‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’
“Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” —RÓÒMÙ 11:33.
1. Àǹfààní gíga jù lọ wo ni àwọn Kristẹni tó ti ṣe ìrìbọmi ní?
ÀǸFÀÀNÍ gíga jù lọ wo lo tíì ní rí? Ó ṣeé ṣe kó o kọ́kọ́ ronú nípa àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n ti gbé fún ẹ rí tàbí ohun kan tí wọ́n ti fi dá ẹ lọ́lá. Àmọ́, ní ti àwa Kristẹni tá a ti ṣe ìrìbọmi, àǹfààní tó ga jù lọ ni bí Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, Jèhófà, ṣe yọ̀ǹda fún wa láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ti mú kí “ó mọ̀” wá.—1 Kọ́r. 8:3; Gál. 4:9.
2. Kí nìdí tí mímọ̀ tá a mọ Jèhófà àti mímọ̀ tó mọ̀ wá fi jẹ́ àǹfààní gíga?
2 Kí nìdí tí mímọ̀ tá a mọ Jèhófà àti mímọ̀ tó mọ̀ wá fi jẹ́ àǹfààní gíga? Ìdí ni pé kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run jẹ́ Ẹni gíga jù lọ láyé àti lọ́run nìkan ni, àmọ́ ó tún máa ń dáàbò bo gbogbo àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí. Ọlọ́run mí sí wòlíì Náhúmù láti kọ̀wé pé: “Jèhófà jẹ́ ẹni rere, ibi odi agbára ní ọjọ́ wàhálà. Ó sì mọ àwọn tí ń wá ibi ìsádi lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Náh. 1:7; Sm. 1:6) Kódà, ká tó lè jogún ìyè ayérayé a gbọ́dọ̀ mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi.—Jòh. 17:3.
3. Kí ló túmọ̀ sí láti mọ Ọlọ́run?
3 Mímọ Ọlọ́run kò mọ sórí wíwulẹ̀ mọ orúkọ tó ń jẹ́. A gbọ́dọ̀ di Ọ̀rẹ́ rẹ̀, ká mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́. Ṣíṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti yíyẹra fún àwọn ohun tí kò fẹ́ tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a mọ̀ ọ́n dáadáa. (1 Jòh. 2:4) Àmọ́, ó ṣì tún ku ohun kan tá a gbọ́dọ̀ ṣe bó bá jẹ́ pé òótọ́ la fẹ́ mọ Jèhófà. Ó pọn dandan pé ká mọ àwọn ohun tó ti ṣe. Kì í wá ṣe ìyẹn nìkan o, ó tún yẹ ká mọ bó ṣe ṣe àwọn nǹkan náà àti ìdí tó fi ṣe wọ́n lọ́nà yẹn. Bá a bá ṣe ń lóye àwọn ètè Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni ‘ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run’ yóò ṣe túbọ̀ máa jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún wa tó.—Róòmù 11:33.
Ọlọ́run Ète
4, 5. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ète” dúró fún gẹ́gẹ́ bí a ṣe lò ó nínú Bíbélì? (b) Ṣàpèjúwe bí ète kan ṣe lè ní ìmúṣẹ ní ọ̀nà tó ju ẹyọ kan lọ.
4 Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ète, Bíbélì sì sọ̀rọ̀ nípa “ète ayérayé” rẹ̀. (Éfé. 3:10, 11) Kí ni ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí gan-an? Ọ̀rọ̀ náà “ète,” gẹ́gẹ́ bí a ṣe lò ó nínú Bíbélì, dúró fún ohun pàtó kan téèyàn ń lépa tàbí tó fojú sùn pé òun máa ṣe, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ọ̀nà tó lè gbà ṣe é ju ẹyọ kan lọ.
5 A lè ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: Ẹnì kan lè fẹ́ láti rìnrìn àjò lọ sí ibi pàtó kan. Dídé ibi tó fẹ́ lọ yẹn ni ète rẹ̀ tàbí ohun tó fojú sùn. Ó lè jẹ́ pé onírúurú ohun ìrìnnà ló wà tó lè gbé e débẹ̀, kí ọ̀nà tó débẹ̀ sì ju ẹyọ kan lọ. Bó ti ń gba èyí tó yàn lára àwọn ọ̀nà náà lọ, ojú ọjọ́ lè ṣàdédé yí pa dà, sún kẹrẹ fà kẹrẹ lè wà lójú títì, ó sì lè dé ibi tí ojú ọ̀nà ti dí, èyí tó máa gba pé kó wá ibòmíì gbà. Bí àwọn ìdíwọ́ wọ̀nyí bá tiẹ̀ mú kó gba ibòmíràn síbẹ̀, bó bá ti dé ibi tó ń lọ, ète rẹ̀ tàbí ohun tó fojú sùn pé òun máa ṣe ti di ṣíṣe nìyẹn.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun lè yí ọ̀nà tí ète òun á gbà ní ìmúṣẹ pa dà?
6 Bákan náà, Jèhófà ti fi hàn pé òun lè yí ọ̀nà tí òun á gbà mú ète ayérayé òun ṣẹ pa dà. Níwọ̀n bó ti mọ̀ pé àwọn ẹ̀dá olóye tí òun dá ní òmìnira láti yan ohun tí wọ́n fẹ́, ó máa ń gba tiwọn rò nípa yíyí ọ̀nà tó ń gbà mú ète rẹ̀ ṣẹ pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò bí ọ̀rọ̀ nípa Irú-ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà ṣe jẹ́ ká rí ọ̀nà tí Jèhófà máa ń gbà mú ète rẹ̀ ṣẹ. Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, Jèhófà sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ náà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:28) Ṣé ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì mú kí ète Ọlọ́run yẹn forí ṣánpọ́n? Rárá o! Jèhófà yára wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà nípa gbígbé nǹkan gba ọ̀nà míì kí ète rẹ̀ bàa lè ní ìmúṣẹ. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “irú-ọmọ” kan tó máa mú ìpalára táwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ti mú bá aráyé kúrò.—Jẹ́n. 3:15; Héb. 2:14-17; 1 Jòh. 3:8.
7. Kí la rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ṣàlàyé irú ẹni tí òun jẹ́ nínú ìwé Ẹ́kísódù 3:14?
7 Bó bá kù díẹ̀ kí ète Jèhófà ní ìmúṣẹ, àmọ́ tí ipò nǹkan yí pa dà, ó lè gbé nǹkan gba ọ̀nà míì. Èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó sọ nípa irú ẹni tí òun jẹ́. Nígbà tí Mósè ń ṣàlàyé ohun tó ṣeé ṣe kó fà á tí kò fi ní lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, Jèhófà mú un lọ́kàn le nípa sísọ fún un pé: “‘Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.’ Ó sì fi kún un pé: ‘Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, “èmi yóò jẹ́ ti rán mi sí yín.”’” (Ẹ́kís. 3:14) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà lè di ohunkóhun tó bá fẹ́ kó bàa lè mú ète rẹ̀ ṣẹ ní kíkún! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe èyí dáadáa ní orí 11 nínú ìwé Róòmù. Nínú orí náà, ó sọ̀rọ̀ nípa igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ kan. Bá a bá gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò, ó máa mú kí ìmọrírì tá a ní fún ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Jèhófà pọ̀ sí i, yálà a nírètí láti lọ sọ́run tàbí láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.
Ète Jèhófà Nípa Irú-Ọmọ Tá A Sọ Tẹ́lẹ̀ Náà
8, 9. (a) Àwọn ohun pàtàkì mẹ́rin wo ló máa jẹ́ ká lóye àpèjúwe nípa igi ólífì? (b) Ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí, kí ni ìdáhùn sí ìbéèrè náà sì máa jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
8 Ká tó lè lóye àpèjúwe nípa igi ólífì, àwọn ohun mẹ́rin kan wà tá a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ nípa bí ètè Jèhófà nípa irú-ọmọ tá a ṣèlérí náà ṣe ń ní ìmúṣẹ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ohun àkọ́kọ́ ni pé Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn” nípasẹ̀ irú-ọmọ, tàbí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Jẹ́n. 22:17, 18) Èkejì, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Ábúráhámù jẹ́ baba ńlá fún ni a fún ní àǹfààní láti pèsè “ìjọba àwọn àlùfáà.” (Ẹ́kís. 19:5, 6) Ìkẹta, torí pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ti ara kò gba Mèsáyà tí Ọlọ́run rán, Jèhófà gbé nǹkan gba ọ̀nà mìíràn kó bàa lè pèsè “ìjọba àwọn àlùfáà.” (Mát. 21:43; Róòmù 9:27-29) Ìkẹrin, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ni apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ Ábúráhámù, àwọn mìíràn tún ní àǹfààní láti di apá kan irú-ọmọ náà.—Gál. 3:16, 29.
9 Ìwé Ìṣípayá tún sọ síwájú sí i nípa àwọn ohun pàtàkì mẹ́rin yìí pé àpapọ̀ àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. (Ìṣí. 14:1-4) Bíbélì tún pe àwọn èèyàn wọ̀nyí ní “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣí. 7:4-8) Ṣé ọmọ Ísírẹ́lì nípa tara, tàbí Júù wá ni gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn náà? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká rí i pé Jèhófà lè yí ọ̀nà tí ète rẹ̀ á gbà ní ìmúṣẹ pa dà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù ṣe jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà.
“Ìjọba Àwọn Àlùfáà”
10. Kí ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan nírètí láti ṣe?
10 Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan ló ní ìrètí láti pèsè àwọn tó máa di “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ka Róòmù 9:4, 5.) Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí Irú-ọmọ tá a ṣèlérí náà bá dé? Ṣé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tara ló máa pèsè gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] èèyàn tó máa di apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù?
11, 12. (a) Ìgbà wo ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àkójọ àwọn tó máa wà nínú Ìjọba ti ọ̀run, kí sì ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù tó gbé láyé nígbà yẹn ṣe? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe rí “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye” àwọn tó máa di irú-ọmọ Ábúráhámù?
11 Ka Róòmù 11:7-10. Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, àwọn Júù tó gbáyé ní ọ̀rúndún kìíní kọ Jésù sílẹ̀. Torí náà, àǹfààní tó jẹ́ tiwọn nìkan láti pèsè irú-ọmọ Ábúráhámù wá sópin. Àmọ́, nígbà tí àkójọ àwọn tó máa di “ìjọba àwọn àlùfáà” bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù kan tí wọ́n ní ọkàn títọ́ tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà. Torí pé àwọn wọ̀nyí kéré níye, ńṣe ni wọ́n dà bí “àṣẹ́kù kékeré” bá a bá fi wọ́n wé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lódindi.—Róòmù 11:5.
12 Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe máa rí “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye” àwọn tó máa di irú-ọmọ Ábúráhámù? (Róòmù 11:12, 25) Kíyè sí ìdáhùn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí ìbéèrè náà. Ó sọ pé: “Kì í ṣe bí ẹni pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti kùnà. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó jáde wá láti inú Ísírẹ́lì [nípa ti ara] ni ‘Ísírẹ́lì’ ní ti gidi. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí pé wọ́n jẹ́ irú-ọmọ [àtọmọdọ́mọ] Ábúráhámù ni gbogbo wọ́n fi jẹ́ ọmọ [apá kan irú-ọmọ Ábúráhámù] . . . Ìyẹn ni pé, àwọn ọmọ nípa ti ara kì í ṣe àwọn ọmọ Ọlọ́run ní ti gidi, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ nípa ìlérí ni a kà sí irú-ọmọ náà.” (Róòmù 9:6-8) Torí náà, kò fi dandan túmọ̀ sí pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù kó tó lè di apá kan lára irú-ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí.
Igi Ólífì Ìṣàpẹẹrẹ
13. Kí ni àwọn nǹkan wọ̀nyí dúró fún (a) igi ólífì, (b) gbòǹgbò rẹ̀, (d) ìtí igi rẹ̀ àti (e) àwọn ẹ̀ka rẹ̀?
13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó nípa fífi àwọn tó di apá kan irú-ọmọ Ábúráhámù wé àwọn ẹ̀ka tó wà lára igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ.a (Róòmù 11:21) Igi ólífì tá a gbìn yìí ṣàpẹẹrẹ bí ète tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tó bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú ṣe ní ìmúṣẹ. Gbòǹgbò igi náà jẹ́ mímọ́ ó sì dúró fún Jèhófà tó mú kí Ísírẹ́lì tẹ̀mí wà láàyè. (Aísá. 10:20; Róòmù 11:16) Ìtí igi náà dúró fún Jésù tó jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ Ábúráhámù. Lápapọ̀, àwọn ẹ̀ka igi náà dúró fún “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye” àwọn tó jẹ́ apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù.
14, 15. Àwọn wo la ‘ṣẹ́ kúrò’ lára igi ólífì tá a gbìn náà, àwọn wo la sì lọ́ sára rẹ̀?
14 Nínú àpèjúwe igi ólífì, àwọn Júù nípa tára tí wọ́n kọ Jésù sílẹ̀ la fi wé àwọn ẹ̀ka igi ólífì tá a ‘ṣẹ́ kúrò.’ (Róòmù 11:17) Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti di apá kan irú-ọmọ Ábúráhámù. Àmọ́, àwọn wo ló máa rọ́pò wọn? Àwọn Júù nípa tara tí wọ́n máa ń fi jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù yangàn kò jẹ́ ronú láé pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ni Ọlọ́run máa fi rọ́pò àwọn. Àmọ́ Jòhánù Olùbatisí ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé bí Jèhófà bá fẹ́, ó lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù láti inú òkúta.—Lúùkù 3:8.
15 Kí wá ni Jèhófà ṣe kó lè mú ète rẹ̀ ṣẹ? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a lọ́ àwọn ẹ̀ka tí wọ́n gé lára igi ólífì ìgbẹ́ sára igi ólífì tá a gbìn náà ká lè fi wọ́n rọ́pò àwọn tí a ṣẹ́ kúrò. (Ka Róòmù 11:17, 18.) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, tí àwọn díẹ̀ nínú wọn wà nínú ìjọ Róòmù, la lọ́ sára igi ólífì yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Wọ́n sì tipa báyìí di apá kan irú-ọmọ Ábúráhámù. Wọ́n ti kọ́kọ́ dà bí àwọn ẹ̀ka igi ólífì ìgbẹ́, wọn kò sì ní àǹfààní kankan láti di apá kan májẹ̀mú àkànṣe yìí. Àmọ́, Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti di Júù nípa tẹ̀mí.—Róòmù 2:28, 29.
16. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe dá orílẹ̀-èdè tẹ̀mí náà sílẹ̀?
16 Bí àpọ́sítélì Pétérù ṣe ṣàlàyé ọ̀ràn náà rèé: “Ẹ̀yin [Ísírẹ́lì tẹ̀mí, títí kan àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni] ni òun [Jésù Kristi] ṣe iyebíye fún, nítorí tí ẹ jẹ́ onígbàgbọ́; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà gbọ́, ‘òkúta kan náà gan-an tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì ti di olórí igun ilé,’ àti ‘òkúta ìkọ̀sẹ̀ àti àpáta ràbàtà ìdìgbòlù.‘ . . . Ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀. Nítorí ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run; ẹ̀yin ni àwọn tí a kò ti fi àánú hàn sí tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ àwọn tí a ti fi àánú hàn sí.”—1 Pét. 2:7-10.
17. Báwo ni ohun tí Jèhófà ṣe ṣe “lòdì sí ti ẹ̀dá”?
17 Jèhófà ṣe ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò jẹ́ retí pé kó rí bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà “lòdì sí ti ẹ̀dá.” (Róòmù 11:24) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ó máa dà bí ohun tó ṣàjèjì tí kò sì bá ọ̀nà téèyàn ń gbà ṣe nǹkan mu pé kí a lọ́ ẹ̀ka ólífì ìgbẹ́ sára igi tá a gbìn; síbẹ̀, ohun táwọn àgbẹ̀ kan ṣe ní ọ̀rúndún kìíní nìyẹn.b Lọ́nà kan náà, Jèhófà ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Lójú àwọn Júù, kò ṣeé ṣe fún àwọn Kèfèrí láti so èso tó ṣètẹ́wọ́gbà. Àmọ́, Jèhófà sọ wọ́n di apá kan “orílẹ̀-èdè” tó so èso Ìjọba náà. (Mát. 21:43) Látìgbà tó ti fi ẹ̀mí yan Kọ̀nílíù, tó jẹ́ Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ àkọ́kọ́ tó di Kristẹni, ní ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, ni àǹfààní ti ṣí sílẹ̀ fún lílọ́ àwọn aláìdádọ̀dọ́ tí kì í ṣe Júù sára igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ náà.—Ìṣe 10:44-48.c
18. Àǹfààní wo ni àwọn Júù nípa tara ní lẹ́yìn ọdún 36 Sànmánì Kristẹni?
18 Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé lẹ́yìn ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù nípa tara kò ní àǹfààní mọ́ láti di apá kan irú-ọmọ Ábúráhámù? Rárá o. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Àwọn [tí wọ́n jẹ́ Júù nípa ti ara] pẹ̀lú ni a óò lọ́ wọlé bí wọn kò bá dúró nínú àìnígbàgbọ́ wọn; nítorí Ọlọ́run lè tún lọ́ wọn wọlé. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé a ké ọ kúrò lára igi ólífì tí ó jẹ́ ti ìgbẹ́ lọ́nà ti ẹ̀dá, tí a sì lọ́ ìwọ lọ́nà tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá sínú igi ólífì ọgbà, mélòómélòó ni a óò lọ́ àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ ti àdánidá sínú igi ólífì tiwọn!”d—Róòmù 11:23, 24.
“A Ó Gba Gbogbo Ísírẹ́lì Là”
19, 20. Gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe fi hàn, kí ni Jèhófà ṣe àṣeparí rẹ̀?
19 Ó dájú pé ète Jèhófà nípa “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti ń ní ìmúṣẹ lọ́nà tó kàmàmà. (Gál. 6:16) Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, “a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là.” (Róòmù 11:26) Bó bá tó àkókò lójú Jèhófà, “gbogbo Ísírẹ́lì,” ìyẹn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye Ísírẹ́lì tẹ̀mí, yóò máa sìn gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà lọ́run. Kò sí ohunkóhun tó lè ní kí ète Jèhófà máà kẹ́sẹ járí!
20 Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, irú-ọmọ Ábúráhámù, ìyẹn Jésù Kristi àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], máa bù kún “àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 11:12; Jẹ́n. 22:18) Lọ́nà yìí, gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run máa jàǹfààní látinú ìṣètò yìí. Ó dájú pé bá a ṣe ń ronú lórí ọ̀nà tí ète ayérayé Jèhófà ń gbà ní ìmúṣẹ, ìyàlẹ́nu ni “ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run” ń jẹ́ fún wa.—Róòmù 11:33.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù kò lo igi ólífì náà láti ṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa ti ara. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa ti ara ní àwọn ọba àti àlùfáà, orílẹ̀-èdè náà kò di ìjọba àwọn àlùfáà. Òfin kò fàyè gba àwọn ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti di àlùfáà. Torí náà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa ti ara kọ́ ni igi ólífì náà dúró fún. Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń ṣàpèjúwe bí ète Ọlọ́run láti pèsè “ìjọba àwọn àlùfáà” ṣe má ṣẹ sí Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí lára. A fi àlàyé yìí ṣe àtúnṣe ohun tó wà nínú Ile-iṣọ Naa, February 15, 1984, ojú ìwé 9 sí 13.
b Wo àpótí náà, “Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Máa Ń Lọ́ Àwọn Ẹ̀ka Igi Ólífì Ìgbẹ́?”
c Èyí wáyé ní òpin ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tá a fi fún àwọn Júù nípa tara láǹfààní láti di apá kan orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun náà. Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa èyí nínú àsọtẹ́lẹ̀ àádọ́rin [70] ọ̀sẹ̀ ti ọdún.—Dán. 9:27.
d Àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ọgbà” nínú Róòmù 11:24 wá látinú ọ̀rọ̀ kan tó túmọ̀ sí “dára, dára lọ́pọ̀lọpọ̀” tàbí “tó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.” A sábà máa ń lò ó fún àwọn nǹkan tó bá ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ète tá a torí rẹ̀ ṣe wọ́n.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí la rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà máa ń gbà mú ète rẹ̀ ṣẹ?
• Nínú Róòmù orí 11, kí ni àwọn nǹkan wọ̀nyí dúró fún . . .
igi ólífì?
gbòǹgbò rẹ̀?
ìtí igi rẹ̀?
àwọn ẹ̀ka rẹ̀?
• Kí nìdí tí lílọ́ ẹ̀ka ólífì ìgbẹ́ sára igi tá a gbìn fi “lòdì sí ti ẹ̀dá”?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Máa Ń Lọ́ Àwọn Ẹ̀ka Igi Ólífì Ìgbẹ́?
▪ Ọmọ ogun ìlú Róòmù àti àgbẹ̀ tó gbáyé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ni Lucius Junius Moderatus Columella. Ó gbajúmọ̀ gan-an torí ìwé méjìlá tó kọ lórí ìgbésí ayé oko àti iṣẹ́ àgbẹ̀.
Nínú ìwé rẹ̀ karùn-ún, ó pa òwe àtijọ́ kan pé: “Ẹni tó bá roko ìdí igi ólífì, ló fẹ́ kó sèso; ẹni bá bu ajílẹ̀ sí ìdí rẹ̀, ló fẹ́ kó yára sèso; ẹni tó bá rẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tó sì tún un ṣe, ló fẹ́ kó sèso rẹpẹtẹ.”
Lẹ́yìn tó ti ṣe àpèjúwe àwọn igi tó ń gbèrú síbẹ̀ tí wọn kò sèso, ohun tó dámọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe rèé: “Ohun tó dára ni pé kí wọ́n fi ohun èlò dá ihò sára àwọn igi náà, kí wọ́n sì ki ẹ̀ka tí ewé rẹ̀ tútù yọ̀yọ̀, èyí tí wọ́n gé lára igi ólífì ìgbẹ́ bọ inú ihò náà, kí wọ́n sì dì í mọ́ ibẹ̀; ńṣe ló máa dà bí ìgbà tí wọ́n sọ òkú igi náà di alààyè, ó sì máa bẹ̀rẹ̀ sí í sèso.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ǹjẹ́ o lóye àpèjúwe igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ náà?