Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?
“Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—ÉFÉ. 5:10.
1, 2. (a) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa? (b) Bí a bá ka eré ìtura sí “ẹ̀bùn Ọlọ́run,” kí la máa ṣe?
ÀWỌN ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká máa wà láàyè ká sì tún máa gbádùn ìgbésí ayé wa fara hàn léraléra nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 104:14, 15 sọ pé Jèhófà ń mú kí “oúnjẹ jáde wá láti inú ilẹ̀, àti wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀, láti mú kí òróró máa mú ojú dán, àti oúnjẹ tí ń gbé ọkàn-àyà ẹni kíkú ró.” Dájúdájú, Jèhófà ń mú kí àwọn irúgbìn dàgbà kí wọ́n lè mú ọkà, òróró àti wáìnì jáde fún ìlò wa. Àmọ́, wáìnì tún máa ‘ń mú ọkàn-àyà yọ̀.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan ká mu wáìnì ká tó lè máa wà láàyè, ó máa ń fi kún ayọ̀ wa. (Oníw. 9:7; 10:19) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀, kí ọkàn-àyà wa sì kún fún “ìmóríyágágá.”—Ìṣe 14:16, 17.
2 Torí náà, kò sí ìdí tó fi yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi tá a bá ń wáyè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti “fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run” àti “àwọn òdòdó lílì pápá” tàbí ká lè ṣe àwọn nǹkan míì tó máa mára tù wá tó sì máa mú kára wá jí pépé. (Mát. 6:26, 28; Sm. 8:3, 4) Ìgbésí ayé tó gbámúṣé jẹ́ “ẹ̀bùn Ọlọ́run.” (Oníw. 3:12, 13) Bá a bá wo àkókò tí ọwọ́ wa dilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan lára ẹ̀bùn yẹn, a ó lè lò ó lọ́nà tó máa mú inú Ọlọ́run tó fún wa lẹ́bùn náà dùn.a
Bá A Ṣe Lè Yan Èyí Tó Tọ́ Lára Ọ̀pọ̀ Eré Ìtura Tó Wà
3. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé onírúurú eré ìtura ló wà?
3 Àwọn tí wọ́n ń fi ojú tó tọ́ wo eré ìtura gbà pé onírúurú eré ìtura ló wà, síbẹ̀ wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn yan èyí tó tọ́. Kí nìdí? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká fi eré ìtura wé oúnjẹ. Àwọn oúnjẹ tó wọ́pọ̀ ní àgbègbè kan yàtọ̀ sí èyí tó wọ́pọ̀ ní àgbègbè míì, bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe rí kárí ayé. Kódà, oúnjẹ tí àwọn tó ń gbé lápá ibì kan kúndùn láti máa jẹ lè má fi bẹ́ẹ̀ wu àwọn tó ń gbé lápá ibòmíì. Lọ́nà kan náà, ohun táwọn Kristẹni tó wà lápá ibì kan lágbàáyé kà sí eré ìtura tó gbádùn mọ́ni lè má wu àwọn Kristẹni tó ń gbé lápá ibòmíì. Kódà, láàárín àwọn Kristẹni tó ń gbé lápá ibì kan náà, ohun tó máa ń gbádùn mọ́ ẹnì kan (bóyá kíka ìwé aládùn), lè máa sú ẹlòmíì; ohun tó ń tu ẹnì kan lára (bóyá kó máa gun kẹ̀kẹ́ najú káàkiri), lè jẹ́ ohun tó máa ń mú kó rẹ ẹlòmíì. Síbẹ̀, a gbà pé bí onírúurú oúnjẹ ṣe wà bẹ́ẹ̀ náà ni onírúurú eré ìtura wà, olúkúlùkù sì lè yan èyí tó fẹ́.—Róòmù 14:2-4.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká rí i dájú pé irú eré ìtura tó tọ́ la yàn? Ṣàpèjúwe.
4 Àmọ́, ti pé onírúurú eré ìtura ló wà kò fún wa lómìnira láti máa ṣe eré ìtura èyíkéyìí tó bá ṣáà ti wù wá. Ẹ jẹ́ ká tún pa dà sórí àpèjúwe oúnjẹ tá a mú wá lẹ́ẹ̀kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè wù wá láti máa jẹ oríṣiríṣi oúnjẹ, a kò ní mọ̀ọ́mọ̀ jẹ oúnjẹ tó ti jẹrà. Kò bọ́gbọ́n mu láti jẹ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ó sì lè ṣàkóbá fún ìlera wa. Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú eré ìtura tó gbámúṣé ló wà, a kò ní máa lọ́wọ́ sáwọn eré tó lè fi ẹ̀mí wewu, èyí tó ní ìwà ipá nínú, tàbí èyí tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Kò bá ìlànà Bíbélì mu pé kéèyàn máa lọ́wọ́ nínú irú àwọn eré bẹ́ẹ̀, wọ́n lè ṣèpalára fún wa tàbí kí wọ́n bá àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Kó lè dá wa lójú pé eré ìtura tó tọ́ la yàn, ó máa dára ká ti pinnu ṣáájú bóyá irú eré ìtura kan tá a fẹ́ ṣe máa ṣe wá láǹfààní tàbí ó máa pa wá lára. (Éfé. 5:10) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
5. Báwo la ṣe lè pinnu bóyá eré ìtura tá a yàn bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu?
5 Kí eré ìtura bàa lè ṣe wá láǹfààní kó sì dára lójú Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ bá àwọn ìlànà pàtó tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. (Sm. 86:11) Kó o lè pinnu bóyá irú eré ìtura tó o fẹ́ràn bá ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, o lè ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí wàá máa tẹ̀ lé. Ó lè dá lórí àwọn ìbéèrè mẹ́ta kan tí wàá máa gbé yẹ̀ wò. Irú bíi, kí ni, ìgbà wo àti àwọn wo. Ẹ jẹ́ ká gbé wọn yẹ̀ wò níkọ̀ọ̀kan.
Kí Ni Eré Náà Ní Nínú?
6. Eré ìtura wo ni a kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí, kí sì nìdí?
6 Kó o tó ṣe irú eré ìtura kan, ìbéèrè tó yẹ kó o kọ́kọ́ bi ara rẹ ni pé, Kí ni? Ìyẹn ni pé, ‘Kí ni eré ìtura tó ń wù mí náà ní nínú?’ Bó o ṣe ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ó dára kó o fi sọ́kàn pé ọ̀nà méjì ni eré ìtura sábà máa ń pín sí. Èyí àkọ́kọ́ ni eré ìtura tí a kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí; ìkejì ni èyí tó ṣeé ṣe ká lọ́wọ́ sí. Kí ni irú eré ìtura àkọ́kọ́? Nínú ayé burúkú yìí, ọ̀pọ̀ eré ìtura ló máa ń kún fún àwọn ìgbòkègbodò tó lòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì tàbí tí kò bá òfin Ọlọ́run mu. (1 Jòh. 5:19) Àwọn Kristẹni tòótọ́ kò jẹ́ lọ́wọ́ sí èyíkéyìí lára irú eré ìtura bẹ́ẹ̀. Lára irú eré ìtura bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tó ní ìwà ìkà, ìbẹ́mìílò, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, tàbí ìwà ipá nínú, tàbí èyí tó ń gbé àwọn ìwà míì tó ń ríni lára tàbí ìṣekúṣe lárugẹ. (1 Kọ́r. 6:9, 10; ka Ìṣípayá 21:8.) Ibi yòówù ká máa gbé, ńṣe là ń fi han Jèhófà pé a “kórìíra ohun burúkú” tá a bá kọ̀ láti ṣe èyíkéyìí lára irú eré ìtura bẹ́ẹ̀.—Róòmù 12:9; 1 Jòh. 1:5, 6.
7, 8. Báwo la ṣe lè mọ bí eré ìtura kan ṣe gbámúṣé tó? Ṣàkàwé.
7 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa oríṣi eré ìtura kejì. Èyí jẹ́ irú àwọn eré ìnàjú téèyàn máa ń ṣe bọ́wọ́ bá dilẹ̀, àmọ́ tí wọn kò ní àwọn ìwà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ní tààràtà pé kò dáa nínú. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ká tó yan irú eré ìtura bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi ìṣọ́ra gbé e yẹ̀ wò, ká lè mọ̀ bóyá ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jèhófà kà sí eré tó gbámúṣé, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìlànà Bíbélì. (Òwe 4:10, 11) Lẹ́yìn náà, a gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó máa jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn rere. (Gál. 6:5; 1 Tím. 1:19) Báwo la ṣe lè ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀? Ro èyí wò ná: Ká tó jẹ irú oúnjẹ kan tí a kò jẹ rí, a máa kọ́kọ́ fẹ́ láti mọ àwọn èròjà tó wà nínú oúnjẹ náà. Bákan náà, ká tó lọ́wọ́ nínú irú eré ìtura kan, a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí eré náà ní nínú.—Éfé. 5:17.
8 Bí àpẹẹrẹ, o lè fẹ́ràn eré ìdárayá, ó sì rọrùn láti lóye ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Eré ìdárayá máa ń gbádùn mọ́ni. Àmọ́, bó bá wá jẹ́ pé ohun tó ń mú kí eré ìdárayá kan wù ẹ́ ni pé wọ́n máa ń bára wọn díje kí wọ́n lè borí ní gbogbo ọ̀nà, wọ́n ń fẹ̀mí ara wọn wewu, wọ́n ń ṣera wọn léṣe gan-an, wọ́n ń ṣe ayẹyẹ aláriwo, wọ́n ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè lárugẹ, tí wọ́n sì ń ṣe irú àwọn nǹkan míì tó fara jọ ìyẹn ńkọ́? Lẹ́yìn tó o bá ti gbé gbogbo ohun tó wé mọ́ ọn yẹ̀ wò, ó ṣeé ṣe kó o pinnu pé eré ìdárayá náà kò bá ìfẹ́ Jèhófà mu, ó sì lòdì sí ìhìn rere àlàáfíà àti ìfẹ́ tá à ń wàásù rẹ̀ fáwọn èèyàn. (Aísá. 61:1; Gál. 5:19-21) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, bó bá jẹ́ pé ohun tí Jèhófà máa kà sí ìgbòkègbodò tó gbámúṣé ló wà nínú eré ìnàjú kan, a jẹ́ pé irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ á ṣe ẹ́ láǹfààní ó sì máa tù ẹ́ lára.—Gál. 5:22, 23; ka Fílípì 4:8.
Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí N Ṣe Irú Eré Ìnàjú Bẹ́ẹ̀?
9. Báwo ni ohun tó wà lọ́kàn wa ṣe lè hàn kedere nínú ìdáhùn wa sí ìbéèrè náà, ‘Ìgbà wo ló yẹ kí n ṣe eré ìnàjú?’
9 Ìbéèrè kejì tó yẹ kó o bi ara rẹ ni pé, Ìgbà wo? Ìyẹn ni pé, ‘Ìgbà wo ló yẹ kí n ṣe eré ìnàjú? Báwo ló ṣe yẹ kí n pẹ́ nídìí eré náà tó?’ Ìdáhùn wa sí ìbéèrè náà kí ni? máa sọ púpọ̀ nípa ohun tó ń wù wá, ìyẹn ni ohun tá a kà sí èyí tó ṣètẹ́wọ́gbà àti èyí tí kò ṣètẹ́wọ́gbà. Àmọ́ ṣá o, ìdáhùn wa sí ìbéèrè náà ìgbà wo? ló ń sọ ohun tá a fi sípò àkọ́kọ́, ìyẹn ohun tá a kà sí pàtàkì àti ohun tí a kò kà sí pàtàkì. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ọwọ́ tá a fi mú eré ìtura kò ṣe pàtàkì ju bó ṣe yẹ lọ?
10, 11. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 6:33 ṣe lè mú ká pinnu ìwọ̀n àkókò tó yẹ ká máa lò nídìí eré ìtura?
10 Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Torí náà, ohun tó gbọ́dọ̀ wà nípò àkọ́kọ́ ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà. Ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé ìfẹ́ fún Jèhófà ló wà nípò àkọ́kọ́ ni pé ká máa ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mát. 6:33) Báwo ni gbólóhùn yẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bí a ó ṣe máa pẹ́ nídìí eré ìtura tó àti bí a ṣe máa kà á sí pàtàkì tó?
11 Fiyè sí àwọn kókó pàtàkì yìí nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ. Ó gbà wá níyànjú pé: ‘Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’ Kò sọ fún wa pé ká ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà nìkan ṣoṣo.’ Ó dájú nígbà náà pé Jésù mọ̀ pé ní àfikún sí wíwá Ìjọba Ọlọ́run, ó máa pọn dandan ká wá ọ̀pọ̀ nǹkan míì nínú ìgbésí ayé. A nílò ilé, oúnjẹ, aṣọ, ẹ̀kọ́ ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, eré ìnàjú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, lára gbogbo ohun tá à ń wá, ọ̀kan ló gbawájú ju gbogbo wọn lọ, ìyẹn ni àwọn ohun tó kan Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 7:29-31) Òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro yìí yẹ kó máa mú ká ṣe àwọn ohun tó yẹ ká fi sípò kejì, tó fi mọ́ eré ìnàjú, lọ́nà tí kò fi ní pa ohun tó yẹ kó wà nípò àkọ́kọ́ lára, ìyẹn bíbójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, eré ìnàjú tí kò pọ̀ jù lè ṣe wá láǹfààní.
12. Báwo la ṣe lè lo ìlànà tó wà nínú Lúùkù 14:28 tá a bá fẹ́ ṣèpinnu nípa eré ìnàjú?
12 Torí náà, ká tó ṣèpinnu nípa eré ìnàjú, ó yẹ ká kọ́kọ́ gbéṣirò lé àkókò tó máa ná wa. (Lúùkù 14:28) A gbọ́dọ̀ mọ bí àkókò tá a ó fi máa ṣeré ìnàjú náà á ṣe pọ̀ tó. Lẹ́yìn náà, a gbọ́dọ̀ pinnu ìwọ̀n àkókò tó yẹ kó máa gbà lọ́wọ́ wa. Bó bá jẹ́ pé lílọ́wọ́ sí eré ìnàjú kan á mú ká máa pa àwọn ìgbòkègbodò tó ṣe pàtàkì tì, irú bí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ìjọsìn Ìdílé, lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ, tàbí lílọ sóde ẹ̀rí, ohun tírú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ fẹ́ gbà lọ́wọ́ wa ti pọ̀ jù nìyẹn. (Máàkù 8:36) Àmọ́, bí eré ìnàjú kan tá à ń ṣe lóòrèkóòrè bá ń fún wa lókun tó ń mú ká lè máa lépa àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, a lè gbà pé a lo àkókò tá a fi ń ṣe irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó ṣàǹfààní.
Àwọn Wo La Jọ Ń Ṣeré Ìtura?
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká fara balẹ̀ ronú nípa àwọn tá a jọ ń ṣeré ìnàjú?
13 Ìbéèrè kẹta tó yẹ kó o bí ara rẹ̀ ni pé, Àwọn wo ni? Ìyẹn ni pé, ‘Àwọn wo la ó jọ máa ṣeré ìtura?’ Ó ṣe pàtàkì ká ronú lórí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé bí ìwà àwọn tá a jọ ń ṣeré ìnàjú bá dáa, ìyẹn máa nípa lórí bí eré ìnàjú tá a jọ ń ṣe á ṣe dáa tó. Bí oúnjẹ ṣe sábà máa ń gbádùn mọ́ ẹ bí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà bá jọ jẹ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ gbádùn eré ìnàjú bí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà bá jọ ṣe é. Torí náà, ó rọrùn láti lóye ìdí tó fi máa ń gbádùn mọ́ ọ̀pọ̀ lára wa, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀dọ́, láti máa bá àwọn míì ṣeré ìnàjú. Àmọ́, ká lè rí i dájú pé ìgbòkègbodò kan máa ṣe wá láǹfààní, ó bọ́gbọ́n mu ká ti kọ́kọ́ pinnu irú àwọn èèyàn tó yẹ ká yàn lọ́rẹ̀ẹ́ àti irú àwọn tó yẹ ká sá fún.—2 Kíró. 19:2; ka Òwe 13:20; Ják. 4:4.
14, 15. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa nípa àwọn tá a bá máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́?
14 Ó máa ṣàǹfààní gan-an pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tá a bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́. Látìgbà ìṣẹ̀dá ni Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (Òwe 8:31) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi ìfẹ́ hàn sí onírúurú èèyàn. (Mát. 15:29-37) Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù bá gbogbo èèyàn lò bí ọ̀rẹ́, kò sọ ara rẹ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú gbogbo èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mú ẹnikẹ́ni ní ọ̀tá, àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun pàtó kan ló ń bá ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Nígbà tí Jésù ń bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ mọ́kànlá sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòh. 15:14; tún wo Jòh. 13:27, 30.) Kìkì àwọn tó tọ Jésù lẹ́yìn tí wọ́n sì sin Jèhófà ni Jésù yàn lọ́rẹ̀ẹ́.
15 Torí náà, bó o bá ń ronú bóyá kó o sọ ẹnì kan di ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tàbí kò yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa bọ́gbọ́n mu kó o fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sọ́kàn. Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ǹjẹ́ ẹni yìí ń fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà rẹ̀ pé òun ń ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà àti ti Jésù? Ǹjẹ́ ó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tó sì ń fi àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ṣèwà hù bíi tèmi? Bí a bá jọ da nǹkan pọ̀, ṣé á máa fún mi níṣìírí kí n lè máa fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi kí n sì jẹ́ ìránṣẹ́ tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà?’ Bó bá dá ẹ lójú pé bẹ́ẹ̀ ni lo máa dáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, a jẹ́ pé o ti rí ọ̀rẹ́ rere tí ẹ̀yin méjèèjì lè jọ máa gbádùn eré ìtura nígbà tọ́wọ́ rẹ bá dilẹ̀ nìyẹn.—Ka Sáàmù 119:63; 2 Kọ́r. 6:14; 2 Tím. 2:22.
Ṣé Eré Ìnàjú Wá Bá Àwọn Ìlànà Bíbélì Mu?
16. Tá a bá fẹ́ ṣeré ìtura, kí ló yẹ ká bi ara wa?
16 A ti gbọ́ àlàyé ṣókí lórí ohun mẹ́ta tó yẹ ká mọ̀ nípa eré ìtura, ìyẹn bó ṣe gbámúṣé tó, bó ṣe máa gbàkókò sí àtàwọn tó yẹ ká jọ máa ṣe é. Ká bàa lè jàǹfààní látinú eré ìtura, a gbọ́dọ̀ rí i pé ó bá ohun tí ìlànà Bíbélì sọ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan lára apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí mu. Torí náà, ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe eré ìnàjú èyíkéyìí, àwọn ìbéèrè kan wà tá a gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn sí. Ní ti bó ṣe gbámúṣé sí, a fẹ́ láti bi ara wa pé: ‘Kí ló ní nínú? Ṣé ó bójú mu àbí kò bójú mu?’ (Òwe 4:20-27) Ní ti bó ṣe máa gbàkókò sí, a fẹ́ láti bi ara wa pé: ‘Báwo ni màá ṣe máa pẹ́ nídìí rẹ̀ tó? Ṣé kò ní gba àkókò tó pọ̀ jù àbí ó máa gba àkókò tó pọ̀ jù?’ (1 Tím. 4:8) Ní ti àwọn tá a ó jọ máa ṣe é, ó tọ́ ká béèrè pé: ‘Èmi àti àwọn wo la ó jọ máa ṣe eré ìtura náà? Ṣé ọ̀rẹ́ rere ni wọ́n àbí wọn kì í ṣe ọ̀rẹ́ rere?’—Oníw. 9:18; 1 Kọ́r. 15:33.
17, 18. (a) Kí la lè ṣe ká lè mọ̀ bóyá eré ìtura tá a yàn bá àwọn ìlànà Bíbélì mu? (b) Kí ni ìwọ fúnra rẹ ti pinnu láti ṣe bó o bá fẹ́ yan eré ìtura?
17 Bí eré ìtura kan kò bá bá ohun tí ìlànà Bíbélì sọ nípa èyíkéyìí lára àwọn ohun mẹ́ta yìí mu, a jẹ́ pé irú eré ìtura bẹ́ẹ̀ kò gbámúṣé nìyẹn. Àmọ́, bó bá dá wa lójú pé àwọn eré tá a fẹ́ máa ṣe nígbà tọ́wọ́ wa bá dilẹ̀ bá ohun tí ìlànà Bíbélì sọ nípa àwọn ohun mẹ́ta náà mu, a jẹ́ pé eré ìnàjú tá a yàn á máa fi ògo fún Jèhófà nìyẹn, ó sì máa ṣe wá láǹfààní.—Sm. 119:33-35.
18 Torí náà, tá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú, ẹ jẹ́ ká sapá láti ṣe ohun tó tọ́, ní àkókò tó tọ́ àti pẹ̀lú àwọn èèyàn tó tọ́. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu látọkàn wá pé a ó máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 10:31.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, níbi tá a bá ti lo ọ̀rọ̀ náà, “eré ìnàjú” àti “eré ìtura” ohun tó ń tọ́ka sí ni àkókò tá à ń yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò tó ń mára tù wá, èyí tá a máa ń ṣe nígbà tí ọwọ́ wá bá dilẹ̀.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
Bó o bá fẹ́ yan eré ìnàjú, báwo lo ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò . . .
• Fílípì 4:8?
• Mátíù 6:33?
• Òwe 13:20?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
✔Kí ni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
✔Ìgbà wo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
✔Àwọn wo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tá a bá fẹ́ yan àwọn ọ̀rẹ́ wa àti irú eré tá a ó máa ṣe bí ọwọ́ wa bá dilẹ̀?