ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 10
Bí Gbogbo Ìjọ Ṣe Lè Mú Kí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Tẹ̀ Síwájú Kó sì Ṣèrìbọmi
“Ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan . . . á mú kí ara máa dàgbà sí i.”—ÉFÉ. 4:16.
ORIN 85 Ẹ Fayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ara Yín
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Ṣé akéde tó ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ nìkan ló lè ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ títí táá fi ṣèrìbọmi? Ṣàlàyé.
ARÁBÌNRIN Amy tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Fíjì sọ pé: “Mo gbádùn ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì gan-an. Mo mọ̀ pé òtítọ́ lohun tí mò ń kọ́. Àmọ́, ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, mo sì tẹ̀ síwájú títí mo fi ṣèrìbọmi.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Amy yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé á túbọ̀ yá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lára láti tẹ̀ síwájú kó sì ṣèrìbọmi táwọn míì nínú ìjọ bá ràn án lọ́wọ́.
2 Gbogbo wa tá a wà nínú ìjọ là ń mú kí ìjọ túbọ̀ gbèrú. (Éfé. 4:16) Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Leilani tó ń gbé ní Vanuatu sọ pé: “Wọ́n sábà máa ń sọ pé ẹnì kan ló ń bímọ, igba èèyàn ló ń wò ó. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tó bá kan ọ̀rọ̀ sísọni dọmọ ẹ̀yìn torí pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ lápapọ̀ ló máa ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe àwọn òbí ni láti tọ́ ọmọ wọn, tẹbítọ̀rẹ́, títí kan àwọn olùkọ́ ló máa ń ran ọmọ náà lọ́wọ́ kó lè yàn kó sì yanjú. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń gba ọmọ náà nímọ̀ràn, wọ́n sì máa ń kọ́ ọ láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé. Lọ́nà kan náà, àwọn ará nínú ìjọ lè gba akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan níyànjú, kí wọ́n fún un níṣìírí, kí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún un. Èyí á jẹ́ kó tẹ̀ síwájú títí táá fi ṣèrìbọmi.—Òwe 15:22.
3. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Ana, Dorin àti Leilani sọ?
3 Kí nìdí tó fi yẹ kínú akéde tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ máa dùn táwọn míì nínú ìjọ bá ń ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́? Ẹ gbọ́ ohun tí Ana tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Moldova sọ. Ó ní: “Kò sí bí akéde kan ṣe mọ̀ọ̀yàn kọ́ tó táá lè pèsè gbogbo ìrànwọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nílò láti tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́.” Dorin tóun náà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lórílẹ̀-èdè Moldova sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn akéde míì máa ń sọ ohun táá wọ akẹ́kọ̀ọ́ mi lọ́kàn, témi sì lè má ronú ẹ̀ rárá.” Leilani tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ń fìfẹ́ hàn tí wọ́n sì ń ṣe inúure sí akẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń mú kó túbọ̀ dá a lójú pé àwa là ń ṣe ìsìn tòótọ́.”—Jòh. 13:35.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Àmọ́ o lè máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ nígbà tí kì í ṣe èmi ni mò ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?’ Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tá a lè ṣe tí akéde kan bá ní ká tẹ̀ lé òun lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan àtohun tá a lè ṣe nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Àá tún rí ohun táwọn alàgbà lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi.
TÍ AKÉDE KAN BÁ NÍ KÓ O TẸ̀ LÉ ÒUN LỌ ṢE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ ẸNÌ KAN
5. Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn tí akéde kan bá ní kó o tẹ̀ lé òun lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan?
5 Ojúṣe akéde tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni láti ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lọ́wọ́ kó lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ dáadáa. Tí akéde náà bá ní kó o tẹ̀ lé òun, fi sọ́kàn pé ṣe lẹ jọ ń ṣiṣẹ́ láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́. (Oníw. 4:9, 10) Ìbéèrè náà ni pé, kí làwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe nígbà tẹ́ ẹ bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà?
6. Báwo lo ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Òwe 20:18 sílò tí akéde kan bá ní kó o tẹ̀ lé òun lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan?
6 Múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ní kí akéde náà sọ díẹ̀ fún ẹ nípa akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. (Ka Òwe 20:18.) O lè béèrè pé: “Kí lo lè sọ fún mi nípa akẹ́kọ̀ọ́ náà? Ibo lẹ bá ìkẹ́kọ̀ọ́ yín dé? Àwọn nǹkan wo lẹ máa fẹ́ tẹnu mọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí? Ṣé ohunkóhun wà tí ẹ ò ní fẹ́ kí n sọ tàbí ṣe níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àwọn nǹkan wo lẹ sì máa fẹ́ kí n ṣe tàbí sọ? Kí lẹ rò pé mo lè sọ táá fún akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí?” Àmọ́ o, má retí pé akéde náà máa sọ ọ̀rọ̀ àṣírí akẹ́kọ̀ọ́ náà fún ẹ, ìwọ̀nba tó bá sọ fún ẹ máa jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Irú àwọn nǹkan yìí ni míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Joy máa ń jíròrò pẹ̀lú àwọn tó máa ń tẹ̀ lé e lọ sọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Irú ìjíròrò yìí máa ń jẹ́ káwọn tá a jọ ṣiṣẹ́ túbọ̀ mọ akẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè sọ ohun táá ṣe é láǹfààní.”
7. Kí nìdí tó fi yẹ kó o múra sílẹ̀ tó o bá máa tẹ̀ lé ẹnì kan lọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́?
7 Tó o bá máa tẹ̀ lé ẹnì kan lọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́, á dáa kó o múra ibi tẹ́ ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀. (Ẹ́sírà 7:10) Arákùnrin Dorin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Inú mi máa ń dùn tẹ́ni tá a jọ ṣiṣẹ́ bá ti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀, torí pé ìyẹn á jẹ́ kó lè sọ ohun tó máa ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní.” Yàtọ̀ síyẹn, akẹ́kọ̀ọ́ náà máa kíyè sí pé ẹ̀yin méjèèjì múra sílẹ̀ dáadáa, ìyẹn á sì fún un níṣìírí láti máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ká tiẹ̀ wá sọ pé o ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ bó o ṣe fẹ́, gbìyànjú kó o mọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú ibi tẹ́ ẹ fẹ́ kà.
8. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí àdúrà tó o máa gbà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ kan nítumọ̀?
8 Àdúrà tá a máa ń gbà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe pàtàkì gan-an, torí náà á dáa kó o ti ronú ohun tó o máa sọ tí wọ́n bá ní kó o gbàdúrà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àdúrà rẹ á nítumọ̀. (Sm. 141:2) Hanae tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Japan ṣì ń rántí àdúrà tí arábìnrin tó tẹ̀ lé ẹni tó ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gbà. Ó sọ pé: “Mo kíyè sí i pé ó ní àjọṣe tó lágbára pẹ̀lú Jèhófà, ó sì wù mí kí n fara wé e. Yàtọ̀ síyẹn, ara tù mí nígbà tó dárúkọ mi nínú àdúrà náà.”
9. Kí ni Jémíìsì 1:19 sọ táá jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ran ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́?
9 Ran ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń jẹ́ Omamuyovbi lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pé: “Ó yẹ kẹ́ni tó wà pẹ̀lú ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Ó lè lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà àmọ́ kò yẹ kó sọ̀rọ̀ jù, torí òun kọ́ ló ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.” Kí lá jẹ́ kó o mọ ìgbà tó yẹ kó o lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà àtohun tó yẹ kó o sọ? (Òwe 25:11) Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń sọ̀rọ̀. (Ka Jémíìsì 1:19.) Ìyẹn lá jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o sọ àti ìgbà tó yẹ kó o sọ̀rọ̀. Àmọ́ o, á dáa kó o ronú jinlẹ̀ kó o tó sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, kò ní dáa kó o sọ̀rọ̀ jù tàbí kó o já ọ̀rọ̀ gbà mọ́ akéde náà lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní dáa kó o gbé ọ̀rọ̀ gba ibòmíì. Lọ́wọ́ kejì, o lè ṣe àlàyé ṣókí tàbí àpèjúwe, o sì lè béèrè ìbéèrè táá mú kí ohun tí wọ́n ń jíròrò túbọ̀ ṣe kedere. Nígbà míì, o lè má ní ohun tó o máa fi kún àlàyé tí akéde náà ṣe. Àmọ́, o lè gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ náà, kó o sì fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó lè tẹ̀ síwájú.
10. Báwo ni ìrírí tó o ní ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ́wọ́?
10 Sọ àwọn ìrírí tó o ní fún un. Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, o lè ṣàlàyé bó o ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, o lè sọ bó o ṣe borí ìṣòro kan tàbí bó o ṣe rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ. (Sm. 78:4, 7) Ohun tó o sọ lè ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára tàbí kó jẹ́ ohun tó nílò nìyẹn kó lè pinnu pé òun máa ṣèrìbọmi. Ó sì lè jẹ́ ohun tó o sọ ló máa jẹ́ kó borí ìṣòro tó ń kojú. (1 Pét. 5:9) Gabriel tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil tó sì ti di aṣáájú-ọ̀nà báyìí rántí bí ìrírí ẹnì kan ṣe ràn án lọ́wọ́ nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Ìrírí àwọn ará tí mo gbọ́ jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà mọ àwọn ìṣòro tá à ń kojú, ó sì jẹ́ kó dá mi lójú pé tí wọ́n bá lè borí àwọn ìṣòro wọn, èmi náà lè borí tèmi.”
TÍ AKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ KAN BÁ WÁ SÍPÀDÉ
11-12. Kí nìdí tó fi yẹ ká kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó wá sípàdé tọ̀yàyàtọ̀yàyà?
11 Kí akẹ́kọ̀ọ́ kan tó lè tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ máa wá sípàdé déédéé, kó sì máa kópa nínú ẹ̀. (Héb. 10:24, 25) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ lá kọ́kọ́ pè é wá sípàdé. Tó bá ti wá sípàdé, ó yẹ kí gbogbo wa fún un níṣìírí kó lè túbọ̀ máa wá déédéé. Àwọn ọ̀nà pàtó wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
12 Kí akẹ́kọ̀ọ́ náà tọ̀yàyàtọ̀yàyà. (Róòmù 15:7) Tá a bá ṣe ohun táá jẹ́ kí ara tu akẹ́kọ̀ọ́ kan nípàdé, ìyẹn lè mú kó túbọ̀ wù ú láti máa wá déédéé. Láìki àṣejù bọ̀ ọ́, fi ọ̀yàyà kí akẹ́kọ̀ọ́ náà, kó o sì fojú ẹ̀ mọ àwọn míì. Má ṣe ronú pé ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ló máa ṣèyẹn torí onítọ̀hún lè má tíì dé tàbí kó ní àwọn ojúṣe míì tó ń bójú tó. Rí i dájú pé o tẹ́tí sí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá sọ, kó o sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ jẹ ẹ́ lọ́kàn. Báwo ló ṣe máa rí lára akẹ́kọ̀ọ́ náà tó o bá ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dmitrii tó ṣèrìbọmi láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn tó sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà àkọ́kọ́ tó wá sípàdé, ó ní: “Ìta Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ni mo wà tí mo ti ń yọjú nígbà tí arákùnrin kan rí mi, tó sì mú mi wọlé. Bí mo ṣe ń wọlé làwọn èèyàn wá ń kí mi lọ́tùn-ún lósì. Ó yà mí lẹ́nu gan-an. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn wú mi lórí gan-an débi pé ṣe ló ń ṣe mí bíi pé ká máa ṣèpàdé lójoojúmọ́. Mi ò rírú ẹ̀ rí ní gbogbo ibi tí mo ti ń lọ tẹ́lẹ̀.”
13. Kí ni nǹkan míì tó o lè ṣe, àǹfààní wo sì nìyẹn máa ṣe akẹ́kọ̀ọ́ kan?
13 Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ìwà tó o bá hù lè jẹ́ kó túbọ̀ dá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lójú pé òun ti rí òtítọ́. (Mát. 5:16) Vitalii tó ti di aṣáájú-ọ̀nà báyìí ní Moldova sọ pé: “Mo kíyè sí bí àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn, irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àti ìwà tí wọ́n ń hù. Ìyẹn sì jẹ́ kó dá mi lójú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe ìsìn tòótọ́.”
14. Báwo ni àpẹẹrẹ rẹ ṣe lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ kan túbọ̀ tẹ̀ síwájú?
14 Kí akẹ́kọ̀ọ́ kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ máa fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. Èyí kì í sábà rọrùn. Àmọ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣe ń kíyè sí bó o ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tó sì ń ṣe ẹ́ láǹfààní, ìyẹn lè mú kó wù ú láti fara wé ẹ. (1 Kọ́r. 11:1) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Hanae tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Ó ní: “Mo rí bí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ sílò, ìyẹn sì jẹ́ kémi náà rí bí mo ṣe lè fi í sílò. Àpẹẹrẹ wọn jẹ́ kí n rí bí mo ṣe lè máa fún àwọn míì níṣìírí, bí mo ṣe lè máa dárí jini, kí n sì máa fìfẹ́ hàn. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń sọ dáadáa nípa àwọn míì, ó sì wù mí kí n fara wé wọn.”
15. Kí ni Òwe 27:17 sọ tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká mú akẹ́kọ̀ọ́ tó ń wá sípàdé lọ́rẹ̀ẹ́?
15 Mú akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́rẹ̀ẹ́. Túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe ń wá sípàdé déédéé. (Fílí. 2:4) O ò ṣe sún mọ́ ọn, kó o lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. Jẹ́ kó mọ bí inú ẹ ṣe dùn tó pé ó ń tẹ̀ síwájú. O tún lè béèrè nípa ìdílé ẹ̀, iṣẹ́ ẹ̀ àti bí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ ṣe ń lọ sí, àmọ́ ṣọ́ra kó o má lọ béèrè ìbéèrè tó lè dójú tì í. Irú àwọn ìjíròrò yìí lè mú kẹ́ ẹ dọ̀rẹ́. Tẹ́ ẹ bá dọ̀rẹ́, á ṣeé ṣe fún ẹ láti ràn án lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi. (Ka Òwe 27:17.) Hanae tó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí sọ bí nǹkan ṣe rí nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Ó ní: “Bí mo ṣe túbọ̀ ń ní àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń wù mí láti máa wá sípàdé déédéé, kódà mi kì í pa ìpàdé jẹ tó bá rẹ̀ mí. Inú mi máa ń dùn láti wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi tó wà nínú ìjọ. Èyí mú kó rọrùn láti já àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ sílẹ̀ torí wọn ò sin Jèhófà. Ó wù mí gan-an láti sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ará. Torí náà, mo pinnu pé màá ṣèrìbọmi.”
16. Kí lo tún lè ṣe táá mú kára tu akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nínú ìjọ?
16 Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, tó sì ń ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, ṣe ohun táá jẹ́ kó mọ̀ pé kì í ṣe ẹni tuntun mọ́ láàárín wa. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń fẹ̀mí aájò àlejò hàn sí i. (Héb. 13:2) Denis tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Moldova sọ bí nǹkan ṣe rí nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ará pe èmi àtìyàwó mi wá sílé wọn. Oníkálùkù wọn sọ bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́, èyí sì fún wa níṣìírí gan-an. Àwọn àsìkò tá a lò pẹ̀lú àwọn ará yẹn jẹ́ kó túbọ̀ wù wá láti sin Jèhófà, a sì mọ̀ pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀.” Lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti di akéde, o lè sọ fún un pé kẹ́ ẹ jọ jáde òde ẹ̀rí. Arákùnrin Diego tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo di akéde, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ní kí n bá àwọn jáde òde ẹ̀rí, ìyẹn sì jẹ́ kí n mọ̀ wọ́n dáadáa. Bí mo ṣe túbọ̀ ń mọ̀ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni mò ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ìyẹn sì mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Jésù.”
BÍ ÀWỌN ALÀGBÀ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́
17. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́?
17 Ẹ máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀yin alàgbà, tẹ́ ẹ bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn á mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á fi ṣèrìbọmi. Ṣé ẹ lè máa wáyè bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípàdé? Tó o bá rántí orúkọ wọn, pàápàá tí wọ́n bá fẹ́ dáhùn nípàdé, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o mọyì àwọn. Ṣé o lè ṣètò láti máa bá akéde kan lọ sọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní ju bó o ṣe rò lọ. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Jackie lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pé: “Ó máa ń ya àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi lẹ́nu tí wọ́n bá gbọ́ pé alàgbà lẹni tó tẹ̀ lé mi wá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ wọn. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi kan tiẹ̀ sọ pé: ‘Pásítọ̀ wa ò lè ṣerú ẹ̀ láéláé. Ọ̀dọ̀ àwọn olówó nìkan ló máa ń lọ, kò sì ní lọ tí wọn ò bá fún un lówó!’ ” Ní báyìí, akẹ́kọ̀ọ́ yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé.
18. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi ìtọ́ni tó wà nínú Ìṣe 20:28 sílò?
18 Ẹ dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́, kẹ́ ẹ sì máa fún wọn níṣìírí. Ẹ̀yin alàgbà, ojúṣe yín ni láti ran àwọn akéde lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. (Ka Ìṣe 20:28.) Tójú bá ń ti akéde kan láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níṣojú ẹ, o lè bá a darí ẹ̀. Jackie tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Gbogbo ìgbà làwọn alàgbà máa ń béèrè nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi. Tí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo máa ń sọ fáwọn alàgbà, wọ́n sì máa ń fún mi nímọ̀ràn tó yẹ.” Ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ̀yin alàgbà lè ṣe láti fún àwọn akéde níṣìírí kí wọ́n má bàa juwọ́ sílẹ̀. (1 Tẹs. 5:11) Jackie fi kún un pé: “Inú mi máa ń dùn táwọn alàgbà bá fún mi níṣìírí tí wọ́n sì sọ fún mi pé àwọn mọyì ìsapá mi. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń tù mí lára gan-an, ó sì máa ń dà bí ìgbà tí wọ́n fún mi lómi tútù lọ́sàn-án gangan. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí yẹn máa ń wú mi lórí, ó sì ń jẹ́ kí n túbọ̀ máa láyọ̀ bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.”—Òwe 25:25.
19. Kí ló máa fún gbogbo wa láyọ̀?
19 Tá ò bá tiẹ̀ ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń darí báyìí, a lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi. Tá a bá ti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ dáadáa, àá lè ṣe àwọn àfikún táá gbé akẹ́kọ̀ọ́ náà ró láìsọ̀rọ̀ jù. A lè mú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́rẹ̀ẹ́ tí wọ́n bá wá sípàdé, a sì lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. Bákan náà, àwọn alàgbà lè fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí tí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn tí wọ́n bá ń dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń gbóríyìn fún wọn, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè máa fayọ̀ bá iṣẹ́ náà nìṣó. Kò sí àní-àní pé gbogbo wa pátá la máa láyọ̀ tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe bó ti wù ó kéré mọ láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ kó lè wá sin Jèhófà Baba wa ọ̀run.
ORIN 79 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in
a Kì í ṣe gbogbo wa la lẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Àmọ́ gbogbo wa la lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú títí táá fi ṣèrìbọmi. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ kó lè ṣèrìbọmi.