ORÍ 6
Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ń Ṣe Ìjọ Láǹfààní
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì pé: “Pọ́ọ̀lù àti Tímótì, àwa ẹrú Kristi Jésù, sí gbogbo ẹni mímọ́ nínú Kristi Jésù, tí wọ́n wà ní ìlú Fílípì, pẹ̀lú àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.” (Fílí. 1:1) Kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó dájú pé ipa pàtàkì ni àwọn ọkùnrin yẹn kó nínú ríran àwọn alàgbà ìjọ lọ́wọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí. Iṣẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe ń ran àwọn alábòójútó lọ́wọ́, ó sì ń jẹ́ kí nǹkan máa lọ létòlétò nínú ìjọ.
2 Ǹjẹ́ o mọ àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà nínú ìjọ rẹ? Ǹjẹ́ o mọ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún àǹfààní rẹ àti ti gbogbo ìjọ lápapọ̀? Ó dájú pé Jèhófà mọrírì ìsapá àwọn arákùnrin yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn ọkùnrin tó ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́nà tó dáa ń ṣe orúkọ rere fún ara wọn, wọ́n á sì lè sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Kristi Jésù.”—1 Tím. 3:13.
OHUN TÍ ÌWÉ MÍMỌ́ SỌ PÉ ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ GBỌ́DỌ̀ KÚNJÚ ÌWỌ̀N RẸ̀
3 Ó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa gbé ìgbésí ayé tó yẹ Kristẹni tòótọ́, kí wọ́n ṣeé fọkàn tán, kí wọ́n sì máa fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ tá a yàn fún wọn. Ó ṣe kedere pé irú ẹni tó yẹ kí wọ́n jẹ́ nìyẹn tá a bá wo ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sí Tímótì, ó ní: “Bákan náà, kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n má ṣe máa mu ọtí lámujù, kí wọ́n má ṣe máa wá èrè tí kò tọ́, kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ bí wọ́n ti ń rọ̀ mọ́ àṣírí mímọ́ ti ìgbàgbọ́. Bákan náà, ká kọ́kọ́ dán wọn wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n; lẹ́yìn náà kí wọ́n di òjíṣẹ́, nítorí wọn ò ní ẹ̀sùn lọ́rùn. Kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ má ṣe ní ju ìyàwó kan lọ, kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ wọn àti ìdílé wọn dáadáa.” (1 Tím. 3:8-10, 12) Ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ kì í ṣe ohun yẹpẹrẹ, tá a bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí, ó máa dáàbò bo ìjọ, ẹnikẹ́ni ò sì ní máa nàka àbùkù pé irú àwọn ọkùnrin wo la gbé iṣẹ́ pàtàkì lé lọ́wọ́.
4 Yálà àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kéré lọ́jọ́ orí tàbí wọ́n dàgbà, wọn kì í gbẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù. Bíi ti Jésù, wọ́n ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Bí wọ́n ṣe ń lo ìtara yìí fi hàn pé àwọn náà fẹ́ kí aráyé rí ìgbàlà bí Jèhófà ṣe fẹ́.—Àìsá. 9:7.
5 Àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tún jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá dọ̀rọ̀ aṣọ wíwọ̀, ìmúra, ọ̀rọ̀ ẹnu wọn, ìwà àti ìṣe wọn. Wọ́n láròjinlẹ̀, èyí sì mú kí àwọn èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ń sapá gidigidi kí àárín àwọn àti Jèhófà má bàa bà jẹ́, wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọ.—Títù 2:2, 6-8.
6 A ti “dán wọn wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n.” Kódà, ká tó yàn wọ́n sípò ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni wọ́n ti fi hàn pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́run tọkàntọkàn. Ire Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ń fi sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn, wọ́n máa ń sapá kọ́wọ́ wọn lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó bá yọjú. Ká sòótọ́, àpẹẹrẹ gidi ni wọ́n jẹ́ fún àwọn míì nínú ìjọ.—1 Tím. 3:10.
IṢẸ́ TÍ WỌ́N Ń ṢE
7 Onírúurú iṣẹ́ tó ń ṣeni láǹfààní ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn, èyí sì ń mú kí àwọn alábòójútó lè máa lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ni àti iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ń pínṣẹ́ fún wọn, wọ́n máa ń kíyè sí ohun tí kálukú wọn lè ṣe àti ohun tí ìjọ nílò.
Onírúurú iṣẹ́ tó ń ṣeni láǹfààní ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe, èyí sì ń mú kí àwọn alábòójútó lè máa lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ni àti iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn
8 Ẹ jẹ́ ká sọ díẹ̀ lára iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe: A lè ní kí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan máa bójú tó àwọn ìwé tá a máa lò fúnra wa àtèyí tá a máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A máa ń ní kí àwọn míì lára wọn máa bójú tó àkọsílẹ̀ ìnáwó ìjọ tàbí àkọsílẹ̀ ìpínlẹ̀ ìwàásù. A máa ń ní kí àwọn míì máa bójú tó makirofóònù, ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tàbí kí wọ́n máa bójú tó èrò, wọ́n sì tún lè máa ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá ká lè máa tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba, kó lè mọ́ tónítóní, torí náà a sábà máa ń pe àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti wá bójú tó àwọn iṣẹ́ náà.
9 Ní àwọn ìjọ kan, ó ṣeé ṣe láti pín àwọn iṣẹ́ yìí lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Láwọn ìjọ míì, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ṣoṣo lè máa ṣe ju iṣẹ́ kan lọ. Ìgbà míì sì rèé, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè máa bójú tó iṣẹ́ kan ṣoṣo. Tí kò bá sí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó pọ̀ tó láti ṣe àwọn kan lára àwọn iṣẹ́ yìí, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè ní kí àwọn arákùnrin míì tí wọ́n ti ṣèrìbọmi tí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere máa ṣe iṣẹ́ tó pọn dandan yìí. Wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó máa wá wúlò nígbà tí wọ́n bá kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí kò bá sì sí àwọn arákùnrin tá a lè lò, a lè ní kí arábìnrin kan tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ máa ṣe àwọn iṣẹ́ kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní yàn án sípò ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹni tá a lè pè ní àpẹẹrẹ rere lẹni tó jẹ́ àwòkọ́ṣe nínú ìwà àti ọwọ́ tó fi mú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó máa ń wá sípàdé déédéé, kì í fiṣẹ́ ìwàásù ṣeré, ó sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe ń bójú tó ìdílé rẹ̀, eré ìnàjú tó ń ṣe, aṣọ tó ń wọ̀, ìmúra rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
10 Ní àwọn ìjọ tí alàgbà kò bá pọ̀ tó, wọ́n lè ní kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi. Àwọn ìbéèrè yìí wà ní ibi tá a pè ní Àfikún nínú ìwé yìí, ìyẹn “Apá Kìíní: Ohun Táwọn Kristẹni Gbà Gbọ́.” Torí pé “Apá Kejì: Ìgbé Ayé Kristẹni,” jẹ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ara ẹni tó jẹ́ ẹlẹgẹ́, alàgbà ni kó bójú tó o.
11 Látìgbàdégbà, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè rí i pé á dáa káwọn yí iṣẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń ṣe pa dà. Àmọ́, ó máa ṣàǹfààní gan-an tí àwọn arákùnrin tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan bá ń ṣe wọn lọ fún àwọn àkókò kan kí wọ́n lè ní ìrírí kí wọ́n sì já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ náà.
12 Bí nǹkan bá ṣe rí nínú ìjọ lè mú káwọn alàgbà yan àwọn iṣẹ́ kan fún ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ‘gbogbo èèyàn rí kedere pé ó ń tẹ̀ síwájú.’ (1 Tím. 4:15) Táwọn alàgbà ò bá pọ̀ tó, wọ́n lè yan ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan pé kó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ alábòójútó àwùjọ, tàbí nígbà míì, wọ́n lè ní kó jẹ́ ìránṣẹ́ àwùjọ, kó máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ àbójútó àwọn alàgbà. Wọ́n lè fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láwọn iṣẹ́ kan nínú Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, wọ́n lè ní kí wọ́n darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ tó bá pọn dandan, wọ́n sì lè ní kí wọ́n sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Láwọn ìgbà míì tó bá pọn dandan, a lè fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn àǹfààní míì, tí wọ́n bá kúnjú ìwọ̀n láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. (1 Pét. 4:10) Ó yẹ káwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti ran àwọn alàgbà lọ́wọ́.
13 Iṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn alàgbà, àmọ́ ara iṣẹ́ ìsìn mímọ́ Ọlọ́run ló jẹ́, ó sì ń jẹ́ kí nǹkan máa lọ dáadáa nínú ìjọ. Táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ń ṣe iṣẹ́ wọn dáadáa, tí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n dámọ̀ràn wọn pé kí wọ́n di alàgbà.
14 Tó o bá jẹ́ arákùnrin tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún tàbí tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, ǹjẹ́ ò ń sapá láti kúnjú ìwọ̀n kó o lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? (1 Tím. 3:1) Torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá sínú òtítọ́ lọ́dọọdún, a nílò àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nípa tẹ̀mí láti bójú tó àwọn iṣẹ́ nínú ìjọ. O lè sapá láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó o bá jẹ́ kó wù ẹ́ láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa ronú jinlẹ̀ lórí àpẹẹrẹ Jésù. (Mát. 20:28; Jòh. 4:6, 7; 13:4, 5) Bó o ṣe ń rí ayọ̀ tó wà nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́, wàá máa fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i. (Ìṣe 20:35) Torí náà, máa yọ̀ǹda ara rẹ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, láti máa tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí láti ṣe iṣẹ́ pàjáwìrì ní Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjísẹ́. Ẹni tó fẹ́ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tún gbọ́dọ̀ sapá kó lè láwọn ànímọ́ tẹ̀mí, wàá sì ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. (Sm. 1:1, 2; Gál. 5:22, 23) Ní àfikún sí ìyẹn, arákùnrin tó ń sapá láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé òun ṣeé gbára lé àti pé òun ṣeé fọkàn tán tí wọ́n bá fún un níṣẹ́ nínú ìjọ.—1 Kọ́r. 4:2.
15 Ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò kí wọ́n lè ṣe ìjọ láǹfààní. Àwọn ará ìjọ lè fi hàn pé àwọn mọrírì iṣẹ́ àṣekára tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe tí wọ́n bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ wọn. Èyí máa fi hàn pé lóòótọ́ ni wọ́n mọrírì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe láti mú kí agbo ilé rẹ̀ wà létòlétò.—Gál. 6:10.