Máa Fi Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Hàn Sáwọn Aláìní
“Ẹ . . . máa bá a lọ ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ . . . sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—SEKARÁYÀ 7:9.
1, 2. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn? (b) Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò?
Ọ̀RỌ̀ Jèhófà Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká “nífẹ̀ẹ́ inú rere.” (Míkà 6:8) Ó tún fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí kan ni pé, “ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.” (Òwe 11:17) Òdodo ọ̀rọ̀! Fífi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn ń jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé a óò ní àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán—èrè ńlá sì lèyí lóòótọ́!—Òwe 18:24.
2 Ìyẹn nìkan kọ́ o, Ìwé Mímọ́ tún sọ fún wa pé: “Ẹni tí ń lépa òdodo àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.” (Òwe 21:21) Bẹ́ẹ̀ ni o, bí a ṣe ń lépa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò jẹ́ kí Ọlọ́run fẹ́ràn wa gidigidi. Èyí yóò sì fún wa láǹfààní láti gbádùn àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú, títí kan ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn? Àwọn wo ló yẹ ká máa fi hàn sí? Ǹjẹ́ ìyàtọ̀ wà láàárín inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ojú àánú tàbí inú rere lásán?
Ojú Àánú àti Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́
3. Báwo ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀ sí ojú àánú?
3 Ojú àánú lásán àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yàtọ̀ síra lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ṣojú àánú lè ṣe é láìsí àjọṣe kan lọ títí láàárín àwọn àti ẹni tí wọ́n ṣojú àánú sí. Àmọ́, a ò lè ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sẹ́nì kan láìjẹ́ pé ọkàn wa fi tìfẹ́tìfẹ́ fà mọ́ onítọ̀hún. Nínú Bíbélì, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ táwọn èèyàn kan ṣe sí àwọn ẹlòmíràn lè jẹ́ nítorí àjọṣe tó ti wà láàárín wọn látilẹ̀wá. (Jẹ́nẹ́sísì 20:13; 2 Sámúẹ́lì 3:8; 16:17) Tàbí kẹ̀, ó lè jẹ́ nítorí àjọṣe kan tó wà láàárín wọn nítorí inú rere tẹ́nì kan ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí. (Jóṣúà 2:1, 12-14; 1 Sámúẹ́lì 15:6; 2 Sámúẹ́lì 10:1, 2) Ká lè rí ìyàtọ̀ yìí dáadáa, ẹ jẹ́ ká fi àpẹẹrẹ méjì látinú Bíbélì wéra, ọ̀kan nípa ojú àánú àti èkejì nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ táwọn èèyàn fi hàn sí àwọn ẹlòmíràn.
4, 5. Báwo ni àwọn àpẹẹrẹ méjì tá a tọ́ka sí níhìn-ín látinú Bíbélì ṣe fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín ojú àánú àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn?
4 Àpẹẹrẹ ojú àánú tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ni tàwọn èèyàn kan tí ọkọ̀ rì, tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lára wọn. Omi ló gbá wọn jù sí etíkun kan ní erékùṣù Málítà. (Ìṣe 27:37–28:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máà dẹ́bi fún àwọn ará Málítà bí wọ́n bá káwọ́ lẹ́rán tí wọ́n ń wo àwọn tí ọkọ̀ rì níran, níwọ̀n bí wọn ò kúkú ti mọ̀ wọ́n rí, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ará erékùṣù yìí ṣaájò àwọn àjèjì yìí, wọ́n fi “àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá ènìyàn” hàn sí wọn. (Ìṣe 28:2, 7) Aájò wọ́n jẹ́ ti inú rere, àmọ́ àyàbá ni, àjèjì sì làwọn tí wọ́n ṣe inú rere náà sí. Nítorí náà, ọ̀ràn ojú ló ń rójú ṣàánú ni.
5 Ẹ wá jẹ́ ká fi èyí wé oore tí Ọba Dáfídì ṣe fún Mefibóṣẹ́tì, ọmọ Jónátánì ọ̀rẹ́ rẹ̀. Dáfídì sọ fún Mefibóṣẹ́tì pé: “Ìwọ alára yóò . . . máa jẹ oúnjẹ ní tábìlì mi nígbà gbogbo.” Nígbà tí Dáfídì ń ṣàlàyé ìdí tóun fi ń ṣe irú ètò yìí, ó sọ fún un pé: “Láìkùnà, èmi yóò ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ọ nítorí Jónátánì baba rẹ.” (2 Sámúẹ́lì 9:6, 7, 13) Òótọ́ kúkú ni Dáfídì sọ nígbà tó pe oore ńláǹlà yìí ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́, tó fi hàn pé kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn ojú ló ń rójú ṣàánú, nítorí pé ó jẹ́ ẹ̀rí pé ó ṣì dúró ṣinṣin ti àjọṣe kan tó ti wà tipẹ́. (1 Sámúẹ́lì 18:3; 20:15, 42) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń ṣojú àánú sí àwọn èèyàn lápapọ̀. Àmọ́, wọ́n ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìyẹn ìfẹ́ adúróṣinṣin, tó jinlẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run.—Mátíù 5:45; Gálátíà 6:10.
6. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ táwọn èèyàn ń fi hàn sáwọn ẹlòmíràn wé mọ́?
6 Ká lè mọ àwọn nǹkan mìíràn tí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wé mọ́, ẹ jẹ́ ká sáré wo àwọn ìtàn mẹ́ta tó dá lórí ànímọ́ yìí nínú Bíbélì. A óò rí i nínú ìtàn wọ̀nyí pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ táwọn èèyàn ṣe (1) máa ń wé mọ́ ìgbésẹ̀ pàtó, (2) ó máa ń jẹ́ látọkànwá, àti pé (3) àwọn aláìní la sábà máa ń fi í hàn sí ní pàtàkì. Kò mọ síbẹ̀ o, ìtàn wọ̀nyí tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn lóde òní.
Bàbá Kan Fi Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Hàn
7. Kí ni ìránṣẹ́ Ábúráhámù sọ fún Bẹ́túélì àti Lábánì, kókó wo ló sì fà yọ?
7 Jẹ́nẹ́sísì 24:28-67 sọ ìyókù ìtàn ìránṣẹ́ Ábúráhámù, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Lẹ́yìn tó pàdé Rèbékà, wọ́n ké sí i wá sí ilé Bẹ́túélì, tó jẹ́ bàbá ọmọbìnrin náà. (Ẹsẹ 28-32) Nígbà tí ìránṣẹ́ náà débẹ̀, ó tẹnu bọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé bóun ṣe ń wá ìyàwó fún ọmọ Ábúráhámù. (Ẹsẹ 33-47) Ó fi yé wọn pé ibi tọ́ràn ọ̀hún ti bọ́ sí i dé yìí jẹ́ àmì pé iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà ni, “ẹni tí ó ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà tòótọ́ láti mú ọmọbìnrin arákùnrin ọ̀gá mi fún ọmọkùnrin rẹ̀.” (Ẹsẹ 48) Láìsí àní-àní, ìránṣẹ́ náà retí pé àlàyé tóun ṣe látọkànwá yìí á mú kí Bẹ́túélì àti Lábánì ọmọ rẹ̀ gbà pé Jèhófà ló fọ̀nà han òun. Ohun tí ìránṣẹ́ náà wá fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá sì lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí ọ̀gá mi ní ti gidi, ẹ sọ fún mi; ṣùgbọ́n bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sọ fún mi, kí n lè yíjú sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì.”—Ẹsẹ 49.
8. Kí ni Bẹ́túélì sọ sí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ nípa Rèbékà?
8 Jèhófà kúkú ti ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Ábúráhámù tẹ́lẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 24:12, 14, 27) Ṣé Bẹ́túélì pẹ̀lú á fẹ́ ṣe bákan náà nípa jíjẹ́ kí Rèbékà máa bá ìránṣẹ́ Ábúráhámù lọ? Ǹjẹ́ èèyàn pẹ̀lú á fẹ́ fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tirẹ̀ kún ti Ọlọ́run, kí méjèèjì lè ṣiṣẹ́ pọ̀ fún rere? Tàbí kẹ̀, ṣé ìránṣẹ́ yẹn á wá rin gbogbo ìrìn yẹn dà nù ni? Kò ní ṣàì tu ìránṣẹ́ Ábúráhámù nínú gan-an nígbà tó gbọ́ tí Lábánì àti Bẹ́túélì sọ pé: “Láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni nǹkan yìí ti wá.” (Ẹsẹ 50) Wọ́n rí i pé gbogbo rẹ̀ kò ṣẹ̀yìn Jèhófà, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìpinnu rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ falẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni Bẹ́túélì wá fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn nípa fífi kún un pé: “Rèbékà nìyí níwájú rẹ. Máa mú un lọ, sì jẹ́ kí ó di aya fún ọmọkùnrin ọ̀gá rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ.” ((Ẹsẹ 51) Rèbékà gbà tọkàntọkàn láti bá ìránṣẹ́ Ábúráhámù lọ. Kò sì pẹ́ tó fi di aya ọ̀wọ́n fún Ísákì.—Ẹsẹ 49, 52 sí 58, àti 67.
Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Tí Ọmọ Kan Fi Hàn
9, 10. (a) Kí ni Jékọ́bù sọ pé kí Jósẹ́fù ọmọ òun ṣe fóun? (b) Báwo ni Jósẹ́fù ṣe ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí bàbá rẹ̀?
9 Jékọ́bù ọmọ-ọmọ Ábúráhámù pẹ̀lú rí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ gbà. Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì orí 47 ti wí, Íjíbítì ni Jékọ́bù ń gbé nígbà yẹn, ‘ọjọ́ sì sún mọ́lé fún un láti kú.’ (Ẹsẹ 27-29) Ó ń dùn ún pé kì í ṣe ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Ábúráhámù lòun máa kú sí. (Jẹ́nẹ́sísì 15:18; 35:10, 12; 49:29-32) Àmọ́ Jékọ́bù kò fẹ́ kí wọ́n sin òun sí Íjíbítì. Fún ìdí yìí, ó ṣètò pé kí wọ́n gbé òkú òun lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Ta ló máa lè rí sí i pé wọ́n ṣe bó ṣe wí, bí kò ṣe Jósẹ́fù tó yọrí ọlá jù lọ nínú àwọn ọmọ rẹ̀?
10 Ìtàn náà sọ pé: “Nítorí náà, [Jékọ́bù] pe Jósẹ́fù ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé: ‘Wàyí o, bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, . . . kí ìwọ . . . lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìṣeégbẹ́kẹ̀lé sí mi. (Jọ̀wọ́, má sin mí sí Íjíbítì.) Èmi yóò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba mi, kí ìwọ sì gbé mi jáde kúrò ní Íjíbítì, kí o sì sin mí sínú sàréè wọn.’” (Jẹ́nẹ́sísì 47:29, 30) Jósẹ́fù ṣèlérí pé òun máa ṣe ohun tó sọ yìí. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí Jékọ́bù kú. Jósẹ́fù àtàwọn ọmọ Jékọ́bù yòókù gbé òkú rẹ̀ “lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sin ín sínú hòrò pápá Mákípẹ́là, pápá tí Ábúráhámù rà.” (Jẹ́nẹ́sísì 50:5-8, 12-14) Bí Jósẹ́fù ṣe ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí bàbá rẹ̀ nìyẹn.
Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Látọ̀dọ̀ Aya Ọmọ
11, 12. (a) Báwo ni Rúùtù ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí Náómì? (b) Báwo ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Rúùtù ti “ìgbà ìkẹyìn” ṣe dára ju ti “àkọ́kọ́”?
11 Ìwé Rúùtù sọ bí Náómì opó ṣe rí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Rúùtù ará Móábù tó jẹ́ aya ọmọ rẹ̀, tóun náà jẹ́ opó. Nígbà tí Náómì pinnu pé òun fẹ́ padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, Rúùtù fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìmúratán hàn, nígbà tó sọ pé: “Ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sì sùn mọ́jú ni èmi yóò sùn mọ́jú. Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.” (Rúùtù 1:16) Rúùtù tún fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn lẹ́yìn náà nígbà tó gbà láti fẹ́ Bóásì àgbàlagbà tó jẹ́ ẹbí Náómì.a (Diutarónómì 25:5, 6; Rúùtù 3:6-9) Ọkùnrin náà sọ fún Rúùtù pé: “Ìwọ ti fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ hàn lọ́nà tí ó dára ní ìgbà ìkẹyìn ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ, ní ti pé ìwọ kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn yálà ẹni rírẹlẹ̀ tàbí ọlọ́rọ̀.”—Rúùtù 3:10.
12 “Ìgbà àkọ́kọ́” tí ibí yìí sọ pé Rúùtù fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn ni ìgbà tó fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fà mọ́ Náómì. (Rúùtù 1:14; 2:11) Kódà ìgbésẹ̀ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ “ìkẹyìn” yìí, ìyẹn gbígbà tí Rúùtù gbà láti fẹ́ Bóásì, tún ré kọjá ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ yẹn. Èyí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Rúùtù láti bí ajogún fún Náómì, ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti kọjá ti ọmọ bíbí. Ìgbéyàwó náà wáyé. Nígbà tí Rúùtù sì bímọ, àwọn obìnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù polongo pé: “A ti bí ọmọkùnrin kan fún Náómì.” (Rúùtù 4:14, 17) “Obìnrin títayọ lọ́lá” ni Rúùtù lóòótọ́. Ìdí sì nìyẹn tí Jèhófà fi fún un ní àgbàyanu àǹfààní láti di ìyá ńlá Jésù Kristi.—Rúùtù 2:12; 3:11; 4:18-22; Mátíù 1:1, 5, 6.
Wọ́n Fi Ṣèwà Hù
13. Báwo ni Bẹ́túélì, Jósẹ́fù àti Rúùtù ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wọn hàn?
13 Ǹjẹ́ o kíyè sí bí Bẹ́túélì, Jósẹ́fù àti Rúùtù ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wọn hàn? Wọn ò fi mọ sọ́rọ̀ ẹnu nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n tún fi ṣèwà hù. Bẹ́túélì kò fi mọ sórí sísọ pé, “Rèbékà nìyí,” ṣùgbọ́n ó dìídì ‘rán Rèbékà lọ.’ (Jẹ́nẹ́sísì 24:51, 59) Jósẹ́fù kò fi mọ sórí sísọ pé, “Èmi yóò ṣe bẹ́ẹ̀ ní pípa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́” ṣùgbọ́n ‘gan-an gẹ́gẹ́ bí Jékọ́bù ti pàṣẹ fún wọn’ ni òun àtàwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 47:30; 50:12, 13) Rúùtù kò fi mọ sórí sísọ pé, “Ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ” ṣùgbọ́n ó fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, ó sì bá Náómì lọ, tó fi jẹ́ pé “àwọn méjèèjì . . . ń bá ọ̀nà wọn lọ títí wọ́n fi dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.” (Rúùtù 1:16, 19) Ní Júdà, Rúùtù tún ṣe “gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ ti pa láṣẹ fún un.” (Rúùtù 3:6) Bẹ́ẹ̀ ni o, bíi ti àwọn yòókù, Rúùtù fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣèwà hù.
14. (a) Báwo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ṣe ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣèwà hù? (b) Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wo ni o mọ̀ tí àwọn Kristẹni tó wà lágbègbè rẹ ń fi hàn?
14 Ó múni lọ́kàn yọ̀ láti rí i bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ṣe ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn tó jẹ́ alábàárò fún àwọn aláìlera, tàbí àwọn tó sorí kọ́ tàbí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí ìbànújẹ́ bá. (Òwe 12:25) Tàbí kẹ̀, ronú nípa ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n ń fi ọkọ̀ wọn gbé àwọn arúgbó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìpàdé ìjọ. Anna, ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin [82], tí àrùn oríkèé-ara-ríro ń yọ lẹ́nu, sọ ohun tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tó sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń fi ọkọ̀ gbé mi lọ sí gbogbo ìpàdé jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà. Mo dúpẹ́, mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ rẹ̀ pé mo ní àwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́.” Ṣé ìwọ náà ń bá wọn ṣe irú iṣẹ́ yẹn nínú ìjọ rẹ? (1 Jòhánù 3:17, 18) Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé a mọrírì inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ gidigidi.
Tinútinú Ni Wọ́n Ṣe É
15. Kí ni nǹkan míì tá a tún mọ̀ nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ nínú ìtàn mẹ́ta tá a gbé yẹ̀ wò látinú Bíbélì?
15 Àwọn ìtàn wọ̀nyí tá a gbé yẹ̀ wò látinú Bíbélì tún fi hàn pé tinútinú ni wọ́n ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wọ̀nyẹn láìgba kọ́bọ̀, kì í sì í ṣe àfipáṣe. Tinútinú ni Bẹ́túélì àti Rèbékà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìránṣẹ́ Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 24:51, 58) Kò sẹ́ni tó fi túláàsì mú Jósẹ́fù láti ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tó ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 50:4, 5) Rúùtù alára ló “tẹpẹlẹ mọ́ bíbá [Náómì] lọ.” (Rúùtù 1:18) Nígbà tí Náómì dá a lábàá pé kí Rúùtù lọ bá Bóásì, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ló mú kí ọmọbìnrin Móábù yìí sọ pé: “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”—Rúùtù 3:1-5.
16, 17. Kí ló mú kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Bẹ́túélì, Jósẹ́fù àti ti Rúùtù wúni lórí lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ló sì sún wọn fi ànímọ́ yìí hàn?
16 Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Bẹ́túélì, Jósẹ́fù àti Rúùtù fi hàn tún pabanbarì nítorí pé Ábúráhámù, Jékọ́bù àti Náómì kò lè fagbára mú wọn ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ bí wọn ò bá fẹ́ ṣe é. Ó ṣe tán, kò sófin tó de Bẹ́túélì pé ó gbọ́dọ̀ ní kí ọmọ òun máa lọ. Bó bá wù ú, ó lè sọ fún ìránṣẹ́ Ábúráhámù pé: ‘Rárá, mi ò fẹ́ kí ọmọ mi tó jẹ́ òṣìṣẹ́kára yìí jìnnà sí mi.’ (Jẹ́nẹ́sísì 24:18-20) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Jósẹ́fù bá kọ̀, tó lóun ò ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ ní kó ṣe, kò sẹ́ni tó máa mú un. Jékọ́bù á kúkú ti gbẹ́mìí mì, kò sì ní lè fagbára mú un ṣe ohun tó ní kó ṣe. Náómì alára fi hàn pé bó bá wu Rúùtù ó lè sọ pé òun ò kúrò nílẹ̀ Móábù. (Rúùtù 1:8) Kò sì lẹ́ṣẹ̀ nínú, bí Rúùtù bá fẹ́ ọ̀kan lára “àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn” dípò fífẹ́ Bóásì arúgbó.
17 Bẹ́túélì, Jósẹ́fù àti Rúùtù múra tán láti ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́; ó ti ọkàn wọn wá. Ọkàn wọn sọ fún wọn pé ojúṣe àwọn ni láti fi ànímọ́ yìí hàn sí àwọn tí nǹkan jọ dà àwọn pọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọba Dáfídì ti gbà pé ojúṣe òun ni láti fi ànímọ́ yìí hàn sí Mefibóṣẹ́tì.
18. (a) Irú ẹ̀mí wo làwọn Kristẹni alàgbà fi ń “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo”? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni alàgbà kan sọ nípa ríran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́?
18 Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣì wà lára ohun tá a fi ń dá àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ lónìí, títí kan àwọn ọkùnrin tí ń bójú tó agbo Ọlọ́run. (Sáàmù 110:3; 1 Tẹsalóníkà 5:12) Irú àwọn alàgbà tàbí alábòójútó bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé nítorí ipò tá a yàn wọ́n sí, ojúṣe wọn ni láti máa hùwà lọ́nà tí ìgbẹ́kẹ̀lé táwọn èèyàn ní nínú wọn ò fi ní yingin. (Ìṣe 20:28) Síbẹ̀ náà, iṣẹ́ àbójútó àtàwọn iṣẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mìíràn tí wọ́n ń ṣe fún ìjọ kì í ṣe “àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú.” (1 Pétérù 5:2) Àwọn alàgbà ń bójú tó agbo nítorí wọ́n mọ̀ pé ojúṣe àwọn ni, àti pé ó tọkàn wọn wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn àgùntàn Kristi nítorí pé ohun tó yẹ kí wọ́n máa ṣe ni, ohun tó sì wù wọ́n láti máa ṣe ni. (Jòhánù 21:15-17) Kristẹni alàgbà kan sọ pé: “Ó máa ń wù mí gan-an láti máa bẹ àwọn ará wo nínú ilé wọn tàbí kí n máa tẹlifóònù wọn, kí wọ́n sáà lè mọ̀ pé ọkàn mi fà sọ́dọ̀ wọn. Bí ẹ bá rí i bí inú mi ṣe máa ń dùn tó láti ran àwọn ará lọ́wọ́!” Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀ràn rí lára àwọn alàgbà tó láájò níbi gbogbo.
Máa Fi Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Hàn Sáwọn Aláìní
19. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la tún rí kọ́ nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ nínú àwọn ìtàn Bíbélì tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
19 Àwọn ìtàn Bíbélì tá a jíròrò tún fi ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́ wa, ìyẹn ni pé ó yẹ ká máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sáwọn tó ń kojú ìṣòro tó kọjá agbára wọn. Kí ìlà ìdílé Ábúráhámù má bàa kú run, ó ń fẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Bẹ́túélì. Jékọ́bù ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ Jósẹ́fù kí òkú rẹ̀ lè dé Kénáánì. Láti lè bí ajogún náà, Náómì nílò ìrànlọ́wọ́ Rúùtù. Àti Ábúráhámù ni o, àti Jékọ́bù ni o, àti Náómì ni o, kò sí ìkankan nínú wọn tó lè dá nǹkan wọ̀nyẹn ṣe. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí. Ó yẹ ká máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn, àgàgà sáwọn tó jẹ́ aláìní. (Òwe 19:17) Ó yẹ ká fìwà jọ Jóòbù baba ńlá nì, tó “gba ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀, tó sì tún gba ọmọdékùnrin aláìníbaba àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́” àti “ẹni tí ń ṣègbé lọ.” Jóòbù tún “mú ọkàn-àyà opó yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,” ó ‘di ojú fún afọ́jú, ó sì jẹ́ ẹsẹ̀ fún ẹni tó yarọ.’—Jóòbù 29:12-15.
20, 21. Àwọn wo ló ń fẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wa, kí ló sì yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pinnu láti ṣe?
20 Ní ti gidi, àwọn “tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́” ń bẹ nínú gbogbo ìjọ Kristẹni. Bóyá ohun tó fà á ni dídáwà, ìrẹ̀wẹ̀sì, ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkan kan, tàbí nítorí ìjákulẹ̀, àìsàn burúkú tàbí ikú èèyàn wọn kan. Ohun yòówù kó fà á, gbogbo irú àwọn ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ ní àwọn ìṣòro tá a lè bá wọn yanjú, tó sì yẹ ká fi tinútinú bá wọn yanjú pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ jíjinlẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 5:14.
21 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó ní fífarawé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó “pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Ẹ́kísódù 34:6; Éfésù 5:1) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi tinútinú gbé ìgbésẹ̀ pàtó, pàápàá jù lọ fún ire àwọn tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́. Ó sì dájú pé a óò máa bọlá fún Jèhófà, a ó sì ní ayọ̀ púpọ̀ bá a ṣe ń ‘bá a lọ ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’—Sekaráyà 7:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé kíkún nípa irú ìgbéyàwó tí ibí yìí ń sọ, wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 370, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀ sí ojú àánú?
• Báwo ni Bẹ́túélì, Jósẹ́fù àti Rúùtù ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn?
• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká máa fi fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn?
• Àwọn wo ló ń fẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Báwo ni Bẹ́túélì ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìfẹ́ adúróṣinṣin tí Rúùtù fi hàn jẹ́ ìbùkún fún Náómì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwa èèyàn máa ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn látọkànwá, wọ́n máa ń fi hàn nípa gbígbé ìgbésẹ̀ pàtó, wọ́n sì máa ń fi hàn fún ire àwọn aláìní