Àsọtẹ́lẹ̀ 3. Àrùn
“Àwọn èèyàn yóò . . . ní àwọn àrùn burúkú.”—LÚÙKÙ 21:11, Bíbélì Contemporary English Version.
● Ọ̀gbẹ́ni Bonzali, tó jẹ́ olùtọ́jú àwọn aláìlera ní orílẹ̀-èdè kan tí ogun ti bà jẹ́ nílẹ̀ Áfíríkà ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tọ́jú àwọn òṣìṣẹ́ tó ń wa kùsà tí àrùn Marburg ń pa ní ìlú rẹ̀.a Ó ní kí àwọn aláṣẹ ìjọba tó wà ní ìlú ńlá ran òun lọ́wọ́, àmọ́ wọn kò dá a lóhùn. Lóṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, ìrànlọ́wọ́ dé, àmọ́, ọ̀gbẹ́ni Bonzali ti kú. Ó kó àrùn Marburg yìí lára àwọn awakùsà tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn là.
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Àwọn àìsàn tí kì í jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa (bí òtútù àyà), àrùn ìgbẹ́ ọ̀rìn, kòkòrò HIV àti àrùn éèdì, ikọ́ ẹ̀gbẹ àti ibà wà lára àwọn àrùn tó burú jù lọ tó ń yọ aráyé lẹ́nu. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn àrùn márùn-ún yìí pa èèyàn mílíọ̀nù tó tó mẹ́wàá àti ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [10, 700,000]. Tá a bá ní ká sọ ọ́ lọ́nà míì, àwọn àrùn yìí ń pa nǹkan bí èèyàn kan ní gbogbo ìṣẹ́jú àáyá mẹ́ta, láàárín ọdún kan.
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Iye àwọn èèyàn ayé ń pọ̀ sí i, nítorí náà ó dájú pé ńṣe ni àrùn á máa pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì lè kó àrùn.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Òótọ́ ni pé, iye àwọn èèyàn ayé ti pọ̀ gan-an. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà táwọn èèyàn lè gbà mọ àrùn kí wọ́n sì kápá rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe lè tọ́jú àrùn ti pọ̀ gan-an. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé kí ipa tí àrùn ń ní lórí èèyàn dín kù? Àmọ́, kò dín kù.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ àrùn burúkú ń ṣe àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀?
Ìmìtìtì ilẹ̀, ìyàn àti àrùn jẹ́ nǹkan ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Àmọ́ àwọn èèyàn fúnra wọn ń fìyà jẹ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn tó yẹ kó dáàbò bo àwọn èèyàn ló ń fìyà jẹ wọ́n. Kíyè sí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tó ń fa àrùn Marburg Hemorrhagic Fever jọ ohun tó ń fa àrùn Ebola.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Ohun tó burú ni kí kìnnìún tàbí ohun kan pani jẹ, àmọ́ ohun tó tún burú bí ìyẹn ni kí àrùn burúkú kan jẹ gbogbo ara èèyàn, kéèyàn sì rí i tí ohun kan náà ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó yíni ká.”—Ọ̀GBẸ́NI MICHAEL OSTERHOLM TÓ JẸ́ ONÍMỌ̀ NÍPA ÀRÙN.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]
© William Daniels/Panos Pictures