Ẹ Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Nìṣó Láìṣojo
1 Àwa Kristẹni mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fetí sí ìwàásù wa. (Mát. 10:14) Síbẹ̀, a kì í tìtorí pé àwọn kan kì í fẹ́ gbọ́, ká wá rẹ̀wẹ̀sì débi tá a ó fi ṣíwọ́ pípolongo ìhìn rere náà. (Òwe 29:25) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a ó fi máa sọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó láìṣojo?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì “ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù.” Èyí ló jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.” (Fílí. 3:8; 1 Tẹs. 1:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ka ìhìn rere tó ń wàásù sí ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ òpònú, ó mọ̀ pé “agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́” ni ìhìn rere tóun ń polongo jẹ́. (Róòmù 1:16) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kódà nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí i, ńṣe ló ṣáà ń sọ̀rọ̀ “pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà.”—Ìṣe 14:1-7; 20:18-21, 24.
3 Bá A Ṣe Ń Rí Okun Gbà: Kì í ṣe agbára Pọ́ọ̀lù náà ló tó bẹ́ẹ̀ débi tó fi lè máa wàásù láìṣojo. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa òun àti Sílà, ó kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ jìyà, tí a sì hùwà sí wa lọ́nà àfojúdi . . . ní ìlú Fílípì, [a] máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.” (1 Tẹs. 2:2; Ìṣe 16:12, 37) Bákan náà, lásìkò tó wà nínú àhámọ́ nílùú Róòmù, ó bẹ̀bẹ̀ pé káwọn ará máa gbàdúrà fóun kóun lè máa bá a lọ láti máa wàásù ìhìn rere náà ‘láìṣojo bó ṣe yẹ kóun máa sọ̀rọ̀.’ (Éfé. 6:18-20) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbára lé Jèhófà dípò agbára tiẹ̀ nìkan ló jẹ́ kó lè máa sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìṣojo.—2 Kọ́r. 4:7; Fílí. 4:13.
4 Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Arákùnrin kan tí kì í fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí kò sì lè bẹ̀rẹ̀ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún sínú àdúrà, bó ṣe dẹni tó ń wàásù láìṣojo nìyẹn o. Nígbà tó ń bá ọkùnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀, ọkùnrin náà kọ́kọ́ kọ̀ jálẹ̀, àfìgbà tí arákùnrin yẹn mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ àjíǹde ló tó gbà pé kó wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Látìgbà yẹn ni arákùnrin yìí kì í ti í jẹ́ kí àǹfààní èyíkéyìí kọjá láìjẹ́ pé òun wàásù. Níbi iṣẹ́ míì tí wọ́n gbà á sí, èèyàn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ló kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ṣèrìbọmi láàárín ọdún mẹ́rìnlá tó fi ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ẹ jẹ́ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa fún wa lókun tá a ó lè ‘fi máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìṣojo.’—Ìṣe 4:29.