Sáàmù
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tó sá nítorí Sọ́ọ̀lù, tó sì lọ sínú ihò àpáta.+
57 Ṣojú rere sí mi, Ọlọ́run, ṣojú rere sí mi,
Nítorí ìwọ ni mo* fi ṣe ibi ààbò,+
Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ sì ni mo sá sí títí wàhálà fi kọjá lọ.+
2 Mo ké pe Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ,
Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó bá mi pa wọ́n rẹ́.
3 Yóò pèsè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀run, yóò sì gbà mí là.+
Yóò mú kí ìsapá ẹni tó ń kù gìrì mọ́ mi já sí asán. (Sélà)
Ọlọ́run yóò fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ ránṣẹ́.+
Àárín àwọn tó fẹ́ fà mí ya ni mo dùbúlẹ̀ sí,
Àwọn tí eyín wọn jẹ́ ọ̀kọ̀ àti ọfà,
Tí ahọ́n wọn sì jẹ́ idà mímú.+
5 Kí a gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;
Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+
Wọ́n ti gbẹ́ kòtò dè mí,
Àmọ́ àwọn fúnra wọn kó sínú rẹ̀.+ (Sélà)
7 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run,+
Ọkàn mi dúró ṣinṣin.
Màá kọrin, màá sì lo ohun ìkọrin.
8 Jí, ìwọ ògo mi.
Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.
Màá jí ní kùtùkùtù.+
10 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+
Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà.
11 Kí a gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;
Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+