ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 41
Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
“Ó ṣe kedere pé ẹ jẹ́ lẹ́tà Kristi tí àwa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kọ.”—2 KỌ́R. 3:3.
ORIN 78 ‘Máa Kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni 2 Kọ́ríńtì 3:1-3 sọ tó jẹ́ ká mọyì àǹfààní tá a ní láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì ṣèrìbọmi? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
BÁWO ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá rí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ní ìjọ yín tó ṣèrìbọmi? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an. (Mát. 28:19) Tó bá wá lọ jẹ́ pé ìwọ lo kọ́ onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́, wàá láyọ̀ lọ́jọ́ tó ṣèrìbọmi! (1 Tẹs. 2:19, 20) Ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ṣèrìbọmi dà bíi “lẹ́tà ìdámọ̀ràn” fún àwọn tó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ àti fún ìjọ lápapọ̀.—Ka 2 Kọ́ríńtì 3:1-3.
2. (a) Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ ká wá ìdáhùn sí, kí sì nìdí? (b) Kí ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (Wo àlàyé ọ̀rọ̀.)
2 Ó wú wa lórí pé láti nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélìb là ń ṣe lóṣooṣù kárí ayé. Láàárín àwọn ọdún yẹn kan náà, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé ọgọ́rin (280,000) ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún tí wọ́n sì ń di ọmọlẹ́yìn Kristi. Kí la lè ṣe láti ran èyí tó pọ̀ jù lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí lọ́wọ́ kí wọn lè ṣèrìbọmi? Torí pé Jèhófà ṣì ń mú sùúrù fún àwọn èèyàn tó sì ń fún wọn láǹfààní láti di ọmọ ẹ̀yìn, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tètè ṣèrìbọmi. Ìdí sì ni pé àkókò tó kù ò tó nǹkan mọ́!—1 Kọ́r. 7:29a; 1 Pét. 4:7.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí nípa bá a ṣe lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Torí pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn báyìí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní kí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wo ohun tá a lè ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè ṣèrìbọmi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó nírìírí, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó àyíká.c (Òwe 11:14; 15:22) Wọ́n sọ ohun táwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè ṣe kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè méso jáde. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun márùn-ún tó yẹ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe kí wọ́n lè ṣèrìbọmi.
Ẹ MÁA ṢE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ NÁÀ LỌ́SỌ̀Ọ̀SẸ̀
4. Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa àwọn ìjíròrò tá à ń ṣe lẹ́nu ọ̀nà?
4 Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń bá àwọn èèyàn jíròrò Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tó dáa láti fi mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì nìyẹn, àmọ́ àwọn ìjíròrò yìí máa ń ṣe ṣókí, ó sì lè má jẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kí ìjíròrò náà lè máa ṣe déédéé, àwọn akéde kan máa ń gba nọ́ńbà fóònù onílé. Wọ́n á wá pe ẹni náà kó tó di ọjọ́ tí wọ́n tún máa lọ síbẹ̀ kí wọ́n lè bá a jíròrò ẹsẹ Bíbélì kan ní ṣókí tàbí kí wọ́n fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí i. Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù, síbẹ̀ kí ìjíròrò náà má di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ ń sọ nìyẹn, ṣé ẹni náà lè tẹ̀ síwájú débi pé á ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi? Kò dájú.
5. Kí ni Jésù sọ nínú Lúùkù 14:27-33 pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?
5 Ìgbà kan wà tí Jésù ṣe àkàwé nípa béèyàn ṣe lè di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó fẹ́ kọ́ ilé gogoro àti ọba kan tó fẹ́ lọ jagun. Jésù sọ pé ẹni tó fẹ́ kọ́ ilé náà máa “kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an” bóyá òun á lè parí ẹ̀. Ọba náà sì gbọ́dọ̀ “kọ́kọ́ jókòó, kó sì gba ìmọ̀ràn” bóyá òun àtàwọn ọmọ ogun òun á lè kojú àwọn tí wọ́n fẹ́ lọ bá jà. (Ka Lúùkù 14:27-33.) Lọ́nà kan náà, Jésù mọ̀ pé ẹni tó bá máa di ọmọ ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú ohun tó máa ná an. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
6. Báwo lo ṣe lè sọ ìjíròrò yín di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
6 Ohun àkọ́kọ́ ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ kí ìjíròrò náà gùn díẹ̀ sí i. Ẹ lè jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì dípò ẹyọ kan tẹ́ ẹ ti máa ń jíròrò tẹ́lẹ̀. Tẹ́ni náà bá ti ń gbádùn ìjíròrò náà, o lè bí i pé ṣé ibì kan wà tẹ́ ẹ lè máa jókòó sí láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ohun tó bá sọ máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ó nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó bá yá, o lè bí i pé ṣé á fẹ́ kẹ́ ẹ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Síbẹ̀, tó bá máa tẹ̀ síwájú, ó kọjá pé kẹ́ ẹ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ẹ̀kan àbí ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀.
MÁA MÚRA ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ KỌ̀Ọ̀KAN SÍLẸ̀
7. Báwo làwa akéde ṣe lè máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀?
7 Àwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀. O lè kọ́kọ́ ka apá tẹ́ ẹ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Jẹ́ kí kókó tẹ́ ẹ fẹ́ jíròrò yé ẹ dáadáa. Ronú nípa àkòrí tẹ́ ẹ fẹ́ jíròrò, àwọn ìsọ̀rí tó wà níbẹ̀, àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí pé ká kà. Lẹ́yìn náà, wo àwòrán ibẹ̀, kó o sì wo fídíò èyíkéyìí tó bá àkòrí náà mu. Ohun tó kàn ni pé kó o ronú nípa bó o ṣe máa ṣàlàyé lọ́nà tó máa wọ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn táá sì fi ohun tó ń kọ́ sílò.—Neh. 8:8; Òwe 15:28a.
8. Kí ni ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Kólósè 1:9, 10 tó jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa?
8 Bó o ṣe ń múra sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ́nà tó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Ka Kólósè 1:9, 10.) Ronú nípa ohun tó lè ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ láti lóye tàbí tó lè má fara mọ́. Fi sọ́kàn pé ohun tó ṣe pàtàkì ni bó ṣe máa tẹ̀ síwájú, kó sì ṣèrìbọmi.
9. Báwo làwa akéde ṣe lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti máa múra sílẹ̀? Ṣàlàyé.
9 A retí pé bá a ṣe ń kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, á mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún un, á sì fẹ́ mọ̀ sí i. (Mát. 5:3, 6) Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá máa jàǹfààní ní kíkún, ó gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ń kọ́. Torí náà, jẹ́ kó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kóun máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀, kó sì ronú lórí bó ṣe kan òun. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ẹ jọ múra ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sílẹ̀ kó o sì fi hàn án bí á ṣe máa ṣe é.d Ṣàlàyé bó ṣe lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè náà, kó o sì kọ́ ọ bó ṣe lè fàlà sí àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó táá jẹ́ kó rántí ìdáhùn náà. Lẹ́yìn náà, sọ pé kó dáhùn lọ́rọ̀ ara ẹ̀. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ̀ bóyá ó lóye ohun tó ń kọ́. Àmọ́, nǹkan míì wà tó yẹ kó o gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó ṣe.
KỌ́ Ọ PÉ KÓ MÁA NÍ ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀PỌ̀ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ LÓJOOJÚMỌ́
10. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kí lá sì jẹ́ kó jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
10 Yàtọ̀ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ jọ ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn nǹkan míì wà tó tún yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà máa dá ṣe lójoojúmọ́. Ó ṣe pàtàkì pé kó máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Lọ́nà wo? Ó yẹ kó máa tẹ́tí sí Jèhófà kó sì máa bá a sọ̀rọ̀. Ó lè máa tẹ́tí sí Jèhófà tó bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Jóṣ. 1:8; Sm. 1:1-3) Kọ́ ọ bó ṣe máa lo “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà” tó wà lórí jw.org.e Àmọ́, kó lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú Bíbélì tó ń kà, ó yẹ kó o gbà á níyànjú pé kó máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí ibẹ̀ ń sọ fún un nípa Jèhófà àti bó ṣe lè fi ẹ̀kọ́ náà sílò.—Ìṣe 17:11; Jém. 1:25.
11. Báwo lo ṣe lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti máa gbàdúrà lọ́nà tó tọ́, kí nìdí tó sì fi ṣe pàtàkì pé kó máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo?
11 Gba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níyànjú pé kó máa gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́. Máa gbàdúrà àtọkànwá níbẹ̀rẹ̀ àti níparí ìkẹ́kọ̀ọ́ yín, kó o sì dárúkọ ẹ̀ nínú àdúrà náà. Bó ṣe ń fetí sí àdúrà rẹ, á kọ́ bó ṣe lè máa gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá ní orúkọ Jésù Kristi. (Mát. 6:9; Jòh. 15:16) Ó dájú pé tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ (tó ń tẹ́tí sí Jèhófà), tó sì ń gbàdúrà sí Jèhófà (tó ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀), á túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà! (Jém. 4:8) Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, á tẹ̀ síwájú sí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Kí ni nǹkan míì tó lè ràn án lọ́wọ́?
JẸ́ KÓ MỌ BÓ ṢE LÈ NÍ ÀJỌṢE TÍMỌ́TÍMỌ́ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ
12. Báwo lo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?
12 Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́kàn, kì í ṣe kó kàn kó ìmọ̀ ságbárí. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó dìgbà tó bá wọ̀ ọ́ lọ́kàn kó tó lè gbé ìgbésẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀kọ́ Jésù máa ń bọ́gbọ́n mu, àwọn èèyàn sì fẹ́ràn láti máa tẹ́tí sí i. Àmọ́ ohun tó mú kí wọ́n tẹ̀ lé e ni pé ẹ̀kọ́ náà máa ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Lúùkù 24:15, 27, 32) Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, kó ṣe tán láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, kó sì mú Jèhófà ní Baba, Ọlọ́run àti Ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Sm. 25:4, 5) Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ yín, máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. (Ẹ́kís. 34:5, 6; 1 Pét. 5:6, 7) Láìka àkòrí tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò sí, pe àfíyèsí ẹ̀ sí irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ràn án lọ́wọ́ kó lè mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, onínúure, tó sì ń gba tẹni rò. Jésù sọ pé “àṣẹ tó tóbi jù lọ, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́” ni pé ká “nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run” wa. (Mát. 22:37, 38) Torí náà, ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá.
13. Sọ ọ̀nà kan tó o lè gbà ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà.
13 Jẹ́ kó máa rí bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó tẹ́ ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀. Èyí á jẹ́ kó rí i pé ó yẹ kóun náà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (Sm. 73:28) Bí àpẹẹrẹ, ṣé ohun kan wà nínú ìwé tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó gbé ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti agbára Jèhófà yọ? Tírú ẹ̀ bá wà, sọ fún un, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ìdí tó o fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run nìyẹn. Síbẹ̀, nǹkan míì tún wà tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi.
GBÀ Á NÍYÀNJÚ PÉ KÓ MÁA WÁ SÍPÀDÉ
14. Kí ni Hébérù 10:24, 25 sọ nípa ìpàdé tó lè ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú?
14 Gbogbo wa la fẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa wá sípàdé. Àwọn akéde tó nírìírí sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó tètè bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ló máa ń tẹ̀ síwájú jù. (Sm. 111:1) Àwọn akéde kan máa ń sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn pé ìdajì nǹkan tó yẹ kí wọ́n mọ̀ ni wọ́n máa kọ́ tí wọn ò bá wá sípàdé torí pé ìpàdé ni wọ́n á ti kọ́ èyí tó kù. Ka Hébérù 10:24, 25 fún un, kó o sì jẹ́ kó mọ àǹfààní tó máa rí tó bá ń wá sípàdé. Jẹ́ kó wo fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?f Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kóun máa wá sípàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
15. Kí la lè ṣe láti gba akẹ́kọ̀ọ́ wa níyànjú kó lè máa wá sípàdé déédéé?
15 Kí lo lè ṣe tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ kò bá wá sípàdé rí tàbí tí kì í wá déédéé? Sọ ohun tó o gbádùn nípàdé fún un, kó o sì jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ pé lóòótọ́ lo gbádùn ẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé dípò kó o kàn máa sọ fún un pé kó wá. Fún un ní Ilé Ìṣọ́ tàbí Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tí ẹ̀ ń lò nípàdé lọ́wọ́lọ́wọ́. Fi ohun tẹ́ ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e hàn án, kó o sì jẹ́ kó sọ èyí tó máa fẹ́ mọ̀ nípa ẹ̀. Ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa rí tó sì máa kọ́ nípàdé àkọ́kọ́ tó wá máa yàtọ̀ pátápátá sóhun tó rí nínú àwọn ilé ìjọsìn míì tó ti lọ. (1 Kọ́r. 14:24, 25) Yàtọ̀ síyẹn, ó máa rí àwọn míì tó lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn tí wọ́n á sì ràn án lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú kó lè ṣèrìbọmi.
16. Báwo la ṣe lè kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa kí wọ́n lè ṣèrìbọmi, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
16 Báwo la ṣe lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ wa kó lè ṣèrìbọmi? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá gbà á níyànjú pé kó máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kó sì máa múra sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká gbà á níyànjú pé kó máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, kó máa tẹ́tí sí i, kó sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Ó tún yẹ ká ran akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ láti máa wá sípàdé déédéé. (Wo àpótí náà “Ohun Tó Yẹ Káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ṣe Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi”.) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ohun márùn-ún míì táwa akéde lè ṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lè ṣèrìbọmi.
ORIN 76 Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?
a Tá a bá ń kọ́ èèyàn ní nǹkan, ó túmọ̀ sí pé à ń ran onítọ̀hún lọ́wọ́ láti “ronú kó sì máa hùwà lọ́nà tó yàtọ̀ sí bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2020, ìyẹn Mátíù 28:19 jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n ṣèrìbọmi, kí wọ́n sì dọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù yìí.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tó o bá ń bá ẹnì kan fọ̀rọ̀ wérọ̀ látinú Bíbélì déédéé, tẹ́ ẹ sì ń ka àkòrí kan tẹ̀ lé òmíì nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lò ń darí yẹn. O lè ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tó o bá ti darí rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lẹ́yìn tó o ti ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún un, tó o sì mọ̀ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà á máa tẹ̀ síwájú.
c Àwọn àbá tó wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú” tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 2004 sí May 2005 náà wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
d Wo fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin tá a pè ní Kọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Láti Múra Sílẹ̀. Ó wà lórí JW Library® ní MEDIA > OUR MEETINGS AND MINISTRY > IMPROVING OUR SKILLS.
e Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÁ A FI Ń KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ.
f Lórí JW Library®, lọ sí MEDIA > OUR MEETINGS AND MINISTRY > TOOLS FOR THE MINISTRY.