Sáàmù
Sí olùdarí; ti Jédútúnì.*+ Orin Dáfídì.
Màá fi ìbonu bo ẹnu mi+
Ní gbogbo ìgbà tí ẹni burúkú bá wà níwájú mi.”
2 Mi ò lè sọ̀rọ̀, ṣe ni mo dákẹ́;+
Mi ò sọ nǹkan kan, kódà nípa ohun rere,
Síbẹ̀, ìrora mi le kọjá sísọ.*
3 Ọkàn mi rọra ń jó* nínú mi bí iná.
Bí mo ṣe ń ronú* ni iná náà ń jó.
Ahọ́n mi wá sọ pé:
4 “Jèhófà, jẹ́ kí n mọ ohun tó máa gbẹ̀yìn mi
Àti bí ọjọ́ ayé mi ṣe máa gùn tó,+
Kí n lè mọ bí ẹ̀mí mi ṣe kúrú tó.*
Ní ti ọmọ èèyàn, bó tilẹ̀ dà bíi pé kò sí nínú ewu, bí èémí lásán ló rí.+ (Sélà)
6 Dájúdájú, bí òjìji ni ọmọ èèyàn ń rìn kiri.
Ó ń sáré kiri* lórí òfo.
Ó ń kó ọrọ̀ jọ pelemọ láìmọ ẹni tó máa gbádùn rẹ̀.+
7 Kí wá ni kí n máa retí, Jèhófà?
Ìwọ nìkan ni ìrètí mi.
8 Yọ mí nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.+
Má ṣe jẹ́ kí àwọn òmùgọ̀ sọ mí di ẹni ẹ̀gàn.
10 Mú ìyọnu rẹ kúrò lórí mi.
Àárẹ̀ mú mi nítorí ọwọ́ rẹ ti gbá mi.
11 O fi ìyà tọ́ èèyàn sọ́nà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;+
O run nǹkan tó kà sí iyebíye bí ìgbà tí òólá* bá jẹ nǹkan.
Dájúdájú, èémí lásán ni ọmọ èèyàn.+ (Sélà)
12 Gbọ́ àdúrà mi, Jèhófà,
Fetí sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+
Má ṣe gbójú fo omijé mi.
13 Má ṣe wò mí nínú ìbínú rẹ, kí n lè túra ká
Kí n tó kọjá lọ tí mi ò sì ní sí mọ́.”