Àṣàrò àti Àdúrà Ṣe Pàtàkì fún Àwọn Òjíṣẹ́ Onítara
1. Kí ni kò jẹ́ kí ọkàn Jésù pínyà lẹ́nu iṣẹ́ tó fi ṣe ohun àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀?
1 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, Jésù wo àwọn èèyàn sàn, ó sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde lára àwọn kan. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí i lọ́jọ́ kejì, wọ́n sọ fún un pé: “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ,” wọ́n sì rọ̀ ọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìyanu lọ. Àmọ́, Jésù kò jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn òun níyà lẹ́nu iṣẹ́ tó fi ṣe ohun àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibòmíràn, sí àwọn ìlú abúlé tí ó wà nítòsí, kí èmi lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú, nítorí fún ète yìí ni mo ṣe jáde lọ.” Kí ni kò jẹ́ kí ọkàn Jésù pínyà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Jésù ti dìde nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́ láti gbàdúrà kó sì ṣe àṣàrò. (Máàkù 1:32-39) Ọ̀nà wo ni àṣàrò àti àdúrà lè gbà ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi ìtara wàásù?
2. Kí la lè ṣe àṣàrò lé lórí tó máa ràn wá lọ́wọ́ kí ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ má bàa dín kù?
2 Kí La Lè Ṣe Àṣàrò Lé Lórí? Nígbà tí Jésù rí àwọn èèyàn, ó ṣàkíyèsí pé, “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Àwa náà lè ronú nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere. A lè ronú nípa bí àkókò tí a wà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó. (1 Kọ́r. 7:29) A lè ṣàṣàrò nípa àwọn iṣẹ́ Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀, àǹfààní tá a ní láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ìṣúra iyebíye tẹ̀mí tá a ti kọ́ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ò tíì mọ̀.—Sm. 77:11-13; Aísá. 43:10-12; Mát. 13:52.
3. Àwọn ìgbà wo la lè máa ṣe àṣàrò?
3 Ìgbà Wo La Lè Máa Ṣe Àṣàrò? Bí Jésù ti ṣe, àwọn kan máa ń jí ní ìdájí nígbà tí ibi gbogbo pa rọ́rọ́ láti ṣe àṣàrò. Ó sì rọ àwọn míì lọ́rùn láti ṣe àṣàrò nírọ̀lẹ́ kí wọ́n tó sùn. (Jẹ́n. 24:63) Bí ọwọ́ wa bá tiẹ̀ sábà máa ń dí, a lè wá àyè láti ṣe àṣàrò. Àwọn kan máa ń ṣe àṣàrò nígbà tí wọ́n bá wà nínú ọkọ̀ èrò. Àwọn míì máa ń fi àkókò díẹ̀ ṣe àṣàrò nígbà ìsinmi ọ̀sán. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àkókò díẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àṣàrò kí wọ́n tó lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n lè fi ìtara àti àìṣojo wàásù.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàṣàrò?
4 Bá a bá ń gbàdúrà tá a sì ń ṣàṣàrò, èyí á jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wá láti sin Jèhófà, á jẹ́ ká lè máa wo ìjọsìn Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa, ó sì máa jẹ́ kí ìpinnu wa láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Jésù ni Òléwájú nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run, ó sì jàǹfààní nínú ṣíṣe àṣàrò. Bí àwa náà bá ń ṣe àṣàrò, a máa jàǹfààní púpọ̀.