18 Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ ń wá ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀;
Gbogbo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ni yóò máa kọ̀.
2 Inú òmùgọ̀ kì í dùn sí òye;
Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń tú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde.+
3 Nígbà tí ẹni burúkú bá dé, ìkórìíra náà á dé,
Ìtìjú ló sì máa ń bá àbùkù rìn.+
4 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn dà bí odò tó jìn.+
Orísun ọgbọ́n dà bí odò tó ń ṣàn.
5 Kò dáa kí a ṣe ojúsàájú sí ẹni burúkú+
Tàbí kí a fi ẹ̀tọ́ olódodo dù ú.+
6 Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ máa ń dá ìjà sílẹ̀,+
Ẹnu rẹ̀ sì máa ń mú kí wọ́n lù ú.+
7 Ẹnu òmùgọ̀ ni ìparun rẹ̀,+
Ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ẹ̀mí rẹ̀.
8 Ọ̀rọ̀ abanijẹ́ dà bí òkèlè dídùn;+
Tí a gbé mì sínú ikùn lọ́hùn-ún.+
9 Ẹni tó bá ya ọ̀lẹ nídìí iṣẹ́ rẹ̀,
Ọmọ ìyá ẹni tó ń fa ìparun ni.+
10 Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára.+
Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.+
11 Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi rẹ̀;
Lọ́kàn rẹ̀, ó dà bí ògiri tó ń dáàbò boni.+
12 Ọkàn gíga ló ń ṣáájú ìṣubú,+
Ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń ṣáájú ògo.+
13 Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀,
Ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.+
14 Ẹ̀mí èèyàn lè mú kó fara da àìsàn,+
Àmọ́, ta ló lè fara da ẹ̀mí tí ìdààmú bá?+
15 Ọkàn ẹni tó ní òye ń gba ìmọ̀,+
Etí ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gbọ́ ìmọ̀.
16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tó fúnni;+
Ó ń jẹ́ kó dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni ńlá.
17 Ẹni tó bá kọ́kọ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ ló ń dà bíi pé ó jàre,+
Títí ẹnì kejì fi wá, tó sì bi í ní ìbéèrè.+
18 Ṣíṣẹ́ kèké máa ń parí awuyewuye+
Ó sì ń làjà láàárín àwọn alágbára tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀.
19 Ọmọ ìyá tí a ṣẹ̀, ó le ju ìlú olódi lọ,+
Àwọn ìjà kan sì wà tó dà bí ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè ilé gogoro tó láàbò.+
20 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa ń fi ohun rere tẹ́ ikùn rẹ̀ lọ́rùn;+
Yóò rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ohun tí ẹnu rẹ̀ sọ.
21 Ahọ́n ní agbára láti fa ikú tàbí ìyè;+
Àwọn tó bá fẹ́ràn láti máa lò ó yóò jẹ èrè rẹ̀.+
22 Ẹni tó bá rí aya rere fẹ́ ti rí ohun rere,+
Ó sì rí ojú rere Jèhófà.+
23 Aláìní máa ń bẹ̀bẹ̀ tó bá ń sọ̀rọ̀,
Àmọ́ ọlọ́rọ̀ máa ń dáhùn lọ́nà líle.
24 Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí wọ́n ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà,+
Àmọ́ ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.+