Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ January 1
“Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí máa dára gan-an tí gbogbo wa bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí? [Ka Hébérù 13:18, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti oṣù yìí sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa.”
Ji! January–February
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe kàyéfì nípa ìwà àgàbàgebè àtàwọn ẹ̀kọ́ èké tó wà nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn. Kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn lọ́jọ́ iwájú? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pàtàkì kan tó wà nínú ìwé Ìṣípayá, èyí tó sọ nípa bí àwọn èèyàn á ṣe kúrò nínú ìsìn èké àti bí Ọlọ́run ṣe máa pa ìsìn èké run pátápátá.”