Sáàmù
Orin Ìgòkè.
132 Jèhófà, jọ̀wọ́ rántí Dáfídì
Àti gbogbo ìyà tó jẹ;+
2 Bó ṣe búra fún Jèhófà,
Bó ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Alágbára Jékọ́bù pé:+
3 “Mi ò ní wọnú àgọ́ mi, àní ilé mi.+
Mi ò ní dùbúlẹ̀ lórí àga tìmùtìmù mi, àní ibùsùn mi;
4 Mi ò ní jẹ́ kí oorun kun ojú mi,
Mi ò sì ní jẹ́ kí ìpéǹpéjú mi tòògbé
5 Títí màá fi rí àyè kan fún Jèhófà,
9 Kí àwọn àlùfáà rẹ gbé òdodo wọ̀,
Kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sì máa kígbe ayọ̀.
11 Jèhófà ti búra fún Dáfídì,
Ó dájú pé kò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé:
12 Tí àwọn ọmọ rẹ bá pa májẹ̀mú mi mọ́
Àti àwọn ìránnilétí mi tí mo kọ́ wọn,+
Àwọn ọmọ tiwọn náà
Yóò jókòó sórí ìtẹ́ rẹ títí láé.”+
14 “Ibi ìsinmi mi títí láé nìyí;
Ibí ni màá máa gbé,+ nítorí ohun tí mo fẹ́ nìyẹn.
15 Màá fi ọ̀pọ̀ oúnjẹ kún ibẹ̀;
Màá fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.+
17 Màá mú kí agbára Dáfídì pọ̀ sí i* níbẹ̀.
Mo ti ṣètò fìtílà fún ẹni àmì òróró mi.+