“Ìjà Ogun Náà Kì í Ṣe Tiyín, Bí Kò Ṣe Ti Ọlọ́run”
GẸ́GẸ́ BÍ W. GLEN HOW TI SỌ Ọ́
Láàárín ẹ̀wádún mẹ́fà tó kọjá, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ ẹjọ́ ní Kánádà. Àwùjọ àwọn amòfin sì ń kíyè sí i bí a ṣe ń jàre nínú àwọn ẹjọ́ náà. Nítorí ipa tí mo kó nínú díẹ̀ lára ẹjọ́ tí a fi jà fún ẹ̀tọ́ náà, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Ẹgbẹ́ Tó Ń Wádìí Ẹjọ́ Wò ní Amẹ́ríkà fi Oyè Agbẹjọ́rò Onígboyà dá mi lọ́lá. Níbi ayẹyẹ náà, wọ́n sọ pé àwọn ẹjọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti “di ohun ìgbèjà pàtàkì lòdì sí àṣejù àwọn aláṣẹ . . . , nítorí àwọn ẹjọ́ náà ṣẹ̀dá ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí òfin tì lẹ́yìn, èyí tó mọ̀ pé òmìnira tọ́ sí gbogbo àwọn ará Kánádà, tó sì dáàbò bo ẹ̀tọ́ yẹn.” Ẹ jẹ́ kí n ṣàjọpín kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ọ̀ràn ilé ẹjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú yín, kí n sì sọ bí mo ṣe di ẹni tó mọ̀ nípa òfin àti bí mo ṣe di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
NÍ ỌDÚN 1924, George Rix tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, bẹ àwọn òbí mi wò nílùú Toronto ní Kánádà. Màmá mi, Bessie How, tó jẹ́ ẹni tí kò lára, ní kó wọlé kí àwọn jùmọ̀ jíròrò. Ọmọ ọdún márùn-ún ni mí nígbà náà, tí Joe, àbúrò mi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Màmá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Toronto. Ní ọdún 1929, ó di aṣáájú ọ̀nà, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ó sì ń bá iṣẹ́ náà lọ títí ó fi di ọdún 1969, nígbà tó parí ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó fọkàn ṣe, tí kò sì ṣàárẹ̀ nídìí ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wa, ó si ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti wá sínú ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì.
Bàbá mi ní tirẹ̀, Frank How, jẹ́ ọkùnrin jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, òun ló sì kọ́kọ́ gbógun ti Màmá nítorí ẹ̀sìn tó ń ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, màmá mi fọgbọ́n ké sí àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, bíi George Young, láti bẹ bàbá mi wò kí wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, Bàbá ò ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò di Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí rí àǹfààní tí òtítọ́ Bíbélì ń ṣe ìdílé rẹ̀, ó ṣètìlẹ́yìn gidigidi.
Yíyàn Láti Sin Ọlọ́run
Ní ọdún 1936, mo jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìfẹ́ nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí ní àwọn ọdún tí mo wà ní ọ̀dọ́langba. Ìṣòro Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé bo ìlú wa, kò sì sí ìdánilójú pé a óò ríṣẹ́. Nítorí náà, mo gba Yunifásítì Toronto lọ. Nígbà tó di ọdún 1940, mo pinnu láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ òfin. Ìpinnu yìí kò jọ màmá mi lójú. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti máa ń fìbínú sọ pé: “Kò sí nǹkan tí ìpátá ọmọ yẹn ò lè jiyàn lé lórí! Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ amòfin ló máa yà!”
Ní July 4,1940, ó kù díẹ̀ ki n bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ òfin, ni ìjọba Kánádà bá fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìsí ìkìlọ̀ kankan tẹ́lẹ̀. Ibí yìí ni ìgbésí ayé mi ti yí padà. Nígbà tí ìjọba fi agbára tí wọ́n ní dójú sọ ètò àjọ kékeré ti àwọn ènìyàn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ àti onírẹ̀lẹ̀ yìí, ó wá dá mi lójú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gangan ni ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́. Bó ti sàsọtẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí, wọ́n jẹ́ “ẹni ikórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ [rẹ̀].” (Mátíù 24:9) Mo pinnu láti sin Alágbára Ọ̀run náà tó ń ti ètò àjọ yìí lẹ́yìn. Ní February 10, 1941, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn sí Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ ìrìbọmi.
Mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n, Jack Nathan, ẹni tó ń darí iṣẹ́ ìwàásù ní Kánádà nígbà yẹn rọ̀ mí láti parí ẹ̀kọ́ òfin tí mo ń kọ́ ná. Mo ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì gboyè jáde ní May 1943, lẹ́yìn náà ní mo wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ní August, wọ́n ké sí mi láti wá sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society ní Toronto kí n sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí àwọn ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú òfin tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dojú kọ. Oṣù tó tẹ̀ lé e ni wọ́n gbà mí sínú ẹgbẹ́ lọ́yà ní Ontario, Kánádà.
Fífi Òfin Gbèjà Ìhìn Rere
Ogun Àgbáyé Kejì ń jà lọ́wọ́, síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣì fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí ní Kánádà. Wọn ń fi tọkùnrin tobìnrin wọn sẹ́wọ̀n kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ń lé àwọn ọmọ kúrò nílé ẹ̀kọ́, kódà wọ́n tiẹ̀ kó àwọn kan lọ sí ilé alágbàtọ́ pàápàá. Èyí jẹ́ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, bíi kíkí àsíá tàbí kíkọ orin orílẹ̀-èdè. Ọ̀jọ̀gbọ́n William Kaplan, ẹni tó kọ ìwé tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ State and Salvation: The Jehovah’s Witnesses and Their Fight for Civil Rights, sọ pé “ìjọba àti àwọn ará ìlú tí ìfẹ́ ogun àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ń tì jagun, pẹ̀gàn àwọn Ẹlẹ́rìí ní gbangba wọ́n sì kógun tì wọ́n.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń wá ọ̀nà láti mú ìfòfindè náà kúrò ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe. Lójijì, ní October 14, 1943, wọ́n fagi lé ìfòfindè náà. Síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣì wà nínú ẹ̀wọ̀n àti nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọn ò sì gba àwọn ọmọ wọn síléèwé ìjọba síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì fòfin de Watch Tower Bible and Tract Society àti International Bible Students Association, ẹgbẹ́ kan lábẹ́ òfin tó ni ilé iṣẹ́ wa tó wà ní Toronto.
Ní ìparí ọdún 1943, mo rìnrìn àjò lọ sí New York pẹ̀lú Percy Chapman, tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka ti Kánádà, láti fikùn lukùn pẹ̀lú Nathan Knorr, ẹni tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn, àti Hayden Covington, tóun náà jẹ́ igbákejì ààrẹ Watch Tower Society àti olùgbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn òfin. Arákùnrin Covington nírìírí gan-an nínú ọ̀ràn òfin. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó jàre mẹ́rìndínlógójì nínú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn márùndínláàádọ́ta tí wọ́n gbé lọ síwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
Ìtura bẹ̀rẹ̀ sí dé díẹ̀díẹ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní Kánádà. Ní ọdún 1944 wọ́n dá ilé iṣẹ́ ẹ̀ka ní Toronto padà, àwọn tó ń sìn níbẹ̀ ṣáájú ìfòfindè náà sì padà síbẹ̀. Ní ọdún 1945, ilé ẹjọ́ tó ga jù fún ẹkùn ìpínlẹ̀ Ontario kéde pé wọn ò lè fipá mú àwọn ọmọ láti kópa nínú ìgbòkègbodò tó tako ẹ̀rí-ọkàn wọn. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n gba àwọn ọmọ tí wọ́n ti lé jáde kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ padà. Níkẹyìn, ní ọdún 1946, ìjọba Kánádà dá gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ sílẹ̀. Lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Arákùnrin Covington, mo kẹ́kọ̀ọ́ láti fìgboyà àti ìmúratán jà fitafita lórí àwọn ọ̀ràn yìí ṣùgbọ́n, ní pàtàkì jù lọ, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà.
Ẹjọ́ Táa Ṣe ní Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Quebec
Ní báyìí tí wọ́n ti bọ̀wọ̀ fún òmìnira ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ibi púpọ̀ jù lọ ní Kánádà, ó ṣì ku ibì kan ṣoṣo tó dá yàtọ̀—ìyẹn ni ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec táwọn Kátólíìkì tí ń sọ èdè Faransé wà. Ìjọ Àgùdà ló ń ṣàkóso ẹkùn ìpínlẹ̀ yìí ní tààràtà fún ohun tó ti ju ọ̀ọ́dúnrún ọdún lọ. Ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́, ọsibítù, àti èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn iṣẹ́ ìlú ló jẹ́ pé àwọn àlùfáà ló ni wọ́n tàbí ló ń darí wọn. Kódà ìtẹ́ kan wà fún kádínà Ìjọ Àgùdà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí alága ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Quebec ń jókòó sí!
Aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ni Maurice Duplessis tó jẹ́ olórí ìjọba àti amòfin àgbà fún Quebec, ẹni tí òpìtàn Quebec náà, Gérard Pelletier, sọ nípa rẹ̀ pé, “ó ṣàkóso fún ogún ọdún, ìṣàkóso rẹ̀ ní ẹkùn ilẹ̀ náà sì kún fún irọ́, ìrẹ́jẹ, ìwà ìbàjẹ́, ṣíṣi agbára lò láìbojúwẹ̀yìn, ìjẹgàba lé àwọn onírònú kúkúrú lórí, àti ìgbélékè ìwà òmùgọ̀.” Duplessis fìdí agbára ìṣèlú rẹ̀ múlẹ̀ nípa wíwọnú àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Kádínà Ìjọ Àgùdà, Villeneuve.
Láàárín ọdún 1940 sí 1944, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Quebec kò ju ọ̀ọ́dúnrún lọ. Ọ̀pọ̀ lára wọn, títí kan Joe, àbúrò mi, ló jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n wá láti apá ibòmíràn ní Kánádà. Bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe ń gbèrú sí i ní Quebec, bẹ́ẹ̀ làwọn ọlọ́pàá àdúgbò, tí àwùjọ àlùfáà ń kọ́, bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí nípa fífàṣẹ ọba mú wọn léraléra, wọ́n sì ń ṣi àwọn òfin tó dá lórí ètò ìṣòwò lò fún ìgbòkègbodò ìjọsìn wa.
Mo máa ń rìnrìn àjò lọ sí Toronto àti Quebec léraléra débi pé nígbà tó yá, wọ́n ní kí n kó lọ sí Quebec kí n lè lọ ran àwọn amòfin tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àmọ́ tí wọ́n ń ṣojú fún àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́wọ́. Lójoojúmọ́, iṣẹ́ tí mo kọ́kọ́ ń gbé ṣe ni láti wádìí iye àwọn tí wọ́n fàṣẹ ọba mú kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó mọ́, kí n sì yára lọ sí ilé ẹjọ́ àdúgbò láti lọ ṣètò bí a ṣe máa gba ìdúró wọn. Ó dùn mọ́ni pé Frank Roncarelli, Ẹlẹ́rìí kan tó rí jájẹ, ń ṣe onídùúró fún wa nínú ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹjọ́ wọ̀nyí.
Láàárín 1944 sí 1946 nìkan, àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá fún rírú àwọn òfin àtọwọ́dá náà lọ sókè láti ogójì sí ẹgbẹ̀rin! Kì í ṣe kìkì pé àwọn aláṣẹ ń kó àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ wọn léraléra nìkan ni ṣùgbọ́n àgbájọ àwọn èèyànkéèyàn, tí àwọn àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì ń kọ́, tún ń gbéjà kò wọ́n pẹ̀lú.
Ní November 2 àti 3, 1946, a ṣe ìpàdé àkànṣe kan nílùú Montreal láti jíròrò ìṣòro yìí. Arákùnrin Knorr ló sọ ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn, tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Kí Ni Ká Ṣe?” Gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ ni inú wọ́n dùn láti gbọ́ ìdáhùn rẹ̀—ó ka àkọsílẹ̀ náà, Quebec’s Burning Hate for God and Christ and Freedom Is the Shame of All Canada, tó ti di ìtàn báyìí sókè ketekete. Ó jẹ́ ìwé àṣàrò kúkúrú olójú ewé mẹ́rin tó múná—ó ní àlàyé kíkún nípa orúkọ, ọjọ́, àti ibi tí àwọn rúkèrúdò tí àwùjọ àlùfáà súnná sí ti ṣẹlẹ̀, ìwà òǹrorò àwọn ọlọ́pàá, ìfàṣẹ-ọba-múni, àti bí àwọn èèyànkéèyàn ṣe gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Quebec. Ọjọ́ méjìlá lẹ́yìn náà ni a bẹ̀rẹ̀ sí pín in jákèjádò gbogbo Kánádà.
Láàárín ọjọ́ díẹ̀, Duplessis kéde “ogun láìsí ojú àánú” lòdì sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n ńṣe ló ṣiṣẹ́ fún ire wa láìmọ̀. Lọ́nà wo? Nípa pípàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ kan ẹnikẹ́ni tó bá ń pín ìwé Quebec’s Burning Hate—tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan tí yóò gbé wa kúrò ní gbogbo ilé ẹjọ́ tó wà ní Quebec tí yóò sì tì wá dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Kánádà. Nítorí inú tó ń bí Duplessis, ó dágunlá sí ohun tí èyí yóò yọrí sí. Lẹ́yìn náà ló fúnra ẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n fòfin de ìwé àṣẹ tí Frank Roncarelli fi ń ta ọtí, ẹni tó ti ń fìgbà gbogbo ṣe onídùúró fún wa. Nígbà tí kò sí wáìnì mọ́, kò ju oṣù mélòó kan lọ tí ilé àrojẹ dídára tí Arákùnrin Roncarelli ní sí Montreal fi di títì pa, ni wọ́n bá sọ ọ́ di ẹdun arinlẹ̀.
Wọ́n túbọ̀ ń kó àwọn èèyàn sí i. Dípò ẹgbẹ̀rin ẹjọ́ tí a ní nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, kíá ló ti di ẹgbẹ̀jọ [1,600]. Ọ̀pọ̀ àwọn amòfin àti àwọn adájọ́ ló ń ráhùn pé ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ti pọ̀ jù ní àwọn kóòtù tó wà ní Quebec, ó sì ń dí àwọn lọ́wọ́. Láti dá wọn lóhùn, àwa náà wá dábàá ọ̀nà rírọrùn tọ́rọ̀ fi lè yanjú fún wọn pé: Ẹ jẹ́ káwọn ọlọ́pàá lọ máa kó àwọn ọ̀daràn kí wọ́n yéé kó àwọn Kristẹni. Kíá lọ̀rọ̀ máa yanjú!
Àwọn amòfin ọmọ Júù onígboyà méjì, A. L. Stein láti Montreal àti Sam S. Bard láti Ìlú Quebec, ràn wá lọ́wọ́ nípa bíbá wa bójú tó púpọ̀ nínú àwọn ẹjọ́ wa, pàápàá kó tó di pé wọ́n gbà mí wọlé sínú ẹgbẹ́ lọ́yà ti Quebec ní 1949. Ẹni tó wá di olórí ìjọba Kánádà lẹ́yìn náà Pierre Elliott Trudeau, kọ̀wé pé gbogbo ará ìlú wa ti fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ráre ní Quebec, pé wọ́n ti “fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, wọ́n tí ṣe inúnibíni sí wọn, wọ́n sì kórìíra wọn; àmọ́ wọ́n ń bá a nìṣó nípa fífi òfin gbèjà ara wọn láti bá Ṣọ́ọ̀ṣì, ìjọba, orílẹ̀-èdè, ọlọ́pàá, àti èròǹgbà àwọn ará ìlú fà á.”
Ọ̀nà tí àwọn ilé ẹjọ́ ní Quebec gbà bá Joe, àbúrò mi jà, lò túbọ̀ fi irú ẹ̀mí tí wọ́n ní hàn gbangba. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́. Ni Jean Mercier, adájọ́ àdúgbò, bá ju Joe sẹ́wọ̀n oṣù méjì. Lẹ́yìn náà, ló bá tún gbaná jẹ, tó sì pariwo láti orí àga ìdájọ́ pé ṣe ni ì bá wu òun kóun rán Joe lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére!
Ìwé ìròyìn kan tiẹ̀ sọ pé Mercier fún àwọn ọlọ́pàá Quebec láṣẹ láti “mú Ẹlẹ́rìí èyíkéyìí tí wọ́n bá rí tàbí tí wọ́n bá fura sí.” Irú ìwà báyìí wulẹ̀ jẹ́rìí sí i pé òtítọ́ ni àwọn ẹ̀sùn tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú wa náà Quebec’s Burning Hate. Àwọn àpẹẹrẹ àkọlé ìwé ìròyìn díẹ̀ láti Kánádà, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe Quebec ni wọ́n ti ṣe wọ́n, kà pé: “Àkókò Ojú Dúdú Padà Dé sí Quebec” (The Toronto Star), “Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ Tún Padà Dé” (The Globe and Mail, Toronto), “Ìjọba Bóofẹ́bóokọ̀ Arínilára” (The Gazette, Glace Bay, Nova Scotia).
A Tako Ẹ̀sùn Ìdìtẹ̀
Ní ọdún 1947, mo ran Ọ̀gbẹ́ni Stein lọ́wọ́ nínú ẹjọ́ ìdìtẹ̀ àkọ́kọ́ tí wọn yóò gbọ́, èyí tí wọ́n fi kan Aimé Boucher. Ńṣe ni Aimé pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú kan nítòsí ilé ẹ̀. Níbi ìgbẹ́jọ́ Aimé, a fẹ̀rí hàn pé ìwé àṣàrò kúkúrú Quebec’s Burning Hate kò ní irọ́ kankan nínú, ó wulẹ̀ lo ọ̀rọ̀ líle láti sọ nípa ìwà burúkú tí wọ́n ń hù sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. A jẹ́ kó yé wọn pé kò sí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n fi kan àwọn tó hu ìwà burúkú yìí. Aimé tó pariwo wọn síta ni wọ́n dá lẹ́bi. A jẹ́ pé ipò tí ẹjọ́ yìí wà báyìí ni pé: Ẹ̀ṣẹ̀ ni kí èèyàn sọ òtítọ́!
Àwọn ilé ẹjọ́ Quebec ṣì gùn lé ìtumọ̀ aláìlẹ́sẹ̀-nílẹ̀, tó ti wà fún àádọ́ta dín nírínwó [350] ọdún tí wọ́n fún “ìdìtẹ̀,” èyí tó sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé ìjọba ò ṣé e re ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lè gbé e dẹ́wọ̀n. Orí ìtumọ̀ yìí náà ni Duplessis gùn lé kó baà lè tẹ àríwísí tó lè wá sórí ìjọba ẹ̀ rì. Ṣùgbọ́n nígbà tó di ọdún 1950, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kánádà gba àkọsílẹ̀ wa wọlé pé, nínú ìjọba tiwa-n-tiwa ti òde-òní o, nǹkan tó ń jẹ́ “ìdìtẹ̀” ni ríru ìwà jàgídíjàgan sókè sí ìjọba tàbí ṣíṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Kò sì sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú Quebec’s Burning Hate àti pé fún ìdí yìí ọ̀rọ̀ olómìnira tó bófin mu ni. Pẹ̀lú ìdájọ́ tó rinlẹ̀ yìí, ni wọ́n bá tú gbogbo ẹjọ́ ìdìtẹ̀ mẹ́tàlélọ́gọ́fà tó wà nílẹ̀ ká! Mo fojú mi rí i kòrókòró bí Jèhófà ṣe mú ìṣẹ́gun wá.
Gbígbógun Ti Ìfòfinde Àwọn Ìwé Wa
Ìlú Quebec ní òfin àdúgbò kan tó ka pípín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kiri láìgba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ọ̀gá ọlọ́pàá léèwọ̀. Fífi òfin deni láìtọ́ lèyí jẹ́, nítorí náà, kò bá òfin òmìnira ìjọsìn mu. Laurier Saumur, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò nígbà yẹn, ni wọ́n gbé jù sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta lábẹ́ òfin àdúgbò yìí, wọ́n sì tún fi oríṣiríṣi ẹ̀sùn mìíràn kàn án lábẹ́ òfin náà.
Ní ọdún 1947, a pe ẹjọ́ lórúkọ Arákùnrin Saumur láti wá nǹkan ṣe kí Ìlú Quebec má baà lo òfin àdúgbò náà lòdì sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ilé ẹjọ́ ní Quebec dá wa lẹ́bi, la bá tún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Kánádà. Nígbà tó di October 1953, lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ọlọ́jọ́ méje níwájú gbogbo àwọn adájọ́ mẹ́sẹ̀ẹ̀sán tó wà ní Ilé Ẹjọ́ náà, wọ́n gba àṣẹ tí a fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè náà wọlé. Ilé Ẹjọ́ náà gbà pé pípín àwọn ìwé tó ní ọ̀rọ̀ Bíbélì nínú jẹ́ apá ṣíṣe pàtàkì nínú ìsìn Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé fún ìdí yìí òfin dáàbò bò ó pé kí wọ́n má ṣe gbẹ́sẹ̀ lé e.
Báyìí ni ẹjọ́ ti Boucher yanjú ọ̀ràn pé ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ kò tako òfin; ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe dá ẹjọ́ ti Saumur fìdí ọ̀ràn bí wọ́n ṣe lè sọ ọ́ àti ibi tí wọ́n ti lè sọ ọ́ múlẹ̀. Ìṣẹ́gun tó wáyé nínú ẹjọ́ ti Saumur yọrí sí títú nǹkan tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100] ẹjọ́ tó dá lórí òfin àdúgbò ní Quebec ká. Ẹjọ́ tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ni wọ́n tún fagi lé ní Montreal nítorí àìsí ẹ̀rí fún wọn rárá. Láìpẹ́, ilẹ̀ ti dá—kò sì sí ẹjọ́ kankan mọ́ ní Quebec!
Oró Tí Duplessis Dá Gbẹ̀yìn
Nígbà tí Duplessis rí i pé òun ò rí òfin kankan tí òun lè fi mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ó dábàá òfin tuntun kan nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ìbẹ̀rẹ̀ January 1954, ìyẹn ni Àbádòfin Kejìdínlógójì, èyí táwọn oníròyìn pè ní ‘òfin ìgbógunti Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’ Nínú ẹ̀ ló ti sọ pé àwọn tó bá fura sí ẹnikẹ́ni tó ń gbèrò láti sọ “ọ̀rọ̀ èébú tàbí ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí” lè pẹjọ́ láìsí pé wọ́n pèsè ẹ̀rí kankan. Níwọ̀n ìgbà tó kúkú jẹ́ pé Duplessis ni amòfin àgbà pátápátá, ó lè pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà sọ̀rọ̀ èyíkéyìí ní gbangba. Tí àṣẹ yìí bá sì ti lè mú ẹnì kan ṣoṣo péré, gbogbo àwọn tó bá jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ onítọ̀ún ni wọ́n yóò fàṣẹ pa lẹ́nu mọ́. Láfikún sí i, gbogbo Bíbélì àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ti ìjọ náà ni wọn yóò gbà tí wọ́n á sì bà á jẹ́, wọ́n á sì tún ti gbogbo ilé ìjọsìn wọn pa títí di ìgbà tí wọ́n bá parí ẹjọ́ náà, ìyẹn sì lè gba ọ̀pọ̀ ọdún.
Àbádòfin Kejìdínlógójì fa òfin kan yọ, èyí tí wọ́n hùmọ̀ ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún lásìkò Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ ní Sípéènì lábẹ́ ìṣàkóso Torquemada. Ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà àti gbogbo àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pàdánù gbogbo ẹ̀tọ́ wọn láìsí ẹ̀rí pé wọ́n ká ìwà àìtọ́ kankan mọ́ wọn lọ́wọ́. Ní ti Àbádòfin Kejìdínlógójì, àwọn oníròyìn kéde pé wọ́n ti fún àwọn ọlọ́pàá ẹkùn ìpínlẹ̀ náà láṣẹ láti ti gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n gba Bíbélì wọn àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn, kí wọn sì bà á jẹ́. Lójú ìhalẹ̀mọ́ni gbígbóná janjan tó dojú kọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí, ńṣe ni wọ́n palẹ̀ gbogbo ìtẹ̀jáde wọn mọ́ kúrò ní ẹkùn ìpínlẹ̀ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ ní gbangba, àmọ́ Bíbélì wọn nìkan ni wọ́n ń lò.
Àbádòfin náà wá di òfin ní January 28, 1954. Ní January 29, ní déédéé agogo mẹ́sàn-án òwúrọ̀, mo ti dé ilé ẹjọ́ láti lọ pẹjọ́ lórúkọ gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec, pé kí wọ́n pàṣẹ tó máa fagi lé òfin yìí pátápátá kí Duplessis tiẹ̀ tó lè lò ó rárá. Adájọ́ ò fún wa láṣẹ táa lè lò fún ìgbà díẹ̀ ná, nítorí pé wọn ò kúkú tíì lo Àbádòfin Kejìdínlógójì náà. Ṣùgbọ́n ó sọ pé bí ìjọba bá gbìyànjú láti lò ó kí n padà wá bá òun fún ìdáàbòbò. Ohun tí adájọ́ ṣe yìí dà bí ìgbà tí wọ́n fún wa ní àṣẹ táa lè lò fún ìgbà díẹ̀, nítorí pé tí Duplessis bá lè gbìyànjú láti lo òfin yìí pẹ́nrẹ́n, kíá ni wọ́n á dá a dúró!
Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a dúró láti wò ó bóyá àwọn ọlọ́pàá á ṣe nǹkan kan lábẹ́ òfin tuntun yìí. Kò mà sí nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀! Láti lè mọ ìdí tí wọn ò fi ṣe nǹkan kan, mó ṣe ìdánwò kan. Àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì, Victoria Dougaluk (ẹni tó di Steele lẹ́yìn náà) àti Helen Dougaluk (ẹni tó di Simcox lẹ́yìn náà), lọ láti ilé dé ilé pẹ̀lú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní Trois-Rivières, ìlú ìbílẹ̀ Duplessis gangan. Síbẹ̀síbẹ̀, a ò gbọ́ nǹkan kan. Bí àwọn arábìnrin náà ti ń bá iṣẹ́ lọ ní pẹrẹu, mo rán Laurier Saumur pé kó fóònù àwọn ọlọ́pàá ẹkùn ìpínlẹ̀ náà. Láìsọ irú ẹni tí òun jẹ́, ló bá rojọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù àti pé àwọn ọlọ́pàá ò lo òfin Duplessis tuntun.
Ọlọ́pàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́ fìtìjú sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, a mọ̀ pé wọ́n ṣe òfin yẹn; ṣùgbọ́n ọjọ́ kejì ẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gba àṣẹ kan tí wọn lè lò fún wa, nítorí náà kò sí nǹkan tí a lè ṣe.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a dá gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa padà sí ẹkùn ìpínlẹ̀ náà, láàárín ọdún mẹ́wàá tí ẹjọ́ náà sì lò níbi táa ti ń pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, iṣẹ́ ìwàásù wa ń bá a lọ láìdúró.
Ní àfikún sí àṣẹ náà, a tún wá ọ̀nà láti sọ Àbádòfin Kejìdínlógójì di èyí tí kò bófin mu. Láti lè jẹ́ kó hàn gbangba pé nítorí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ṣe ṣe òfin náà, a pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ aláìṣojo kan—ìyẹn ni láti fi ìwé pe Duplessis fúnra ẹ̀ sílé ẹjọ́, èyí tó sọ́ ọ di dandan fún un láti wá sí ibi ìgbẹ́jọ́ náà, kó sì pèsè ẹ̀rí. Mo fi ìbéèrè wá a lẹ́nu wò fún wákàtí méjì àti ààbọ̀. Mo sì ń bi í léraléra nípa ìpolongo ìta gbangba ẹ̀ tó ṣe, ìyẹn ti “ogun láìsí àánú fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà” àti ọ̀rọ̀ tó sọ pé Àbádòfin Kejìdínlógójì ló máa fòpin sí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Quebec. Pẹ̀lú ìbínú, ló bá sọ̀rọ̀ sí mi pé: “Ìwọ ọ̀dọ́mọkùnrin yìí, aláfojúdi gbáà ni ẹ́!”
Mo wá fún un lésì pé: “Ọ̀gbẹ́ni Duplessis, tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ìwà ni à ń sọ ni, ǹ bá rí díẹ̀ sọ nípa ẹ. Àmọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ táa ṣì wà lẹ́nu ẹ̀ yìí, ì bá dáa kí o ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́ yìí, ìdí tí o fi kọ̀ láti dáhùn ìbéèrè tó kẹ́yìn yẹn.”
Ní ọdún 1964, mo jiyàn Àbádòfin Kejìdínlógójì níwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kánádà. Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti kéde bóyá ó bófin mu àbí kò bófin mu nítorí pé wọn ò fi ìgbà kankan lò ó. Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbo ìgbà yẹn Duplessis ti kú, kò sì sẹ́ni tó tún bìkítà mọ́ nípa Àbádòfin Kejìdínlógójì. Wọn ò lò ó rárá yálà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí fún ẹnikẹ́ni.
Kó tó di pé Duplessis kú ní ọdún 1959, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Kánádà pàṣẹ fún un pé kí ó sanwó gbà-máà-bínú fún Arákùnrin Roncarelli nítorí pé bó ṣe fòfin de ìwé àṣẹ tó fi ń ta ọtí kò tọ́. Láti ìgbà náà ni púpọ̀ lára àwọn ènìyàn Quebec ti wá di ẹni tó kóòyàn mọ́ra. Ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìkànìyàn tí ìjọba ṣe, iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ti pọ̀ sí i láti ọ̀ọ́dúnrún ní ọdún 1943 sí ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33,000] lónìí. Ipò kẹrin ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà nísinsìnyí nínú àwọn ìsìn tó tóbi jù lọ ní ẹkùn ìpínlẹ̀ náà. Mi ò ka àwọn ẹjọ́ tí a borí nínú wọn yìí tàbí àṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí sí nǹkan tí ẹ̀dá ènìyàn kankan ṣàṣeyọrí rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti hàn sí mi gbangba pé Jèhófà ló mú àwọn ìṣẹ́gun náà wá, nítorí pé tirẹ̀ ni ìjà ogun náà, kì í ṣe tiwa.—2 Kíróníkà 20:15.
Ipò Nǹkan Ń Yí Padà
Ní 1954, mo gbé Margaret Biegel, aṣáájú ọ̀nà rírẹwà kan láti England níyàwó, a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà papọ̀. Mo ṣì ń bójú tó àwọn ẹjọ́ tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kánádà àti ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, mo sì tún ń ṣíṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùgbani-nímọ̀ràn lórí àwọn ẹjọ́ kan ní Yúróòpù àti Ọsirélíà. Margaret di akọ̀wé mi, ó sì jẹ́ alátìlẹyìn tí kò ṣeé díye lé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ní ọdún 1984, èmi pẹ̀lú Margaret padà láti lọ gbé ní ẹ̀ka Kánádà, mo sì ṣèrànwọ́ láti tún dá Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó bà mí nínú jẹ́ pé ní ọdún 1987, àrùn jẹjẹrẹ ṣekú pa Margaret.
Lẹ́yìn ikú ìyá mi ní 1969, Joe àbúrò mi àti Elsie aya rẹ̀, tí àwọn méjèèjì ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní kíláàsì kẹsàn-án ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, mú bàbá mi tira nínú ilé wọn, wọ́n sì ń tọ́jú ẹ̀ títí tó fi kú ní ọdún mẹ́rìndínlógún lẹ́yìn náà. Nítorí gbígbà láti gbé ẹrù yẹn, ó ṣeé ṣe fún mi láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mi lọ, títí ayé mi ni n óò sì máa ṣọpẹ́ fún ohun tí wọ́n ṣe náà.
Àwọn Ogun Tí Ń Bá A Nìṣó
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, àwọn ẹjọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ti yí padà. Àwọn ẹjọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú dídáàbò bo ohun ìní àti gbígba àṣẹ fún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ ló pọ̀ jù báyìí. Àwọn mìíràn tún ni ti àríyànjiyàn ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ nínú èyí tí àwọn òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ti ń lo ìtara òdì ti ìsìn bóyá láti gba ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ lábẹ́ òfin pátápátá tàbí láti má ṣe jẹ́ kí àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣàjọpín àwọn ìgbàgbọ́ àti àṣà ìsìn tí ń ṣeni láǹfààní pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.
Amòfin Linda Manning, tó jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà, wá sí ẹ̀ka Kánádà ní ọdún 1989 láti ràn wá lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀ nínú ọ̀ràn òfin. Ní November ọdún yẹn, a ṣègbéyàwó, a sì ti jọ ń sìn papọ̀ tayọ̀tayọ̀ níbí láti ìgbà náà.
Ní àwọn ọdún 1990 sí 1999, èmi àti John Burns, amòfin ẹlẹgbẹ́ mi kan ní ẹ̀ka Kánádà jọ lọ sí Japan, a sì ran àwọn Kristẹni arákùnrin wa níbẹ̀ lọ́wọ́ nínú ẹjọ́ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú òmìnira akẹ́kọ̀ọ́ kan láti má ṣe kópa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí eré ìgbèjà ara ẹni, èyí tí ilé ẹ̀kọ́ náà ní kí wọ́n ṣe. Bákan náà ni a tún borí nínú ẹjọ́ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ tí àgbàlagbà kan ní láti má ṣe gbẹ̀jẹ̀ sára.
Nígbà tí ó tún di ọdún 1995 àti 1996, èmi àti Linda ní àǹfààní láti lọ lo oṣù márùn-ún ní Singapore nítorí ìfòfindè iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ yẹn àti ẹjọ́ tí a ṣe látàrí rẹ̀. Mo gbèjà àwọn ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọ̀dọ́ tí iye gbogbo wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlélọ́gọ́ta tí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn nítorí pé wọ́n lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti nítorí pé wọ́n ní Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ti ìsìn wọn lọ́wọ́. A ò jàre ìkankan lára àwọn ẹjọ́ wọ̀nyí, ṣùgbọ́n a rí i bí Jèhófà ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ lókun láti lo ìfaradà nínú pípa ìwà títọ́ àti ayọ̀ wọn mọ́.
Inú Mi Dùn Pé Mó Kópa Ńbẹ̀
Ní ẹni ọgọ́rin ọdún, mo láyọ̀ pé ara mi ṣì le dáadáa, mo sì ń nípìn-ín síbẹ̀ nínú jíja ìjà òfin fún àwọn ènìyàn Jèhófà. Mo ṣì wà ní sẹpẹ́ láti lọ sí ilé ẹjọ́ nígbàkigbà, kí n sì mú ìdúró fún ohun tó tọ́. Ó dùn mọ́ mi nínú láti rí i tí iye àwọn Ẹlẹ́rìí ní Kánádà pọ̀ sí i láti ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ní ọdún 1940 sí ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́fà ní àkókò táa wà yìí. Àwọn ènìyàn àti ìṣẹ̀lẹ̀ lóríṣiríṣi ń yí padà, ṣùgbọ́n Jèhófà ń mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ tẹ̀ síwájú, ó sì ń rí i dájú pé wọ́n lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí.
Ṣé àwọn ìṣòrò wà? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Jèhófà mú un dá wa lójú pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.” (Aísáyà 54:17) Pẹ̀lú ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tí mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní ‘gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere náà múlẹ̀ lọ́nà òfin,’ mo lè jẹ́rìí sí bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti jẹ́ òtítọ́ tó!—Fílípì 1:7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Èmi àti àbúrò mi ọkùnrin àti àwọn òbí wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Hayden Covington, olùgbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn òfin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Èmi àti Nathan Knorr
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Duplessis tó kúnlẹ̀ níwájú Kádínà Villeneuve
[Credit Line]
Fọ́tò tí W. R. Edwards yà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Frank Roncarelli
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Canada Wide
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Aimé Boucher
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Èmi àti John Burns, tó jẹ́ amòfin bíi tèmi, àti Linda aya mi