Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Ní Àárẹ̀ Ọpọlọ Lọ́wọ́
BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo,ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—ÒWE 17:17.
Ohun Tó Túmọ̀ Sí
Ó máa ń dùn wá gan-an tí èèyàn wa kan bá ní àárẹ̀ ọpọlọ, a sì lè má mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Àmọ́, àwọn ohun kan wà tá a lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ kó lè fara da ìṣòro náà. Kí làwọn nǹkan náà?
Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
“Yára láti gbọ́rọ̀”—JÉMÍÌSÌ 1:19.
Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà ran èèyàn ẹ lọ́wọ́ ni pé kó o tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀. Má ṣe rò pé gbogbo ohun tó bá sọ lo gbọ́dọ̀ fèsì ẹ̀. Jẹ́ kó mọ̀ pé ò ń fọkàn bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ àti pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣe pàtàkì sí ẹ. Máa ronú nípa bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, má sì dá a lẹ́bi. Fi sọ́kàn pé ohun tó ń ṣe é lè mú kó sọ̀rọ̀ tí kò yẹ, kó sì wá dùn ún tó bá yá.—Jóòbù 6:2, 3.
“Máa sọ̀rọ̀ ìtùnú.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:14.
Ọkàn ọ̀rẹ́ ẹ lè má balẹ̀, ó sì lè gbà pé òun ò wúlò rárá. Tó ò bá tiẹ̀ mọ ohun tó o lè sọ, tó o bá jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an sí ẹ, ìyẹn máa tù ú nínú, ó sì máa fún un lókun.
“Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.”—ÒWE 17:17.
Ṣe ohun tó máa ràn án lọ́wọ́. Dípò tí wàá fi gbà pé o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe láti ràn án lọ́wọ́, ńṣe ni kó o béèrè ohun tó fẹ́. Tí kò bá rọrùn fún un láti sọ ohun tó fẹ́, o lè dábàá ohun kan tẹ́ ẹ lè jọ ṣe pa pọ̀, bóyá kẹ́ ẹ jọ ṣeré jáde. O sì lè bá a ra nǹkan lọ́jà, kó o bá a tún ilé ṣe tàbí kó o bá a ṣe àwọn nǹkan míì.—Gálátíà 6:2.
“Máa mú sùúrù.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:14.
Àwọn ìgbà míì wà tó lè má rọrùn fún ọ̀rẹ́ ẹ láti sọ̀rọ̀. Jẹ́ kó mọ̀ pé inú ẹ máa dùn láti tẹ́tí sí i tó bá ti ṣe tán láti sọ̀rọ̀. Torí ohun tó ń ṣe é, ó lè sọ̀rọ̀ tàbí kó ṣe ohun tó máa dùn ẹ́. Ó lè ṣàdédé sọ pé òun ò ṣe ohun tẹ́ ẹ ti jọ sọ pé ẹ fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀ tàbí kó kàn máa kanra. Má torí ìyẹn sọ pé o ò ní ràn án lọ́wọ́ mọ́, ńṣe ni kó o ṣe sùúrù, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ yé ẹ.—Òwe 18:24.
Ìrànlọ́wọ́ Ẹ Ṣe Pàtàkì
“Mo jẹ́ kí ọ̀rẹ́ mi mọ̀ pé mo wà fún un lọ́jọ́kọ́jọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè yanjú àwọn ìṣòro ẹ̀, mo máa ń tẹ́tí sí i tó bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé gbogbo ohun tó fẹ́ ò ju pé kó rẹ́ni sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún, ìyẹn máa ń jẹ́ kára tù ú.”—Farrah,a tí ọ̀rẹ́ ẹ̀ níṣòro àníyàn àṣejù àti ìdààmú ọkàn tí kì í jẹ́ kó wù ú láti jẹun.
“Mo lọ́rẹ̀ẹ́ kan tó lójú àánú tó sì máa ń fún mi níṣìírí. Ó ní kí n wá sílé òun ká lè jọ jẹun. Torí bó ṣe fìfẹ́ hàn sí mi, mo túra ká, mo sì sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún un. Ìyẹn jẹ́ kára tù mí gan-an!”—Ha-eun, tó níṣòro ìdààmú ọkàn tó lágbára.
“Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa mú sùúrù fáwọn tó ní àárẹ̀ ọpọlọ. Tí ìyàwó mi bá ṣohun tó dùn mí, mo máa ń rán ara mi létí pé irú ẹni tó jẹ́ kọ́ nìyẹn, ohun tó ń ṣe é ló fà á. Ìyẹn ni kì í jẹ́ kí n bínú, tó sì máa ń jẹ́ kí n ṣe é jẹ́jẹ́.”—Jacob, tí ìyàwó ẹ̀ níṣòro ìdààmú ọkàn tó lágbára.
“Ìyàwó mi máa ń dúró tì mí gan-an, ó sì máa ń tù mí nínú. Tí àníyàn bá gbà mí lọ́kàn, tí ò sì jẹ́ kí n ṣe àwọn nǹkan tó yẹ, ìyàwó mi kì í fipá mú mi ṣe ohun tí mi ò fẹ́. Láwọn ìgbà míì sì rèé, ìṣòro tí mo ní yìí kì í jẹ́ kíyàwó mi lè ṣe àwọn nǹkan tó fẹ́ràn láti máa ṣe. Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an torí pé ó lawọ́, kò sì mọ tara ẹ̀ nìkan.”—Enrico, tó níṣòro àníyàn àṣejù.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.