ORIN 8
Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 91)
1. Jèhófà ni ààbò wa.
Ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.
Òjìji rẹ la sá di,
A ò ní sá kúrò láé.
Torí a mọ̀ pé wàá gbèjà
Àwọn tó bá gbára lé ọ.
Jèhófà l’Olùṣọ́ wa;
Olódodo, olóòótọ́ ni.
2. Jèhófà máa ń dáàbò bo
Àwọn olódodo
Àti ọlọ́kàn tútù;
Kò ní pa wọ́n tì láé.
Torí náà, kò yẹ ká bẹ̀rù
Torí ìyọnu àjálù.
Òun yóò máa dá wa nídè
Kúrò lọ́wọ́ ẹni ibi.
3. Ó ń tọ́ wa, ó sì ńṣọ́ wa
Ká má kó sídẹkùn.
Ó ń fún wa lókun ká lè
Máa kojú àtakò.
Kò sí ìdí kankan fún wa
Láti bẹ̀rù ohunkóhun.
Jèhófà ni ààbò wa,
Yóò dáàbò bò wá títí láé.
(Tún wo Sm. 97:10; 121:3, 5; Àìsá. 52:12.)