Sí olùdarí. Ti Dáfídì, kí ó jẹ́ ìránnilétí.
70 Ọlọ́run, gbà mí;
Jèhófà, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+
2 Kí ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ bá
Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi.
Kí àwọn tí inú wọn ń dùn sí àjálù tó bá mi
Sá pa dà nínú ẹ̀tẹ́.
3 Kí àwọn tó ń sọ pé: “Àháà! Àháà!”
Fi ìtìjú sá pa dà.
4 Àmọ́ kí àwọn tó ń wá ọ
Máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ.+
Kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ máa sọ nígbà gbogbo pé:
“Ẹ gbé Ọlọ́run ga!”
5 Àmọ́, aláìní ni mí, mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́;+
Ọlọ́run, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùgbàlà mi;+
Jèhófà, má ṣe jẹ́ kó pẹ́.+