Orin Ásáfù.+
82 Ọlọ́run dúró sí àyè rẹ̀ nínú àpéjọ ọ̀run;+
Ó ń ṣe ìdájọ́ ní àárín àwọn ọlọ́run+ pé:
2 “Títí dìgbà wo ni ẹ ó máa fi àìṣòdodo dá ẹjọ́,+
Tí ẹ ó sì máa ṣe ojúsàájú àwọn ẹni burúkú?+ (Sélà)
3 Ẹ gbèjà aláìní àti ọmọ aláìníbaba.+
Ẹ dá ẹjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ àti òtòṣì bó ṣe tọ́.+
4 Ẹ gba aláìní àti tálákà sílẹ̀;
Ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.”
5 Wọn ò mọ̀, kò sì yé wọn;+
Wọ́n ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
Gbogbo ìpìlẹ̀ ayé ń mì tìtì.+
6 “Mo sọ pé, ‘ọlọ́run ni yín,+
Gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.
7 Àmọ́, ẹ̀yin yóò kú bí àwọn èèyàn ṣe ń kú;+
Ẹ ó sì ṣubú bí àwọn olórí ṣe ń ṣubú!’”+
8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,+
Nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ́ tìrẹ.