Ṣé Àpẹẹrẹ Rere Ló Jẹ́ Fún ẹ Àbí Àpẹẹrẹ Búburú?
“Ọlọ́run Jékọ́bù . . . yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.”—AÍSÁ. 2:3.
1, 2. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà jàǹfààní nínú àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì?
ṢÓ DÁ ẹ lójú pé o lè jàǹfààní nínú àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ? Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ ló wà nínú Bíbélì tí wàá fẹ́ láti fi ọ̀nà tí wọ́n gbà gbé ìgbé ayé wọn àtàwọn ànímọ́ wọn ṣe àwòkọ́ṣe. (Héb. 11:32-34) Àmọ́, ó tún ṣeé ṣe kó o ti kà nípa àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ búburú, tí o kò ní fẹ́ láti fìwà jọ.
2 Bíbélì sì tún sọ nípa àwọn èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere torí pé wọ́n gbé ìgbé ayé tó yẹ, tí wọ́n sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ búburú torí pé wọ́n hu ìwà tó yẹ ká sá fún. Ronú nípa Dáfídì, olùṣọ́ àgùntàn rírẹlẹ̀ tó wá di ọba alágbára. Ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa jíjẹ́ ẹni tó fẹ́ràn òtítọ́ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Síbẹ̀, Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Ó ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó pa Ùráyà, ó sì hùwà òmùgọ̀ nípa kíka àwọn èèyàn. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọmọ rẹ̀, ìyẹn Sólómọ́nì tó jẹ́ ọba àti ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì. A óò kọ́kọ́ kíyè sí ọ̀nà méjì tó gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere.
“Ọgbọ́n Sólómọ́nì”
3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Sólómọ́nì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa?
3 Jésù Kristi tó jẹ́ Sólómọ́nì Títóbi Jù sọ̀rọ̀ rere nípa Sólómọ́nì Ọba, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ká rí i pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Jésù sọ fún àwọn Júù kan tó ń ṣiyè méjì pé: “A óò gbé ọbabìnrin gúúsù dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí pé ó wá láti àwọn òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, ṣùgbọ́n, wò ó! ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ wà níhìn-ín.” (Mát. 12:42) Bẹ́ẹ̀ ni, ọgbọ́n tí Sólómọ́nì ní sọ ọ́ di olókìkí, ó sì rọ àwa náà pé ká jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
4, 5. Báwo ni Sólómọ́nì ṣe di ọlọ́gbọ́n, àmọ́ báwo ni ọ̀nà tá a lè gbà di ọlọ́gbọ́n ṣe yàtọ̀?
4 Nígbà tí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, Ọlọ́run fara hàn án nínú àlá ó sì ní kó béèrè ohun tó bá fẹ́. Sólómọ́nì mọ̀ pé òun ò tíì ní ìrírí, torí náà ó ní kí Ọlọ́run fún òun ní ọgbọ́n. (Ka 1 Àwọn Ọba 3:5-9.) Inú Ọlọ́run dùn pé Sólómọ́nì béèrè fún ọgbọ́n dípò ọrọ̀ àti ògo, torí náà ó fún un ní “ọkàn-àyà ọgbọ́n àti òye” àti aásìkí. (1 Ọba 3:10-14) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ọgbọ́n Sólómọ́nì tayọ débi pé ọbabìnrin Ṣébà gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì rin ìrìn àjò gígùn láti wá fetí ara rẹ̀ gbọ́ ọ.—1 Ọba 10:1, 4-9.
5 Ẹnikẹ́ni nínú wa kò retí pé kí Ọlọ́run fún òun ní ọgbọ́n lọ́nà ìyanu. Òótọ́ ni pé Sólómọ́nì sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n.” Àmọ́, ó fẹ́ ká sapá láti ní ọgbọ́n tó jẹ́ ànímọ́ Ọlọ́run yìí, torí náà ó sọ pé: “Dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀.” Ó tún lo àwọn gbólóhùn míì tó jọ ìyẹn, irú bíi “ké pe,” ọgbọ́n, máa “bá a nìṣó ní wíwá a” àti máa “bá a nìṣó ní wíwá a kiri.” (Òwe 2:1-6) Ó dájú pé a lè ní ọgbọ́n.
6. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé à ń jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ rere Sólómọ́nì bó bá kan ti ọgbọ́n?
6 Ó máa dára ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ èmi náà ka ọgbọ́n Ọlọ́run sí ìṣúra ṣíṣeyebíye bí Sólómọ́nì ti ṣe?’ Ètò ọrọ̀ ajé tí kò dúró sójú kan ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn àti ọ̀ràn ìnáwó tàbí kó mú kí wọ́n pinnu pé ó nírú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìwé táwọn gbọ́dọ̀ ní àti ibi tó yẹ káwọn kàwé dé. Ìwọ àti ìdílé rẹ ńkọ́? Ṣé ohun tẹ́ ẹ yàn láti ṣe ń fi hàn pé ẹ ka ọgbọ́n Ọlọ́run sí ohun tó ṣeyebíye tẹ́ ẹ sì ń wá a? Ṣé o lè ní ọgbọ́n púpọ̀ sí i tó o bá yí ohun tó o gbájú mọ́ tàbí ohun tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ pa dà? Ó dájú pé bó o bá ní ọgbọ́n Ọlọ́run tó o sì ń fi ọgbọ́n náà ṣèwà hù, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó máa wà pẹ́ títí. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.”—Òwe 2:9.
Àlàáfíà Wà Nígbà Tí Sólómọ́nì Gbé Ìjọsìn Tòótọ́ Lárugẹ
7. Ta ló kọ́ tẹ́ńpìlì àrímáleèlọ fún Ọlọ́run?
7 Nígbà tí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ó kọ́ tẹ́ńpìlì ọlọ́lá ńlá kan dípò àgọ́ ìjọsìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń lò látìgbà ayé Mósè. (1 Ọba 6:1) A lè pè é ní tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, àmọ́ òun kọ́ ló mú àbá wá pé kí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà, kò sì kọ́ ọ kó bàa lè ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi kọ́lékọ́lé tàbí ẹlẹ́yinjú-àánú tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Dáfídì gan-an ló kọ́kọ́ mú àbá wá pé kí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì, Ọlọ́run sì fún un ní àwòrán tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí wọ́n ṣe máa kọ́ ọ àti àwọn nǹkan tó máa wà nínú rẹ̀. Dáfídì sì fi owó rẹpẹtẹ ṣètọrẹ fún kíkọ́ ilé náà. (2 Sám. 7:2, 12, 13; 1 Kíró. 22:14-16) Síbẹ̀, Sólómọ́nì ni iṣẹ́ já lé léjìká láti kọ́ ilé náà, èyí tó gba ọdún méje àtààbọ̀.—1 Ọba 6:37, 38; 7:51.
8, 9. (a) Báwo ni Sólómọ́nì ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa tẹpẹlẹ mọ́ iṣẹ́ rere? (b) Kí ni bí Sólómọ́nì ṣe gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ yọrí sí?
8 Sólómọ́nì tipa báyìí fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa tẹpẹlẹ mọ́ iṣẹ́ rere, ó sì gbájú mọ́ ohun tó tọ́. Nígbà tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà tán tí wọ́n sì gbé àpótí májẹ̀mú sínú rẹ̀, Sólómọ́nì gbàdúrà níwájú àwùjọ àwọn èèyàn náà. Díẹ̀ lára ohun tó sọ nínú àdúrà tó gbà sí Jèhófà rèé: “[Ǹjẹ́] kí ojú rẹ . . . là sí ilé yìí tọ̀sán-tòru, sí ibi tí o sọ pé, ‘Orúkọ mi yóò wà níbẹ̀,’ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà síhà ibí yìí.” (1 Ọba 8:6, 29) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì lè gbàdúrà síhà ilé tá a fi orúkọ Ọlọ́run pè yìí.—1 Ọba 8:30, 41-43, 60.
9 Kí ni bí Sólómọ́nì ṣe gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ yọrí sí? Lẹ́yìn tí wọ́n parí ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì náà, àwọn èèyàn náà “ń yọ̀, wọ́n sì ń ṣàríyá nínú ọkàn-àyà wọn lórí gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti fún Ísírẹ́lì.” (1 Ọba 8:65, 66) Kódà, ní ogójì ọdún tí Sólómọ́nì fi ṣàkóso, àwọn èèyàn gbádùn àlàáfíà àti aásìkí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Ka 1 Àwọn Ọba 4:20, 21, 25.) Sáàmù Kejìléláàádọ́rin [72] ṣàlàyé èyí, ó sì tún jẹ́ ká lóye tó jinlẹ̀ nípa àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù náà, Jésù Kristi.—Sm. 72:6-8, 16.
Ẹ̀kọ́ Ni Àṣìṣe Sólómọ́nì Jẹ́ fún Wa
10. Àṣìṣe tí Sólómọ́nì ṣe wo ló máa ń tètè wá síni lọ́kàn?
10 Àmọ́, kí nìdí tá a fi lè sọ pé Sólómọ́nì tún jẹ́ àpẹẹrẹ búburú ní ti ọ̀nà tó gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó o kọ́kọ́ ronú nípa àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè àtàwọn wáhàrì rẹ̀. A kà pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń darúgbó lọ pé àwọn aya rẹ̀ alára ti tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà.” (1 Ọba 11:1-6) Ó dájú pé o kò ní fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú tí Sólómọ́nì fi lélẹ̀ yìí. Àmọ́, ṣé ọ̀nà kan ṣoṣo tí Sólómọ́nì gbà jẹ́ àpẹẹrẹ búburú fún wa nìyẹn? Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn nípa ìgbésí ayé rẹ̀ tó rọrùn láti gbójú fò dá, ká sì rí bá a ṣe lè fi wọ́n ṣe àríkọ́gbọ́n.
11. Kí la lè sọ nípa ìyàwó tí Sólómọ́nì kọ́kọ́ fẹ́?
11 Sólómọ́nì ṣàkóso fún ogójì [40] ọdún. (2 Kíró. 9:30) Torí náà, kí lo lè sọ nípa àkọsílẹ̀ inú 1 Àwọn Ọba 14:21? (Kà á.) Bí ẹsẹ yẹn ṣe sọ, lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kú, Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì [41] nígbà tó di ọba, “Náámà ọmọbìnrin Ámónì” sì ni ìyá rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé kí Sólómọ́nì tó di ọba ló ti fẹ́ obìnrin ilẹ̀ òkèèrè kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jagun tí wọ́n sì ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké. (Oníd. 10:6; 2 Sám. 10:6) Ṣé obìnrin náà jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké yẹn? Ká tiẹ̀ sọ pé ó ti jọ́sìn wọn nígbà kan rí, ó ṣeé ṣe kó ti fi àwọn ọlọ́run èké sílẹ̀ kó sì ti di olùjọsìn tòótọ́, bíi ti Ráhábù àti Rúùtù. (Rúùtù 1:16; 4:13-17; Mát. 1:5, 6) Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Sólómọ́nì ní àwọn àna àtàwọn ìbátan tí wọ́n jẹ́ ará Ámónì tí wọn kì í sì í ṣe olùjọsìn Jèhófà.
12, 13. Ìpinnu tí kò dára wo ni Sólómọ́nì ṣe nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, kí ló sì ṣeé ṣe kó jẹ́ èrò rẹ̀?
12 Àwọn nǹkan tún wá burú sí i lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba. Ó “bá Fáráò ọba Íjíbítì dána, ó sì mú ọmọbìnrin Fáráò, ó sì mú un wá sí Ìlú Ńlá Dáfídì.” (1 Ọba 3:1) Ṣé obìnrin ará Íjíbítì yìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Rúùtù nípa títẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́? Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, nígbà tó yá, Sólómọ́nì kọ́ ilé fún un lẹ́yìn òde Ìlú Dáfídì, ó sì ṣeé ṣe kó kọ́lé fáwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ tí wọ́n bá a wá láti Íjíbítì náà. Kí nìdí tó fi kọ́lé wọn sẹ́yìn òde ìlú? Ìwé Mímọ́ sọ pé ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kò bójú mu pé kí ẹni tó ń jọ́sìn ọlọ́run èké máa gbé nítòsí àpótí májẹ̀mú.—2 Kíró. 8:11.
13 Ó ṣeé ṣe kí Sólómọ́nì rò pé bóun ṣe fẹ́ ọmọbìnrin ọba Íjíbítì yẹn máa jẹ́ kí òun túbọ̀ rọ́wọ́ mú bí ọ̀ràn ìṣèlú bá da òun àti orílẹ̀-èdè Íjíbítì pọ̀. Síbẹ̀, ṣó lè torí ìyẹn sọ pé ohun tóun ṣe tọ̀nà? Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn ni Ọlọ́run ti sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ará Kénáánì abọ̀rìṣà, ó tiẹ̀ fún wọn ní orúkọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò gbọ́dọ̀ bá da nǹkan pọ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì. (Ẹ́kís. 34:11-16) Àbí Sólómọ́nì rò pé òun lè fẹ́ ará Íjíbítì torí pé wọn kò sí lára orílẹ̀-èdè tí Jèhófà dárúkọ? Bó bá tiẹ̀ jẹ́ ohun tó rò nìyẹn, ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ tọ̀nà? Ó dájú pé ohun tó ṣe yẹn fi hàn pé kò bìkítà nípa ewu tí Jèhófà sọ pé ó lè jẹ́ àbájáde ohun tó ṣe. Ewu náà sì ni pé wọ́n lè mú kí ọmọ Ísírẹ́lì kan fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ kó sì máa bọ̀rìṣà.—Ka Diutarónómì 7:1-4.
14. Báwo ni àṣìṣe Sólómọ́nì ṣe lè jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún wa?
14 Ṣé a máa fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sólómọ́nì ṣe àríkọ́gbọ́n? Arábìnrin kan lè máa rò pé kò burú bóun bá ṣe ohun tó lòdì sí ìtọ́ni Ọlọ́run pé kí òun ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Irú èrò yìí lè mú kí ẹnì kan máa kópa nínú àwọn eré ìdárayá lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ tàbí kó wẹgbẹ́ tí wọ́n máa ń dá sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́, ó lè mú kí ẹnì kan má máa san iye owó orí tó yẹ kó san lórí owó tó ń wọlé fún un, tàbí kó máa purọ́ bí wọ́n bá ní kó ṣàlàyé ohun kan tó lè dójú tini tó hù níwà. Kókó inú ọ̀rọ̀ náà ni pé èrò tí kò tọ́ ló mú kí Sólómọ́nì ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, àwa pẹ̀lú sì lè kó sínú irú ewu bẹ́ẹ̀.
15. Báwo ni Jèhófà ṣe fi àánú hàn nínú ọ̀nà tó gbà bá Sólómọ́nì lò, àmọ́ kí ló yẹ́ ká rántí nípa ìyẹn?
15 Ó gba àfiyèsí pé lẹ́yìn tí Bíbélì ti mẹ́nu kàn án pé Sólómọ́nì fẹ́ ọmọ ọba ilẹ̀ òkèèrè yẹn, ó wá ṣàlàyé pé Ọlọ́run fún un ní ọgbọ́n tó béèrè fún, Ó sì tún fún un ní ọrọ̀. (1 Ọba 3:10-13) Sólómọ́nì kò tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run, síbẹ̀ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà yára kọ̀ ọ́ lọ́ba tàbí pé ó fún un ní ìbáwí líle koko. Ìyẹn ṣe rẹ́gí pẹ̀lú òtítọ́ náà pé Ọlọ́run mọ̀ pé ẹ̀dá aláìpé tí a fi erùpẹ̀ mọ ni wá. (Sm. 103:10, 13, 14) Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé ìwà tá a bá ń hù lè nípa lórí wa nísinsìnyí tàbí lọ́jọ́ iwájú.
Ìyàwó Rẹpẹtẹ!
16. Òfin wo ni Sólómọ́nì ṣàìgbọràn sí nígbà tó fẹ́ ìyàwó rẹpẹtẹ?
16 Nínú orin tí Sólómọ́nì Ọba kọ, ó sọ nípa wúńdíá kan tó nífẹ̀ẹ́ sí, ó ní ó rẹwà ju ọgọ́ta [60] ọbabìnrin àti ọgọ́rin [80] wáhàrì lọ. (Orin Sól. 6:1, 8-10) Bó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì ni ibí yìí ń tọ́ka sí, a jẹ́ pé lákòókò yẹn ó ti kó obìnrin rẹpẹtẹ jọ. Kódà bí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn tàbí gbogbo wọn bá tiẹ̀ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà, ìtọ́ni Ọlọ́run nípasẹ̀ Mósè ni pé ọba èyíkéyìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì kò “gbọ́dọ̀ sọ aya di púpọ̀ fún ara rẹ̀, kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa yà kúrò.” (Diu. 17:17) Síbẹ̀ náà, Jèhófà kò kọ Sólómọ́nì sílẹ̀. Kódà, Ọlọ́run ṣì bù kún Sólómọ́nì, ó sì lò ó láti kọ ìwé Orin Sólómọ́nì tó wà nínú Bíbélì.
17. Ohun pàtàkì wo ni a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé?
17 Ṣé èyí wá fi hàn pé Sólómọ́nì lè ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run síbẹ̀ kó má jìyà ohun tó ṣe tàbí pé àwa náà lè ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ká sì mú un jẹ? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi hàn pé sùúrù Ọlọ́run lè máa bá a nìṣó títí di àkókò kan. Síbẹ̀, ti pé ọ̀kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run lè ṣàìgbọràn sí ìtọ́ni rẹ̀ kí ohun búburú kankan má sì ṣẹlẹ̀ sí i lójú ẹsẹ̀ kò túmọ̀ sí pé kò ní jìyà ohun tó ṣe bó bá yá. Rántí ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ pé: “Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.” Ó fi kún un pé: “Èmi mọ̀ pẹ̀lú pé yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.”—Oníw. 8:11, 12.
18. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sólómọ́nì ṣe jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ohun tó wà nínú Gálátíà 6:7?
18 Ẹ wo bí ì bá ṣe dára tó ká sọ pé Sólómọ́nì tẹ̀ lé òótọ́ pọ́ńbélé tí Bíbélì sọ yìí! Òótọ́ ni pé ó ti ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere, ó sì ti gbádùn ìbùkún Ọlọ́run fún àkókò gígùn. Àmọ́, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ti orí àṣìṣe kan bọ́ sórí àṣìṣe mìíràn. Bó ṣe di pé ìwà tí kò dára mọ́ ọn lára nìyẹn. Ẹ sì wo bí ohun tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́yìn náà ṣe wá já sí òtítọ́! Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gál. 6:7) Nígbà tó yá, Sólómọ́nì jìyà ìwà àìgbọ́ràn tó hù. A kà pé: “Sólómọ́nì Ọba alára sì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya ilẹ̀ òkèèrè, pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Fáráò, ọmọ Móábù, ọmọ Ámónì, ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì àti àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hétì.” (1 Ọba 11:1) Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára àwọn aya ilẹ̀ òkèèrè náà ṣì máa sin ọlọ́run èké, kò sì sí bí Sólómọ́nì ò ṣe ní bá wọn lọ́wọ́ sí i. Ó fi Jèhófà sílẹ̀ ó sì pàdánù ojú rere Ọlọ́run wa tó jẹ́ onísùúrù.—Ka 1 Àwọn Ọba 11:4-8.
Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Ohun Rere àti Ohun Búburú Tó Ṣe
19. Kí nìdí tó o fi lè sọ pé ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ rere wà nínú Bíbélì?
19 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, torí náà ó mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Àpẹẹrẹ rere àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó ta yọ wà lára gbogbo ohun tí a ti kọ yẹn. Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Kí ni kí n tún wí? Nítorí àkókò kì yóò tó fún mi bí mo bá ń bá a lọ láti ṣèròyìn nípa Gídíónì, Bárákì, Sámúsìnì, Jẹ́fútà, Dáfídì, àti Sámúẹ́lì àti àwọn wòlíì yòókù, àwọn tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba nínú ìforígbárí, wọ́n ṣiṣẹ́ òdodo yọrí, wọ́n rí àwọn ìlérí gbà, . . . láti ipò àìlera, a sọ wọ́n di alágbára.” (Héb. 11:32-34) A lè jàǹfààní látinú àwọn àpẹẹrẹ rere tó wà nínú Ìwé Mímọ́, ká máa tẹ̀ lé àwọn àpẹẹrẹ àtàtà náà tàbí kí wọ́n jẹ́ àwòkọ́ṣe fún wa, ohun tó sì yẹ ká ṣe gan-an nìyẹn.
20, 21. Kí nìdí tí wàá fi fẹ́ láti máa fi àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe àríkọ́gbọ́n?
20 Àmọ́, Bíbélì sọ nípa àwọn kan tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àṣìṣe tí wọ́n ṣe. A lè kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti sin Jèhófà rí tí wọ́n sì rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Bá a ṣe ń ka Bíbélì, a lè máa kíyè sí ohun tí kò tọ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run kan ṣe àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe bẹ́ẹ̀ káwa náà má bàa ṣe irú àṣìṣe yẹn. A lè fi òye mọ̀ pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ làwọn kan lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tí kò dáa tàbí tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò tọ́, kó tó wá di pé ó yọrí sí ibi tí kò dáa. Báwo la ṣe lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn? A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ tá a bá ń bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ló mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hu irú ìwà bẹ́ẹ̀? Ṣé èmi náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í hu irú ìwà bẹ́ẹ̀? Kí ni mo lè ṣe tí mi ò fi ní hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, àmọ́ tí màá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ṣe àríkọ́gbọ́n?’
21 Ó ṣe pàtàkì pé ká fọwọ́ gidi mú àwọn àpẹẹrẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, torí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.”—1 Kọ́r. 10:11.
Kí Lo Rí Kọ́?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àpẹẹrẹ rere àti àpẹẹrẹ búburú wà nínú Bíbélì?
• Báwo ni Sólómọ́nì ṣe jẹ́ kí ìwà tí kò dára mọ́ òun lára?
• Kí lo lè rí kọ́ látinú àwọn àṣìṣe Sólómọ́nì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Sólómọ́nì lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ṣé ò ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àṣìṣe Sólómọ́nì?