Ẹ̀yin Ọkùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Tẹrí Ba Fún Ipò Orí Kristi?
“Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi.”—1 KỌ́R. 11:3.
1. Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run ètò ni Jèhófà?
ÌWÉ Ìṣípayá 4:11 sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Torí pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá, òun ni Ọba Aláṣẹ Gíga Jù Lọ láyé àti lọ́run, ó sì ní àṣẹ lórí gbogbo ohun tó dá. A lè rí i nínú ọ̀nà tí Jèhófà gba ṣètò àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́rùn pé “kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.”—1 Kọ́r. 14:33; Aísá. 6:1-3; Héb. 12:22, 23.
2, 3. (a) Ta ni Jèhófà kọ́kọ́ dá? (b) Ipò wo ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run wà sí Baba rẹ̀?
2 Kó tó di pé Ọlọ́run dá ohunkóhun, Òun fúnra rẹ̀ ti wà fún àìmọye ọdún. Ẹ̀dá ẹ̀mí tó kọ́kọ́ dá la wá mọ̀ sí “Ọ̀rọ̀ náà” torí pé òun ni Agbọ̀rọ̀sọ fún Jèhófà. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ náà ni Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá gbogbo ohun yòókù tó dá. Nígbà tó ṣe, Ọ̀rọ̀ yìí wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé ó sì di ẹni tá a mọ̀ sí Jésù Kristi.—Ka Jòhánù 1:1-3, 14.
3 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa ipò tí Ọlọ́run àti àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ yìí wà síra wọn? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé lábẹ́ ìmísí, ó sọ fún wa pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 11:3) Kristi wà lábẹ́ ipò orí Baba rẹ̀. Èyí sì fi hàn pé ipò orí àti ìtẹríba ṣe pàtàkì kí àlàáfíà lè jọba láàárín àwọn ẹ̀dá olóye tí Ọlọ́run dá kí ohun gbogbo sì máa lọ déédéé. Kódà, a rétí pé kí ẹni tí Ọlọ́run tipasẹ̀ rẹ̀ “dá gbogbo ohun mìíràn” máa tẹrí ba fún ipò orí Ọlọ́run.—Kól. 1:16.
4, 5. Ojú wo ni Jésù fi wo ipò tó wà sí Jèhófà?
4 Báwo ló ṣe rí lára Jésù láti wá sáyé kó sì tipa bẹ́ẹ̀ tẹrí ba fún ipò orí Jèhófà? Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Kristi Jésù pẹ̀lú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.”—Fílí. 2:5-8.
5 Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń fìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ohun tí Baba rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí. Ó sọ pé: “Èmi kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara mi; . . . òdodo sì ni ìdájọ́ tí mo ń ṣe, nítorí pé kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mo ń wá, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòh. 5:30) Ó polongo pé: ‘Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wu Baba mi.’ (Jòh. 8:29) Ní apá ìparí ìwàláàyè Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ nínú àdúrà sí Baba rẹ̀ pé: “Mo ti yìn ọ́ lógo ní ilẹ̀ ayé, ní píparí iṣẹ́ tí ìwọ ti fún mi láti ṣe.” (Jòh. 17:4) Ó dájú pé kò ṣòro fún Jésù láti mọ̀ pé Ọlọ́run ni orí òun, kò sì nira fún un láti gbà bẹ́ẹ̀.
Ọmọ Jàǹfààní Látinú Bó Ṣe Ń Tẹrí Ba fún Baba Rẹ̀
6. Àwọn ànímọ́ fífani mọ́ra wo ni Jésù fi hàn?
6 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi ọ̀pọ̀ ànímọ́ tó jẹ́ àgbàyanu hàn. Lára wọn ni ìfẹ́ ńláǹlà tó ní sí Baba rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòh. 14:31) Ó tún fi ìfẹ́ ńláǹlà hàn fún àwọn èèyàn. (Ka Mátíù 22:35-40.) Jésù jẹ́ onínúure àti olùgbatẹnirò, kì í dáni lágara kì í sì í jẹ gàba léni lórí. Ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, . . . èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Àwọn èèyàn bí àgùntàn, tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, pàápàá jù lọ àwọn wọnnì tá a tẹ̀ lórí ba tá a sì ń ni lára, máa ń rí ìtùnú lọ́dọ̀ Jésù torí pé ó ní ànímọ́ tó fani mọ́ra, ìwàásù rẹ̀ sì máa ń gbé wọn ró.
7, 8. Kí ni Òfin sọ pé obìnrin tó bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ kò gbọ́dọ̀ ṣe, àmọ́ báwo ni Jésù ṣe hùwà sí obìnrin kan tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀?
7 Ṣàgbéyẹ̀wò bí Jésù ṣe hùwà sáwọn obìnrin. Ọjọ́ ti pẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin ti ń hùwà tí kò dára sí àwọn obìnrin. Bí àwọn aṣáájú ìsìn sì ṣe ń ṣe ní Ísírẹ́lì ìgbàanì náà nìyẹn. Àmọ́, Jésù máa ń fọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀nà tó gbà hùwà sí obìnrin kan tó ti ní àìsàn ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá. “Ọ̀pọ̀ oníṣègùn . . . ti mú ọ̀pọ̀ ìrora bá a,” ó sì ti ná gbogbo owó rẹ̀ níbi tó ti ń gbìyànjú láti rí ìwòsàn. Pẹ̀lú gbogbo ipá tó sà yìí, ńṣe ni àìsàn náà ń “burú sí i.” Aláìmọ́ ni wọ́n kà á sí lábẹ́ Òfin. Ẹnikẹ́ni tó bá sì fọwọ́ kàn án á di aláìmọ́.—Léf. 15:19, 25.
8 Nígbà tí obìnrin náà gbọ́ pé Jésù ń wo àwọn aláìsàn sàn, ó dara pọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó yí i ká, ó ń sọ pé: “Bí mo bá fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi yóò dá.” Ó fọwọ́ kan Jésù, ara rẹ̀ sì yá lọ́gán. Jésù mọ̀ pé kò yẹ kó fọwọ́ kan aṣọ òun. Síbẹ̀ náà, kò fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi inú rere hàn sí i. Ó lóye bí ọ̀ràn á ṣe rí lára rẹ̀ ní gbogbo ọdún tó fi ń ṣàìsàn, ó sì fi òye mọ̀ pé ó nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì. Jésù wá fi ìyọ́nú sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera.”—Máàkù 5:25-34.
9. Kí ni Jésù ṣe nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ rẹ̀?
9 Ara máa ń tu àwọn ọmọdé pàápàá nígbà tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ Jésù. Nígbà kan tí àwọn èèyàn mú àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá wọn wí gidigidi, torí wọ́n lérò pé Jésù kò ní fẹ́ káwọn ọmọdé dí òun lọ́wọ́. Àmọ́, Jésù ò rí wọn bí ìdíwọ́. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Ní rírí èyí, ìkannú Jésù ru, ó sì wí fún [àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀] pé: ‘Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.’” Yàtọ̀ síyẹn, ó “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” Kì í ṣe pé Jésù fàyè gba àwọn ọmọdé nìkan ni, ó tún fi ọ̀yàyà gbá wọn mọ́ra.—Máàkù 10:13-16.
10. Báwo ni Jésù ṣe ní àwọn ànímọ́ tó fi ṣèwà hù?
10 Báwo ni Jésù ṣe ní àwọn ànímọ́ tó fi ṣèwà hù nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? Kí Jésù tó wá sáyé, ó ti fara balẹ̀ kíyè sí Baba rẹ̀ ọ̀run fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún, ó sì ti kọ́ bó ṣe máa ń ṣe nǹkan. (Ka Òwe 8:22, 23, 30.) Ní ọ̀run, ó ti rí bí Jèhófà ṣe máa ń fi ìfẹ́ lo ipò orí rẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀dá tó dá, òun náà sì ti kọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ká ní Jésù ò ní ìtẹríba ni, ǹjẹ́ ó máa ṣeé ṣe fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdùnnú ló jẹ́ fún un láti máa tẹrí ba fún Baba rẹ̀, ó sì dún mọ́ Jèhófà náà nínú láti ní irú Ọmọ bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi àwọn àgbàyanu ànímọ́ tí Baba rẹ̀ ní ṣèwà hù lọ́nà pípé. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún àwa náà láti máa tẹrí ba fún Kristi, ẹni tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ Alákòóso Ìjọba ọ̀run!
Máa Fi Àwọn Ànímọ́ Kristi Ṣèwà Hù
11. (a) Àpẹẹrẹ ta ló yẹ ká ṣiṣẹ́ kára láti máa tẹ̀ lé? (b) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ máa sapá gidigidi láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
11 Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni, pàápàá jù lọ àwọn ọkùnrin, gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ kára láti máa fi àwọn ànímọ́ Kristi ṣèwà hù. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi.” Bí Kristi ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run òtítọ́, tó jẹ́ Orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ làwọn arákùnrin ṣe gbọ́dọ̀ máa sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, tó jẹ́ orí wọn. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gan-an nìyẹn nígbà tó di Kristẹni. Ó gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni níyànjú pé, “ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́r. 11:1) Àpọ́sítélì Pétérù sì sọ pé: “Ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pét. 2:21) Ìdí mìíràn kan tún wà tó fi yẹ kí àwọn ọkùnrin tó fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó sọ pé kí wọ́n máa ṣe àfarawé Kristi. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ló máa ń di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà. Bí títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ṣe ń mú kí Jésù láyọ̀, ó yẹ káwọn arákùnrin náà máa láyọ̀ torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, wọ́n sì ń fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù.
12, 13. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn alàgbà máa ṣe sí àwọn àgùntàn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn?
12 Àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ Kristẹni láti gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe lè fìwà jọ Kristi. Pétérù gba àwọn àgbà ọkùnrin, tàbí àwọn alàgbà, níyànjú pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:1-3) Àwọn alàgbà inú ìjọ Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apàṣẹwàá, ẹni tó ń jẹ gàba léni lórí, aṣetinú-ẹni, tàbí ẹni tó le koko. Bí àwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, wọ́n á sapá láti jẹ́ onífẹ̀ẹ́, agbatẹnirò, onírẹ̀lẹ̀ àti onínúure nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn àgùntàn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn lò.
13 Aláìpé ni àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ, ó sì yẹ kí wọ́n máa rántí ibi tí agbára wọ́n mọ nígbà gbogbo. (Róòmù 3:23) Torí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù kí ìfẹ́ tó ní sì jẹ́ àwòkọ́ṣe fún wọn. Ó yẹ kí wọ́n ṣe àṣàrò lórí bí Ọlọ́run àti Kristi ṣe máa ń bá àwọn èèyàn lò kí wọ́n sì sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Pétérù gbà wá níyànjú pé: “Gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Pét. 5:5.
14. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn alàgbà máa bu ọlá fún àwọn míì tó?
14 Ó yẹ kí àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò nínú ìjọ máa fi àwọn ànímọ́ rere hàn nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bá agbo Ọlọ́run lò. Ìwé Róòmù 12:10 sọ pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” Àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń bu ọlá fun ara wọn. Bíi tàwọn yòókù tó wà nínú ìjọ, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kò gbọ́dọ̀ máa ‘ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wọ́n lọ.’ (Fílí. 2:3) Ńṣe ló yẹ kí àwọn tó ń mú ipò iwájú máa wo àwọn mìíràn bí ẹni tó lọ́lá jù wọ́n lọ. Nípa ṣíṣe báyìí, àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò á máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun, kí a má sì máa ṣe bí ó ti wù wá. Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.”—Róòmù 15:1-3.
Ẹ ‘Máa Fi Ọlá fún Àwọn Aya’
15. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ọkọ máa ṣe sí àwọn aya wọn?
15 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé ìmọ̀ràn tí Pétérù fún àwọn ọkọ yẹ̀ wò. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá [àwọn aya yín] gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Pét. 3:7) Fífi ọlá fún ẹnì kan túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ọ̀wọ̀ tó ga fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Èyí tó túmọ̀ sí pé èèyàn á máa gba èrò onítọ̀hún rò, èèyàn á mọ ohun tó ṣaláìní, èèyàn á sì fẹ́ láti gbà pẹ̀lú rẹ̀ bí kò bá sí ìdí pàtàkì kan téèyàn fi ní láti ṣe ohun tó yàtọ̀. Bó ṣe yẹ kí ọkọ máa ṣe sí aya rẹ̀ nìyẹn.
16. Ìkìlọ̀ wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ọkọ nípa bíbu ọlá fún àwọn aya wọn?
16 Nígbà tí Pétérù ń sọ fún àwọn ọkọ pé kí wọ́n máa bu ọlá fún àwọn aya wọn, ó fi ìkìlọ̀ kan kún un pé: “Kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.” (1 Pét. 3:7) Lọ́nà tó ṣe kedere, ìyẹn tún jẹ́ ká rí i pé ojú pàtàkì ni Jèhófà fi ń wo ọ̀nà tí ọkùnrin kan ń gbà hùwà sí aya rẹ̀. Bó bá kùnà láti bu ọlá fún un, ó lè mú kí àdúrà rẹ̀ ní ìdènà. Ọ̀pọ̀ aya ló sì máa ń ṣe ojúṣe wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ bí àwọn ọkọ wọn bá ń bu ọlá fún wọn.
17. Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ tó?
17 Ní ti pé kí ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn ọkọ níyànjú pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. . . . Nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ . . . Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.” (Éfé. 5:28, 29, 33) Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn tó? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfé. 5:25) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọkọ kan gbọ́dọ̀ múra tán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ fún aya rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe fún àwọn ẹlòmíì. Bí Kristẹni tó jẹ́ ọkọ bá ń hùwà sí aya rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, lọ́nà tó fi ìgbatẹnirò hàn, tó ń tẹ́tí sí i, tí kò sì mọ ti ara rẹ̀ nìkan, ó máa rọrùn fún aya rẹ̀ láti tẹrí bá fún ipò orí rẹ̀.
18. Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn ọkùnrin lè rí gbà láti bójú tó ojúṣe wọn nínú ìgbéyàwó?
18 Ṣé ó ti pọ̀ jù láti retí pé kí àwọn ọkọ máa bu ọlá fún aya wọn lọ́nà yìí? Rárá o, Jèhófà ò jẹ́ retí pé kí àwọn ọkọ ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ. Ó ṣe tán, àwọn olùjọsìn Jèhófà lè béèrè fún agbára tó ga jù lọ láyé àtọ̀run, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Torí náà, nígbà tí àwọn ọkọ bá ń gbàdúrà, wọ́n lè béèrè pé kí Jèhófà fi ẹ̀mí rẹ̀ ran àwọn lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀nà tí àwọn ń gbà hùwà sí àwọn ẹlòmíì, tó fi mọ́ àwọn aya wọn, sunwọ̀n sí i.—Ka Ìṣe 5:32.
19. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
19 Dájúdájú, iṣẹ́ ńlá ló já lé àwọn ọkùnrin léjìká láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa tẹrí bá fún Kristi kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa lo ipò orí wọn. Àwọn obìnrin wá ńkọ́, pàápàá jù lọ àwọn ìyàwó ilé? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa jíròrò ojú tó yẹ kí wọ́n máa fi wo ojúṣe wọn nínú ìṣètò Jèhófà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn ànímọ́ Jésù wo ló yẹ ká máa tẹ̀ lé?
• Ọwọ́ wo ló yẹ kí àwọn alàgbà máa fi mú àwọn àgùntàn?
• Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa ṣe sí aya rẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa bíbu ọlá fún àwọn ẹlòmíì