Sáàmù
93 Jèhófà ti di Ọba!+
Ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí aṣọ;
Jèhófà gbé agbára wọ̀;
Ó fi di ara rẹ̀ bí àmùrè.
3 Àwọn odò ru sókè, Jèhófà,
Àwọn odò ru sókè, wọ́n sì pariwo;
Àwọn odò ń ru sókè, wọ́n ń ru gùdù.
4 Jèhófà jẹ́ ọlọ́lá ńlá ní ibi gíga,+
Lórí ìró omi púpọ̀,
Agbára rẹ̀ ju ti ìgbì òkun tó ń ru gùdù lọ.+
5 Àwọn ìránnilétí rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá.+