Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Oníyebíye
1 Ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ní ojú ìwé 57, sọ nípa àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pé: “Wọn ti fi ara wọn hàn pe wọn jẹ olufọkansin tootọ, awọn ẹni tí igbagbọ wọn ti farahan ninu iṣẹ-isin onitara fun Ijọba ati riran awọn ẹlomiran lọwọ lati fẹsẹmulẹ gbọn-in-gbọn-in ninu igbagbọ.” Ní tòótọ́, àpẹẹrẹ tẹ̀mí tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń fi lélẹ̀ yẹ láti fara wé. Jíjùmọ̀ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn àti pẹ̀lú àwọn alàgbà “ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.”—Éfé. 4:16.
2 Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ. Ronú nípa gbogbo iṣẹ́ oníyebíye tí wọ́n ń ṣe! Wọ́n máa ń bójú tó àkáǹtì, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwé ìròyìn, àsansílẹ̀ owó, àti àwọn ìpínlẹ̀; wọ́n máa ń ṣàbójútó èrò, wọ́n máa ń bójú tó ohun èlò ìbánisọ̀rọ̀, wọ́n sì máa ń ṣèrànwọ́ láti ṣètọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n máa ń lọ́wọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Àwọn kan lára wọn tilẹ̀ máa ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn tàbí kí wọ́n darí àwọn kan nínú àwọn ìpàdé ìjọ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ńbà ara ìyára, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí a ń fẹ́.—1 Kọ́r. 12:12-26.
3 Nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá rí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn alàgbà gẹ́gẹ́ bí ara ẹgbẹ́ ìránṣẹ́ kan náà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìgbọ́ra-ẹni-yé tọ̀tún tòsì, ó máa ń fún wọn níṣìírí láti ṣe bákan náà. (Kól. 2:19) Nípa fífi ìṣòtítọ́ ṣe ojúṣe wọn déédéé àti nípa fífi ọkàn-ìfẹ́ hàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹlòmíràn, wọ́n ń fi kún mímú kí ìjọ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
4 Kí la lè ṣe láti fi ìmọrírì wa hàn fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ kára? Ó yẹ ká dojúlùmọ̀ àwọn iṣẹ́ táa yàn fún wọn kí a sì fi hàn pé a múra tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn nígbà tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Lọ́rọ̀ tàbí níṣe, a lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọrírì iṣẹ́ wọn. (Òwe 15:23) Ó yẹ ká ka àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nítorí wa sí gidigidi.—1 Tẹs. 5:12, 13.
5 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàgbékalẹ̀ ojúṣe àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ohun táa béèrè fún láti tóótun. (1 Tím. 3:8-10, 12, 13) Iṣẹ́ ìsìn oníyebíye tí wọ́n ń ṣe kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn bí ìjọ yóò bá ṣe déédéé. Ó yẹ ká máa bá a nìṣó láti fún irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ níṣìírí bí gbogbo wọn ṣe ń ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa.”—1 Kọ́r. 15:58.