Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Fáwọn Èèyàn Láti Mọ Orúkọ Ọlọ́run
ẸNÌ kan wà tí kò fẹ́ kó o mọ ẹni tó ń jẹ́ Jèhófà, kò sì fẹ́ kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Ta ni ọ̀tá burúkú yìí? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.” Sátánì Èṣù ni ọlọ́run ayé tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run yìí. Ó fẹ́ fi ẹ́ sínú òkùnkùn kí “ìmọ̀ ológo nípa Ọlọ́run,” má bàa wọnú ọkàn rẹ. Sátánì kò fẹ́ kó o mọ ẹni tó ń jẹ́ Jèhófà. Àmọ́, báwo ni Sátánì ṣe ń fọ́ ojú inú àwọn èèyàn?—2 Kọ́ríńtì 4:4-6.
Sátánì ti lo ìsìn èké láti mú kó ṣòro fún àwọn èèyàn láti mọ orúkọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Júù kan láyé àtijọ́ pa Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí tì, wọ́n wá ń tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kan tí kò fàyè gba lílo orúkọ Ọlọ́run. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ó jọ pé wọ́n ti sọ fún àwọn Júù tí wọ́n máa ń kàwé ní gbangba pé wọn ò gbọ́dọ̀ ka orúkọ Ọlọ́run jáde bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ wọn mọ́, dípò ìyẹn, kí wọ́n máa lo Adho·naiʹ, tó túmọ̀ sí “Olúwa.” Kò sí àní-àní pé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yìí ṣàkóbá ńlá fún àwọn èèyàn tí wọn kò fi ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ni kò jàǹfààní tó wà nínú àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ Jésù ńkọ́? Kí ni èrò rẹ̀ nípa orúkọ náà, Jèhófà?
Jésù Àtàwọn Ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ Orúkọ Ọlọ́run
Jésù sọ gbangba nínú àdúrà sí Bàbá rẹ̀ pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ . . . ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀.” (Jòhánù 17:26) Kò sí iyè méjì pé Jésù pe orúkọ Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tó kàwé, tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tó ní orúkọ pàtàkì yẹn tàbí nígbà tó ṣàlàyé àwọn apá ibì kan nínú rẹ̀. Èyí fi hàn pé Jésù ti ní láti lo orúkọ Ọlọ́run ní fàlàlà bí àwọn wòlíì tó ṣáájú rẹ̀ ṣe lò ó. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn Júù kan ti pa lílo orúkọ Ọlọ́run tì nígbà tí Jésù ń wàásù, ó dájú pé Jésù kò jẹ́ tẹ̀ lé irú àṣà bẹ́ẹ̀. Ó ta ko àwọn aṣáájú ìsìn nígbà tó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín.”—Mátíù 15:6.
Àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì ń bá a nìṣó láti máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù. (Wo àpótí náà, “Ǹjẹ́ Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Lo Orúkọ Ọlọ́run?”) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn lọ́jọ́ tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, ó sọ fún ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n jẹ́ Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Ìṣe 2:21; Jóẹ́lì 2:32) Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ran ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ẹni tó ń jẹ́ Jèhófà. Nítorí ìdí yìí, nínú ìpàdé kan táwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù ṣe, ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù sọ pé: “Ọlọ́run ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè . . . láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.”—Ìṣe 15:14.
Àmọ́, àwọn ọ̀tá orúkọ Ọlọ́run kò sinmi. Ní gbàrà tí àwọn àpọ́sítélì ti kú tán, Sátánì kò jáfara láti mú kí ìpẹ̀yìndà gbilẹ̀. (Mátíù 13:38, 39; 2 Pétérù 2:1) Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bí àkókò kan náà tí Jòhánù ẹni tó jẹ́ àpọ́sítélì tó kẹ́yìn kú ni wọ́n bí ọ̀gbẹ́ni Justin Martyr tó sọ pé òun ń kọ̀wé nípa ẹ̀sìn Kristẹni. Síbẹ̀, Justin sọ ọ́ lásọtúnsọ nínú àwọn ìwé rẹ̀ pé, Olùpèsè ohun gbogbo ni “Ọlọ́run tí a kò fi orúkọ pàtó kan pè.”
Nígbà táwọn Kristẹni apẹ̀yìndà ṣe ẹ̀dá Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó hàn gbangba pé wọ́n yọ Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú rẹ̀ tí wọ́n sì fi Kyʹri·os, ìyẹn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀. Ohun kan náà ló sì ṣẹlẹ̀ sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Wọn ò ka orúkọ Ọlọ́run jáde fún àwọn èèyàn mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn Júù apẹ̀yìndà tí wọ́n jẹ́ akọ̀wé òfin fi Adho·naiʹ rọ́pò orúkọ Ọlọ́run ní ohun tó lé ní àádóje [130] ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ wọn. Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Látìn tó gbayì gan-an, èyí tí ọ̀gbẹ́ni Jerome ṣe parí ní ọdún 405 Sànmánì Kristẹni tí wọ́n wá ń pè ní Vulgate náà yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò.
Bí Wọ́n Ṣe Fẹ́ Yọ Orúkọ Ọlọ́run Kúrò Lóde Òní
Lóde òní, àwọn ọ̀mọ̀wé mọ̀ pé orúkọ náà, Jèhófà fara hàn nínú Bíbélì ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000]. Torí náà, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan wà táwọn Kátólíìkì ṣe, táwọn èèyàn sì ń lò dáadáa, irú bíi Jerusalem Bible, La Biblia Latinoamérica ní èdè Sípáníìṣì àti ẹ̀dà Reina Valera tó gbajúmọ̀ gan-an tóun náà jẹ́ ní èdè Sípáníìṣì. Fàlàlà ni àwọn Bíbélì wọ̀nyẹn lo orúkọ Ọlọ́run. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan pe orúkọ Ọlọ́run ní “Yáwè.”
Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì tó ṣètìlẹ́yìn fún ìtumọ̀ Bíbélì ń fúngun mọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé pé kí wọ́n yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà June 29, 2008, tí àwọn aláṣẹ Vatican kọ sí àwọn ààrẹ àpérò àwọn bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì, wọ́n sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn ti ń dọ́gbọ́n mú àṣà pípe orúkọ tí Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jẹ́ gangan wọlé.” Wọ́n pa àṣẹ tó ṣe ṣàkó yìí nínú lẹ́tà náà pé: “Orúkọ Ọlọ́run . . . kò yẹ láti lò ó tàbí pè é.” Síwájú sí i, “nínú ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe ní èdè òde òní, . . . Adonai tàbí Kyrios tó túmọ̀ sí ‘Olúwa’ ni kó rọ́pò lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run.” Ó ṣe kedere wàyí pé àṣẹ táwọn aláṣẹ Vatican pa yìí jẹ́ láti mú káwọn èèyàn má lo orúkọ Ọlọ́run mọ́.
Àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì pàápàá kò bọ̀wọ̀ fún orúkọ náà, Jèhófà. Agbẹnusọ fún ìtumọ̀ Bíbélì New International Version, tí àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1978, kọ̀wé pé: “Jèhófà ni orúkọ tó mú kí Ọlọ́run yàtọ̀, òun gan-an ló yẹ ká ti lò. Àmọ́, ká ní bí àpẹẹrẹ, a túmọ̀ Sáàmù 23 sí, ‘Yáwè ni olùṣọ́ àgùntàn mi’ ni, ohun tó lé ní mílíọ̀nù méjì owó dọ́là tá a ná sórí ìtumọ̀ yìí ì bá ṣòfò dà nù.”
Síwájú sí i, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kò jẹ́ káwọn èèyàn Látìn Amẹ́ríkà mọ orúkọ Ọlọ́run. Ọ̀gbẹ́ni Steven Voth, tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn fún àwọn atúmọ̀ èdè ẹgbẹ́ United Bible Societies, kọ̀wé pé: “Orí lílo orúkọ náà, Jehová ni ọ̀kan lára ìjíròrò tó ń lọ lọ́wọ́ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ní Látìn Amẹ́ríkà dá lé . . . Ó yani lẹ́nu pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì pentecostal ìgbàlódé tí wọ́n ń pọ̀ sí i . . . ló sọ pé àwọn fẹ́ ẹ̀dà Bíbélì Reina-Valera tí wọ́n ṣe lọ́dún 1960, àmọ́ kó má ṣe ní orúkọ náà, Jehová. Dípò ìyẹn, wọ́n fẹ́ ọ̀rọ̀ náà Señor [Olúwa].” Ọ̀gbẹ́ni Voth, sọ pé ẹgbẹ́ United Bible Societies kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí ohun tí wọ́n fẹ́ yìí, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n gbà, wọ́n sì tẹ ẹ̀dà Bíbélì Reina-Valera jáde “láì sí orúkọ náà, Jehová nínú rẹ̀.”
Bí wọ́n ṣe yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì wá fi “Olúwa” rọ́pò rẹ̀ yìí mú kó ṣòro fún àwọn èèyàn láti mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Àyípadà yìí ti fa ìdàrúdàpọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, òǹkàwé lè má mọ̀ bóyá Jèhófà tàbí Jésù Ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ń tọ́ka sí nígbà tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ náà, “Olúwa.” Nínú Ìwé Mímọ́ lápá ibi tí àpọ́sítélì Pétérù ti fa ọ̀rọ̀ Dáfídì yọ pé: “Jèhófà sọ fún Olúwa mi [Jésù tó ti jíǹde] pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,’” ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló túmọ̀ rẹ̀ sí: “OLUWA wi fun Oluwa mi pe.” (Ìṣe 2:34, Bibeli Mimọ) Síwájú sí i, nínú àròkọ kan tí Ọ̀gbẹ́ni David Clines kọ, tó pe àkòrí rẹ̀ ní “Yáwè àti Ọlọ́run àwọn Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni,” ó sọ pé: “Ọ̀kan lára ìdí tó mú káwọn Kristẹni gbọ́kàn kúrò lára lílo Yáwè ni láti kó àfiyèsí wọn sórí ẹni tí Kristi jẹ́.” Èyí wá mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láti mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ ẹni tí Jésù gbàdúrà sí jẹ́ Ẹni gidi tó ní orúkọ kan, ìyẹn Jèhófà.
Sátánì ti sapá gan-an láti fọ́ ojú inú àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Láìka gbogbo ìyẹn sí, o ṣì lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́.
O Lè Mọ Ẹni Tí Jèhófà Jẹ́
Ó dájú pé Sátánì ti gbógun ti orúkọ Ọlọ́run, ó sì ti lo ìsìn èké gan-an fún ètekéte yìí. Àmọ́, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí alágbára kankan lọ́run tàbí láyé tó lè dá Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ dúró pé kó má ṣe sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ àtàwọn ìlérí ológo tó ṣe fún àwọn olóòótọ́ èèyàn.
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípa bó o ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó sọ fún Ọlọ́run pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn.” (Jòhánù 17:26) Bó o ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa onírúurú nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún àǹfààní aráyé, wàá wá mọ ọ̀pọ̀ ànímọ́ rẹ̀ tó ta yọ.
Jóòbù bàbá ńlá ìgbàanì ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run,” ìwọ náà lè ní in. (Jóòbù 29:4) Ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á jẹ́ kó o mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Irú ìmọ̀ yìí á fún ẹ ní ìdánilójú pé Jèhófà máa gbé ìgbésẹ̀ tó bá ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ mu, ìyẹn ‘Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ.’ (Ẹ́kísódù 3:14) Ó sì dájú pé, á tipa bẹ́ẹ̀ mú ìlérí rere tó ṣe fún aráyé ṣẹ.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ǹjẹ́ Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Lo Orúkọ Ọlọ́run?
Lákòókò àwọn àpọ́sítélì Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, wọ́n dá ọ̀pọ̀ ìjọ Kristẹni sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àwọn ará ìjọ yìí máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Ṣé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yìí rí orúkọ náà, Jèhófà, nínú Ìwé Mímọ́ wọn?
Nítorí pé èdè Gíríìkì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ lórílẹ̀-èdè púpọ̀ nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ ìjọ ló ń lo ìtumọ̀ Gíríìkì Septuagint, èyí tí wọ́n túmọ̀ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n sì parí ìtumọ̀ rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, látìgbà tí wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì Septuagint ni wọ́n ti fi orúkọ oyè náà Kyʹri·os, tó jẹ́ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé kò rí bẹ́ẹ̀.
Àwọn àjákù ìwé tí àwòrán rẹ̀ wà níbí jẹ́ ara ìtumọ̀ Septuagint tó jẹ́ èdè Gíríìkì, tí wọ́n kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Kedere ni wọ́n fi orúkọ náà, Jèhófà, hàn, wọ́n kọ lẹ́tà Hébérù mẹ́rin náà יהוה (YHWH), ní èdè Hébérù sínú ìtumọ̀ Gíríìkì. Ọ̀jọ̀gbọ́n George Howard kọ̀wé pé: “A ní oríṣiríṣi ẹ̀dà Bíbélì Septuagint mẹ́ta ti èdè Gíríìkì tó wà ṣáájú ìgbà àwọn Kristẹni, kò sí ibì kankan nínú wọn tí wọ́n ti túmọ̀ lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run sí kyrios tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ túmọ̀ rẹ̀ rárá kúrò ní èdè Hébérù. A lè fi ìdánilójú sọ pé, àṣà àwọn Júù ló jẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó kọ Májẹ̀mú Tuntun àti nígbà tí wọ́n ń kọ ọ́ àti lẹ́yìn tí wọ́n kọ ọ́ tán láti máa kọ orúkọ Ọlọ́run ní èdè Hébérù . . . ní tààràtà sínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì.”—Biblical Archaeology Review.
Ǹjẹ́ àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí wọn láti kọ? Ọ̀jọ̀gbọ́n Howard kíyè sí i pé: “Nígbà tí ìjọ tí Májẹ̀mú Tuntun sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lo Bíbélì Septuagint tí wọ́n sì ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Hébérù tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run, kò sí àní-àní pé àwọn tó kọ Májẹ̀mú Tuntun máa fi lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run sínú ọ̀rọ̀ wọn nìyẹn.”
Nígbà náà, a lè fi ìdánilójú sọ pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ máa ka orúkọ Ọlọ́run nínú ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó wà lọ́wọ́ wọn.
[Credit Line]
Gbogbo àwòrán wá látọwọ́: Société Royale de Papyrologie du Caire
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Apá kan ìwé Aísáyà tó wà nínú àkájọ Ìwé Òkun Òkú, tí a ti sàmì sí ibi tí orúkọ Ọlọ́run wà
[Credit Line]
Shrine of the Book, Photo © The Israel Museum, Jerusalem
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù tàbí nítorí èrè àbòsí pàápàá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa jíjẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run