Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ May 1
“Ká sọ pé o lè yanjú ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tó wà láyé, èwo ni wàá fẹ́ yanjú? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ pé láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí ìṣòro yẹn àti gbogbo ìṣòro tó wà láyé. [Ka ẹsẹ Bíbélì kan tó bá a mu, irú bíi Dáníẹ́lì 2:44; Òwe 2:21, 22; Mátíù 7:21-23; tàbí 2 Pétérù 3:7.] Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ ìgbà tí Ọlọ́run máa ṣe àwọn àyípadà rere yìí ní ayé yìí àti bó ṣe máa ṣe é.”
Ji! May–June
“À wá ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ yín ká lè fún yín ní ìwé ìròyìn Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. [Fi iwájú ìwé ìròyìn náà hàn án.] Kálukú ló ní èrò tiẹ̀ nípa ìbéèrè yìí: ‘Ǹjẹ́ O Gbà Pé Ọlọ́run Wà?’ Lérò tiyín, ta ló máa gbà pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ṣé ẹni tó gbà pé Ọlọ́run wà ni àbí ẹni tí kò gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹ gbọ́ ìlérí kan tí Ọlọ́run ṣe tó ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìrètí. [Ka Sáàmù 37:10, 11.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìdí mẹ́rin tó fi yẹ ká ṣèwádìí bóyá Ọlọ́run wà.”