Ṣé Ò Ń Sá Di Jèhófà?
“Jèhófà ń tún ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rà padà; kò sì sí ìkankan lára àwọn tí ń sá di í tí a ó kà sí ẹlẹ́bi.”—SM. 34:22.
1. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tá a bá dẹ́ṣẹ̀?
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa ara rẹ̀, ó ní: “Èmi abòṣì ènìyàn!” (Róòmù 7:24) Bó ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù náà ló rí lára ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí. Torí pé gbogbo wa la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, ó máa ń ká wa lára gan-an tá a bá ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà. Àwọn Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tiẹ̀ máa ń ronú pé Jèhófà ò lè dárí ji àwọn láéláé torí ohun táwọn ṣe.
2. (a) Kí ni Sáàmù 34:22 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi mọ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti dárí jì wá? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Wo àpótí náà, “Ṣé ẹ̀kọ́ Bíbélì ló ṣe pàtàkì ni àbí ohun tí ìtàn kan ṣàpẹẹrẹ?”)
2 Bó ti wù kó rí, Ìwé Mímọ́ fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá sá di Jèhófà, a ò tún ní máa dá ara wa lẹ́bi mọ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti dárí jì wá. (Ka Sáàmù 34:22.) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn sá di Jèhófà? Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe kí Jèhófà lè ṣàánú wa kó sì dárí jì wá? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, a máa jíròrò ètò tí Jèhófà ṣe nípa àwọn ìlú ìsádi tàbí ìlú ààbò ní Ísírẹ́lì àtijọ́. Ká sòótọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Jèhófà fún ní májẹ̀mú Òfin lètò yẹn wà fún, ó sì fi ohun míì rọ́pò rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀ torí pé Jèhófà ló fún wọn ní Òfin yẹn. Torí náà, tá a bá ronú lórí ètò tí Jèhófà ṣe nípa ìlú ààbò, àá mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀, àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ àti ìrònúpìwàdà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn ìlú ààbò náà wà fún àti àǹfààní tó ṣe àwọn èèyàn náà.
Ẹ YAN ÀWỌN ÌLÚ ÀÀBÒ FÚN ARA YÍN
3. Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe fún ẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn?
3 Ọwọ́ kékeré kọ́ ni Jèhófà fi mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. Òfin Ọlọ́run sọ pé bí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn, kí wọ́n pa onítọ̀hún. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ìbátan tímọ́tímọ́ ẹni tí wọ́n pa ló máa gbẹ̀san ikú rẹ̀, òun sì ni Bíbélì pè ní “olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.” (Núm. 35:19) Ìgbésẹ̀ yẹn máa mú kí apààyàn náà jìyà ohun tó ṣe. Bákan náà, wọn kì í fi ìdájọ́ yìí falẹ̀ kí Ilẹ̀ Ìlérí má bàa di ẹlẹ́gbin, torí Jèhófà pàṣẹ pé: “Kí ẹ má sì sọ ilẹ̀ tí ẹ wà nínú rẹ̀ di eléèérí; nítorí pé [títa ẹ̀jẹ̀ èèyàn sílẹ̀] ní ń sọ ilẹ̀ di eléèérí.”—Núm. 35:33, 34.
4. Kí ni wọ́n máa ń ṣe fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn nílẹ̀ Ísírẹ́lì?
4 Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀, síbẹ̀ ó ṣì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé ẹ̀mí èèyàn ti ọwọ́ rẹ̀ bọ́. (Jẹ́n. 9:5) Àmọ́ torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó gbà kí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò mẹ́fà kí ọwọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má bàa tẹ̀ ẹ́. Á rí ààbò níbẹ̀ àmọ́ kò gbọ́dọ̀ jáde nílùú ààbò yẹn títí tí àlùfáà àgbà fi máa kú.—Núm. 35:15, 28.
5. Báwo ni àwọn ìlú ààbò ṣe jẹ́ ká túbọ̀ mọyì Jèhófà?
5 Kì í ṣe èèyàn ló pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣètò àwọn ìlú ààbò. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló pàṣẹ fún Jóṣúà pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Ẹ pèsè àwọn ìlú ńlá ìsádi fún ara yín.’ ” Ibi mímọ́ ni wọ́n ka àwọn ìlú ààbò yẹn sí. (Jóṣ. 20:1, 2, 7, 8) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló dìídì pàṣẹ pé kí wọ́n yan àwọn ìlú yẹn, a lè béèrè pé: Báwo ni ètò yìí ṣe jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àánú Jèhófà? Kí nìyẹn sì kọ́ wa nípa bá a ṣe lè sá di Jèhófà?
KÍ Ó “SỌ Ọ̀RỌ̀ RẸ̀ NÍ ETÍ-ÌGBỌ́ ÀWỌN ÀGBÀ ỌKÙNRIN”
6, 7. (a) Ṣàlàyé bí àwọn àgbà ọkùnrin ṣe máa ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó ṣèèṣì pààyàn. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹni náà sá lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin?
6 Lẹ́yìn tẹ́nì kan bá ṣèèṣì pààyàn, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ “sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní etí-ìgbọ́ àwọn àgbà ọkùnrin” tó wà ní ẹnubodè ìlú ààbò tó sá lọ, àwọn yẹn á sì gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. (Jóṣ. 20:4) Lẹ́yìn àsìkò díẹ̀, wọ́n á rán an pa dà sọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin ìlú tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, kí wọ́n lè bójú tó ẹjọ́ náà. (Ka Númérì 35:24, 25.) Báwọn àgbà ọkùnrin náà bá dá ẹni náà láre pé kò mọ̀ọ́mọ̀ pa onítọ̀hún, wọ́n á dá a pa dà sí ìlú ààbò.
7 Kí nìdí táwọn àgbà ọkùnrin fi ní láti dá sọ́rọ̀ náà? Ìdí ni pé àwọn ló ń mú káwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní mímọ́, wọ́n sì tún ń ṣèrànwọ́ fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn náà kó lè rí àánú Jèhófà gbà. Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé tẹ́ni tó ṣèèṣì pààyàn náà kò bá lọ bá àwọn àgbà ọkùnrin, ṣe ló ń “fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu.” Ó wá fi kún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ máa wà lọ́rùn rẹ̀ torí pé kò sá lọ síbi ààbò tí Ọlọ́run ṣètò fún un.” Òótọ́ ni pé ẹni tó ṣèèṣì pààyàn lè rí ìrànwọ́ gbà, àmọ́ òun náà gbọ́dọ̀ sapá kó lè rí ìrànwọ́ náà gbà. Tí kò bá sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò tí Jèhófà pèsè, ìbátan ẹni tó pa lè gbẹ̀mí rẹ̀.
8, 9. Tí Kristẹni kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kí nìdí tó fi yẹ kó lọ bá àwọn alàgbà?
8 Lóde òní, tí Kristẹni kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ó ṣe pàtàkì pé kó lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Kí nìdí? Àkọ́kọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló ṣètò pé káwọn alàgbà máa bójú tó irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. (Ják. 5:14-16) Ìkejì, tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà, wọ́n á ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà rí ojúure Ọlọ́run, kó má sì pa dà sídìí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. (Gál. 6:1; Héb. 12:11) Ìkẹta, ojúṣe àwọn alàgbà ni láti fi ẹni tó ronú pìwà dà lọ́kàn balẹ̀ kí ara lè tù ú, kódà wọ́n ti dá àwọn alàgbà lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pe àwọn alàgbà ní “ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Aísá. 32:1, 2) Ìṣètò yìí fi hàn pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
9 Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà lọkàn wọn balẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n tọ àwọn alàgbà lọ, tí wọ́n sì rí ìrànwọ́ gbà. Àpẹẹrẹ kan ni ti arákùnrin kan tó ń jẹ́ Daniel. Ó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì àmọ́ kò sọ fáwọn alàgbà. Ó sọ pé: “Ó ti pẹ́ jù, torí náà kò sídìí pé mò n yọ àwọn alàgbà lẹ́nu mọ́. Síbẹ̀, ìgbà gbogbo lẹ̀rù máa ń bà mí torí pé mi ò mọ ohun tó lè tẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà yọ. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń gbàdúrà sí Jèhófà ni mo kọ́kọ́ máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì mí.” Nígbà tó yá, Daniel tọ àwọn alàgbà lọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, ó sọ pé: “Kí n sòótọ́, ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí láti sọ fáwọn alàgbà. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ràn mí lọ́wọ́, ṣe ló dà bíi pé wọ́n gbé ẹrù tó ti wọ̀ mí lọ́rùn kúrò. Ní báyìí, ṣe lọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbàkigbà tí mo bá ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀.” Ẹ̀rí ọkàn Daniel kò dá a lẹ́bi mọ́, ó sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí.
‘KÍ Ó SÁ LỌ SÍ Ọ̀KAN NÍNÚ ÀWỌN ÌLÚ ŃLÁ YÌÍ’
10. Tí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn bá máa rí àánú gbà, ìgbésẹ̀ wo ló yẹ kó gbé?
10 Ìgbésẹ̀ pàtàkì kan wà tó yẹ kẹ́ni tó ṣèèṣì pààyàn gbé kó tó lè rí àánú gbà. Ó gbọ́dọ̀ sá lọ sí ìlú ààbò tó sún mọ́ ọn jù lọ. (Ka Jóṣúà 20:4.) Kì í ṣe ìgbà yẹn lẹni náà á máa yan fanda kiri. Tí kò bá tètè sá lọ sílùú ààbò, kó sì dúró síbẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ lè lọ sí i. Èyí gba pé kó yááfì àwọn nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, ó máa fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, á fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kò sì ní kúrò nílùú ààbò yẹn títí tí àlùfáà àgbà fi máa kú.a (Núm. 35:25) Àmọ́ àwọn ohun tó yááfì tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tẹ́ni náà bá jáde kúrò nílùú ààbò, ṣe ló ń fi hàn pé òun ò kábàámọ̀ bí ẹ̀mí èèyàn ṣe tọwọ́ òun bọ́, ẹ̀mí òun fúnra rẹ̀ sì lè lọ sí i.
11. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló yẹ kí Kristẹni kan tó ti ronú pìwà dà gbé kó lè fi hàn pé òun mọyì àànú Ọlọ́run?
11 Kí Kristẹni kan tó ronú pìwà dà tó lé rí àànú Ọlọ́run gbà, ó gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan. Lóòótọ́ ó gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, àmọ́ ó tún gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké tó lè mú kéèyàn dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìgbésẹ̀ táwọn Kristẹni tó ronú pìwà dà ní Kọ́ríńtì gbé, ó ní: “Ohun yìí gan-an, bíbà yín nínú jẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run, ẹ wo irú ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan tí ó mú jáde nínú yín, bẹ́ẹ̀ ni, wíwẹ ara yín mọ́, bẹ́ẹ̀ ni, ìkannú, bẹ́ẹ̀ ni, ìbẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni, ìyánhànhàn, bẹ́ẹ̀ ni, ìtara, bẹ́ẹ̀ ni, ṣíṣe àtúnṣe àìtọ́ náà!” (2 Kọ́r. 7:10, 11) Tá a bá sapá láti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, a sì mọyì àánú tó fi hàn sí wa.
12. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan yááfì tó bá fẹ́ kí Jèhófà máa fàánú hàn sóun?
12 Kí ló yẹ kí Kristẹni kan yááfì tó bá fẹ́ kí Jèhófà máa fàánú hàn sóun? Ó gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan tó nífẹ̀ẹ́ sí tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan ọ̀hún lè sún un dẹ́ṣẹ̀. (Mát. 18:8, 9) Tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ kan tó máa ń fẹ́ kó o ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra, ṣé wàá yẹra fún wọn? Tó bá jẹ́ pé o sábà máa ń ṣàṣejù nídìí ọtí, ṣé wàá ṣì máa lọ sáwọn ibi tó o mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kó o ti mu ọtí lámujù? Tó bá sì jẹ́ pé èròkerò ló sábà máa ń wá sí ẹ lọ́kàn, ṣé wàá yẹra fáwọn fíìmù, ìkànnì orí íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn nǹkan míì tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ? Ká rántí pé ohunkóhun tá a bá yááfì ká lè rí ojúure Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kò sóhun tó dunni tó kí Jèhófà pa èèyàn tì. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kò sóhun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó kí Jèhófà fi “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” hàn síni títí lọ fáàbàdà.—Aísá. 54:7, 8.
‘KÍ WỌ́N JẸ́ IBI ÌSÁDI FÚN YÍN’
13. Ṣé ẹni tó ṣèèṣì pààyàn lè láyọ̀ kọ́kàn rẹ̀ sí balẹ̀ nílùú ààbò? Ṣàlàyé.
13 Tí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn bá ti wà nílùú ààbò, kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i. Jèhófà sọ nípa àwọn ìlú ààbò náà pé: ‘Kí wọ́n jẹ́ ibi ìsádi fún yín.’ (Jóṣ. 20:2, 3) Jèhófà ò sọ pé kí wọ́n tún dá ẹjọ́ míì fún ẹni tó ṣèèṣì pààyàn náà, òfin ò sì fàyè gba olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ láti wọnú ìlú ààbò wá pa ẹni náà. Torí náà, ọkàn ẹni tó ṣèèṣì pààyàn balẹ̀ pé kò sẹ́ni tó máa wá pa òun. Níwọ̀n ìgbà tó bá ti wà nílùú ààbò, Jèhófà máa dáàbò bò ó. Àmọ́ ìlú ààbò yìí kì í ṣe ẹ̀wọ̀n. Ìdí ni pé ó lè ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó lè ran àwọn míì lọ́wọ́, kó sì sin Jèhófà bó ṣe fẹ́. Èyí fi hàn pé ó lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, kó sì láyọ̀.
14. Ìdánilójú wo ni Kristẹni tó bá ronú pìwà dà ní?
14 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ṣì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ronú pìwà dà. Ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé ojú ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku ni Jèhófà fi ń wo àwọn. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tí Jèhófà bá ti dárí jì ẹ́, á fàánú hàn sí ẹ, kò sì ní máa fojú ẹlẹ́ṣẹ̀ wò ẹ́ mọ́. Daniel tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Lẹ́yìn táwọn alàgbà fún un nímọ̀ràn tí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ó sọ pé: “Ṣe lara tù mí wá. Lẹ́yìn táwọn alàgbà bójú tó ọ̀rọ̀ náà, ọkàn mi ò dá mi lẹ́bi mọ́. Tí Jèhófà bá ti dárí jini, ó ti tán nìyẹn. Bí Jèhófà ṣe sọ, ṣe ló máa ń mú ẹ̀dùn ọkàn wa jìnnà réré sí wa. A ò sì ní rí wọn mọ́ láé.” Tí ẹni tó ṣèèṣì pààyàn bá ti wà nílùú ààbò, kò ní máa bẹ̀rù pé olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ máa pa òun. Lọ́nà kan náà, tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kò yẹ ká máa bẹ̀rù pé ó máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà tàbí pé ó máa fìyà ẹ̀ jẹ wá.—Ka Sáàmù 103:8-12.
15, 16. Tó o bá ń ronú nípa bí Jésù ṣe rà wá pa dà àti bó ṣe jẹ́ Àlùfáà Àgbà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí ẹ?
15 Ìdí míì tún wà tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí wa. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ bó ṣe dun òun tó pé òun ò lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ délẹ̀délẹ̀, ó sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣì ń sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, tó sì ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó dá sẹ́yìn, ó dá a lójú pé Ọlọ́run ti dárí ji òun lọ́lá ìràpadà Jésù. Torí pé Jésù ti rà wá pa dà, a ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ọkàn wa sì balẹ̀. (Héb. 9:13, 14) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé òun ni Àlùfáà Àgbà, “ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.” (Héb. 7:24, 25) Iṣẹ́ tí àlùfáà àgbà ń ṣe nílẹ̀ Ísírẹ́lì mú kó dá àwọn èèyàn náà lójú pé Ọlọ́run máa dárí jì wọ́n. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé kò yẹ kó dá àwa náà lójú pé iṣẹ́ tí Jésù Àlùfáà Àgbà wa ń ṣe máa jẹ́ “kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́”?—Héb. 4:15, 16.
16 Torí náà, tó o bá fẹ́ sá di Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé kó o lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà Jésù. Má kàn wò ó bíi pé gbogbo èèyàn ni Jésù kú fún. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa wò ó bíi pé ìwọ gan-an ni Jésù kú fún. (Gál. 2:20, 21) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọlá ìràpadà Jésù ni Jèhófà ń wò tó fi ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìràpadà Jésù ló mú kó o nírètí ìyè àìnípẹ̀kun. Bákan náà, máa wò ó bíi pé ìwọ ni Jèhófà dìídì fún ní ẹ̀bùn ìràpadà náà.
17. Ṣé wàá sá di Jèhófà, kí nìdí?
17 Àwọn ìlú ààbò yìí jẹ́ ká mọ bí àánú Jèhófà ṣe pọ̀ tó, ó jẹ́ ká rí i pé ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì gan-an lójú rẹ̀. Ó tún jẹ́ ká mọ bí àwọn alàgbà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ àtohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé a ronú pìwà dà lóòótọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú háún pé Jèhófà máa ń dárí jini pátápátá. Ìbéèrè náà ni pé, ṣé ò ń sá di Jèhófà? Ká sòótọ́, kò sẹ́lòmíì tá a lè sá di. (Sm. 91:1, 2) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, àá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlú ààbò yìí, àá sì rí bá a ṣe lè fara wé Jèhófà tó bá dọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo àti àánú.
a Ìwé ìwádìí àwọn Júù kan sọ pé, ó ṣeé ṣe kí ìdílé ẹni tó ṣèèṣì pààyàn náà kó wá sílùú ààbò náà kí wọ́n lè máa gbé pẹ̀lú rẹ̀.