Kó Gbogbo Àníyàn Rẹ lé Jèhófà
‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé [Jèhófà], nítorí ó bìkítà fún yín.’—1 PÉT. 5:7.
1, 2. (a) Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ṣàníyàn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÀSÌKÒ tó le gan-an là ń gbé yìí. Sátánì Èṣù ń bínú burúkú burúkú, ó sì ń “rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8; Ìṣí. 12:17) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà máa ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó ṣe tán, àwọn ìgbà kan wà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ náà ṣàníyàn. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ọba Dáfídì. (Sm. 13:2) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní “àníyàn fún gbogbo àwọn ìjọ.” (2 Kọ́r. 11:28) Torí náà, kí la lè ṣe tí àníyàn bá bò wá mọ́lẹ̀?
2 Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láyé àtijọ́, ó sì dájú pé á ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè rí ìtura lọ́wọ́ àníyàn tàbí àwọn ìṣòro tá a ní. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: ‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.’ (1 Pét. 5:7) Ìbéèrè náà ni pé, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A máa jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. (1) Ká máa gbàdúrà tọkàntọkàn, (2) ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa ṣàṣàrò lé e, (3) ká jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, àti (4) ká máa sọ bí nǹkan ṣe ń ṣe wá fún àwọn tó ṣeé finú hàn. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn ọ̀nà mẹ́rin yìí, máa ronú àwọn ọ̀nà pàtó tó o lè gbà fi wọ́n sílò kó o lè borí àníyàn.
“JU ẸRÙ ÌNIRA RẸ SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ”
3. Báwo lo ṣe lè “ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà” nípasẹ̀ àdúrà?
3 Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ ká ṣe ni pé ká gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà. Tí nǹkan bá tojú sú ẹ, tọ́kàn rẹ ò balẹ̀ tàbí tí àníyàn fẹ́ bò ẹ́ mọ́lẹ̀, sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún Jèhófà Baba rẹ ọ̀run. Dáfídì bẹ Jèhófà pé: “Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà ló tún sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sm. 55:1, 22) Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro kan, á dáa kó o gbàdúrà àtọkànwá torí ìyẹn á ṣe ẹ́ láǹfààní ju kó o máa ṣàníyàn lọ. Àmọ́, báwo ni àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí àníyàn àti ẹ̀dùn ọkàn kò fi ní bò ẹ́ mọ́lẹ̀?—Sm. 94:18, 19.
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà nígbà tá a bá ń ṣàníyàn?
4 Ka Fílípì 4:6, 7. Tá a bá ń gbàdúrà tọkàntọkàn, tá ò sì jẹ́ kó sú wa, Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa. Báwo ló ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ó máa ń mú ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀, kára sì tù wá. Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Dípò tí wọn ì bá fi máa ṣàníyàn, ṣe ni Ọlọ́run mú kí ọkàn wọn balẹ̀, tí ara sì tù wọ́n pẹ̀sẹ̀ lọ́nà tó yani lẹ́nu. Ó lè rí bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà, torí pé, “àlàáfíà Ọlọ́run” á jẹ́ kó o borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè yọjú. Jẹ́ kí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, pé: “Má wò yí ká, [tàbí ṣàníyàn] nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”—Aísá. 41:10.
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN MÁA MÚ KÓ O NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN
5. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn?
5 Ohun kejì tó o lè ṣe láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn ni pé kó o máa ka Bíbélì, kó o sì máa ṣàṣàrò lé ohun tó ò ń kà. Kí nìyẹn máa ṣe fún ẹ? Àwọn ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì máa jẹ́ kó o yẹra fún ohun tó lè fa àníyàn, wọ́n á jẹ́ kó o lè dín in kù, kó o sì borí ẹ̀. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, á sì tù ẹ́ nínú, torí pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà ló wà nínú rẹ̀. Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, láàárọ̀ tàbí lálẹ́, tó o sì ń ronú bí wàá ṣe fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, wàá rí i pé á fún ẹ lókun gan-an. Kódà, Jèhófà sọ pé téèyàn bá ń ka Ọ̀rọ̀ òun, èèyàn á jẹ́ “onígboyà àti alágbára” kò sì ní máa ‘gbọ̀n rìrì tàbí kí ó jáyà.’—Jóṣ. 1:7-9.
6. Àǹfààní wo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù máa ṣe ẹ́?
6 A tún lè rí ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jésù sọ nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ tó bá àwọn èèyàn sọ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ tù wọ́n nínú gan-an. Àwọn èèyàn máa ń wá sọ́dọ̀ Jésù torí pé ó máa ń tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú, ó ń fáwọn tó ti rẹ̀ lókun, ó sì máa ń gbé àwọn tó ti sọ̀rètí nù ró. (Ka Mátíù 11:28-30.) Jésù máa ń gba tàwọn èèyàn rò, títí kan àwọn tó fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn tó ní ìbànújẹ́ ọkàn àtàwọn tí ara ń ni. (Máàkù 6:30-32) Jésù ṣèlérí pé òun máa tu àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nínú, á sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà. Kò dìgbà tí Jésù bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kó tó lè tù ẹ́ nínú. Ní báyìí tí Jésù ti ń jọba lọ́run, ó ń kíyè sí ẹ, ó sì ń gba tìẹ rò. Torí náà, tó o bá ń ṣàníyàn, á fàánú hàn sí ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní “àkókò tí ó tọ́.” Ó dájú pé Jésù lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro rẹ, á sì mú kó o ní ìgboyà àti ìrètí.—Héb. 2:17, 18; 4:16.
Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ Ń JẸ́ KÁ NÍ ÀWỌN ÀNÍMỌ́ RERE
7. Àǹfààní wo ni wàá rí tí Ọlọ́run bá fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ tó o béèrè fún?
7 Ohun kẹta táá jẹ́ ká lè borí àníyàn ni èso tẹ̀mí tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. Jésù ṣèlérí pé tá a bá bẹ Baba wa ọ̀run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kò ní ṣàì fún wa. (Lúùkù 11:10-13) Àwọn ànímọ́ rere tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run Olódùmarè jẹ́ gan-an. (Ka Gálátíà 5:22, 23; Kól. 3:10) Bó o ṣe ń fi àwọn ànímọ́ yìí ṣèwàhù, àárín ìwọ àtàwọn èèyàn á túbọ̀ gún régé. Wàá wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó sábà máa ń fa àníyàn kò ní wáyé. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ lórí bí èso tẹ̀mí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
8-12. Báwo ni èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àníyàn?
8 “Ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà.” Tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, wàá rí i pé o ò ní fi bẹ́ẹ̀ máa ṣàníyàn. Lọ́nà wo? Wò ó báyìí ná. Tó o bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì, tó ò ń pọ́n wọn lé, tó o sì ń buyì kún wọn, àwọn nǹkan tó lè fa àníyàn fún ẹ máa dín kù.—Róòmù 12:10.
9 “Ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere.” Àárín ìwọ àtàwọn míì á dùn tó o bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò, pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.” (Éfé. 4:32) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tó lè fa àníyàn kò ní yọjú. Bákan náà, á rọrùn fún ẹ láti bójú tó ìṣòro tí àìpé ẹ̀dá máa ń fà.
10 “Ìgbàgbọ́.” Lóde òní, ọ̀rọ̀ owó àtàwọn ohun ìní ló sábà máa ń fa àníyàn fáwọn èèyàn. (Òwe 18:11) Torí náà, ìgbàgbọ́ tó lágbára tó o ní pé Jèhófà máa fìfẹ́ bójú tó ẹ á jẹ́ kó o lè borí àníyàn tàbí kó o má tiẹ̀ fàyè gbà á rárá. Lọ́nà wo? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò pé ká “ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: “Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’ Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’ ”—Héb. 13:5, 6.
11 “Ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” Tó o bá ń fàwọn ànímọ́ yìí ṣèwàhù, wàá lè yanjú èdèkòyédè, ọkàn rẹ á sì balẹ̀. Èyí á jẹ́ kó o wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, o ò sì ní máa ṣàníyàn. Bákan náà, wàá jàǹfààní tó o bá ń yẹra fún “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.”—Éfé. 4:31.
12 Ká sòótọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló máa jẹ́ kó o fi ara rẹ sábẹ́ “ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run,” kó o sì “kó gbogbo àníyàn [rẹ] lé e.” (1 Pét. 5:6, 7) Bó o ṣe ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀, wàá máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o rí ojúure Ọlọ́run àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀. (Míkà 6:8) Tó o bá mọ̀wọ̀n ara ẹ, tó ò sì ṣe ju ara ẹ lọ, wàá máa gbára lé Jèhófà, àníyàn ò sì ní bò ẹ́ mọ́lẹ̀.
“Ẹ MÁ ṢÀNÍYÀN LÁÉ”
13. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé”?
13 Nínú Mátíù 6:34 (kà á), Jésù gbà wá nímọ̀ràn kan, ó sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé.” Àmọ́, ó lè nira fún wa díẹ̀ láti fi ìmọ̀ràn yẹn sílò. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé”? Ó ṣe kedere pé kò ní in lọ́kàn pé gbogbo nǹkan á máa dùn yùngbà-yùngbà fáwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tàbí pé a ò ní róhun tó máa mú ká ṣàníyàn. Ó ṣe tán, àwọn ìpínrọ̀ tá a kà ṣáájú fi hàn pé Dáfídì àti Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn. Torí náà, ohun tí Jésù ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé kéèyàn máa ṣe àníyàn tí kò pọn dandan tàbí kéèyàn máa ṣàníyàn àṣejù kì í yanjú ìṣòro. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ló ní ìṣòro tiẹ̀, torí náà kò sídìí tí Kristẹni kan á fi máa pa àníyàn tàná àti tọ̀la mọ́ tòní. Báwo ni ìmọ̀ràn Jésù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa ṣàníyàn àṣejù?
14. Kí lo lè ṣe tọ́kàn rẹ bá ń dá ẹ lẹ́bi torí àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn?
14 Nígbà míì, ó lè jẹ́ àṣìṣe tẹ́nì kan ṣe sẹ́yìn ló ń kó àníyàn bá a. Ọ̀pọ̀ ọdún lè ti kọjá tó ti ṣàṣìṣe ọ̀hún, síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ ṣì lè máa dá a lẹ́bi. Àwọn ìgbà kan wà tí Ọba Dáfídì sọ pé ‘àwọn ìṣìnà òun ti gba orí òun kọjá.’ Ó wá fi kún un pé: “Mo ti ké ramúramù nítorí ìkérora ọkàn-àyà mi.” (Sm. 38:3, 4, 8, 18) Nínú ipò tí Dáfídì wà yìí, ó ṣe ohun kan tó mọ́gbọ́n dání. Ó yíjú sí Jèhófà pé kó fàánú hàn sí òun, kó sì dárí ji òun. Abájọ tó fi sọ tọkàntọkàn pé: ‘Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì.’—Ka Sáàmù 32:1-3, 5.
15. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́? (b) Àwọn ìgbésẹ̀ wo lo lè gbé láti dín àníyàn kù? (Wo àpótí náà, “Àwọn Nǹkan Tó O Lè Ṣe Láti Dín Àníyàn Kù.”)
15 Láwọn ìgbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ló ń mú kó o máa ṣàníyàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì kọ Sáàmù 55, ẹ̀rù ń bà á pé òun lè kú. (Sm. 55:2-5) Síbẹ̀, kò jẹ́ kí àníyàn yẹn mú kóun sọ̀rètí nù nínú Jèhófà. Dáfídì sọ àwọn ìṣòro rẹ̀ fún Jèhófà. Ìyẹn nìkan kọ́, ó rí i pé ó yẹ kóun náà gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan táá jẹ́ kóun borí ìṣòro náà. (2 Sám. 15:30-34) Ẹ̀kọ́ gidi nìyẹn kọ́ wa. Dípò tí wàá fi fọwọ́ lẹ́rán, kí àníyàn wá bò ẹ́ mọ́lẹ̀, o ò ṣe gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó bá ìlànà Bíbélì mu láti bójú tó ìṣòro náà, kó o sì fọ̀rọ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́.
16. Báwo ni ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára?
16 Tí Kristẹni kan bá ń ronú ṣáá nípa ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀, ó lè mú kó máa ṣàníyàn tí kò pọn dandan. Àmọ́, kò sídìí tó fi yẹ kó o máa kọ́kàn sókè lórí ohun tó lè má ṣẹlẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan téèyàn ń rò kì í le tó béèyàn ṣe rò pó máa rí. Yàtọ̀ síyẹn, kò sí bí ìṣòro kan ṣe lè le tó táá kọjá agbára Ọlọ́run. Ó ṣe tán, òun náà ló ní ká ju ìṣòro wa sọ́dọ̀ òun. A sì rántí ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí, ìyẹn “Alèwílèṣe.” (Ẹ́kís. 3:14) Ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí kò ní ṣe. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn àníyàn tí wọ́n ní nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, èyí tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àtèyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀.
MÁA SỌ TINÚ RẸ FÁWỌN MÍÌ
17, 18. Tó o bá sọ tinú rẹ fáwọn míì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o borí àníyàn?
17 Ohun kẹrin tó o lè ṣe láti borí àníyàn ni pé kó o máa sọ tinú rẹ fún ẹlòmíì, kó o sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún ẹnì kan tó ṣeé finú hàn. O lè fọ̀rọ̀ lọ ọkọ tàbí aya rẹ, ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tàbí alàgbà ìjọ, wọ́n á sì jẹ́ kọ́rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn rẹ. Bíbélì sọ pé, “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Tó o bá sọ ohun tó ń ṣe ẹ́, láìfi nǹkan kan pa mọ́, ó ṣeé ṣe kó o rọ́nà àbáyọ. Bíbélì sọ fún wa pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.”—Òwe 15:22.
18 Jèhófà tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn àníyàn wa nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ. Níbẹ̀, a máa ń wà pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí. (Héb. 10:24, 25) Irú “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” yìí máa fún ìgbàgbọ́ ẹ lókun, á sì mú kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti borí àníyàn rẹ.—Róòmù 1:12.
ÀJỌṢE RẸ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN LÓ LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́ JÙ
19. Kí nìdí tó o fi lè gbà pé tó o bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wàá lè fara da ìṣòro rẹ?
19 Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa alàgbà kan lórílẹ̀-èdè Kánádà tó gbà pé ohun tó dáa jù ni pé kóun ju àníyàn òun sọ́dọ̀ Jèhófà. Olùkọ́ iléèwé àti agbani-nímọ̀ràn ni, iṣẹ́ náà sì máa ń tán an lókun gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìsoríkọ́ tó lékenkà. Kí ló wá ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé, “Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ jù lọ ni pé mo tẹra mọ́ àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ lókun láti fara da àwọn ìṣòro mi. Àwọn ọ̀rẹ́ mi àtàwọn ará kò fi mí sílẹ̀, ó ṣe tán ìgbà ìpọ́njú làá mọ̀rẹ́. Mo máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí gẹ́lẹ́ fún ìyàwó mi. Alábòójútó àyíká àtàwọn tá a jọ jẹ́ alàgbà máa ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì ràn mí lọ́wọ́. Bákan náà, mo lọ rí dókítà, mo sì dín àkókó tí mò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ kù kí n lè ráyè máa sinmi, kí n sì lè máa ṣe eré ìmárale. Bó ṣe di pé ara bẹ̀rẹ̀ sí í tù mí nìyẹn. Àmọ́ tí ìṣòro tó kọjá agbára mi bá yọjú, mo máa ń fi lé Jèhófà lọ́wọ́.”
20. (a) Báwo la ṣe ń ju àníyàn wa sọ́dọ̀ Jèhófà? (b) Kí la máa jíròrò nínu àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Ẹ jẹ́ ká wá ṣàkópọ̀ ohun tá a ti kọ́. A ti rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ju àníyàn wa sọ́dọ̀ Jèhófà. A sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí. A tún rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fi èso tẹ̀mí ṣèwàhù, ká máa sọ bó ṣe ń ṣe wá fún ẹni tó ṣeé finú hàn, ká sì máa wà pẹ̀lú àwọn ará ká lè rókun gbà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun á san wá lẹ́san ṣe túbọ̀ ń gbé wa ró.—Héb. 11:6.