Máa Fi Ayọ̀ Kọrin!
“Ó dára láti máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run wa.”—SM. 147:1.
1. Kí làwọn orin wa máa ń jẹ́ ká ṣe?
GBAJÚMỌ̀ olórin kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn ronú. Orin sì máa ń jẹ́ kéèyàn fi ìmọ̀lára hàn.” Àwọn orin wa máa ń jẹ́ ká yin Jèhófà Baba wa ọ̀run, ó sì máa ń jẹ́ ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé apá pàtàkì ni orin jẹ́ nínú ìjọsìn tòótọ́, yálà à ń dá kọrin tàbí à ń kọrin pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ.
2, 3. (a) Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn kan tó bá di pé kí wọ́n kọrin sókè nípàdé? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
2 Ṣé ó máa ń wù ẹ́ láti kọrin sókè nípàdé, àbí ojú máa ń tì ẹ́? Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn ọkùnrin kì í fẹ́ kọrin níṣojú àwọn míì. Irú èrò yìí lè ní ipa tí kò dáa lórí àwọn ará ìjọ, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn tó ń múpò iwájú kì í kọrin tàbí tí wọ́n ń ṣe nǹkan míì nígbà táwọn ará ń kọrin lọ́wọ́.—Sm. 30:12.
3 Tá a bá gbà lóòótọ́ pé apá pàtàkì lorin jẹ́ nínú ìjọsìn wa, àá sapá láti wà níbẹ̀ kí orin tó bẹ̀rẹ̀, a ò sì ní máa rìn lọ rìn bọ̀ tí orin bá ń lọ lọ́wọ́. Torí náà, ó yẹ kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé ó máa ń wù mí láti kọrin nípàdé? Kí ni mo lè ṣe tójú bá ń tì mí láti kọrin níṣojú àwọn míì? Báwo ni mo ṣe lè máa fìtara kọrin nípàdé?’
ORIN JẸ́ APÁ PÀTÀKÌ NÍNÚ ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́
4, 5. Ètò wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fún orin kíkọ nínú ìjọsìn wọn?
4 Ọjọ́ pẹ́ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti máa ń fi orin yin Jèhófà. Lásìkò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, apá pàtàkì ni orin kíkọ jẹ́ nínú ìjọsìn wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Dáfídì ń ṣètò àwọn táá máa sìn ní tẹ́ńpìlì, ó ṣètò pé kí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] àwọn ọmọ Léfì máa kọrin ìyìn. Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín méjìlá [288] lára wọn ló jẹ́ àwọn “tí a kọ́ ní iṣẹ́ orin kíkọ sí Jèhófà,” gbogbo wọn sì ni akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.—1 Kíró. 23:5; 25:7.
5 Lásìkò tí wọ́n ń ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́, orin kíkọ kó ipa pàtàkì. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn afunkàkàkí àti àwọn akọrin ṣe ọ̀kan ní mímú kí a gbọ́ ìró kan ní yíyin Jèhófà àti dídúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, gbàrà tí wọ́n sì mú ìró náà dún sókè pẹ̀lú kàkàkí àti pẹ̀lú aro àti pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin ní yíyin Jèhófà, . . . ògo Jèhófà kún ilé Ọlọ́run tòótọ́.” Ẹ ò rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn máa mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára!—2 Kíró. 5:13, 14; 7:6.
6. Ètò wo ni Nehemáyà ṣe fún orin kíkọ nígbà tó jẹ́ gómìnà Jerúsálẹ́mù?
6 Lásìkò tí Nehemáyà jẹ́ gómìnà Jerúsálẹ́mù, ó ṣètò báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, ó tún ṣètò àwọn ọmọ Léfì láti kọrin pẹ̀lú onírúurú ohun èlò ìkọrin. Nígbà tí wọ́n ya ògiri náà sí mímọ́, orin tí wọ́n kọ mú kí ìyàsímímọ́ náà lárinrin. Ó ṣètò “ẹgbẹ́ akọrin ìdúpẹ́ méjì tí ó tóbi.” Ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe ń kọrin, wọ́n sì pàdé ní orí ògiri nítòsí tẹ́ńpìlì, ìró orin náà ń dún débi pé àwọn èèyàn gbọ́ ọ níbi tó jìnnà gan-an. (Neh. 12:27, 28, 31, 38, 40, 43) Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn gan-an bó ṣe ń gbọ́ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń fìtara kọrin ìyìn sí i.
7. Báwo ni Jésù ṣe mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọyì orin kíkọ nínú ìjọsìn wọn?
7 Nígbà tí Jésù wà láyé, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú orin kíkọ nínú ìjọsìn wọn. Bí àpẹẹrẹ, lálẹ́ ọjọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn, Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì kọrin lẹ́yìn tí wọ́n ṣe tán.—Ka Mátíù 26:30.
8. Àpẹẹrẹ wo làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ orin kíkọ?
8 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá di pé ká fi orin yin Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ilé àdáni ni wọ́n ti sábà máa ń péjọ, wọn ò jẹ́ kíyẹn dí wọn lọ́wọ́ àtimáa fìtara kọrin sí Jèhófà. Kódà, Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ìgbà yẹn ní ìtọ́ni, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní kíkọ́ ara yín àti ní ṣíṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú àwọn sáàmù, àwọn ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin tẹ̀mí pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, kí ẹ máa kọrin nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà.” (Kól. 3:16) Àwọn orin tẹ̀mí ló wà nínú ìwé orin wa, ó sì yẹ ká máa fi ẹ̀mí ìmoore kọ wọ́n. Àwọn orin yìí wà lára oúnjẹ tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè fún wa.—Mát. 24:45.
OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ OJÚ BÁ Ń TÌ Ẹ́ LÁTI KỌRIN
9. (a) Kí nìdí tí kò fi rọrùn fáwọn kan láti máa kọrin sókè láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa? (b) Báwo ló ṣe yẹ ká máa kọrin nípàdé, àwọn wo ló sì yẹ kó múpò iwájú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
9 Kí lẹ lè ṣe tí kò bá mọ́ yín lára láti máa kọrin nínú ìdílé yín tàbí lágbègbè yín? Ní báyìí táwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ti wà, ó ṣeé ṣe kó o máa gbádùn orin táwọn olórin kọ. Síbẹ̀, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ yá ẹ lára tàbí kí ojú máa tì ẹ́ torí pé o ò lóhùn bíi tàwọn olórin inú ayé. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kíyẹn dí ẹ lọ́wọ́ àtimáa fi orin yin Jèhófà lógo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o gbé ìwé orin rẹ sókè, gbé orí rẹ sókè kó o sì fìtara kọrin jáde. (Ẹ́sírà 3:11; ka Sáàmù 147:1.) Lóde òní, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba ló máa ń gbé ọ̀rọ̀ àwọn orin wa sójú tẹlifíṣọ̀n, káwọn ará lè kọrin sókè. Yàtọ̀ síyẹn, orin kíkọ ti wá wà lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ táwọn alàgbà ń gbádùn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Èyí mú káwọn alàgbà rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa múpò iwájú nínú kíkọ orin nípàdé.
10. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tí ẹ̀rù bá ń bà wá láti kọrin sókè?
10 Ìbẹ̀rù wà lára ohun tí kì í jẹ́ káwọn kan fi gbogbo ẹnu kọrin. Wọ́n lè máa bẹ̀rù pé ohùn àwọn máa dá yàtọ̀ láàárín àwọn tó kù. Àmọ́, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà” nínú ọ̀rọ̀ sísọ. (Ják. 3:2) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní ká má sọ̀rọ̀ mọ́. Torí náà, ṣó wá yẹ ká tìtorí pé ohùn wa ò fi bẹ́ẹ̀ dáa, ká wá dákẹ́?
11, 12. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ morin kọ?
11 Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa bà wá láti kọrin torí pé kò dá wa lójú pé a mọ béèyàn ṣe ń kọrin. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ mọ orin kọ.a
12 Tó o bá fẹ́ morin kọ dáadáa kí ohùn rẹ sì já geere, ó yẹ kó o mọ béèyàn ṣe ń mí sínú mí síta bó ṣe yẹ. Bí iná mànàmáná ṣe máa ń mú kí gílóòbù tàn yòò, bẹ́ẹ̀ náà ni mímí ṣe máa ń jẹ́ ká lè kọrin tàbí sọ̀rọ̀ sókè. Bí ohùn wa ṣe máa ń ròkè tá a bá ń sọ̀rọ̀ náà ló ṣe yẹ kí ohùn wa ròkè tá a bá ń kọrin, ó tiẹ̀ yẹ kó ròkè ju bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. (Wo àwọn àbá tó wà nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 181 sí 184, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Darí Afẹ́fẹ́ Tí Ò Ń Mí Sínú Sóde Bó Ṣe Tọ́.”) Tó bá dọ̀rọ̀ orin kíkọ, Ìwé Mímọ́ gba àwa èèyàn Jèhófà níyànjú pé ká “fi ìdùnnú ké jáde.”—Sm. 33:1-3.
13. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táá jẹ́ kó o túbọ̀ máa fìtara kọrin?
13 Nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín tàbí níwọ nìkan, gbìyànjú àbá yìí wò: Yan ọ̀kan lára àwọn orin tó o fẹ́ràn jù nínú ìwé orin wa. Ka ọ̀rọ̀ orin náà jáde sókè, má ṣe jẹ́ kí ohùn rẹ gbọ̀n, kó o sì jẹ́ kó rinlẹ̀. Lẹ́yìn náà, lo ohùn kan náà yẹn láti ka ìlà kan lára orin náà láìdá ẹnu dúró. Wá fi ohùn tó ròkè yẹn kọ ìlà náà. (Aísá. 24:14) Kó o tó mọ̀, ohùn rẹ á máa jáde sókè bó o bá ń kọrin. Kò jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ náà ti ń morin kọ nìyẹn. Torí náà, má ṣe jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́ tàbí kí ojú tì ẹ́!
14. (a) Báwo ni líla ẹnu dáadáa ṣe máa jẹ́ ká lè kọrin? (Wo àpótí náà, “Bó o Ṣe Lè Túbọ̀ Mọ Orin Kọ.”) (b) Èwo lára àwọn àbá yìí ló ti ràn ẹ́ lọ́wọ́?
14 Tó o bá fẹ́ kí ohùn rẹ jáde ketekete nígbà tó o bá ń kọrin, o gbọ́dọ̀ la ẹnu rẹ dáadáa. Torí náà, tó o bá ń kọrin á dáa kó o la ẹnu ju ìgbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ lọ. Kí lo lè ṣe tí ohùn rẹ kì í bá jáde dáadáa tàbí tó bá ń han? Wàá rí àwọn àbá táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 184, nínú àpótí tá a pè ní “Bíborí Àwọn Ìṣòro Pàtó Kan.”
MÁA KỌRIN LÁTỌKÀN WÁ
15. (a) Ìfilọ̀ wo ni wọ́n ṣe níbi ìpàdé ọdọọdún tó wáyé lọ́dún 2016? (b) Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe ìwé orin tuntun wa?
15 Nínú ìpàdé ọdọọdún Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tọdún 2016, Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí kéde pé a máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé orin tuntun nípàdé. A pe ìwé orin náà ní “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ nígbà táwọn ará gbọ́ ìkéde yìí. Arákùnrin Lett jẹ́ ká mọ̀ pé àtúnṣe tí wọ́n ṣe sí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì wà lára ìdí tí wọ́n fi ṣe ìwé orin tuntun náà. Èyí mú kó pọn dandan pé ká ṣàtúnṣe sáwọn orin tí ọ̀rọ̀ wọn ò bá Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013 mu, a sì yọ àwọn kan kúrò. Yàtọ̀ síyẹn, a fi àwọn orin tó sọ nípa iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn táá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà kún ìwé orin náà. Bákan náà, torí pé orin ṣe pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn wa, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fẹ́ ká máa lo ìwé orin tó lálòpẹ́, tí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ sì jọ ti Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013.
16, 17. Àwọn àtúnṣe wo ló wà nínú ìwé orin wa tuntun?
16 Kó lè rọrùn fún wa láti lo ìwé “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà, a to àwọn orin inú rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n dá lé. Bí àpẹẹrẹ, orin méjìlá àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, orin mẹ́jọ tó tẹ̀ lé e sọ̀rọ̀ nípa Jésù àti ìràpadà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ìwé orin náà ní atọ́ka àwọn àkòrí táá mú kó rọrùn láti rí orin tá à ń wá, á sì tún mú kó rọrùn fáwọn tó fẹ́ sọ àsọyé láti yan orin tí wọ́n máa lò.
17 Kó lè ṣeé ṣe fún wa láti kọ àwọn orin yìí tọkàntọkàn, a ṣàtúnṣe sáwọn orin kan. A mú káwọn ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ rọrùn lóye, a sì yọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò wọ́pọ̀ lẹ́nu àwọn èèyàn mọ́. Bí àpẹẹrẹ, a ṣe àyípadà àkòrí tá a pè ní “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ,” a sì pè é ní “À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa.” Kí nìdí tá a fi ṣe àyípadà náà? Ìdí ni pé tá a bá ń kọrin yẹn bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ṣe ló dà bíi pé à ń fún àwọn míì ní ìtọ́ni. Ìyẹn sì lè rí bá kan lára àwọn ẹni tuntun, àwọn olùfìfẹ́hàn, àwọn ọmọdé àtàwọn arábìnrin tá a jọ máa ń wà láwọn ìpàdé wa àtàwọn àpéjọ wa. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu bá a ṣe yí ọ̀rọ̀ orin náà pa dà.
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ àwọn orin tó wà nínú ìwé orin wa tuntun? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
18 Ọ̀pọ̀ àwọn orin tó wà nínú ìwé orin “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà ló dà bí àdúrà. Tá a bá ń kọ àwọn orin yìí, ńṣe là ń tú ọkàn wa jáde fún Jèhófà. Àwọn orin míì tó wà nínú rẹ̀ máa jẹ́ ká lè “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24) Ó dájú pé a máa fẹ́ mọ ohùn àwọn orin náà, ká mọ ọ̀rọ̀ inú wọn ká sì rí i pé a mọ àwọn orin náà kọ dáadáa. A tún lè mọ àwọn orin yìí tá a bá ń gbọ́ àwọn orin tá a fẹnu kọ lórí ìkànnì jw.org. Tó o bá ń kọ àwọn orin yìí nílé, wàá lè túbọ̀ máa fìtara kọ àwọn orin náà látọkàn wá.b
19. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè pa ohùn pọ̀ jọ́sìn Jèhófà?
19 Ká rántí pé apá pàtàkì ni orin jẹ́ nínú ìjọsìn wa. Tá a bá ń fayọ̀ kọrin, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì rẹ̀. (Ka Aísáyà 12:5.) Tó o bá ń fayọ̀ kọrin tó o sì gbóhùn sókè, wàá mú kó túbọ̀ yá àwọn míì lára láti máa fìtara kọrin. Gbogbo wa pátá ló yẹ ká máa fìtara kọrin sókè sí Jèhófà, yálà a jẹ́ ọmọdé, àgbàlagbà tàbí ẹni tuntun. Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ àtimáa kọrin sókè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ohun tí onísáàmù náà ní ká máa ṣe, ó ní: “Ẹ kọrin sí Jèhófà!” Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ jẹ́ ká máa fayọ̀ kọrin!—Sm. 96:1.
a Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè túbọ̀ morin kọ, wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW ti oṣù December 2014 lédè Gẹ̀ẹ́sì (lára àwọn fídíò tó wà ní abala FROM OUR STUDIO).
b Kí ara wa lè wà lọ́nà láti kọrin, a máa ń gbọ́ ohùn orin oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká àti àgbègbè tó bẹ̀rẹ̀. Wọ́n kọ àwọn orin yìí lọ́nà tó gbádùn mọ́ni kó lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Torí náà, ó dáa kí gbogbo wa ti jókòó kí ohùn orin tó bẹ̀rẹ̀, ká sì fara balẹ̀ gbádùn rẹ̀.