Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere!
1 Bá a ti ń wọ sáà Ìṣe Ìrántí ọdún 2003, a ní ìdí tó pọ̀ rẹpẹtẹ láti jẹ́ “onítara fún ohun rere.” (1 Pét. 3:13) Èyí tó gbapò iwájú jù lọ nínú àwọn ìdí náà ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (Mát. 20:28; Jòh. 3:16) Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí, ó kọ̀wé pé: “Kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè díbàjẹ́, pẹ̀lú fàdákà tàbí wúrà, ni a fi dá yín nídè kúrò nínú ọ̀nà ìwà yín aláìléso. . . . Ṣùgbọ́n ó jẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí ti ọ̀dọ́ àgùntàn aláìlábààwọ́n àti aláìléèérí, àní ti Kristi.” (1 Pét. 1:18, 19) Ìmọrírì wa fún ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí ló ń sún wa láti jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú ṣíṣe ohun rere, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé Jésù “fi ara rẹ̀ fúnni nítorí wa kí ó bàa lè dá wa nídè kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà àìlófin, kí ó sì wẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe mọ́ fún ara rẹ̀, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—Títù 2:14; 2 Kọ́r. 5:14, 15.
2 Nígbà tá a bá ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí, èyí á jẹ́ ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀ a ó sì wà lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Pétérù sọ síwájú sí i pé: “Ẹni tí yóò bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè, tí yóò sì rí àwọn ọjọ́ rere, . . . kí ó yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí ó sì máa ṣe ohun rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀. Nítorí tí ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.” (1 Pét. 3:10-12) Ní àwọn àkókò eléwu tí à ń gbé yìí, ìbùkún ló mà jẹ́ fún wa o, láti mọ̀ pé Jèhófà ń bójú tó wa ó sì múra tán láti dáàbò bò wá, “láti fi ìṣọ́ ṣọ́ [wa] bí ọmọlójú ojú rẹ̀.”—Diu. 32:10; 2 Kíró. 16:9.
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ìjímìjí tí Pétérù kọ̀wé sí ń dojú kọ àwọn àdánwò, ìtara wọn ń jó lala láìsí ohunkóhun tó lè bomi paná rẹ̀, wọ́n sì kéde ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn bó ti lè ṣeé ṣe tó. (1 Pét. 1:6; 4:12) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ni à ń gbé, ìmọrírì tá a ní fún oore Jèhófà ń sún wa láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tìtaratìtara. (2 Tím. 3:1; Sm. 145:7) Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn iṣẹ́ rere tí ọwọ́ wa máa dí pẹrẹu nínú rẹ̀ ní sáà Ìṣe Ìrántí yìí.
4 Ké Sí Àwọn Ẹlòmíràn Wá sí Ìṣe Ìrántí: Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi ìmọrírì wa hàn fún ẹ̀bùn ìràpadà tí kò lẹ́gbẹ́ náà ni nípa wíwà níbi ayẹyẹ ọdọọdún ti ikú Jésù, èyí tí a óò ṣe lọ́dún yìí ní ọjọ́ Wednesday, April 16, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. (Lúùkù 22:19, 20) Lọ́dún tó kọjá, nígbà tá a ṣàkójọ ìròyìn àwọn ìjọ tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlèláàádọ́rùn-ún ó lé ẹgbẹ̀ta [94,600], àròpọ̀ gbogbo àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlẹ́gbẹ̀ta, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́rìndínláàádọ́ta [15,597,746]! Èyí fi ẹgbàá mọ́kànlá [220,000] lé sí ti ọdún tó ṣáájú.
5 Ẹni mélòó ni yóò wá lọ́dún yìí? Èyí sinmi lórí ìsapá tá a bá ṣe tọkàntara láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí láti péjú pésẹ̀ pẹ̀lú wa. Bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ orúkọ gbogbo àwọn tí wàá fẹ́ láti pè. Àwọn tí wàá fi ṣáájú nínú àkọsílẹ̀ náà ní láti jẹ́ àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ. Bí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ bá jẹ́ aláìgbàgbọ́, sọ fún un pé ó wù ọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ pé kó bá ọ pésẹ̀ síbẹ̀. Ọkọ kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ pé ohun tó mú òun wá sí Ìṣe Ìrántí ọdún tó kọjá ni pé, òun rí bí wíwá òun ṣe ṣe pàtàkì sí ìyàwó òun tó. Lẹ́yìn náà, orúkọ àwọn tí wàá kọ tẹ̀ lé e nínú àkọsílẹ̀ rẹ lè jẹ́ àwọn ẹbí rẹ, àwọn aládùúgbò rẹ, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, tàbí àwọn ọmọléèwé rẹ. Rí i dájú pé o kò ṣaláì ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ.
6 Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe àkọsílẹ̀ yìí tán, ṣètò àkókò láti rí i pé o fúnra rẹ dé ọ̀dọ̀ wọn o sì fún wọn ní ìwé ìkésíni. Ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí tí a tẹ̀ ni kó o lò. Láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rántí àkókò àti ibi tí ayẹyẹ náà yóò ti wáyé, fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tẹ àkókò àti ibi tí Ìṣe ìrántí náà yóò ti wáyé sísàlẹ̀ ìwé ìkésíni náà tàbí kó o fọwọ́ kọ ọ́ kó hàn ketekete. Bí April 16 ti ń wọlé bọ̀, máa rán àwọn tí orúkọ wọn wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ létí, bóyá nípa lílọ sọ́dọ̀ wọn tàbí nípasẹ̀ tẹlifóònù. Ẹ jẹ́ ká ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó lọ́wọ́ láti wá síbi ayẹyẹ mímọ́ jù lọ yìí.
7 Ran Àwọn Tó Wá sí Ìṣe Ìrántí Lọ́wọ́: Àkókò ayọ̀ ni alẹ́ ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí sábà máa ń jẹ́. A ní àǹfààní láti kí àwọn èèyàn tí kì í wá sí àwọn ìpàdé wa káàbọ̀. Ṣètò láti tètè dé kó o sì tẹsẹ̀ dúró lẹ́yìn ayẹyẹ náà, bí ipò nǹkan lágbègbè rẹ bá ti gbà ọ́ láyè tó. Lo ìdánúṣe láti dojúlùmọ̀ àwọn ẹni tuntun tí wọ́n wá. Yọ̀ mọ́ wọn kó o sì ṣaájò wọn.—Róòmù 12:13.
8 Ǹjẹ́ a lè ran àwọn kan tí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí lọ́wọ́ láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí nípa ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn nínú ilé wọn? Gbìyànjú láti gba orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn àlejò tí kò tíì sí ẹnì kankan tó ń lọ sọ́dọ̀ wọn kó o lè máa bá a lọ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ wa, díẹ̀ lára àwọn èèyàn wọ̀nyí lè tẹ̀ síwájú dórí dídi ẹni tó tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi kó tó dìgbà Ìṣe Ìrántí ọdún tó ń bọ̀. Nígbà tó o bá ń bẹ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí wò, ké sí wọn láti wá sí àkànṣe àsọyé tí a ó sọ ní April 27.
9 Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Sáà Ìṣe Ìrántí Yìí? Lọ́dọọdún, ìtara wa fún Jèhófà ń sún wa láti sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láwọn oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò. Lọ́dún tó kọjá, ní Nàìjíríà, àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún àti mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún [16,101] ló ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March, nígbà tí àwọn akéde tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, irínwó àti mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [13,487] ṣe é ní oṣù April. Ìsapá tí gbogbo ìjọ bá pawọ́ pọ̀ ṣe láti wàásù ìhìn rere náà tìtaratìtara ní sáà Ìṣe Ìrántí lè mú àwọn àbájáde tó dára gan-an wá.
10 Ìjọ kan tó ní akéde mẹ́tàdínláàádọ́fà [107] àti aṣáájú ọ̀nà déédéé mẹ́sàn-án ròyìn pé, “oṣù tó ṣàrà ọ̀tọ̀” ni oṣù April tó kọjá jẹ́ fún wọn, nítorí pé akéde mẹ́tàléláàádọ́ta [53] ló ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, gbogbo àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló sì wà lára wọn. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe mú kí ìtara àwọn ará pọ̀ sí i láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù yẹn? Ṣáájú kí oṣù March àti April tó dé ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í rọ ọ̀pọ̀ akéde bó ti lè ṣeé ṣe tó láti forúkọ sílẹ̀. Wọ́n ṣe àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá láwọn àkókò tó yàtọ̀ síra lóòjọ́, lọ́nà tó fi máa rọrùn fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ.
11 Arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún, tí kò lè rìn nítorí àìsàn, forúkọ sílẹ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù ní òwúrọ̀, nípa jíjókòó nídìí tábìlì ilé ìgbọ́únjẹ tí yóò sì jẹ́rìí fún bíi wákàtí mélòó kan. Lẹ́yìn náà yóò lọ sinmi díẹ̀, yóò sì tún padà wá láti wá ṣe díẹ̀ sí i. Ọ̀kan lára àwọn tó pè lórí tẹlifóònù ti pàdánù ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì tí wọn ò tíì pé ogún ọdún láàárín ọdún méjì sígbà náà, kò sì lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ láti ṣẹlẹ̀. Arábìnrin náà jẹ́rìí kúnnákúnná fún obìnrin náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Èyí fi hàn pé ìtara fún Jèhófà lè sún àwọn tí ara wọn kò le pàápàá láti sa ipá wọn ní kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà láwọn oṣù tó wà fún àkànṣe ìgbòkègbodò wọ̀nyí. Àwọn tí kò ní tẹlifóònù náà lè sa gbogbo ipá wọn bákan náà. Àwọn tí kò bá lè rìn lè rọra jókòó sí ibi tí wọ́n á ti lè jẹ́rìí fún àwọn èèyàn tó ń kọjá lọ.
12 Àwọn alàgbà ìjọ náà kádìí ọ̀rọ̀ wọn nípa sísọ pé: “Oṣù náà gbádùn mọ́ wa gan-an ni, a sì mọrírì àwọn àǹfààní tí Jèhófà ṣílẹ̀kùn rẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa àtàwọn ìbùkún rẹ̀ lórí wa.” Bí ẹ bá ṣe ètò tó dára, ìjọ tiyín náà lè gbádùn irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀.
13 Sapá Láti Ṣe Gbogbo Ohun Tó O Bá Lè Ṣe Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà: Ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa ló ń sún wa láti ra àkókò padà lóṣooṣù láti sọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn. (Mát. 22:37-39) Àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àtàwọn olùrànlọ́wọ́ wọn ní láti sapá láti ran àwọn tó wà nínú àwùjọ wọn lọ́wọ́ láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lóṣooṣù. Ọ̀nà dáradára kan láti ṣe èyí ni nípa ṣíṣètò ṣáájú láti bá àwọn kan pàtó nínú àwùjọ náà ṣiṣẹ́. Dípò tí ẹ óò fi dúró di ìgbà tí oṣù bá parí kẹ́ ẹ tó ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ tètè bẹ̀rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti ròyìn ní ìlàjì oṣù. Èyí yóò fún yín ní àǹfààní púpọ̀ sí i láti ṣe ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ fún wọn.
14 Ǹjẹ́ àwọn akéde aláìlera tó ṣòro fún gan-an láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà wà nínú àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ yín? Bó bá jẹ́ pé ilé ìwòsàn làwọn kan wà tàbí tí wọn kò lè jáde nílé, ó ṣe kedere pé wọn ò ní fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti jẹ́rìí. Àmọ́ nípa lílo ìwọ̀nba àǹfààní tí wọ́n ní láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn tàn, wọ́n lè sún àwọn tó ń rí iṣẹ́ rere wọn láti ní ìfẹ́ àtọkànwá sí òtítọ́. (Mát. 5:16) Kí àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rí i dájú pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé wọ́n lè ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá látorí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sókè. Ohun ìṣírí ló jẹ́ fún àwọn akéde olùṣòtítọ́ wọ̀nyí láti lè ròyìn àkókò tí wọ́n lò láti jẹ́rìí, ó sì máa ń mú inú wọn dùn gan-an. Èyí tún ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ìròyìn ìgbòkègbodò táwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe kárí ayé pé pérépéré.
15 Àwọn Ọ̀dọ́ Tí Ọwọ́ Wọn Dí Nínú Ṣíṣe Ohun Rere! Ẹ ò rí i pé ara wa máa ń yá gágá láti rí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí wọ́n ń lo okun wọn àti agbára wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! (Òwe 20:29) Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ọ̀nà wo lo lè gbà fi ìtara rẹ fún Jèhófà hàn láwọn oṣù àkànṣe tó kún fún ìgbòkègbodò yìí?
16 Bó bá jẹ́ pé akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi ṣì ni ọ́ nínú ìjọ, ǹjẹ́ o lè sapá kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àǹfààní yẹn? Béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lọ́wọ́ ara rẹ: ‘Ṣé mo ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú Bíbélì? Ǹjẹ́ ó wù mí láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà? Ṣé àwọn ẹlòmíràn lè fi ìwà mi ṣe àwòkọ́ṣe? Ǹjẹ́ mo lè fúnra mi ṣàlàyé ìgbàgbọ́ mi, nípa sísọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn? Ǹjẹ́ ọkàn mi ń sún mi láti ṣe bẹ́ẹ̀?’ Bó o bá lè dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, nígbà náà, bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ọkàn rẹ láti di akéde. Àwọn òbí rẹ yóò lọ bá ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn.
17 Bó o bá ti di akéde ìhìn rere, ǹjẹ́ o lè lo àǹfààní àkókò ìsinmi ilé ẹ̀kọ́ láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? Nípa níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó dára pa pọ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn òbí àti ti àwọn ẹlòmíràn, ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ti ṣèrìbọmi láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bí ìyẹn kò bá ṣeé ṣe, pinnu nígbà náà láti ṣe ju ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Gbé góńgó kan tí wàá máa lépa kalẹ̀ fún ara rẹ. Yàtọ̀ sí pé o pinnu láti fi kún wákàtí rẹ, tún gbé góńgó mìíràn kalẹ̀, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú mímú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ sunwọ̀n sí i. Bóyá o lè sapá láti rí i pé ò ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ní ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan tó o bá dé, o lè mú kí bó o ṣe ń darí ìpadàbẹ̀wò dára sí i, o lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, tàbí kó o mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i nípa fífi ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù tàbí àwọn apá mìíràn nínú iṣẹ́ ìsìn náà kún un. Ṣé o lè gbé góńgó mìíràn kalẹ̀, ìyẹn ni pé kó o ṣètò kí aládùúgbò rẹ kan, ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ rẹ kan, tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan tẹ̀ lé ọ wá sí Ìṣe Ìrántí ọdún yìí? Kíkópa ní kíkún nínú irú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ yóò mú ìbùkún wá fún ọ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì dájú pé yóò jẹ́ ìṣírí fún àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ.—1 Tẹs. 5:11.
18 Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú: Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ní ìpíndọ́gba lóṣù kọ̀ọ̀kan, àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a darí ní Nàìjíríà jẹ́ ogún ọ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún méje, igba àti mẹ́tàlélógójì [407,243]. Bí àkókò ti ń lọ, ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí yóò tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Àmọ́ o, kí ọwọ́ wọn tó lè tẹ góńgó yẹn, a ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere náà. Ìgbésẹ̀ pàtàkì lèyí jẹ́ nínú kíkọ́ àwọn ẹni tuntun láti di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. (Mátíù 9:9; Lúùkù 6:40) Ṣé o ní akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ti múra tán láti gbé ìgbésẹ̀ yẹn?
19 Bí kò bá dá ọ lójú bóyá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ń tẹ̀ síwájú, wá ìrànlọ́wọ́ alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ tàbí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Bóyá o lè ní kó bá ọ lọ nígbà tó o bá fẹ́ lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí ní ìrírí aláìlẹ́gbẹ́ tó o lè jàǹfààní nínú rẹ̀ láti mọ bí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nípa tẹ̀mí. Wọ́n lè pèsè àwọn àbá tó máa ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní títẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
20 Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bá sọ pé òun fẹ́ láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, tó o sì ronú pé ó ti kúnjú ìwọ̀n, bá alábòójútó olùṣalága sọ̀rọ̀. Yóò ṣètò láti rí i pé àwọn alàgbà méjì pàdé pọ̀ pẹ̀lú rẹ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà láti wò ó bóyá ó tóótun, nípa lílo ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 98 àti 99 nínú ìwé Iṣetojọ. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 15, 1988, ojú ìwé 17.) Bí wọ́n bá fọwọ́ sí i pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà di akéde, o ní láti bẹ̀rẹ̀ sí í dá a lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yẹ-ò-sọkà. Gbàrà tó bá ti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá àkọ́kọ́ sílẹ̀, àwọn alàgbà yóò ṣèfilọ̀ fún ìjọ pé akẹ́kọ̀ọ́ náà ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ìrètí wa ni pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akéde tuntun, lọ́mọdé àti lágbà, yóò lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi ní àwọn oṣù àkànṣe tó kún fún ìgbòkègbodò yìí.
21 Mímúrasílẹ̀ Ṣáájú Yóò Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Ṣe Ọ̀pọ̀ Ohun Rere: Ipa kékeré kọ́ ni mímúrasílẹ̀ ṣáájú yóò kó láti mú ká kẹ́ṣẹ́ járí nínú àwọn ìgbòkègbodò wa ní sáà Ìṣe Ìrántí yìí. (Òwe 21:5) Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn alàgbà yóò nílò láti pe àfiyèsí sí.
22 Láti lè ran ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn alàgbà ní láti ṣe àwọn ètò tó yẹ láti rí i pé ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ń wáyé lójoojúmọ́ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀ àti ní òpin ọ̀sẹ̀. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn mú ipò iwájú nínú ṣíṣe àwọn ètò wọ̀nyí. Ǹjẹ́ ẹ lè ṣètò àfikún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní òwúrọ̀, ọ̀sán, tàbí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́? Kí a jẹ́ kí ìjọ mọ̀ nípa àwọn ètò wọ̀nyí. Yóò ṣèrànwọ́ bí ẹ bá lẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.
23 Kí àwọn alàgbà rí i dájú pé àwọn ètò tó wà fún Ìṣe Ìrántí ti wà ní sẹpẹ́ ṣáájú April 16. Èyí kan ètò bí ìjọ yín àtàwọn ìjọ mìíràn tó ń pàdé níbẹ̀ yóò ṣe pín Gbọ̀ngàn Ìjọba lò, mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní, yíyan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri, àti rírí i pé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà ti wà lọ́wọ́. Kí a jẹ́ kí ìjọ mọ àkókò àti ibi tí Ìṣe Ìrántí náà yóò ti wáyé àti ìyípadà èyíkéyìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé fún ọ̀sẹ̀ náà. Bíbójú tó àwọn nǹkan wọ̀nyí tọkàntọkàn yóò mú kí ayẹyẹ náà “ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.
24 Àwọn olórí ìdílé lè lo díẹ̀ lára àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn láti jíròrò bí ìdílé wọn ṣe lè kópa nínú ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i ní sáà Ìṣe Ìrántí. Ǹjẹ́ gbogbo ìdílé yín lápapọ̀ lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Àbí ìdílé yín lè kọ́wọ́ ti ẹnì kan tàbí méjì lẹ́yìn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Bí ìyẹn kò bá ṣeé ṣe, ẹ gbé àwọn góńgó pàtó kalẹ̀ nínú ìdílé yín láti lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ǹjẹ́ ẹnì kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré wà nínú ìdílé yín, tó jẹ́ pé bí ẹ bá fún un ní ìṣírí díẹ̀ tí ẹ sì ràn án lọ́wọ́, ó lè di ẹni tó tóótun bí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi? Ẹni mélòó ni ìdílé yín lè ké sí wá sí Ìṣe Ìrántí ọdún yìí? Ìwéwèé tó dára yóò mú ọ̀pọ̀ ìbùkún àti ayọ̀ wá fún ìdílé yín.
25 Lo Ìwọ̀nba Àkókò Tó Ṣẹ́ Kù ní Kíkún: Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ó rán wọn létí bí àkókò náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó nítorí òpin ètò nǹkan àwọn Júù ti sún mọ́lé. (1 Pét. 4:7) Lónìí, gbogbo ẹ̀rí tí à ń rí fi hàn pé òpin ètò àwọn nǹkan lágbàáyé ti sún mọ́lé. Lójoojúmọ́, ọ̀nà tí à ń gbà gbé ìgbésí ayé wa gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé a gbà pé òtítọ́ lèyí. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà onítara, a gbọ́dọ̀ pọkàn wa pọ̀ sórí iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere náà, èyí tó ti di kánjúkánjú báyìí.—Títù 2:13, 14.
26 Àkókò tá a wà yìí la ní láti fi ìtara hàn ká sì gbé ìgbésẹ̀! Ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ọ, fún ìdílé rẹ, àti fún ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè san ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní tá a ti rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ padà láé, ó kéré tán, a lè fún Jèhófà ní ìjọsìn tó wá látọkàn wa. (Sm. 116:12-14) Gbogbo ìsapá aláápọn wa ni Jèhófà yóò bù kún. (Òwe 10:22) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa jẹ́ “onítara fún ohun rere” ní sáà àkànṣe tó kún fún ìgbòkègbodò yìí, “kí a lè yin Ọlọ́run lógo nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ Jésù Kristi.”—1 Pét. 3:13; 4:11.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Iye Àwọn Tí Wọ́n Wá sí Ìṣe Ìrántí Jákèjádò Ayé
199914,088,751
200014,872,086
200115,374,986
200215,597,746
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ta Ni Wàá Pè Wá sí Ìṣe Ìrántí?
□ Ìdílé rẹ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tó sún mọ́ ọ
□ Àwọn aládùúgbò àtàwọn ojúlùmọ̀ rẹ
□ Àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń relé ìwé
□ Àwọn ìpadàbẹ̀wò àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ran Àwọn Tó Wá sí Ìṣe Ìrántí Lọ́wọ́
□ Kí wọn káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà
□ Bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn náà
□ Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n
□ Ní kí wọ́n wá gbọ́ àkànṣe àsọyé
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Góńgó Wo Lo Gbé Kalẹ̀ fún Sáà Ìṣe Ìrántí?
□ Rí i pé ẹnì kan tó o ké sí wá sí Ìṣe Ìrántí
□ Kí o tóótun láti di akéde ìhìn rere
□ Lo iye wákàtí kan pàtó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́
□ Tẹ̀ síwájú ní ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan pàtó
□ Ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́