Jẹ́ Kí “Òfin Inú-rere-onífẹ̀ẹ́” Máa Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ahọ́n Rẹ
“Ó fi ọgbọ́n la ẹnu rẹ̀, òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ń bẹ ní ahọ́n rẹ̀.”—ÒWE 31:26.
1, 2. (a) Ànímọ́ wo la rọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti ní? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
OHUN téèyàn fi ń mọ aya rere lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ wà lára àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Lémúẹ́lì Ọba kan láyé ìgbàanì gbọ́ látẹnu ìyá rẹ̀. Ìyá ọba yìí sọ fún un pé: “Ó fi ọgbọ́n la ẹnu rẹ̀, òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ń bẹ ní ahọ́n rẹ̀.” (Òwe 31:1, 10, 26) Ó yẹ kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ máa wà lórí ahọ́n obìnrin tó bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti gbogbo èèyàn tó bá ń fẹ́ máa ṣe ohun tí inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sí. (Ka Òwe 19:22.) Ó yẹ kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ máa hàn nínú ọ̀rọ̀ tí gbogbo olùjọ́sìn tòótọ́ bá ń sọ.
2 Kí ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́? Àwọn wo ló yẹ ká máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí? Kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi “òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́” sórí ahọ́n wa? Báwo ló ṣe lè nípa lórí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wa pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìdílé wa àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni?
Ìfẹ́ Ìdúró Ṣinṣin Ló Ń Múni Jẹ́ Onínúure
3, 4. (a) Kí ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́? (b) Báwo ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀ sí inú rere tá à ń fi hàn sí gbogbo èèyàn?
3 Bí ọ̀rọ̀ náà inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe fi hàn, a ó rí i pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ àti inú rere. Ó kan inú rere, ìyẹn ni pé kí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹni lógún, kí èèyàn sì fi hàn nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ àti sísọ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró fún wọn. Níwọ̀n bí ìfẹ́ ti ṣe kókó nínú ọ̀ràn yìí, fífi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn gba pé kí ìfẹ́ mú kí ire àwọn ẹlòmíì máa jẹ wá lógún. Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ kọjá inú rere tí ìfẹ́ súnni ṣe o. Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni inú rere téèyàn dìídì fi òótọ́ inú ṣe sí ẹnì kan títí tí ohun tó mú kéèyàn máa ṣe inú rere náà á fi kẹ́sẹ járí.
4 Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tún yàtọ̀ sí inú rere láwọn ọ̀nà míì. Èèyàn lè ṣe inúure sí ẹnikẹ́ni kódà kó jẹ́ ẹni téèyàn kò mọ̀ rí. Àwọn èèyàn erékùṣù Málítà fi àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá èèyàn hàn sí Pọ́ọ̀lù àtàwọn èèyàn tó jẹ́ igba ó lé márùndínlọ́gọ́rin [275] tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó rì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ̀ wọ́n rí. (Ìṣe 27:37–28:2) Àmọ́, kéèyàn tó lè fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí ẹnì kan, àjọṣe tímọ́tímọ́ ti ní láti wà láàárín ẹni tó ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn àti ẹni tó ń fi hàn sí.a Irú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yìí ni àwọn Kénì fi hàn sí “gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń gòkè bọ̀ láti Íjíbítì.”—1 Sám. 15:6.
Àṣàrò àti Àdúrà Ṣe Pàtàkì
5. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa kó ahọ́n wa níjàánu?
5 Kò rọrùn láti máa sọ ọ̀rọ̀ tó fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn. Nígbà tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn ń sọ̀rọ̀ nípa ahọ́n, ó kọ̀wé pé: “Kò sí ẹnì kan nínú aráyé tí ó lè rọ̀ ọ́ lójú. Ohun ewèlè tí ń ṣeni léṣe, ó kún fún panipani májèlé.” (Ják. 3:8) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa kó ẹ̀yà ara wa tó ṣòro láti darí yìí níjàánu? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ jẹ́ ká lóye ohun tá a lè ṣe. Ó sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tó lè máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ahọ́n wa, a ní láti gbin ànímọ́ yẹn sínú ọkàn-àyà wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí àṣàrò àti àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
6. Kí nìdí tó fi yẹ kí ìmọrírì fún Jèhófà mú ká ṣàṣàrò lórí bó ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn?
6 Bíbélì sọ pé, Jèhófà Ọlọ́run “pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Ẹ́kís. 34:6) Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ti kún ilẹ̀ ayé.” (Sm. 119:64) Ìwé Mímọ́ kún fún onírúurú àkọsílẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀. Bí ìmọrírì fún Ọlọ́run bá mú ká fara balẹ̀ ṣàṣàrò nípa ‘ìbálò Jèhófà,’ ó lè mú kó máa wù wá láti ní ànímọ́ Ọlọ́run yìí.—Ka Sáàmù 77:12.
7, 8. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀? (b) Báwo ló ṣe rí lára Dáfídì nígbà tí Ọlọ́run fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí i?
7 Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí Jèhófà ṣe dá Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ nídè, nígbà tó pa ìlú Sódómù tí wọ́n ń gbé run. Bí àkókò ìparun yẹn ṣe ń sún mọ́lé, àwọn áńgẹ́lì tó wá sọ́dọ̀ Lọ́ọ̀tì rọ̀ ọ́ pé kó mú ìdílé rẹ̀, kí wọ́n sì jáde kúrò ní ìlú yẹn kíákíá. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ó ń lọ́ra ṣáá, nígbà náà, nínú ìyọ́nú Jèhófà lórí rẹ̀, àwọn [áńgẹ́lì] náà gbá ọwọ́ rẹ̀ àti ọwọ́ aya rẹ̀ àti ọwọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì mú, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú un jáde àti láti mú un dúró ní òde ìlú ńlá náà.” Ǹjẹ́ orí wa kì í wú tá a bá ronú nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá àwọn èèyàn yìí nídè, ǹjẹ́ ìyẹn kì í sì í mú ká gbà pé ó jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn?—Jẹ́n. 19:16, 19.
8 Tún gbé àpẹẹrẹ ti Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì yẹ̀ wò, ó kọrin pé: “[Jèhófà] ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì, [ó] ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn.” Dáfídì ti ní láti mọrírì bí Ọlọ́run ṣe dárí jì í nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà! Ó wá gbé Jèhófà ga, ó sọ pé: “Bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Sm. 103:3, 11) Ṣíṣe àṣàrò lórí ìtàn yìí àtàwọn àkọsílẹ̀ míì nínú Ìwé Mímọ́ ń mú kí ọkàn wa túbọ̀ kún fún ìmọrírì fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí sì ń sún wa láti máa yìn ín ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Bí ìmọrírì bá ṣe kúnnú ọkàn wa tó, bẹ́ẹ̀ láá ṣe máa wù wá tó láti di aláfarawé Ọlọ́run tòótọ́.—Éfé. 5:1.
9. Kí ni ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí àwọn olùjọsìn Jèhófà máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́?
9 Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jèhófà máa ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìyẹn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, hàn sí àwọn tó ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́ àwọn tí kò ní irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run alààyè ńkọ́? Ṣé Jèhófà le koko mọ́ wọn, tí kì í sì í fi àánú hàn sí wọn? Rárá o. Lúùkù 6:35, sọ pé: “[Ọlọ́run] jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú.” Bákan náà, ó “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mát. 5:45) Ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tá a sì ń fi ṣèwà hù, à ń jọlá inú rere Ọlọ́run tàbí inú rere tí Ọlọ́run ń fi hàn sí gbogbo èèyàn lápapọ̀. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí olùjọ́sìn rẹ̀, a ti wá ń gbádùn ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ìyẹn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka Aísáyà 54:10.) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa dúpẹ́ gan-an nítorí èyí! Ìdí pàtàkì sì lèyí jẹ́ fún wa láti máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn nínú ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde àti nínú bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa lójoojúmọ́!
10. Báwo ni àdúrà ti ṣe pàtàkì tó láti mú kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ di ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ wa?
10 Ohun pàtàkì kan tó lè mú ká máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn ni àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà. Ìdí èyí ni pé ìfẹ́ àti inú rere, tó para pọ̀ di inú-rere-onífẹ̀ẹ́ jẹ́ ara èso ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. (Gál. 5:22) A lè gbin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sọ́kàn ara wa tá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa. Ọ̀nà tó ṣe tààrà jù lọ láti gba ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ni pé ká béèrè fún un nípasẹ̀ àdúrà. (Lúùkù 11:13) Ó tọ́ ká máa gbàdúrà lemọ́lemọ́ láti tọrọ ẹ̀mí Ọlọ́run, ká sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, àṣàrò àti àdúrà ṣe pàtàkì gan-an tá a bá fẹ́ kí òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wà lórí ahọ́n wa.
Bí Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ṣe Lè Máa Wà Lórí Ahọ́n Àwọn Tọkọtaya
11. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn ọkọ máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn aya wọn? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ lè gbà ran ọkọ lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ahọ́n rẹ̀?
11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ọkọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfé. 5:25) Pọ́ọ̀lù tún rán wọn létí ohun tí Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà. Ó kọ̀wé pé: “Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” (Éfé. 5:31) Ó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn ọkọ máa fi ìṣòtítọ́ bá àwọn aya wọn gbé, kí wọ́n sì máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí wọn ní gbogbo ìgbà. Ọkọ tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ń darí ahọ́n rẹ̀ kì í sọ àṣìṣe aya rẹ̀ kiri fáyé gbọ́, tàbí kó máa sọ̀rọ̀ tó bu aya rẹ̀ kù. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti gbóríyìn fún un. (Òwe 31:28) Tí ohun kan bá fa èdèkòyédè láàárín wọn, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ á mú kí ọkọ máa kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu láti má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tó máa tàbùkù sí aya rẹ̀.
12. Báwo ni ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu aya jáde ṣe lè fi hàn pé òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń darí ahọ́n rẹ̀?
12 Òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ gbọ́dọ̀ máa darí ahọ́n àwọn aya náà. Ẹ̀mí ayé kò gbọ́dọ̀ máa hàn nínú ọ̀rọ̀ tí aya ń sọ jáde lẹ́nu. Níwọ̀n bó ti ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀,” á máa sọ̀rọ̀ tó dáa nípa ọkọ rẹ̀ lójú àwọn ẹlòmíì, á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ọ̀wọ̀ tí wọ́n ti ní fún ọkọ rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i. (Éfé. 5:33) Bí kò ti fẹ́ kí ọ̀wọ̀ tí àwọn ọmọ ní fún bàbá wọn dín kù, á máa ṣọ́ra fún bíbá a jiyàn, tàbí títako èrò rẹ̀ lójú àwọn ọmọ. Ìgbà tó bá ku àwọn méjèèjì nìkan ló máa yanjú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀.” (Òwe 14:1) Ilé rẹ̀ á jẹ́ ibi tó tòrò tó sì tura láti gbé fún ìdílé lápapọ̀.
13. Ibo ló ti ṣe pàtàkì jù lọ kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti gbilẹ̀, báwo ló sì ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?
13 Kódà tó bá ku tọkọtaya nìkan, wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti máa lo ahọ́n wọn lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” Ó fi kún un pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. . . . Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:8, 12-14) Tí àwọn ọmọ bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ àti onínúure, wọ́n á máa ṣe dáadáa, wọ́n á sì tún lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn òbí wọn nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ̀rọ̀.
14. Ọ̀nà wo ni àwọn olórí ìdílé lè gbà lo ahọ́n wọn láti tu àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn nínú?
14 Onísáàmù náà sọ nípa Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ kí ó tù mí nínú.” (Sm. 119:76) Ọ̀nà tó ta yọ tí Jèhófà ń gbà tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú jẹ́ nípa gbígbà wọ́n níyànjú àti títọ́ wọn sọ́nà. (Sm. 119:105) Báwo làwọn olórí ìdílé ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ Baba wa ọ̀run, kí wọ́n sì máa fi ahọ́n wọn tu àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn nínú? Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífún wọn ní ìtọ́sọ́nà àti ìṣírí tí wọ́n nílò. Àǹfààní ńlá gbáà ni Ìjọsìn Ìdílé jẹ́ nínú ṣíṣàwárí àwọn ìṣúra tẹ̀mí!—Òwe 24:4.
Fi Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Hàn sí Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́
15. Báwo làwọn alàgbà àtàwọn míì tó dàgbà nípa tẹ̀mí ṣe lè lo ahọ́n wọn láti dáàbò bo àwọn ará nínú ìjọ?
15 Dáfídì Ọba gbàdúrà pé: “Jẹ́ kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ máa fi ìṣọ́ ṣọ́ mi nígbà gbogbo.” (Sm. 40:11) Báwo làwọn alàgbà àtàwọn míì tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà lọ́nà yìí? Lílo ahọ́n wa láti pe àfiyèsí sí ìsọfúnni tó wà nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ ọ̀nà láti fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn.—Òwe 17:17.
16, 17. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ló ń darí ọ̀rọ̀ ẹnu wa?
16 Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá kíyè sí i pé Kristẹni kan ti forí lé ọ̀nà tó forí gbárí pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì? Ǹjẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ kò ní mú ká lo ahọ́n wa láti mú kó yíwà pa dà? (Sm. 141:5) Tá a bá mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ dá, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ á mú ká fún ẹni náà ní ìṣírí pé kó “pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,” kí wọ́n bàa lè “gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà.” (Ják. 5:14) Tí oníwà àìtọ́ náà bá kọ̀ láti tọ àwọn alàgbà lọ, ìwà àìnífẹ̀ẹ́ àti ìwà àìláàánú ni tí àwa náà bá kọ̀ tí a kò sọ. Àwọn kan lára wa lè ní ìrẹ̀wẹ̀sì, wọ́n lè dá nìkan wà, ó sì lè máa ṣe wọ́n bíi pé wọn kò já mọ́ nǹkan, tàbí kí ìjákulẹ̀ mú wọn banú jẹ́. Ọ̀nà kan tó dáa láti fi hàn pé òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wà lórí ahọ́n wa ni pé ká máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.”—1 Tẹs. 5:14.
17 Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run bá ń sọ àhesọ ọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? Dípò tí a ó fi máa ṣiyè méjì nípa ìṣòtítọ́ àwọn ará wa, ńṣe ló yẹ ká fọgbọ́n pa ọ̀rọ̀ náà tì, tàbí tí ẹni tó mú ẹ̀sùn náà wá bá jẹ́ olórí pípé èèyàn, a lè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó dá a lójú pé òótọ́ ni ohun tó sọ. Bí àwọn ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run bá fẹ́ mọ ibi tí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin wa wà, kí wọ́n lè ṣe wọ́n ní jàǹbá, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tá a ní fún àwọn ará wa kò ní jẹ́ ká sọ fún wọn.—Òwe 18:24.
Ẹni Tó Ní “Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Yóò Rí Ìyè”
18, 19. Kí nìdí tí òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ kò fi gbọ́dọ̀ kúrò lórí ahọ́n wa nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà?
18 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ gbọ́dọ̀ hàn gbangba nínú gbogbo àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà. Kódà, tí ipò nǹkan bá le koko, òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ kò gbọ́dọ̀ kúrò lẹ́nu wa. Inú Jèhófà kò dùn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wọn dà “gẹ́gẹ́ bí ìrì tí ń tètè lọ.” (Hós. 6:4, 6) Àmọ́, inú Jèhófà máa ń dùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí kò yẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò bó ṣe ń bù kún àwọn tó ń lépa ànímọ́ yìí.
19 Òwe 21:21 sọ pé: “Ẹni tí ń lépa òdodo àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.” Lára àwọn ìbùkún tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa gbádùn ni pé, ó máa ní ìwàláàyè, kì í ṣe ìwàláàyè kúkúrú o, àmọ́ ìyè tí kò lópin. Jèhófà á ràn án lọ́wọ́ láti “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tím. 6:12, 19) Torí náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé, à ń ‘bá a lọ ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’—Sek. 7:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i lórí bí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀ sí ìdúróṣinṣin, ìfẹ́ àti inúure, wo Ilé Ìṣọ́ May 15, 2002, ojú ìwé 12 sí 13 àti ojú ìwé 18 sí 19.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́?
• Kí ló máa mú ká ní òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ lórí ahọ́n wa?
• Báwo ni àwọn tọkọtaya ṣe lè máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ wọn?
• Kí ló ń fi hàn pé òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wà lórí ahọ́n wa nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Dáfídì gbé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà ga
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ṣé o máa ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé?