Sáàmù
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rán àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ máa ṣọ́ ilé Dáfídì* kí ó lè pa á.+
2 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń hùwà burúkú,
Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.*
Àwọn alágbára gbéjà kò mí
Àmọ́ Jèhófà, kì í ṣe torí pé mo ṣọ̀tẹ̀ tàbí pé mo dẹ́ṣẹ̀.+
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣe ohun tí kò dáa, wọ́n sáré múra sílẹ̀ láti bá mi jà.
Dìde nígbà tí mo bá pè, kí o sì wò mí.
5 Nítorí ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
Jí láti yí àfiyèsí rẹ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.
Wọ́n ń kùn* bí ajá,+ wọ́n sì ń dọdẹ kiri ìlú.+
10 Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi yóò ràn mí lọ́wọ́;+
Ọlọ́run yóò mú kí n rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.+
11 Má pa wọ́n, kí àwọn èèyàn mi má bàa gbàgbé.
Fi agbára rẹ mú kí wọ́n máa rìn gbéregbère;
Mú kí wọ́n ṣubú, ìwọ Jèhófà, apata wa.+
12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lẹ́nu wọn àti ọ̀rọ̀ ètè wọn,
Kí ìgbéraga wọn dẹkùn mú wọn,+
Nítorí ègún àti ẹ̀tàn tí wọ́n ń sọ lẹ́nu.
13 Yanjú wọn nínú ìbínú rẹ;+
Yanjú wọn, kí wọ́n má bàa sí mọ́;
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ń ṣàkóso ní Jékọ́bù títí dé gbogbo ìkángun ayé.+ (Sélà)
15 Jẹ́ kí wọ́n máa wá ohun tí wọ́n á jẹ kiri;+
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yó tàbí kí wọ́n rí ibi sùn.
16 Àmọ́ ní tèmi, màá kọrin nípa okun rẹ;+
Ní àárọ̀, màá fi ìdùnnú sọ nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.