ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 22
Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Jẹ́ Káyé Wa Dùn
“Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n.”—ÒWE 2:6.
ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí nìdí tí gbogbo wa fi nílò ọgbọ́n Ọlọ́run? (Òwe 4:7)
Ó DÁJÚ pé tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, o máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ lọ́gbọ́n, ohun tó sì yẹ kó o ṣe nìyẹn. (Jém. 1:5) Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Ọgbọ́n ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.” (Ka Òwe 4:7.) Ó dájú pé kì í ṣe ọgbọ́n kan lásán ni Sólómọ́nì ń sọ, ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ló ń sọ. (Òwe 2:6) Àmọ́ ṣé ọgbọ́n Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tá à ń ní lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí.
2. Kí ló máa mú ká di ọlọ́gbọ́n?
2 Ohun tó máa jẹ́ ká di ọlọ́gbọ́n ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa fi ìmọ̀ràn tí àwọn èèyàn méjì kan fún wa sílò torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọgbọ́n wọn ti wá. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Sólómọ́nì. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ gan-an.” (1 Ọba 4:29) Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa Jésù tó gbọ́n jù lọ láyé. (Mát. 12:42) Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù pé: “Ẹ̀mí Jèhófà máa bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye.”—Àìsá. 11:2.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Sólómọ́nì àti Jésù lo ọgbọ́n tí Jèhófà fún wọn láti fún wa nímọ̀ràn nípa àwọn ohun pàtàkì nígbèésí ayé wa. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò mẹ́ta lára wọn. Àwọn nǹkan náà ni, ojú tó yẹ ká fi wo owó, iṣẹ́ wa àti ara wa.
OJÚ TÓ YẸ KÁ FI WO OWÓ
4. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín bí nǹkan ṣe rí fún Sólómọ́nì àti Jésù?
4 Sólómọ́nì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sì gbádùn ara ẹ̀ dọ́ba. (1 Ọba 10:7, 14, 15) Àmọ́ ní ti Jésù, ohun ìní díẹ̀ ló ní, kò sì nílé tara ẹ̀. (Mát. 8:20) Síbẹ̀, ojú tó tọ́ làwọn méjèèjì fi wo ohun ìní torí pé Jèhófà Ọlọ́run ló fún wọn lọ́gbọ́n.
5. Ojú tó tọ́ wo ni Sólómọ́nì fi wo owó?
5 Sólómọ́nì gbà pé owó “jẹ́ ààbò.” (Oníw. 7:12) Tá a bá lówó, àá lè ra àwọn ohun kòṣeémáàní àtàwọn nǹkan míì tá a nílò. Síbẹ̀, bí Sólómọ́nì ṣe lówó tó, ó gbà pé àwọn nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì ju owó lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Orúkọ rere ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀.” (Òwe 22:1) Sólómọ́nì tún sọ pé inú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó kì í fi bẹ́ẹ̀ dùn torí ohun tí wọ́n ní kì í tó wọn. (Oníw. 5:10, 12) Ó sì kìlọ̀ fún wa pé ká má gbẹ́kẹ̀ lé owó torí pé owó tá a ní lè lọ lójijì.—Òwe 23:4, 5.
6. Ojú tó tọ́ wo ni Jésù fi wo àwọn nǹkan tara? (Mátíù 6:31-33)
6 Ojú tó tọ́ ni Jésù fi wo àwọn nǹkan tara. Ó máa ń gbádùn oúnjẹ àti ohun mímu. (Lúùkù 19:2, 6, 7) Ìgbà kan wà tó ṣe wáìnì tó dáa gan-an, kódà iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tó ṣe nìyẹn. (Jòh. 2:10, 11) Lọ́jọ́ tó sì kú, aṣọ olówó ńlá ló wọ̀. (Jòh. 19:23, 24) Àmọ́ kì í ṣe àwọn nǹkan tara yẹn ni Jésù gbájú mọ́. Ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì . . . Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.” (Mát. 6:24) Jésù kọ́ wa pé tá a bá ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run máa pèsè ohun tá a nílò fún wa.—Ka Mátíù 6:31-33.
7. Àǹfààní wo ni arákùnrin kan rí torí pé ojú tó tọ́ ló fi wo owó?
7 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló ti jàǹfààní torí pé wọ́n ń lo ọgbọ́n Ọlọ́run tó bá dọ̀rọ̀ owó. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tí kò tíì gbéyàwó tó ń jẹ́ Daniel. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, mo pinnu pé ìjọsìn Jèhófà ló máa gbawájú láyé mi.” Torí pé Daniel jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ó ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì, ó sì máa ń yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ran àwọn tí àjálù dé bá lọ́wọ́. Ó tún sọ pé: “Mi ò kábàámọ̀ ìpinnu tí mo ṣe rí. Lóòótọ́, ká sọ pé owó ni mo fẹ́ ní, màá ti lówó gan-an báyìí. Àmọ́ ṣé owó lè rọ́pò àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí mo ti ní báyìí? Àbí ṣé owó lè fún mi ní ìtẹ́lọ́rùn tí mo ní báyìí torí pé mo fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé mi? Kò sí owó tó lè ra àwọn ohun rere tí Jèhófà ti fún mi.” Ó ti hàn gbangba pé a máa jàǹfààní gan-an tó bá jẹ́ pé ìjọsìn Ọlọ́run la gbájú mọ́ dípò owó.
OJÚ TÓ YẸ KÁ FI WO IṢẸ́ WA
8. Báwo la ṣe mọ̀ pé ojú tó tọ́ ni Sólómọ́nì fi wo iṣẹ́? (Oníwàásù 5:18, 19)
8 Sólómọ́nì sọ pé téèyàn bá ń gbádùn iṣẹ́ tó ń ṣe, “ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.” (Ka Oníwàásù 5:18, 19.) Ó sọ pé: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.” (Òwe 14:23) Sólómọ́nì mọ̀ pé bó ṣe rí nìyẹn torí pé òṣìṣẹ́ kára lòun náà. Ó kọ́ ọ̀pọ̀ ilé, ó gbin àwọn ọgbà àjàrà, ó sì ṣe àwọn ọgbà ọ̀gbìn àtàwọn adágún omi. Yàtọ̀ síyẹn, ó kọ́ àwọn ìlú. (1 Ọba 9:19; Oníw. 2:4-6) Ó dájú pé iṣẹ́ àṣekára ló ṣe, àmọ́ iṣẹ́ yẹn fún un láyọ̀. Síbẹ̀, Sólómọ́nì mọ̀ pé àwọn iṣẹ́ yẹn nìkan ò lè fún òun láyọ̀. Torí náà, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó bójú tó iṣẹ́ tẹ́ńpìlì ológo kan tí wọ́n kọ́ fún ìjọsìn Jèhófà, ọdún méje gbáko ni wọ́n sì fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà! (1 Ọba 6:38; 9:1) Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run àti iṣẹ́ tara ẹ̀, ó rí i pé iṣẹ́ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì ju gbogbo iṣẹ́ yòókù lọ. Ó sọ pé: “Òpin ọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—Oníw. 12:13.
9. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ojú tó tọ́ ló fi wo iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀?
9 Òṣìṣẹ́ kára ni Jésù. Nígbà tí Jésù wà lọ́dọ̀ọ́, iṣẹ́ káfíńtà ló ṣe. (Máàkù 6:3) Ó dájú pé àwọn òbí ẹ̀ mọyì ìrànlọ́wọ́ tó ṣe fún wọn kí wọ́n lè pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò. Torí pé ẹni pípé ni Jésù, àwọn èèyàn máa fẹ́ràn iṣẹ́ tó bá ṣe gan-an! Ó sì dájú pé Jésù náà gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an. Síbẹ̀, bí Jésù ṣe ń ṣiṣẹ́ káfíńtà ẹ̀ lọ, ó ṣì ya àkókò sọ́tọ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. (Jòh. 7:15) Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé: “Ẹ má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:27) Bákan náà, nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù sọ pé: “Ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.”—Mát. 6:20.
10. Ìṣòro wo làwọn kan máa ń ní níbi iṣẹ́ wọn?
10 Tá a bá ń lo ọgbọ́n Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ ká fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ oúnjẹ ọ̀ọ̀jọ́ wa. A ti kọ́ àwa Kristẹni pé ká “máa ṣiṣẹ́ kára . . . , iṣẹ́ rere.” (Éfé. 4:28) Àwọn tó gbà wá síṣẹ́ máa ń rí i pé olóòótọ́ ni wá, a sì máa ń ṣiṣẹ́ kára, kódà wọ́n lè sọ fún wa pé àwọn mọyì bá a ṣe ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́. Torí náà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi kún iye wákàtí tá a fi ń ṣiṣẹ́ ká lè fi han àwọn ọ̀gá wa pé èèyàn dáadáa làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, a lè wá rí i pé a ti ń pa ojúṣe wa nínú ìdílé tì, a ò sì fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wa mọ́. Tí irú ẹ̀ bá ti ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ẹ jẹ́ ká tètè ṣàtúnṣe.
11. Kí ni arákùnrin kan kọ́ nípa ojú tó yẹ ká máa fi wo iṣẹ́ oúnjẹ ọ̀ọ̀jọ́?
11 Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ William ti rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa alàgbà kan tó gbà á síṣẹ́ rí, ó ní: “Àpẹẹrẹ rere ni arákùnrin yìí tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, inú àwọn tó ń gbéṣẹ́ fún un sì máa ń dùn torí pé iṣẹ́ ẹ̀ dáa gan-an. Àmọ́ tí iṣẹ́ ọjọ́ yẹn bá ti parí, ó máa ń kúrò níbi iṣẹ́, á sì lọ lo àkókò tó kù fún ìdílé ẹ̀ àti ìjọsìn Ọlọ́run. Ṣé ẹ rí i, arákùnrin yìí wà lára àwọn tó láyọ̀ jù tí mo mọ̀!”b
OJÚ TÓ YẸ KÁ MÁA FI WO ARA WA
12. Kí ni Sólómọ́nì ṣe tó fi hàn pé ojú tó tọ́ ló fi wo ara ẹ̀, àmọ́ àṣìṣe wo ló ṣe?
12 Nígbà tí Sólómọ́nì ń fi òótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ojú tó tọ́ ló fi ń wo ara ẹ̀. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó gbà pé òun ò gbọ́n tó, ó sì bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. (1 Ọba 3:7-9) Nígbà tí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, ó gbà pé ó léwu téèyàn bá ń gbéra ga. Ó ní: “Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun, ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.” (Òwe 16:18) Ó ṣeni láàánú pé nígbà tó yá, Sólómọ́nì ò fi ìmọ̀ràn tóun fúnra ẹ̀ sọ sílò mọ́. Bó ṣe ń jọba lọ, ó di agbéraga, kò sì ka òfin Ọlọ́run sí mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn òfin yẹn sọ pé àwọn ọba Ísírẹ́lì ò ‘gbọ́dọ̀ kó ìyàwó rẹpẹtẹ jọ fún ara wọn, kí ọkàn wọn má bàa yí pa dà.’ (Diu. 17:17) Àmọ́ Sólómọ́nì ò ka òfin yẹn sí. Ṣe ló fẹ́ ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, abọ̀rìṣà ló pọ̀ jù nínú wọn! (1 Ọba 11:1-3) Sólómọ́nì lè rò pé “kò séwu kankan.” Àmọ́ ohun yòówù kó mú kó ṣe ohun tó ṣe yẹn, ó jìyà ẹ̀ nígbà tó yá torí pé ó fi Jèhófà sílẹ̀.—1 Ọba 11:9-13.
13. Kí la rí kọ́ látinú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní?
13 Jésù fi ojú tó tọ́ wo ara ẹ̀, kò sì gbéra ga rárá. Kó tó wá sáyé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti bá Jèhófà ṣe lọ́run. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé nípasẹ̀ Jésù “ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé.” (Kól. 1:16) Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó rántí àwọn nǹkan tó ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ Bàbá ẹ̀ lọ́run. (Mát. 3:16; Jòh. 17:5) Síbẹ̀, àwọn nǹkan tó rántí yẹn ò mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, kó sì ronú pé òun dáa ju gbogbo àwọn èèyàn yòókù lọ. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé òun wá kì í ṣe torí ‘ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún òun, àmọ́ kóun lè ṣe ìránṣẹ́, kóun sì fi ẹ̀mí òun ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.’ (Mát. 20:28) Kódà, ó sọ pé òun ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara òun. (Jòh. 5:19) Ẹ ò rí i pé Jésù nírẹ̀lẹ̀ gan-an! Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fún gbogbo wa.
14. Kí la rí kọ́ lára Jésù nípa ojú tó yẹ ká máa fi wo ara wa?
14 Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa fojú tó tọ́ wo ara wọn. Nígbà kan, Jésù fi dá wọn lójú pé: “Gbogbo irun orí yín la ti kà.” (Mát. 10:30) Ọ̀rọ̀ yẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an pàápàá tá a bá ń rò pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Ìyẹn fi hàn pé Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, a sì níyì lójú ẹ̀. Tí Jèhófà bá kà wá yẹ láti máa jọ́sìn ẹ̀ àti láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun, kò yẹ ká rò pé ohun tí Jèhófà ṣe ò tọ́.
15. (a) Ojú tó tọ́ wo ni Ilé Ìṣọ́ kan ní ká máa fi wo ara wa? (b) Bá a ṣe rí i nínú àwòrán ojú ìwé 24, kí la máa pàdánù tó bá jẹ́ pé tara wa nìkan là ń rò?
15 Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ kan sọ irú ojú tó yẹ ká máa fi wo ara wa, ó ní: “Dájúdájú, a ò ní fẹ́ ro ara wa ju bó ti yẹ lọ débi tá a máa fi di agbéraga. Bẹ́ẹ̀ la ò tún ní rora wa pin pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa wo ara wa bá a ṣe rí gan-an, ìyẹn ni pé ká mọ ibi tágbára wa dé ká sì mọ̀wọ̀n ara wa. Ọ̀nà tí arábìnrin kan gbà sọ ọ́ nìyí, ó ní: ‘Mi ò kì í ṣe èèyàn burúkú; bẹ́ẹ̀ ni mi ò dára ju àwọn èèyàn tó kù lọ. Mo láwọn ànímọ́ tó dára mo sì láwọn ànímọ́ tí ò dáa, bí gbogbo èèyàn tó kù sì ṣe rí nìyẹn.’ ”c Ṣé ẹ ti wá rídìí tó fi yẹ ká máa fojú tó tọ́ wo ara wa báyìí?
16. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń tọ́ wa sọ́nà?
16 Jèhófà ń fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà ká lè gbọ́n. Ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká láyọ̀. (Àìsá. 48:17, 18) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a gbọ́n, ohun tó dáa jù tó yẹ ká ṣe ni pé ká fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, ìyẹn ló sì máa fún wa láyọ̀ jù lọ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní níṣòro táwọn tó ń fi gbogbo ayé wọn wá owó máa ń ní, a ò sì ní kó síṣòro tí àwọn tí ò mọ̀ ju iṣẹ́ àti ara wọn máa ń kó sí. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pinnu pé a máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n, àá sì mú ọkàn Jèhófà yọ̀!—Òwe 23:15.
ORIN 94 A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
a Ọgbọ́n tí Sólómọ́nì àti Jésù ní pọ̀ gan-an. Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run ló fún wọn ní gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ní yẹn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Sólómọ́nì àti Jésù fún wa. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ojú tó yẹ ká máa fi wo owó, iṣẹ́ wa àti ara wa. A tún máa rí bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n fi ìmọ̀ràn Bíbélì nípa àwọn nǹkan yìí sílò.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Bí O Ṣe Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára” nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2015.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti Rí Ayọ̀” nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2005.
d ÀWÒRÁN: Ìjọ kan náà ni àwọn ọ̀dọ́ méjì kan tó ń jẹ́ John àti Tom wà. John máa ń fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò ẹ̀ bójú tó mọ́tò ẹ̀. Àmọ́ Tom máa ń fi mọ́tò tiẹ̀ gbé àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí àti ìpàdé.
e ÀWÒRÁN: John ń ṣe àfikún iṣẹ́ torí pé ó fẹ́ kí inú ọ̀gá òun máa dùn sóun. Torí náà, gbogbo ìgbà tí ọ̀gá ẹ̀ bá ti sọ pé kó ṣe àfikún iṣẹ́ ló máa ń ṣe é. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí John ń ṣe àfikún iṣẹ́, Tom tó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tẹ̀ lé alàgbà kan lọ ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ arábìnrin kan. Ṣáájú ìgbà yẹn, Tom ti ṣàlàyé fún ọ̀gá ẹ̀ pé àwọn ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan wà láàárín ọ̀sẹ̀ tóun máa fi ń ṣe ìjọsìn Jèhófà.
f ÀWÒRÁN: Ọ̀rọ̀ tara ẹ̀ ni John gbájú mọ́. Tom ní tiẹ̀ fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé ẹ̀, ó sì láwọn ọ̀rẹ́ tuntun níbi tó ti lọ yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti tún Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan ṣe.