Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà Kí O sì Gba Ìbùkún
“Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere.”—SM. 106:1.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?
JÈHÓFÀ ló ń fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé,” torí náà ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Ják. 1:17) Olùṣọ́ Àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, ó ń pèsè àwọn ohun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí fún wa. (Sm. 23:1-3) Ó ti fi hàn kedere pé òun jẹ́ “ibi ìsádi àti okun fún wa” pàápàá nígbà ìṣòro. (Sm. 46:1) Láìsí àní-àní, tọkàntọkàn la fi fara mọ́ ohun tí onísáàmù kan sọ pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere; nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sm. 106:1.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2015: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere.”—Sáàmù 106:1
2, 3. (a) Ewu wo ló wà níbẹ̀ tá ò bá kí í dúpẹ́ oore? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jíròrò ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́? Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí àwọn èèyàn máa jẹ́ aláìlọ́pẹ́. (2 Tím. 3:2) Ọ̀pọ̀ ló ti di abaraámóorejẹ. Bí àwọn oníṣòwò ṣe máa ń polówó ọjà ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn máa ṣe kìràkìtà kí wọ́n lè ra tibí ra tọ̀hún dípò kí wọ́n jẹ́ kí ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Tá ò bá kíyè sára, ìwà yìí lè ràn wá. Bíi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, a lè di aláìmoore, ká má sì ka àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà àti ọ̀pọ̀ nǹkan tó ti ṣe fún wa sí nǹkan pàtàkì mọ́.—Sm. 106:7, 11-13.
3 Láfikún síyẹn, ẹ tún wo ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá dojú kọ àdánwò tó le koko. Ní irú àwọn àkókò yẹn, àníyàn lè gbà wá lọ́kàn débi pé a lè má fọkàn sí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa. (Sm. 116:3) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó? Kí ló sì máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ kódà nígbà tá a bá ń kojú àwọn àdánwò tó le koko? Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè ṣe é.
“Ọ̀PỌ̀ NǸKAN NI ÌWỌ FÚNRA RẸ TI ṢE . . . JÈHÓFÀ”
4. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a moore?
4 Ká tó lè fi hàn pé a moore a gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò, ká gbà pé Jèhófà ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa, ká ṣàṣàrò lé wọn lórí, ká sì ronú lórí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti fi inúure hàn sí wa. Nígbà tí onísáàmù kan ṣe bẹ́ẹ̀, ó yà á lẹ́nu gan-an láti rí ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe fún un.—Ka Sáàmù 40:5; 107:43.
5. Kí la kọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa bí a ṣe lè máa dúpẹ́ oore?
5 A lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa bí a ṣe lè máa dúpẹ́ oore. Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù máa ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìbùkún tó ń rí gbà, tọkàntọkàn ló sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé nígbà kan rí òun jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.” Torí náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé láìka àwọn ìwàkíwà tí òun ti hù sẹ́yìn sí, Ọlọ́run àti Kristi fojú àánú hàn sóun, ó sì ti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ síkàáwọ́ òun. (Ka 1 Tímótì 1:12-14.) Pọ́ọ̀lù tún mọyì àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni gan-an, ó sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé wọ́n ní àwọn ìwà tó dára àti pé wọ́n ń fì ìṣòtítọ́ jọ́sìn Rẹ̀. (Fílí. 1:3-5, 7; 1 Tẹs. 1:2, 3) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì dojú kọ àwọn ipò tó le koko, ojú ẹsẹ̀ ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé òun rí ìrànwọ́ tó bọ́ sákòókò látọ̀dọ̀ àwọn ará. (Ìṣe 28:15; 2 Kọ́r. 7:5-7) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni níyànjú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: ‘Ẹ fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́. Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú àwọn sáàmù, àwọn ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin tẹ̀mí pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.’—Kól. 3:15-17.
ÀṢÀRÒ ÀTI ÀDÚRÀ NI OHUN PÀTÀKÌ TÓ Ń JẸ́ KÉÈYÀN MỌ ỌPẸ́ DÁ
6. Kí lóhun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ tó o mọrírì rẹ̀ gan-an?
6 Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere Pọ́ọ̀lù, káwa náà lè máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore tó ṣe fún wa? Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a ní láti máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa. (Sm. 116:12) Báwo lo ṣe máa dáhùn tí wọ́n bá bi ẹ́ pé, ‘Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ tó o mọrírì gan-an? Ṣé wàá dárúkọ àjọṣe tímọ́tímọ́ tó o ní pẹ̀lú Jèhófà? Àbí wàá sọ ìdáríjì tó o rí gbà torí pé o nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi? Ṣé wàá mẹ́nu kan àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n dúró tì ẹ́ nígbà ìṣòro tó le koko? Ó dájú pé, o ò ní gbàgbé láti dárúkọ ọkọ tàbí aya àtàwọn ọmọ rẹ ọ̀wọ́n. Tó o bá ń ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà Baba rẹ onífẹ̀ẹ́ ti ṣe fún ẹ, wàá moore, wàá sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́.—Ka Sáàmù 92:1, 2.
7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà ìdúpẹ́ sí Jèhófà? (b) Àǹfààní wo ló máa ṣe ẹ́ tó o bá ń dúpẹ́ oore nínú àdúrà rẹ?
7 Tá ò bá gbàgbé gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ó máa rọrùn fún wa láti gbàdúrà sí Jèhófà ká sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Sm. 95:2; 100:4, 5) Ọ̀pọ̀ ló rò pé téèyàn bá fẹ́ tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan ló yẹ kéèyàn gbàdúrà. Àmọ́, àwa mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá dúpẹ́ oore tó ṣe fún wa. Nínú Bíbélì, a máa rí oríṣiríṣi àdúrà ìdúpẹ́ tó ń múnú ẹni dùn, lára wọn ni àdúrà tí Hánà gbà àti ti Hesekáyà. (1 Sám. 2:1-10; Aísá. 38:9-20) Torí náà, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyẹn tí wọ́n fi hàn pé àwọn moore. Tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí àwọn ìbùkún tó ò ń rí gbà. (1 Tẹs. 5:17, 18) Àǹfààní tí o máa rí tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ kò lóǹkà. Wàá máa láyọ̀, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, wàá sì sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.—Ják. 4:8.
8. Kí ló lè mú ká má mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa mọ́?
8 Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára kí a má lọ dẹni tí kò mọyì àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa? Ìdí ni pé aláìpé ni wá, a sì ti jogún ìwà àìmoore. Wò ó bí àpẹẹrẹ: Inú ọgbà ẹlẹ́wà ni Jèhófà dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà sí. Kò sí nǹkan tí wọ́n nílò tí Ọlọ́run kò pèsè fún wọn, wọ́n sì tún láǹfààní láti máa gbé títí láé ní àlàáfíà. (Jẹ́n. 1:28) Àmọ́, wọn ò mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn. Ojúkòkòrò mú kí wọ́n máa wò ó pé ohun tí Jèhófà fún àwọn kò tó. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n pàdánù gbogbo nǹkan tí wọ́n ní. (Jẹ́n. 3:6, 7, 17-19) Torí pé inú ayé táwọn èèyàn ti ya aláìmoore là ń gbé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Jèhófà ti fún wa lè má jọ wá lójú mọ́. A lè má ka àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ sí nǹkan pàtàkì mọ́. Àǹfààní tá a ní láti wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé lè máà jámọ́ nǹkan kan lójú wa mọ́. A sì lè lọ tara bọ àwọn nǹkan ayé tó máa tó kọjá lọ yìí. (1 Jòh. 2:15-17) Ká má bàa kó sínú ìṣòro yìí, ẹ jẹ́ ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ déédéé fún àǹfààní tó fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀.—Ka Sáàmù 27:4.
MAA FI HÀN PÉ O MOORE KÓDÀ NÍGBÀ ÌṢÒRO
9. Tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro tó le koko pàápàá, kí nìdí tó fi yẹ ká ronú lórí àwọn ìbùkún tí à ń rí gbà?
9 Tá a bá ń dúpẹ́ oore, èyí máa jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro tó le koko pàápàá. Nígbà míì, ó lè ṣe wá bíi pé ìṣòro kan ti fẹ́ kọjá agbára wa, pàápàá tí a bá dojú kọ àwọn ìṣòro tó lè mú àyípadà bá ìgbésí ayé wa, irú bíi kí ọkọ tàbí aya wa di aláìṣòótọ́, àìsàn tó fẹ́ gbẹ̀mí wa, ikú èèyàn wa kan tá a fẹ́ràn tàbí ìbànújẹ́ tí àjálù máa ń fà. Nírú àkókò yìí, a máa rí ìtùnú àti okun gbà tí a bá ń ronú lórí àwọn ìbùkún tí à ń rí gbà. Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn kan yẹ̀ wò.
10. Báwo ni Irina ṣe jàǹfààní nígbà tó ronú lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún un?
10 Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni Arábìnrin Irinaa ní Amẹ́ríkà ti Àríwá. Ó fẹ́ alàgbà kan tó di aláìṣòótọ́ tó sì pa òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ tì. Kí ló jẹ́ kí Arábìnrin Irina lè máa sin Jèhófà nìṣó? Ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oore rẹ̀ lórí mi. Bí mo ṣe ń ronú lójoojúmọ́ lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún mi, mo wá rí i pé àǹfààní ló jẹ́ fún mi pé Baba wa ọ̀run aláàbò mọ̀ mí, ó sì nífẹ̀ẹ́ mi. Mo mọ̀ pé kò ní pa mí tì láé.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìpọ́njú ni Irina ti dojú kọ́, bó ṣe ń láyọ̀ jẹ́ kó lè máa fara dà á, ìṣírí ló sì jẹ́ fún àwọn míì.
11. Kí ló mú kí Kyung-sook lè fara da àìsàn kan tó fẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀?
11 Arábìnrin Kyung-sook àti ọkọ rẹ̀ ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà, wọ́n sì ti lo ohun tó lé ní ogún ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́jọ́ kan, àwọn dókítà sọ fún un pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀fóró àti pé kò ju oṣù mẹ́ta sí mẹ́fà lọ tó fi máa gbé láyé. Òun àti ọkọ rẹ̀ ti dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, àmọ́ koko lára wọn máa ń le. Arábìnrin Kyung-sook sọ pé: “Àìsàn yìí bà mí nínú jẹ́ gan-an. Ó ṣe mí bíi pé kò sọ́nà àbáyọ mọ, èyí sì dẹ́rù bà mí lọ́pọ̀lọpọ̀.” Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á? Ó sọ pé: “Ní alaalẹ́ kí n tó lọ sùn, mo máa ń lọ sórí òrùlé ilé wa kí n lè gbàdúrà sí Jèhófà, mó máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ohun márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó kéré tán, tó ṣe fún mi lọ́jọ́ yẹn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀, ó sì jẹ kí n lè máa sọ bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó.” Àǹfààní wo ni àdúrà alaalẹ́ yìí ṣe fún Arábìnrin Kyung-sook? Ó sọ pé: “Mo wá rí i pé Jèhófà kì í dá wa dá àwọn ìṣòro wa àti pé ìbùkún tá à ń rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà pọ̀ fíìfíì ju àwọn ìṣòro wa lọ.”
12. Kí ló tu Jason nínú lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀?
12 Arákùnrin Jason ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì kan nílẹ̀ Áfíríkà. Ó ti lé ní ọgbọ́n [30] ọdún tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó sọ pé: “Ìyàwó mi kú lọ́dún méje sẹ́yìn, ẹ̀dùn ọkàn tó sì kó bá mi pọ̀ lápọ̀jù. Ọkàn mi máa ń bà jẹ́ gan-an ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń ronú lórí ìrora tó jẹ nígbà tó ní àrùn jẹjẹrẹ.” Kí ló jẹ́ kí Arákùnrin Jason lè fara dà á? Ó sọ pé: “Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rántí àwọn àkókò tó lárinrin témi àti ìyàwó mi jọ lò pa pọ̀, mo sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tí mo bá ń gbàdúrà, pé ó jẹ́ kí n lè rántí irú àwọn àkókò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í fúyẹ́ díẹ̀díẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà déédéé pé ó jẹ́ kí n lè máa rántí irú àwọn àkókò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀. Bí mo ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà mú kí nǹkan sàn fún mi. Ràbọ̀ràbọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ò tíì kúrò lára mi, àmọ́ mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí ìgbéyàwó mi tura àti pé ó fún mi ní ìyàwó tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an tá a jọ sìn ín. Èyí sì ti mú kí n máa fi ojú tí ó tọ́ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi.”
“Mo dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà ni Ọlọ́run mi.”—Sheryl
13. Kí ló mú kí Sheryl lè fara dà á nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìdílé rẹ̀ kú?
13 Ìjì lílé kan jà ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Philippines ní apá ìparí ọdún 2013, ká ṣáà sọ pé gbogbo nǹkan tí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sheryl ní ló pàdánù pátápátá, kò sì tíì ju ọmọ ọdún mẹ́tàlá lọ nígbà yẹn. Ó sọ pé: “Mo pàdánù ọ̀pọ̀ mọ̀lẹ́bí mi àti ilé mi.” Bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀ àti àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́ta ló kú nínú ìjì líle yẹn. Kí ló jẹ́ kí Sheryl lè fara da àjálù tó dé bá a yìí tí kò sì bara jẹ́ jù? Ó ní ẹ̀mí ìmoore, ó sì mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ṣì wà níwájú fún òun. Ó sọ pé: “Mo rí gbogbo ohun tí àwọn ará ṣe kí wọ́n lè ran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́ kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí. Mo mọ̀ pé gbogbo ará kárí ayé ló ń gbàdúrà fún mi.” Ó wá fi kún un pé: “Mo dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà ni Ọlọ́run mi. Gbogbo ìgbà ló máa ń fún wa ní ohun tá a nílò.” Tá a bá ń dúpẹ́ oore tí Jèhófà ń ṣe fún wa, ìbànújẹ́ kò ní dorí wa kodò. Ẹ̀mí ìmoore máa jẹ́ ká lè máa fara dà á bá a tiẹ̀ ń dojú kọ àwọn ipò tó le koko.—Éfé. 5:20; ka Fílípì 4:6, 7.
“NÍ TÈMI, DÁJÚDÁJÚ, ÈMI YÓÒ MÁA YỌ AYỌ̀ ŃLÁǸLÀ NÍNÚ JÈHÓFÀ”
14. Ohun tó ń múni láyọ̀ wo ló ń dúró dè wá? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
14 Jálẹ̀ ìtàn, inú àwọn èèyàn Jèhófà máa ń dùn sáwọn ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin ìyìn àti ọpẹ́ láti fi bí inú wọn ti dùn tó hàn lẹ́yìn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní Òkun Pupa. (Ẹ́kís. 15:1-21) Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tí a ṣìkẹ́ jù lọ lóde òní ní ìrètí tó dájú pé a máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ohun tó ń kó ìrora àti ìdààmú bá wa. (Sm. 37:9-11; Aísá. 25:8; 33:24) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wa nígbà tí Jèhófà bá pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run pátápátá, tó sì mú wa wọnú ayé tuntun tí àlàáfíà àti òdodo máa wà. Ọjọ́ tí ọpẹ́ máa gbẹnu wa lọ́jọ́ náà máa jẹ́!—Ìṣí. 20:1-3; 21:3, 4.
15. Kí lo pinnu láti ṣe jálẹ̀ ọdún 2015?
15 À ń fojú sọ́nà fún ọ̀pọ̀ ìbùkún tẹ̀mí tá a máa rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà lọ́dún 2015. Lóòótọ́, a lè dojú kọ àwọn ìṣòro o, àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé kò sóhun tó ń bọ̀ lókè tí ilẹ̀ ò gbà, Jèhófà ò sì ní fi wa sílẹ̀ láé. (Diu. 31:8; Sm. 9:9, 10) Á fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu bíi ti wòlíì Hábákúkù tó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè má yọ ìtànná, àjàrà sì lè má mú èso jáde; iṣẹ́ igi ólífì lè yọrí sí ìkùnà ní ti tòótọ́, àwọn ilẹ̀ onípele títẹ́jú sì lè má mú oúnjẹ wá ní ti tòótọ́; a lè ya agbo ẹran nípa kúrò nínú ọgbà ẹran ní ti tòótọ́, ọ̀wọ́ ẹran sì lè má sí nínú àwọn gbàgede; síbẹ̀, ní tèmi, dájúdájú, èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Háb. 3:17, 18) Jálẹ̀ ọdún tó ń bọ̀, ẹ jẹ́ kí a máa fayọ̀ ronú lórí àwọn ìbùkún tí à ń rí gbà, kíyẹn sì mú ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2015: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere.”—Sm. 106:1.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.