Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ronú Jinlẹ̀
1. Ọ̀nà wo ló gbéṣẹ́ jù lọ láti máa gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
1 Ọ̀nà wo ló gbéṣẹ́ jù lọ láti gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣé èyí tó máa dà bíi pé ńṣe là ń fọ̀rọ̀ gún wọn lára ni àbí èyí tó máa jẹ́ kí ẹni tí à ń bá sọ̀rọ̀ ronú, kó sì parí èrò síbi tó tọ̀nà? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn Júù tó wà ní Tẹsalóníkà sọ̀rọ̀, ńṣe ló bá wọn fèrò wérò, ohun tí èyí sì yọrí sí ni pé “àwọn kan lára wọ́n di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 17:2-4) Báwo la ṣe máa fèrò wérò pẹ̀lú àwọn èèyàn?
2. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nígbà tá a bá ń wàásù ìhìn rere?
2 Ronú Nípa Ìmọ̀lára Ẹni Náà àti Ibi Tó Ti Wá: Tá a bá fẹ́ fèrò wérò pẹ̀lú ẹni tí à ń wàásù fún, a ní láti ronú nípa bí ọ̀rọ̀ ṣe máa rí lára rẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ bá àwọn aláìgbàgbọ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì sọ̀rọ̀ ní Gbọ̀ngàn Áréópágù, ńṣe ló kọ́kọ́ sọ àwọn ohun tó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ̀, tí wọ́n sì gbà gbọ́. (Ìṣe 17:22-31) Torí náà, tó o bá ń múra bó o ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí, ronú nípa ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín gbà gbọ́ àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń fi ṣe àtakò. (1 Kọ́r. 9:19-22) Bí ẹni tí ò ń wàásù fún bá ṣe àtakò, gbìyànjú láti wá ibi tí ọ̀rọ̀ yín ti jọra, kó o sì jẹ́ kí ìjíròrò yín dá lórí rẹ̀.
3. Báwo la ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú àwọn èèyàn lọ́nà tó gbẹ́ṣẹ́ nípa fífi ọgbọ́n lo ìbéèrè?
3 Máa Fọgbọ́n Lo Ìbéèrè: A kò lè júwe ọ̀nà fún ẹnì kan tí a kò bá mọ ibi tí ẹni náà wà gan-an. Bákan náà, a kò lè ran ẹni tí à ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ láti parí èrò sí ibi tó tọ́ bí a kò bá mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Kí Jésù tó fèrò wérò pẹ̀lú ẹnì kan, ó sábà máa ń béèrè ìbéèrè kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn onítọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹnì kan béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?,” Jésù kọ́kọ́ béèrè ohun tí ọkùnrin yẹn fúnra rẹ̀ rò kó tó dáhùn ìbéèrè rẹ̀. (Lúùkù 10:25-28) Nígbà kan tí Pétérù kò dáhùn ìbéèrè kan bó ṣe yẹ, Jésù fọgbọ́n lo ìbéèrè láti tún ìrònú rẹ̀ ṣe. (Mát. 17:24-26) Torí náà, bí ẹni tí ò ń wàásù fún bá béèrè ìbéèrè tàbí tó sọ ọ̀rọ̀ kan tí kò tọ̀nà, a lè lo ìbéèrè láti ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú nípa ọ̀ràn náà.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká ran ẹni tí à ń wàásù fún lọ́wọ́ kó lè ronú jinlẹ̀?
4 Tá a bá ran ẹni tí à ń wàásù fún lọ́wọ́ kó lè ronú jinlẹ̀, àpẹẹrẹ Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà àti tàwọn ajíhìnrere tí wọ́n já fáfá ní ọ̀rúndún kìíní là ń tẹ̀ lé yẹn. A máa ń buyì kún ẹni tí à ń bá sọ̀rọ̀, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un. (1 Pét. 3:15) Ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ gbà wá láyè láti pa dà wá lọ́jọ́ míì.