ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Gbà Torí Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Tó Fi Àpẹẹrẹ Tó Dáa Lélẹ̀
NÍGBÀ tí mo ṣì kéré, kò rọrùn fún mi láti lọ sóde ẹ̀rí. Àmọ́ nígbà tí mo dàgbà, mo ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó kà mí láyà, tí mi ò sì ronú láé pé màá lè ṣe. Torí náà, ẹ jẹ́ kí n sọ díẹ̀ fún yín nípa àwọn tó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún mi tó jẹ́ kí n borí ìbẹ̀rù. Bí wọ́n ṣe ràn mí lọ́wọ́ mú kí n rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà, ìyẹn ló sì mú kí n wà lẹ́nu iṣẹ́ alákòókò kíkún fún ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58) títí di báyìí.
Ìpínlẹ̀ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé ni wọ́n bí mi sí nílùú Quebec City. Louis àti Zélia lorúkọ àwọn òbí mi, wọ́n sì fìfẹ́ hàn sí mi gan-an bí mo ṣe ń dàgbà. Onítìjú ni bàbá mi, wọ́n sì fẹ́ràn kí wọ́n máa kàwé. Ní tèmi, mo gbádùn kí n máa kọ̀wé, mo sì ronú pé màá di akọ̀ròyìn lọ́jọ́ kan.
Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá (12), ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Rodolphe Soucy tóun àti bàbá mi jọ ń ṣiṣẹ́ wá sílé wa pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn méjèèjì. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ púpọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn wọn. Síbẹ̀, bí wọ́n ṣe ń fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wa mú kí n ronú jinlẹ̀, bó sì ṣe rí lára àwọn òbí mi náà nìyẹn. Torí náà, a gbà kí wọ́n máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nígbà yẹn, ilé ìwé Kátólíìkì kan ni mò ń lọ, mo sì máa ń sọ nípa àwọn nǹkan tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ọmọ kíláàsì mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn tíṣà tó jẹ́ àlùfáà gbọ́ nípa ẹ̀. Dípò kí wọ́n fi Bíbélì ta ko ohun tí mò ń sọ, ṣe ni ọ̀kan lára wọn pè mí ní ọlọ̀tẹ̀ níṣojú gbogbo ọmọ kíláàsì mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò yẹn ò rọrùn fún mi rárá, ó jẹ́ kí n rí i pé ohun tí ẹ̀sìn yẹn ń kọ́ wa kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé irú ilé ìwé yẹn kọ́ ló yẹ kí n wà. Torí náà, àwọn òbí mi mú mi lọ sílé ìwé míì.
ÀWỌN OHUN TÍ MO KỌ́ MÚ KÍ N NÍFẸ̀Ẹ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Mò ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ, àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ síwájú torí ẹ̀rù máa ń bà mí láti wàásù láti ilé dé ilé. Ìdí sì ni pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ló ń darí ọ̀pọ̀ nǹkan níbẹ̀, wọ́n sì ń ta kò wá gan-an torí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Maurice Duplessis ni olórí ìpínlẹ̀ Quebec nígbà yẹn, òun àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sì mọwọ́ ara wọn dáadáa. Torí náà, ó gbà káwọn jàǹdùkú máa halẹ̀ mọ́ wa, kí wọ́n sì máa fojú pọ́n wa. Ká sòótọ́, ó gba ìgboyà gidi kéèyàn tó lè wàásù nígbà yẹn.
Arákùnrin John Rae tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹsàn-án ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ló jẹ́ kí n borí ìbẹ̀rù. Arákùnrin John nírìírí gan-an, ó ní sùúrù, ó sì ṣeé sún mọ́. Kì í tẹnu mọ́ àwọn àṣìṣe mi, dípò bẹ́ẹ̀ àpẹẹrẹ tó dáa tó fi lélẹ̀ mú kó rọrùn fún mi láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Arákùnrin John ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè Faransé, torí náà mo sábà máa ń bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí kí n lè ràn án lọ́wọ́. Bí mo ṣe ń bá a rìn ló jẹ́ kí n pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Mo ṣèrìbọmi ní May 26, 1951, ìyẹn ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àwa tá a wà níjọ tó wà nílùú Quebec City ò pọ̀, síbẹ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà ló pọ̀ jù láàárín wa. Àpẹẹrẹ tó dáa tí wọ́n fi lélẹ̀ ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà yẹn, Bíbélì nìkan la máa ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé. Torí pé a kì í lo ìtẹ̀jáde míì, ó di dandan pé ká mọ Bíbélì dunjú. Torí náà, mo sapá gan-an kí n lè mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo lè fi ti ohun tí mo gbà gbọ́ lẹ́yìn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn kì í fẹ́ ka Bíbélì tí kò bá ti ní àmì àṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nínú.
Lọ́dún 1952, mo fẹ́ arábìnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Simone Patry tá a jọ wà nínú ìjọ kan náà. Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, a kó lọ sílùú Montreal, a sì bí ọmọ obìnrin kan tó ń jẹ́ Lise láàárín ọdún kan tá a ṣègbéyàwó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ku díẹ̀ kí n ṣègbéyàwó ni mi ò ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mọ́, èmi àti Simone rí i pé a jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn kí ìdílé wa lè ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà.
Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìyẹn ni mo tó ronú nípa bí màá ṣe túbọ̀ mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi gbòòrò sí i. Lọ́dún 1962, mo lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà fún oṣù kan, èmi àti Arákùnrin Camille Ouellette la sì jọ wà níyàrá. Ìtara tí Arákùnrin Camille ní fún iṣẹ́ ìsìn wú mi lórí gan-an pàápàá torí pé ó ti níyàwó, ó sì láwọn ọmọ. Ìdí sì ni pé nígbà yẹn, ó ṣòro ká tó rí ẹni tó ti ní ìdílé tó sì tún ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ohun tí Camille ń gbìyànjú àtiṣe gan-an nìyẹn. Ní gbogbo àkókò tá a jọ lò, ó gbà mí níyànjú pé kí n túbọ̀ ronú nípa bí mo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, mo rí i pé mo ṣì lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kọminú sí ìpinnu tí mo ṣe yẹn, mi ò ṣiyèméjì. Mo gbà pé Jèhófà máa bù kún mi bí mo ṣe ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.
A DI AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ ÀKÀNṢE NÍ QUEBEC CITY
Ní 1964, ètò Ọlọ́run sọ èmi àti Simone di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Quebec City, ìlú ìbílẹ̀ wa, a sì ṣiṣẹ́ sìn níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà yẹn, àtakò tá à ń kojú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ti dín kù, àmọ́ àwọn kan ṣì ń ta kò wá.
Nígbà tí mò ń wàásù láti ilé dé ilé lọ́sàn-án Saturday kan, ọlọ́pàá kan mú mi. Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Sainte-Marie tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Quebec City ni mo ti ń wàásù lọ́jọ́ náà. Ọlọ́pàá náà mú mi lọ sí àgọ́ wọn, ó sì tì mí mọ́lé torí wọ́n ní mò ń wàásù láìgbàṣẹ. Nígbà tó yá, wọ́n gbé mi lọ síwájú adájọ́ kan tó ń jẹ́ Baillargeon, ọkùnrin yìí sì máa ń halẹ̀ mọ́ọ̀yàn gan-an. Ó bi mí pé ta ni agbẹjọ́rò mi, mo sì sọ fún un pé Glen Howa ni. Ṣe ló pariwo pé: “Láéláé, kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Agbẹjọ́rò ni Arákùnrin Glen How, gbogbo èèyàn ló sì mọ̀ pé tó bá di pé ká gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sí ẹlẹ́gbẹ́ ẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ilé ẹjọ́ sọ fún mi pé wọ́n ti fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí.
Àtakò tí wọ́n ń ṣe sí wa ní Quebec ò jẹ́ kó rọrùn láti ríbi tó bójú mu tá a ti máa ṣèpàdé. Ibi ìgbọ́kọ̀sí kan tí wọn ò lò mọ́ la ti ń ṣèpàdé, ibẹ̀ sì máa ń tutù gan-an nígbà òtútù. Torí náà ká lè móoru, àwọn ará máa ń gbé ẹ̀rọ kan wá tó máa ń múlé móoru. A máa ń jókòó yí ẹ̀rọ náà ká fún wákàtí díẹ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, àá sì máa sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró.
Inú mi dùn gan-an bí mo ṣe ń rí bí iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń méso jáde lọ́dọọdún. Lọ́dún 1960 sí 1969, ìwọ̀nba ìjọ ló wà ní Quebec City, ìyẹn lágbègbè Côte-Nord àti Gaspé Peninsula lápapọ̀. Àmọ́ lónìí, wọ́n ti lé ní àyíká méjì, wọ́n sì ti ní àwọn ilé ìpàdé tó rẹwà gan-an.
A DI ALÁBÒÓJÚTÓ ARÌNRÌN ÀJÒ
Lọ́dún 1970, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti Simone bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Nígbà tó sì dọdún 1973, wọ́n sọ wá di alábòójútó agbègbè. Láwọn ọdún yẹn, mo kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára àwọn arákùnrin tó tóótun bí Arákùnrin Laurier Saumurb àti Arákùnrin David Splanec táwọn náà wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn àjò. Lẹ́yìn àpéjọ kọ̀ọ̀kan tá a bá ṣe, èmi àti Arákùnrin David máa ń fún ara wa nímọ̀ràn nípa bá a ṣe lè túbọ̀ di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́. Mo rántí ìgbà kan tí Arákùnrin David sọ fún mi pé: “Léonce, mo gbádùn àsọyé tó o sọ níparí ìpàdé yẹn. Ó dáa gan-an, àmọ́ ká sọ pé èmi ni, àsọyé mẹ́ta ni màá fi sọ!” Òótọ́ sì ni torí ṣe ni mo kó ìsọfúnni jọ pelemọ sínú àsọyé náà. Mo rí i pé mo gbọ́dọ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ mi máa ṣe pàtó, kó sojú abẹ níkòó, kó sì ṣe ṣókí.
Ètò Ọlọ́run ṣètò pé kí àwọn alábòójútó agbègbè máa bẹ àwọn alábòójútó àyíká wò, kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí. Àmọ́ torí pé ọ̀pọ̀ àwọn akéde tó wà ní Quebec mọ̀ mí dáadáa, wọ́n máa ń fẹ́ kí n bá àwọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tí n bá bẹ àyíká wọn wò. Mo máa ń gbádùn bí mo ṣe ń bá wọn lọ sóde ẹ̀rí, àmọ́ mi ò kì í lo àkókò tó tó pẹ̀lú alábòójútó àyíká. Nígbà kan, alábòójútó àyíká kan sọ fún mi pé: “Bí ẹ ṣe ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará dáa, àmọ́ ẹ má gbàgbé pé èmi ni mo ni ọ̀sẹ̀ yìí. Ó yẹ kẹ́ ẹ fún èmi náà níṣìírí torí mo nílò ẹ̀ gan-an!” Ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí arákùnrin yìí fún mi jẹ́ kí n túbọ̀ mọ bó ṣe yẹ kí n ṣètò àkókò mi kí n lè ráyè fún àwọn alábòójútó àyíká tí mò ń bẹ̀ wò.
Lọ́dún 1976, ìbànújẹ́ sorí mi kodò nígbà tí Simone ìyàwó mi ṣàìsàn tó sì kú. Mo nífẹ̀ẹ́ Simone gan-an torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó nítara fún iṣẹ́ ìsìn, ó sì máa ń gba tàwọn míì rò. Bí mo ṣe jẹ́ kí ọwọ́ mi dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ò jẹ́ kí n banú jẹ́ kọjá bó ṣe yẹ, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe ràn mí lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tí nǹkan le gan-an yẹn. Nígbà tó yá, mo fẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kan tó wá sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ní Quebec. Orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló ti wá, Carolyn Elliott sì lorúkọ rẹ̀. Carolyn máa ń kóni mọ́ra, ọ̀rọ̀ àwọn míì sì jẹ ẹ́ lógún pàápàá àwọn tó dá wà àtàwọn tó ń tijú. Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tó dara pọ̀ mọ́ mi lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn àjò.
ỌDÚN KAN TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀
Ní January 1978, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ darí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà àkọ́kọ́ ní Quebec. Ẹ̀rù bà mí gan-an torí mi ò lọ sílé ẹ̀kọ́ yẹn rí, mi ò sì rí ìwé ilé ẹ̀kọ́ náà rí bíi tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wá sí kíláàsì náà. Àmọ́ mo dúpẹ́ pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó nírìírí ló pọ̀ jù nílé ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tí mo darí. Torí náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ lọ́dọ̀ wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi ni olùkọ́.
Nígbà tó dọdún 1978, a ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbáyé tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ìgbàgbọ́ Aṣẹ́gun” ní pápá ìṣeré kan tó ń jẹ́ Montreal Olympic Stadium. Òun ni àpéjọ tó tóbi jù tá a tíì ṣe ní Quebec, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin (80,000) ló wá síbẹ̀. Ẹ̀ka Tó Ń Ṣàkójọ Ìròyìn ni wọ́n ní kí n bá ṣiṣẹ́, mo sì bá àwọn akọ̀ròyìn tó pọ̀ sọ̀rọ̀ nípa àpéjọ náà. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo rí àwọn nǹkan rere tí wọ́n kọ nípa wa. Ó lé ní ogún (20) wákàtí táwọn ilé tẹlifíṣọ̀n àtàwọn ilé iṣẹ́ rédíò fi sọ̀rọ̀ nípa àpéjọ wa, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àpilẹ̀kọ ni wọ́n sì gbé jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn wọn. Ẹ ò rí i pé ìjẹ́rìí náà délé dóko lóòótọ́!
ÈTÒ ỌLỌ́RUN RÁN WA LỌ SÍ ÌPÍNLẸ̀ MÍÌ
Ìyípadà ńlá kan dé bá mi lọ́dún 1996. Èdè Faransé ni wọ́n ń sọ ní Quebec, ibẹ̀ ni mo sì ti sìn látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ní ká lọ sìn ní agbègbè Toronto, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n sì ń sọ níbẹ̀. Mo ronú pé mi ò ní lè ṣe é, ẹ̀rù sì ń bà mí pé báwo ni màá ṣe máa sọ àsọyé lédè tí mi ò gbọ́ dáadáa. Mo fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, mo sì gbára lé Jèhófà pátápátá.
Kí n tó dé àyíká yìí, ẹ̀rù bà mí, àmọ́ ní báyìí mo lè sọ pé gbogbo ọdún méjì tá a lò níbẹ̀ la gbádùn dọ́ba. Carolyn ṣe sùúrù gan-an bó ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tì mí lẹ́yìn, wọ́n sì fún mi níṣìírí. Kò pẹ́ rárá tá a fi láwọn ọ̀rẹ́ tuntun níbẹ̀.
Bá a ṣe ń múra àpéjọ àtàwọn iṣẹ́ míì tá a máa ṣe lópin ọ̀sẹ̀ sílẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà mo tún máa ń lo nǹkan bíi wákàtí kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé nírọ̀lẹ́ Friday. Àwọn kan lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tí mo fi ń jáde nírọ̀lẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú àpéjọ, tí mo sì mọ̀ pé ọwọ́ máa ń dí gan-an láwọn àpéjọ náà?’ Tóò, ohun tí mo kíyè sí ni pé ara máa ń tù mí tí mo bá dé láti òde ẹ̀rí. Kódà títí di báyìí, inú mi máa ń dùn, ara mi sì máa ń yá gágá tí mo bá lọ sóde ẹ̀rí.
Nígbà tó dọdún 1998, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti Carolyn di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Montreal. Lára iṣẹ́ mi ni pé kí n máa ṣètò bá a ṣe máa wàásù láwọn ibi térò pọ̀ sí. Mo tún máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oníròyìn kí n lè tún ojú ìwòye àwọn tó ń ṣenúnibíni sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo sì fi ṣe iṣẹ́ yìí. Ní báyìí, èmi àti Carolyn gbádùn ká máa wàásù fáwọn tó kó wá sórílẹ̀-èdè Kánádà tí wọ́n sì ń sọ èdè àjèjì. Kódà, ọ̀pọ̀ wọn ló fẹ́ ká máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Tí mo bá ń ronú nípa ọdún méjìdínláàádọ́rin (68) tí mo ti wà nínú ètò Jèhófà, mo máa ń gbà pé Jèhófà ti bù kún mi gan-an. Èyí tó ń fún mi láyọ̀ jù ni bí mo ṣe ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi àti bí mo ṣe ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. Ohun míì tó tún ń fún mi láyọ̀ ni pé lẹ́yìn tí ọmọ mi Lise àti ọkọ ẹ̀ tọ́ àwọn ọmọ wọn darí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Inú mi máa ń dùn gan-an bí mo ṣe ń rí ìtara tó ní fún iṣẹ́ ìsìn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn ará tó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tí wọ́n sì fìfẹ́ gbà mí nímọ̀ràn. Àwọn nǹkan tó jẹ́ kí n tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí tó sì jẹ́ kí n bójú tó onírúurú iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run nìyẹn. Mo ti rí i pé kéèyàn tó lè máa fòótọ́ bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lọ, àfi kó gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà pátápátá. (Sm. 51:11) Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi láǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti máa yin orúkọ rẹ̀!—Sm. 54:6.
a Wo ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin W. Glen How nínú Jí! May 8 2000. Àkòrí ẹ̀ ni “Ìjà Ogun Náà Kì í Ṣe Tiyín, Bí Kò Ṣe Ti Ọlọ́run.”
b Wo ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Laurier Saumur nínú Ile-Iṣọ Na, May 15 1977. Àkòrí ẹ̀ ni “Mo Rí Ohun Kan Tí Ó Tó Jà Fún.”
c David Splane wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.