Tuesday, July 30
Kí o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.—Máàkù 12:30.
Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, o ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni “orísun ìyè” àti pé òun ló fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Sm. 36:9; Jém. 1:17) Torí náà, Ọlọ́run ló fún ẹ ní gbogbo ohun rere tó ò ń gbádùn torí pé ọ̀làwọ́ ni, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. Ìràpadà ni ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa, ó sì ṣeyebíye. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó. Jésù sọ pé: ‘Baba nífẹ̀ẹ́ mi,’ ‘mo sì nífẹ̀ẹ́ Baba.’ (Jòh. 10:17; 14:31) Àtìgbà tí wọ́n ti jọ wà pa pọ̀ fún àìmọye ọdún ni ìfẹ́ tó wà láàárín wọn ti ń lágbára sí i. (Òwe 8:22, 23, 30) Ẹ wo bó ṣe máa dun Ọlọ́run tó nígbà tó gbà kí wọ́n fìyà jẹ Ọmọ ẹ̀, tó sì kú. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ aráyé títí kan ìwọ náà. Ìdí nìyẹn tó ṣe fi Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ, kí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì lè wà láàyè títí láé. (Jòh. 3:16; Gál. 2:20) Kò sí ìdí míì tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. w23.03 4-5 ¶11-13
Wednesday, July 31
Ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin.—Ìfi. 2:25.
A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Jésù bá àwọn kan ní Págámù wí torí pé wọ́n ń fa ìyapa nínú ìjọ. (Ìfi. 2:14-16) Ó gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà torí wọ́n ti yẹra fún “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì,” ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘di òtítọ́ mú ṣinṣin.’ (Ìfi. 2:24-26) Torí náà, ó yẹ káwọn Kristẹni tó ti gba ẹ̀kọ́ èké ronú pìwà dà. Kí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe lónìí? A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó lòdì sí èrò Jèhófà. Àwọn apẹ̀yìndà lè “jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,” àmọ́ ‘ìṣe wọn ò fi agbára Ọlọ́run hàn.’ (2 Tím. 3:5) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó máa rọrùn fún wa láti mọ ẹ̀kọ́ èké, ká sì ta kò ó. (2 Tím. 3:14-17; Júùdù 3, 4) A gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Tá a bá ti ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ó yẹ ká ṣàtúnṣe ká lè rí ojúure ẹ̀.—Ìfi. 2:5, 16; 3:3, 16. w22.05 4 ¶9; 5 ¶11
Thursday, August 1
Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà àti àwọn tó ń ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.—Mál. 3:16.
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí orúkọ rẹ̀, tó sì wá ń kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìrántí” rẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Ohun tó wu Jèhófà ni pé káwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gbádùn ayé wọn títí láé nínú ayé tuntun. Àwọn ọ̀rọ̀ tá a bá ń sọ ló máa fi hàn bóyá Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. (Jém. 1:26) Àwọn kan tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń fìbínú sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ gúnni lára, wọ́n sì máa ń fọ́nnu. (2 Tím. 3:1-5) A ò ní fẹ́ fìwà jọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kó máa wù wá láti máa sọ ohun tó máa múnú Jèhófà dùn. Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó tuni lára nípàdé àti lóde ẹ̀rí àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sáwọn tó wà nínú ìdílé wa?—1 Pét. 3:7. w22.04 5 ¶4-5