Monday, July 29
Ó rí i tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀.—Mát. 3:16.
Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ ká sọ pé o wà níbi tí Jésù ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an bí Jésù ṣe ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ láìwo ìwé rárá! Ìgbà tí Jésù ṣèrìbọmi, tí Jèhófà sì fẹ̀mí mímọ́ yàn án ni Jèhófà jẹ́ kó rántí àwọn nǹkan tó ti kọ́ lọ́run kó tó wá sáyé. Kódà, inú Ìwé Mímọ́ ni Jésù ti fa ọ̀rọ̀ tó sọ yọ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi àtàwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kẹ́yìn kó tó kú. (Diu. 8:3; Sm. 31:5; Lúùkù 4:4; 23:46) Yàtọ̀ síyẹn, ní gbogbo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi wàásù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ka Ìwé Mímọ́, tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹ̀, tó sì ṣàlàyé ẹ̀ ní gbangba. (Mát. 5:17, 18, 21, 22, 27, 28; Lúùkù 4:16-20) Ọ̀pọ̀ ọdún kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló ti máa ń ka Ìwé Mímọ́, tó sì máa ń gbọ́ báwọn míì ṣe ń kà á. Ó dájú pé á máa gbọ́ bí Màríà àti Jósẹ́fù ṣe ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nínú ilé. (Diu. 6:6, 7) Gbogbo ọjọ́ Sábáàtì ni Jésù àti ìdílé ẹ̀ máa ń lọ sínú sínágọ́gù. (Lúùkù 4:16) Kò sí àní-àní pé Jésù máa ń tẹ́tí sílẹ̀ gan-an bí wọ́n ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá débẹ̀. w23.02 8 ¶1-2
Tuesday, July 30
Kí o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Máàkù 12:30.
Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, o ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni “orísun ìyè” àti pé òun ló fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Sm. 36:9; Jém. 1:17) Torí náà, Ọlọ́run ló fún ẹ ní gbogbo ohun rere tó ò ń gbádùn torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Ìràpadà ni ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa, ó sì ṣeyebíye. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó. Jésù sọ pé: ‘Baba nífẹ̀ẹ́ mi,’ ‘mo sì nífẹ̀ẹ́ Baba.’ (Jòh. 10:17; 14:31) Àtìgbà tí wọ́n ti jọ wà pa pọ̀ fún àìmọye ọdún ni ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ti ń lágbára sí i. (Òwe 8:22, 23, 30) Ẹ wo bó ṣe máa dun Ọlọ́run tó nígbà tó gbà kí wọ́n fìyà jẹ Ọmọ ẹ̀, tó sì kú. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ aráyé títí kan ìwọ náà. Ìdí nìyẹn tó ṣe fi Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ, kí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì lè wà láàyè títí láé. (Jòh. 3:16; Gál. 2:20) Kò sí ìdí míì tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. w23.03 4-5 ¶11-13
Wednesday, July 31
Ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin.—Ìfi. 2:25.
A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Jésù bá àwọn kan ní Págámù wí torí pé wọ́n ń fa ìyapa nínú ìjọ. (Ìfi. 2:14-16) Ó gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà torí wọ́n ti yẹra fún “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì,” ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘di òtítọ́ mú ṣinṣin.’ (Ìfi. 2:24-26) Torí náà, ó yẹ káwọn Kristẹni tó ti gba ẹ̀kọ́ èké ronú pìwà dà. Kí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe lónìí? A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó lòdì sí èrò Jèhófà. Àwọn apẹ̀yìndà lè “jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,” àmọ́ ‘ìṣe wọn ò fi agbára Ọlọ́run hàn.’ (2 Tím. 3:5) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó máa rọrùn fún wa láti mọ ẹ̀kọ́ èké, ká sì ta kò ó. (2 Tím. 3:14-17; Júùdù 3, 4) A gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Tá a bá ti ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ó yẹ ká ṣàtúnṣe ká lè rí ojúure ẹ̀.—Ìfi. 2:5, 16; 3:3, 16. w22.05 4 ¶9; 5 ¶11