Oníwàásù
3 Ohun gbogbo ni àkókò wà fún,
Àkókò wà fún gbogbo iṣẹ́ lábẹ́ ọ̀run:
2 Ìgbà bíbímọ àti ìgbà kíkú;
Ìgbà gbígbìn àti ìgbà fífa ohun tí a gbìn tu;
3 Ìgbà pípa àti ìgbà wíwòsàn;
Ìgbà wíwólulẹ̀ àti ìgbà kíkọ́;
4 Ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín;
Ìgbà pípohùnréré ẹkún àti ìgbà jíjó;*
5 Ìgbà jíju òkúta sọ nù àti ìgbà kíkó òkúta jọ;
Ìgbà gbígbánimọ́ra àti ìgbà téèyàn ò ní gbáni mọ́ra;
6 Ìgbà wíwá àti ìgbà gbígbà pé ó ti sọ nù;
Ìgbà fífi pa mọ́ àti ìgbà jíjù sọ nù;
8 Ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra;+
Ìgbà ogun àti ìgbà àlàáfíà.
9 Kí ni èrè tí òṣìṣẹ́ rí jẹ látinú gbogbo ìsapá rẹ̀?+ 10 Mo ti rí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún ọmọ aráyé láti mú kí ọwọ́ wọn dí. 11 Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente* ní ìgbà tirẹ̀.+ Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.
12 Mo ti wá rí i pé kò sí ohun tó dáa fún wọn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ayé wọn,+ 13 àti pé kí kálukú máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.+
14 Mo ti wá mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ ṣe máa wà títí láé. Kò sí nǹkan kan tí a máa fi kún un, kò sì sí nǹkan kan tí a máa yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe é bẹ́ẹ̀ kí àwọn èèyàn lè máa bẹ̀rù rẹ̀.+
15 Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí, ohun tó sì ń bọ̀ ti wà tẹ́lẹ̀;+ àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ń wá ohun tí a ti lépa.*
16 Mo tún ti rí i lábẹ́ ọ̀run* pé: Ìwà burúkú ti rọ́pò ìdájọ́ òdodo, ìwà burúkú sì ti rọ́pò òdodo.+ 17 Torí náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ẹni burúkú,+ nítorí àkókò wà fún gbogbo iṣẹ́ àti gbogbo akitiyan.”
18 Mo tún sọ nípa àwọn ọmọ aráyé lọ́kàn mi pé Ọlọ́run tòótọ́ máa dán wọn wò, á sì jẹ́ kí wọ́n rí i pé bí ẹranko ni wọ́n rí, 19 nítorí pé ohun* kan wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn, ohun kan sì wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko; ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ Bí ọ̀kan ṣe ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní.+ Torí náà, èèyàn kò lọ́lá ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni ohun gbogbo. 20 Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ.+ Inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá,+ inú erùpẹ̀ sì ni gbogbo wọn ń pa dà sí.+ 21 Ta ló mọ̀ bóyá ẹ̀mí èèyàn ń lọ sí òkè tàbí ẹ̀mí ẹranko ń lọ sí ilẹ̀?+ 22 Mo sì rí i pé kò sí ohun tó dáa fún èèyàn ju pé kó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀,+ nítorí ìyẹn ni èrè* rẹ̀; torí ta ló lè mú kó rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti lọ?+