ṣe lè nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n rí i “nínú tẹ́ńpìlì, ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó sì ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.” Kí ni àbájáde rẹ̀? “Gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” (Lúùkù 2:42, 46, 47) Síbẹ̀, ìmọ̀ tí Jésù ní kò mú kó máa gbéra ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló mú kó bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.”—Lúùkù 2:51.
Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, ka orí 14 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.