Ṣé O Ti Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run?
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—HÉB. 4:12.
1. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà wọnú ìsinmi Ọlọ́run lónìí, àmọ́ kí ló lè mú kí èyí ṣòro?
NÍNÚ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a ti rí i pé a lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run tá a bá ń bá a nìṣó láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tá a sì ń ṣègbọràn sí i. Àmọ́, ó lè ṣòro láti jẹ́ onígbọràn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mọ̀ pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan tá a fẹ́ràn láti máa ṣe, ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti má ṣe nǹkan náà mọ́. Ìyẹn fi hàn pé a gbọ́dọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń “múra tán láti ṣègbọràn.” (Ják. 3:17) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká máa ṣègbọràn sí òun látọkànwá. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mélòó kan tó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá lóòótọ́ la múra tán láti ṣègbọràn.
2, 3. Kí la gbọ́dọ̀ máa sapá láti ṣe ká lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra lójú Jèhófà?
2 Bó o bá rí ìmọ̀ràn kan tá a gbé karí Bíbélì gbà, ǹjẹ́ o máa ń múra tán láti tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé Ọlọ́run fẹ́ láti kó “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Hág. 2:7) Òótọ́ ni pé nígbà tí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a kì í ṣe ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra. Àmọ́, ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n mú ká ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì nínú ọ̀nà tá a gbà ń hùwà àti ọ̀nà tá a gbà ń ronú, ká bàa lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Lẹ́yìn tá a gbàdúrà tá a sì sapá gidigidi, níkẹyìn ọjọ́ aláyọ̀ náà dé tá a fínnú fíndọ̀ ṣèrìbọmi, ká lè di ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi.—Ka Kólósè 1:9, 10.
3 Àmọ́ lẹ́yìn ìrìbọmi, a ṣì gbọ́dọ̀ máa sapá kí àìpé má bàa mú ká pàdánù ojú rere Ọlọ́run. Irú ìsapá bẹ́ẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì jẹ́ aláìpé. Àmọ́, ó dá wa lójú pé bí a kò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá tá a sì pinnu láti túbọ̀ jẹ́ ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra lójú Ọlọ́run, Jèhófà á máa bù kún ìsapá wa.
Tá A Bá Nílò Ìtọ́sọ́nà
4. Ọ̀nà mẹ́ta wo la lè gbà rí ìtọ́sọ́nà látinú Ìwé Mímọ́?
4 Ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí àwọn ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí nítorí àìpé, ó yẹ ká mọ ohun tá a fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí. Tá a bá gbọ́ àsọyé kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí tó mú ká wádìí ọkàn ara wa wò tàbí tá a ka àpilẹ̀kọ kan tó mú wa ronú jinlẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, wọ́n lè jẹ́ ká rí i pé ohun kan wà tá à ń ṣe tó kù díẹ̀ káàtó. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé bá ò bá kíyè sí kókó kan tá a gbọ́ nínú àsọyé tàbí tí a kò rí bí ìtọ́ni tá a kà nínú àpilẹ̀kọ kan ṣe kàn wá, Jèhófà lè lo arákùnrin tàbí arábìnrin kan nínú ìjọ láti sọ ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí fún wa.—Ka Gálátíà 6:1.
5. Sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tí kò yẹ ká máa ṣe bí ẹnì kan bá tọ́ wa sọ́nà, kó o sì ṣàlàyé ìdí tí àwọn Kristẹni tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn fi gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti ràn wá lọ́wọ́.
5 Bó ti wù kí ẹni tá a jọ jẹ́ aláìpé fi ọgbọ́n àti ìfẹ́ tọ́ wa sọ́nà tó, kì í rọrùn fún wa láti gba ohun tó sọ. Síbẹ̀, Gálátíà 6:1 ṣàlàyé pé Jèhófà pàṣẹ fún àwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí pé kí wọ́n “gbìyànjú” láti tọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà, kí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ “nínú ẹ̀mí ìwà tútù.” Bí a bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí wọ́n fún wa, a máa túbọ̀ jẹ́ ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra lójú Ọlọ́run. Ká sì tún rántí pé, bá a bá ń gbàdúrà, a máa ń sọ fún Jèhófà pé aláìpé ni wá. Àmọ́, bí ẹnì kan bá jàjà sọ àṣìṣe wa fún wa, ńṣe la máa ń fẹ́ láti dá ara wa láre, ká ṣàlàyé pé àṣìṣe náà kò fi bẹ́ẹ̀ burú, ká sọ pé ẹni tó tọ́ wa sọ́nà yẹn kò fẹ́ràn wa ni tàbí ká sọ pé kò mọ ọ̀rọ̀ sọ. (2 Ọba 5:11) Bí ẹni tó ń tọ́ wa sọ́nà bá mẹ́nu kan ohun kan tó ká wa lára, bí ìwà tí ẹnì kan nínú ìdílé wa hù, ìwọṣọ àti ìmúra wa, ìmọ́tótó ara wa, tàbí tó bá wa sọ̀rọ̀ nípa irú eré ìnàjú kan tá a kúndùn láti máa ṣe àmọ́ tí Jèhófà kórìíra, a lè gbà á sí ìbínú. A lè má mọ̀ pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ á bí wa nínú, ohun tá a sọ sì lè ba arákùnrin tó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ lọ́kàn jẹ́! Àmọ́ lẹ́yìn tí ìbínú wa bá ti rọlẹ̀, a sábà máa ń gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó sọ.
6. Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa ń jẹ́ ká mọ “ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà”?
6 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà rán wa létí pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa “ń sa agbára.” Bó sì ṣe rí nìyẹn, torí pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè sa agbára tó lè yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà. Bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ ká tó ṣe ìrìbọmi, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Hébérù, ó tún sọ fún wọn pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Héb. 4:12) Torí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé tá a bá ti ní òye tó ṣe kedere nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe, ọ̀nà tá a bá gbà ṣe nǹkan náà ló máa sọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. A wá lè béèrè pé, Ṣé ìgbà míì máa ń wà tí ohun táwọn èèyàn ń rò pé a jẹ́ bó ti fara hàn lóde ara (ìyẹn “ọkàn”) máa ń yàtọ̀ sí ohun tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún (ìyẹn “ẹ̀mí”)? (Ka Mátíù 23:27, 28.) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ìwọ ni àwọn nǹkan tá a fẹ́ sọ yìí ṣẹlẹ̀ sí, kí lo máa ṣe?
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ètò Jèhófà Fi Ẹ́ Sílẹ̀
7, 8. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí àwọn Júù kan tó di Kristẹni kò fi jáwọ́ nínú pípa àwọn kan lára Òfin Mósè mọ́? (b) Báwo lèyí ṣe mú kí wọ́n máa ṣe ohun tó lòdì sí ọ̀nà tí ìfẹ́ Jèhófà gbà ń ní ìmúṣẹ?
7 Ọ̀pọ̀ nínú wa lè sọ ohun tó wà nínú Òwe 4:18 láìwòwé. Ó sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ ni ìwà wa á máa sunwọ̀n sí i tí òye tá a ní nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe á sì máa pọ̀ sí i.
8 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, lẹ́yìn ikú Jésù ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó di Kristẹni ṣì fẹ́ láti máa pa Òfin Mósè mọ́. (Ìṣe 21:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣe àlàyé lọ́nà tó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin mọ́, àwọn kan kọ̀ láti fara mọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí i láti bá wọn sọ. (Kól. 2:13-15) Bóyá wọ́n lérò pé, ó kéré tán, táwọn bá ń bá a nìṣó láti máa pa àwọn kan mọ́ lára Òfin Mósè, àwọn Júù tí kì í ṣe Kristẹni kò ní lè ṣe inúnibíni sáwọn. Bó ti wù kó rí, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ó sì sọ fún wọn lọ́nà tó ṣe kedere pé bí wọ́n bá ń bá a nìṣó láti máa ṣe ohun tó lòdì sí ọ̀nà tí ìfẹ́ Jèhófà gbà ń ní ìmúṣẹ, wọn kò ní lè wọnú ìsinmi rẹ̀.a (Héb. 4:1, 2, 6; ka Hébérù 4:11.) Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa gbà jọ́sìn òun ti yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
9. Bí ẹrú olóòótọ́ àti olóye bá ṣàtúnṣe òye tá a ní nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ojú wo ló yẹ ká fi wo àtúnṣe náà?
9 Lónìí, àwọn ìgbà míì wà tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye máa ń mú kí ọ̀nà tá a gbà lóye àwọn ẹ̀kọ́ kan tí Bíbélì fi kọ́ni sunwọ̀n sí i. Kò yẹ ká dààmú nítorí èyí; ńṣe ló yẹ kí èyí mú ká túbọ̀ fọkàn tán ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà. Nígbà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú fún “ẹrú” náà bá fi òye mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n mú kí ẹ̀kọ́ kan tí Bíbélì fi kọ́ni túbọ̀ ṣe kedere tàbí kí wọ́n ṣàtúnṣe òye tá a ní nípa irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, wọn kì í fà sẹ́yìn láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Ẹgbẹ́ ẹrú náà mọ̀ pé àwọn kan lè sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa àwọn nítorí irú àwọn àtúnṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò ka ìyẹn sí pàtàkì. Ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì jù lọ ni pé káwọn má ṣe ṣe ohun tó lòdì sí ọ̀nà tí ìfẹ́ Ọlọ́run gbà ń ní ìmúṣẹ. Bí ẹrú olóòótọ́ àti olóye bá ṣàtúnṣe òye tá a ní nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ojú wo ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan fi ń wo irú àtúnṣe bẹ́ẹ̀?—Ka Lúùkù 5:39.
10, 11. Nígbà tí ètò Ọlọ́run sọ ọ̀nà tuntun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà á máa gbà wàásù, kí làwọn kan ṣe, kí la sì lè rí kọ́ látinú ohun tí wọ́n ṣe?
10 Ẹ jẹ́ ká tún ronú lórí àpẹẹrẹ mìíràn. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí wọ́n mọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn sọ dáadáa rò pé ọ̀nà tó dára jù lọ táwọn lè máa gbà ṣe iṣẹ́ ìwàásù ni pé káwọn máa sọ àsọyé Bíbélì táwọn ti múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa níwájú àwùjọ èèyàn tó mọyì irú àsọyé bẹ́ẹ̀. Ó máa ń dùn mọ́ wọn láti máa sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, àwọn kan lára wọn sì fẹ́ràn káwọn èèyàn máa yìn wọ́n torí irú àsọyé bẹ́ẹ̀. Àmọ́, nígbà tó yá, ó túbọ̀ yé àwọn èèyàn Ọlọ́run pé kì í ṣe àsọyé nìkan ni Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa sọ, ó tún fẹ́ kí ọwọ́ wọ́n dí fún wíwàásù ní onírúurú ọ̀nà, tó fi mọ́ lílọ láti ilé dé ilé. Àwọn kan lára àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ yẹn kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ohun tó yàtọ̀. Ẹni bá ń wò wọ́n á rò pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, pé gbogbo ọkàn pátá ni wọ́n fi ń sin Olúwa. Àmọ́, nígbà tó ṣe kedere sí wọn pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ni irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tó fára hàn. Ṣé inú Jèhófà dùn sí ohun tí wọ́n ṣe yìí? Rárá o. Wọn kò rí ìbùkún Jèhófà gbà. Wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀.—Mát. 10:1-6; Ìṣe 5:42; 20:20.
11 Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ó rọrùn fún gbogbo àwọn tó fara mọ́ ohun tí ètò Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n máa wàásù láti ilé dé ilé. Ó kọ́kọ́ ṣòro fún ọ̀pọ̀ lára wọn, pàápàá ní ìbẹ̀rẹ̀. Àmọ́ wọ́n ṣègbọràn. Nígbà tó ṣe, wọ́n borí àníyàn wọn, Jèhófà sì bù kún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí ẹrú olóòótọ́ àti olóye bá sọ pé kí ìwọ náà ṣe irú iṣẹ́ ìwàásù kan tí kò mọ́ ẹ lára ńkọ́, kí lo máa ṣe? Ṣé o máa fẹ́ láti dán ohun tó yàtọ̀ sí ohun tó o ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ wò?
Bí Èèyàn Wa Kan Bá Fi Jèhófà Sílẹ̀
12, 13. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ká máa yọ oníwà-àìtọ́ tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́? (b) Kí ló máa ń dán ìdúróṣinṣin àwọn òbí kan tó jẹ́ Kristẹni wò, kí ló sì máa ń mú kó ṣòro fún wọn láti borí ìdánwò náà?
12 Ó dájú pé gbogbo wa la gbà pé ká bàa lè máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nípa tara, nínú ọ̀nà tá a gbà ń hùwà àti nípa tẹ̀mí. (Ka Títù 2:14.) Àmọ́, àwọn ìgbà míì máa ń wà tí ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run láwọn ọ̀nà yìí lè dán ìdúróṣinṣin wa wò. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé tọkọtaya kan tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ wà nínú ìjọ, ọmọkùnrin wọn kan ṣoṣo wá kúrò nínú òtítọ́. Ó yàn láti jẹ “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,” dípò kó ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà àti pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, torí náà, wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.—Héb. 11:25.
13 Ọ̀rọ̀ náà ba àwọn òbí rẹ̀ lọ́kàn jẹ́! Wọ́n mọ ohun tí ìyọlẹ́gbẹ́ túmọ̀ sí. Wọ́n mọ̀ pé Bíbélì sọ pé ká “jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí [a] má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.” (1 Kọ́r. 5:11, 13) Wọ́n sì tún mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà, “ẹnikẹ́ni” tí Pọ́ọ̀lù lò nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn lè túmọ̀ sí ẹni tó jẹ́ ara ìdílé wọn ṣùgbọ́n tí kò gbé nínú ilé kan náà pẹ̀lú wọn. Síbẹ̀, tọkọtaya yìí nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn gan-an! Ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí i yìí mú kí wọ́n ronú pé: ‘Báwo la ṣe lè ran ọmọ wa lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà bí a bá dín àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ kù? Ṣé kì í ṣe pé tá a bá ń kàn sí i déédéé la máa lè ràn án lọ́wọ́ láti pa dà sínú ètò Ọlọ́run?’b
14, 15. Ìpinnu pàtàkì wo làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n bá yọ ọmọ wọn lẹ́gbẹ́?
14 Ipò tí irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ bá ara wọn kò dùn mọ́ wa nínú. Ọmọ wọ́n ní òmìnira láti yan ohun tó wù ú. Ṣùgbọ́n ńṣe ló yàn láti máa gbé ìgbé ayé tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu dípò tí ì bá fi máa gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ nìṣó pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Ó wu àwọn òbí náà pé kí wọ́n ran ọmọ wọn lọ́wọ́, àmọ́ wọn kò lè bá a pinnu ohun tó máa ṣe. Ìyẹn ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà dùn wọ́n gan-an.
15 Kí wá ni arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n tí wọ́n jẹ́ òbí ọmọ náà máa ṣe báyìí? Ṣé wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà ṣíṣe kedere tí Jèhófà fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn náà? Àbí wọ́n á ronú pé àwọn lè máa bá ọmọ wọn tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà sọ ohun tí wọ́n kà sí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó jẹ mọ́ ti ìdílé déédéé? Bí wọ́n bá ń pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, wọn kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láti ronú lórí ohun tí Jèhófà máa fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ohun tó fẹ́ ni pé kí ètò rẹ̀ wà ní mímọ́, bó bá sì ṣeé ṣe, ká ran àwọn oníwà àìtọ́ lọ́wọ́ láti pé orí ara wọn wálé. Báwo làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè fi hàn pé ohun tó wu Jèhófà làwọn ń fẹ́?
16, 17. Tá a bá ronú lórí àpẹẹrẹ Áárónì, kí la lè rí kọ́?
16 Áárónì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè bá ara rẹ̀ nínú ipò tó ṣòro nítorí ohun tí méjì nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe. Ronú nípa bó ṣe máa rí lára rẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀, Nádábù àti Ábíhù rú ẹbọ tí kò bá ìlànà mu sí Jèhófà, tí Jèhófà sì pa wọ́n. Ikú àwọn ọmọ náà fòpin sí àjọṣe èyíkéyìí tí wọ́n lè ní pẹ̀lú àwọn òbí wọn. Síbẹ̀, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ ṣòro fún Áárónì àti ìdílé rẹ̀. Jèhófà pàṣẹ fún òun àti àwọn méjì yòókù tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ banú jẹ́ nítorí wọn. Ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí orí yín wà láìtọ́jú, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ya ẹ̀wù yín [torí pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀], kí ẹ má bàa kú, kí ìkannú [Jèhófà] má bàa ru sí gbogbo àpéjọ yìí.” (Léf. 10:1-6) Ẹ̀kọ́ tí èyí kọ́ wa ṣe kedere. Ẹ̀kọ́ náà sì ni pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ lágbára ju ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ìbátan wa tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Jèhófà.
17 Lónìí, Jèhófà kì í pa àwọn tó bá rú òfin rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó máa ń fún wọn láǹfààní láti ronú pìwà dà kúrò nínú ìwà àìṣòdodo wọn. Àmọ́, bí àwọn òbí oníwà àìtọ́ kan tí kò ronú pìwà dà bá ń bá a nìṣó láti máa dán Jèhófà wò nípa bíbá ọmọ wọn ọkùnrin tàbí obìnrin tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ sọ̀rọ̀ déédéé, ojú wo ni Jèhófà máa fi wò wọ́n?
18, 19. Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá fara mọ́ ìtọ́ni Jèhófà nípa àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́, ìbùkún wo ni wọ́n máa rí gbà?
18 Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ rí máa ń gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbà wọ́n pa dà pé ohun tó mú káwọn tètè pe orí ara àwọn wálé ni pé àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìbátan àwọn fọwọ́ pàtàkì mú àṣẹ Ọlọ́run pé wọn kò gbọ́dọ̀ kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́. Nígbà táwọn alàgbà kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn fẹ́ gba ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ pa dà, wọ́n sọ pé “lára ohun” tó mú kó tún ọ̀ràn ara rẹ̀ ṣe ni pé “ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà nípa àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́.” Ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún àwọn alàgbà pé “bí ẹ̀gbọ́n mi ṣe fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wà lára ohun tó mú kí n fẹ́ láti pa dà.”
19 Kí la rí kọ́ nínú èyí? Pé a gbọ́dọ̀ jà fitafita ká máa bàa fàyè gba ọkàn-àyà àìpé wa tó lè mú ká ṣe ohun tó lòdì sí ìtọ́sọ́nà látinú Ìwé Mímọ́. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú hán-únhán-ún pé ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà yanjú àwọn ìṣòro wa ló dára jù lọ.
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè”
20. Ọ̀nà méjì wo la lè gbà lóye ohun tó wà nínú Hébérù 4:12? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
20 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “ọ̀rọ̀ ọlọ́run yè,” kì í ṣe Bíbélì ló ń tọ́ka sí ní tààràtà.c Àwọn ẹsẹ míì nínú orí yẹn fi hàn pé ìlérí Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ohun tó sì ń sọ ni pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti ṣèlérí ohun kan, kì í gbàgbé ìlérí tó ṣe. Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, Jèhófà sọ nípa ọ̀rọ̀ tó bá ti ẹnu rẹ̀ jáde pé: “Ọ̀rọ̀ mi . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n . . . yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísá. 55:11) Torí náà, kò sí ìdí fún wa láti máa kánjú bí Ọlọ́run kò bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nígbà tá a fọkàn sí. Jèhófà ‘ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́’ kó bàa lè ṣe àṣeparí àwọn ohun tó ní lọ́kàn.—Jòh. 5:17.
21. Báwo ni ohun tó wà nínú Hébérù 4:12 ṣe lè fún àwọn tó ti dàgbà lára àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ní ìṣírí?
21 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn tó ti dàgbà lára àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀. (Ìṣí. 7:9) Ọ̀pọ̀ lára wọn kò lérò pé àwọn máa darúgbó nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Síbẹ̀, wọn kò rẹ̀wẹ̀sì. (Sm. 92:14) Wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè àti pé àwọn ìlérí rẹ̀ kò ní ṣaláì ní ìmúṣẹ. Wọ́n sì tún mọ̀ pé Jèhófà ń ṣiṣẹ́ kó bàa lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Níwọ̀n bí Ọlọ́run sì ti máa ń fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ohun tó fẹ́ ṣe, inú rẹ̀ máa ń dùn bí àwa náà bá fọwọ́ pàtàkì mú un. Ní ọjọ́ keje tí Jèhófà fi ń sinmi yìí, kò sí ohunkóhun tó máa dá a dúró láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó sì mọ̀ pé àwọn èèyàn òun lápapọ̀ á fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú òun. Ìwọ ńkọ́? Ṣé o ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run?
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù máa ń pa Òfin Mósè mọ́ fínnífínní, àmọ́ nígbà tí Mèsáyà dé, wọn kò gbà pé òun ni. Wọ́n kùnà láti fara mọ́ ọ̀nà tí ìfẹ́ Ọlọ́run gbà ń ní ìmúṣẹ.
c Lónìí, Ọlọ́run máa ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó lè yí ìgbésí ayé wa pa dà, láti bá wa sọ̀rọ̀. Torí náà, ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Hébérù 4:12 yìí tún kan Bíbélì.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run lónìí?
• Tá a bá múra tán láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ báwo nìyẹn ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ láti ṣe ohun tó wu Ọlọ́run?
• Ìgbà wo ló lè ṣòro fún wa láti ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, àmọ́ kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣègbọràn?
• Ọ̀nà méjì wo la lè gbà lóye ohun tó wà nínú Hébérù 4:12?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ọ̀rọ̀ náà ba àwọn òbí rẹ̀ lọ́kàn jẹ́!