Fi Awọn Apa Jehofa Wiwa Titilae Ṣe Itilẹhin Rẹ
“Ọlọrun ayeraye ni ibugbe rẹ, ati labẹ rẹ̀ ni awọn apa wiwa titilae wà.”—DEUTARONOMI 33:27, American Standard Version.
1, 2. Eeṣe ti awọn eniyan Jehofa fi le nigbọkanle ninu itilẹhin rẹ̀?
JEHOFA bikita fun awọn eniyan rẹ̀. Fun apẹẹrẹ, lakooko gbogbo ipọnju awọn ọmọ Isirẹli, “o jẹ́ ipọnju fun un”! Nipa ifẹ ati ìyọ́nú, oun “bẹrẹ si fà wọn dide o si gbé wọn.” (Aisaya 63:7-9, NW) Nitori naa bi awa ba jẹ oloootọ si Ọlọrun, a le ni igbọkanle ninu itilẹhin rẹ̀.
2 Wolii Mose wi pe: “Ibi ìlùmọ́ ni Ọlọrun akoko igbaani, ati labẹ rẹ̀ ni awọn apa wiwa pẹtiti wà.” (Deutaronomi 33:27, NW) Itumọ miiran wi pe: “Ọlọrun ayeraye ni ibugbe rẹ, ati labẹ rẹ̀ ni awọn apa wiwa titilae wà. (American Standard Version) Ṣugbọn bawo ni awọn apa Ọlọrun ṣe nti awọn iranṣẹ rẹ̀ lẹhin?
Eeṣe Ti Ọpọlọpọ Inira Fi Wa?
3. Nigba wo ni araye onigbọran yoo gbadun “ominira ologo ti awọn ọmọ Ọlọrun” ni kikun?
3 Ṣiṣiṣẹsin Jehofa ko ṣíji bo wa kuro ninu inira ti o wọpọ fun awọn eniyan alaipe. Joobu iranṣẹ Ọlọrun wi pe: “Eniyan ti a bi ninu obinrin ọlọjọ diẹ ni, o si kun fun ipọnju.” (Joobu 14:1) Niti ọjọ “ọdun wa,” onisaamu naa wi pe: “Agbara wọn làálàá oun ibinujẹ ni.” (Saamu 90:10) Igbesi-aye yoo ri bẹẹ titi di igba ti ‘a ba dá ẹda silẹ lominira kuro ninu isọnidẹru fun idibajẹ ki o si ni ominira ologo ti awọn ọmọ Ọlọrun.’ (Roomu 8:19-22) Iyẹn yoo ṣẹlẹ ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun Kristi. Nigba naa ni awọn eniyan ọmọ abẹ Ijọba naa yoo niriiri idande kuro ninu ẹṣẹ ati iku, lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu. Ni opin Ẹgbẹrundun naa, Kristi ati awọn ajumọjẹ alufaa-ọba rẹ̀ yoo ti ran araye lọwọ lati de ijẹpipe, awọn wọnni ti wọn si jẹ aduroṣinṣin ti Ọlọrun lakooko idanwo ikẹhin lati ọwọ Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ ni a o kọ orukọ wọn sinu “iwe iye” laiṣee yipada mọ́ (Iṣipaya 20:12-15) Nigba naa wọn yoo gbadun ominira ologo ti awọn ọmọ Ọlọrun ni kikun.
4. Dipo rirahun nipa ipo wa ninu igbesi-aye, ki ni awa nilati ṣe?
4 Ki o to di akoko yẹn, dipo rirahun nipa ipo wa ninu igbesi-aye, ẹ jẹ ki a nigbẹkẹle ninu Jehofa. (1 Samuẹli 12:22; Juuda 16) Ẹ jẹ ki a tun kun fun imoore fun Alufaa Agba wa, Jesu, nipasẹ ẹni ti a le sunmọ Ọlọrun “ki a le ri aanu gbà ki a si ri inurere ailẹtọọsi fun iranlọwọ ni akoko ti o tọ́.” (Heberu 4:14-16, NW) Awa ko gbọdọ dabi Adamu lae. Nitootọ, o fẹsun kan Jehofa pe o fun oun ni aya buburu lọna aitọ, ni wiwi pe: “Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, oun ni o fun mi ninu eso igi naa, emi si jẹ.” (Jẹnẹsisi 3:12) Ọlọrun a maa funni ni awọn ohun rere kii sii mu inira wa ba wa. (Matiu 5:45; Jakobu 1:17) Awọn ipọnju saba maa njẹ iyọrisi aini ọgbọn tiwa funraawa tabi aṣiṣe awọn ẹlomiran. Wọn tun le wá ba wa nitori pe a jẹ ẹlẹṣẹ a si ngbe ninu aye kan ti o wà labẹ agbara Satani. (Owe 19:3; 1 Johanu 5:19) Sibẹ, apa wiwa titilae ti Jehofa saba maa nti awọn iranṣẹ rẹ̀ aduroṣinṣin lẹhin ti wọn nfi taduratadura gbarale e ti wọn si nfi imọran Ọrọ rẹ̀ silo funraawọn.—Saamu 37:5; 119:105.
A Fokun Fun Wọn Lakooko Àmódi
5. Iṣiri wo ni awọn alámòódi le ri ni Saamu 41:1-3?
5 Àmódi nfa ipọnju fun ọpọ julọ ninu wa nigba miiran. Sibẹ, Dafidi wi pe: “Alayọ ni ẹnikẹni ti nhuwa pẹlu igbatẹniro siha ọdọ ẹni rirẹlẹ; ni ọjọ ajalu Jehofa yoo pese atiyọ fun un. Jehofa funraarẹ yoo ṣọ ọ yoo sì pa a mọ láàyè. A o pe e ni alayọ ni ilẹ-aye; ki yoo si le ṣeeṣe fun ọ lati fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fun awọn ọta rẹ̀. Jehofa funraarẹ yoo fun un lokun lori akete àmódi; gbogbo ibusun rẹ̀ ni iwọ yoo yipada dajudaju lakooko aisan rẹ̀.”—Saamu 41:1-3, NW.
6, 7. Bawo ni Ọlọrun ṣe ran Dafidi lọwọ nigba ti o wa lori akete aisan, bawo si ni eyi ṣe le fun awọn iranṣẹ Jehofa niṣiiri lonii?
6 Agbatẹniro kan nran awọn alaini lọwọ. “Ọjọ ajalu” le jẹ iṣẹlẹ alajaalu eyikeyii tabi saa inira ọlọjọ pipẹ ti o ńkórẹ̀wẹ̀sì ba ẹnikan. O nigbẹẹkẹle ninu Ọlọrun lati daabobo o lakooko ailera, awọn miiran si ‘pe e ni alayọ ni ilẹ-aye’ nipa titan irohin awọn ibalo alaaanu ti Jehofa pẹlu rẹ̀ kalẹ. Ọlọrun fun Dafidi lokun “lori akete amodi,” boya ni akoko onipakanleke nigba ti Abusalomu ọmọkunrin Dafidi wa ọna lati fipa gba ìtẹ́ Isirẹli.—2 Samuẹli 15:1-6.
7 Niwọn igba ti Dafidi ti fi igbatẹniro han fun awọn ẹni rirẹlẹ, o nimọlara pe Jehofa yoo fun oun lokun nigba ti oun wà lainiranlọwọ lori ibusun aisan kan. (Saamu 18:24-26) Bi o tilẹ jẹ pe o ṣamodi lọna lilewu, o nigbọkanle pe Ọlọrun yoo ‘yi ibusun rẹ pada,’ kii ṣe nipa mimu aisan naa kuro lọna iṣẹ iyanu ṣugbọn nipa fifun un lokun pẹlu awọn ironu atunininu. Yoo dà bii pe Jehofa nyi ibusun rẹ pada kuro ni ti alamoodi si ti ìkọ́fẹpadà. Lọna ti o farajọra, gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun bi a ba njiya lọwọ amodi, apa Jehofa wiwa titilae yoo ti wa lẹhin.
Itunu Fun Awọn Ti A Músoríkọ́
8. Bawo ni Kristẹni kan ti nṣaisan ṣe fi igbarale Ọlọrun rẹ̀ han?
8 Aisan le ṣokunfa irẹwẹsi ero ori. Kristẹni kan ti nṣamodi gidigidi, ti o sì le ṣaini okun ti o pọ tó nigba miiran lati kawe paapaa sọ pe: “Eyi mu ki nniriiri ọpọlọpọ imọlara isorikọ, imọlara aito nǹkankan, ati bibu sẹkun paapaa.” Ni mimọ pe Satani nfẹ lati ba ọkan rẹ jẹ patapata pẹlu ijakulẹ, oun jà pada, ni mimọ pe pẹlu iranlọwọ Jehofa oun ko le kuna. (Jakobu 4:7) Ọkunrin yii jẹ iṣiri fun awọn ẹlomiran ti wọn mọ pe o nigbẹẹkẹle ninu Ọlọrun. (Saamu 29:11) Ani nigba ti a gbe e lọ si ile iwosan paapaa, o ké si awọn alaisan ati awọn miiran lori tẹlifoonu lati gbé wọn ró nipa tẹmi. Oun funraarẹ ni a gbéró nipa fifetisilẹ si awọn ohùn orin Ijọba ati awọn ọrọ-ẹkọ ninu iwe irohin yii ati alabaakẹgbẹ rẹ̀, Ji! ti a gbà sori kasẹẹti, ati nipa kikẹgbẹpọ pẹlu awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀. Arakunrin yii sọ pe: “Mo nba Jehofa sọrọ deedee ninu adura, ni sisọ fun un pe ki o fun mi ni okun, itọsọna, itunu, ati iranlọwọ lati farada a.” Bi iwọ ba jẹ Kristẹni ti nniriiri iṣoro ilera lilekoko, maa nigbẹkẹle ninu Jehofa nigba gbogbo ki o sì fi apa rẹ̀ wiwatitilae ṣe itilẹhin rẹ.
9. Awọn apẹẹrẹ wo ni o fihan pe irẹwẹsi ọpọlọ nigbamiran ńda awọn eniyan oniwa-bi-Ọlọrun láàmú?
9 Isorikọ jẹ iṣoro atayebaye. Nigba ti o wà labẹ idanwo, Joobu sọrọ gẹgẹ bi ọkunrin ti o nimọlara pe Ọlọrun ti kọ oun silẹ. (Joobu 29:2-5) Aniyan lori ipo isọdahoro Jerusalẹmu ati ogiri rẹ̀ mu ki Nehemaya dorikodo, Peteru ni a sì mu sorikọ nipa sisẹ Kristi tobẹẹ gẹẹ ti o fi sunkun kikoro. (Nehemaya 2:1-8; Luuku 22:62) Ẹpafiroditọsi ni a mu sorikọ nitori pe awọn Kristẹni ni Filipi gbọ pe o ti dubulẹ aisan. (Filipi 2:25, 26) Isorikọ mu inira ba awọn Kristẹni melookan ni Tẹsalonika, nitori Pọọlu rọ awọn ara nibẹ lati “sọrọ itunu fun awọn ọkàn ti wọn sorikọ.” (1 Tẹsalonika 5:14, NW) Nitori naa bawo ni Ọlọrun ṣe ran iru awọn ẹnikọọkan bẹẹ lọwọ?
10. Ki ni o le ṣeranlọwọ ninu gbigbiyanju lati koju isorikọ ti ero ori?
10 Ipinnu ti ara ẹni ni a gbọdọ ṣe nipa itọju iṣegun fun isorikọ mimuna.a (Galatia 6:5) Isinmi ti o tó ati igbokegbodo ti o wà deedee le ṣeranlọwọ. Dipo fifoju wo awọn iṣoro melookan gẹgẹ bi ipo iṣoro titobi kan, ẹnikan ti a musorikọ le ri pe o ṣeranlọwọ lati ṣiṣẹ lati yanju wọn lọkọọkan. Iranlọwọ ti ntuni ninu lati ọdọ awọn alagba ijọ le ṣanfaani gan an, ni pataki bi iṣoro ero imọlara yii ba fa aniyan tẹmi. (Jakobu 5:13-15) Leke gbogbo rẹ̀, o ṣe pataki lati gbarale Jehofa, ‘ni kiko gbogbo aniyan wa le e, nitori pe oun bikita fun wa.’ Adura ti a tẹpẹlẹ mọ ti ntọkanwa le mu ‘alaafia Ọlọrun ti yoo ṣọ ọkan-aya ati agbara ero-ori nipasẹ Kristi Jesu’ wá fun ẹnikan.—1 Peteru 5:6-11; Filipi 4:6, 7.
Jehofa Nran Wa Lọwọ Lati Farada Ibanujẹ
11-13. Ki ni o le ṣeranlọwọ lati mu ibanujẹ ọkan nitori iku ololufẹ kan dinku?
11 Iriri ti npọniloju miiran ni iku ololufẹ kan. Aburahamu kedaaro ipadanu aya rẹ̀, Sera. (Jẹnẹsisi 23:2) Nigba ti Abusalomu ọmọkunrin rẹ̀ kú, Dafidi ni irobinujẹ bò mọlẹ. (2 Samuẹli 18:33) Họwu, ani ọkunrin pipe naa Jesu “sọkun” nitori iku ọrẹ rẹ̀ Lasaru! (Johanu 11:35) Nitori naa ibanujẹ maa ńwà nigba ti iku ba mu ololufẹ kan lọ. Ṣugbọn ki ni ohun ti o le ṣeranlọwọ lati mu iru ẹdun ọkan bẹẹ kuro?
12 Ọlọrun nran awọn eniyan rẹ̀ lọwọ lati farada ibanujẹ lílégbákan ti adanu ọ̀fọ̀. Ọrọ rẹ wi pe ajinde yoo wà. Fun idi yii, awa kii “karisọ gan an gẹgẹ bi awọn yooku pẹlu ti nṣe awọn ti wọn ko ni ireti.” (1 Tẹsalonika 4:13, NW; Iṣe 24:15) Ẹmi Jehofa nran wa lọwọ lati ni alaafia ati igbagbọ ati lati ronu jinlẹ lori agbayanu ọjọ ọla ti a ṣeleri ninu Ọrọ rẹ̀, kí ero ibanujẹ nipa ololufẹ kan ti o ti ku ma baa bò wá mọ́lẹ̀ patapata. Itunu tun nwa lati inu kika Iwe mimọ ati gbigbadura si “Ọlọrun itunu gbogbo.”—2 Kọrinti 1:3, 4; Saamu 68:4-6.
13 A le ri itunu lati inu ireti ajinde gẹgẹ bi Joobu oniwa-bi-Ọlọrun ti ṣe, ẹni ti o ké jade pe: “Áà! Iwọ [Jehofa] iba fi mi pamọ ni ipo oku, ki iwọ ki o fi mi pamọ ni ikọkọ, titi ibinu rẹ yoo fi rekọja, iwọ iba lana igba kan silẹ fun mi, ki o si ranti mi! Bi eniyan ba kú yoo si tun yè bi? Gbogbo ọjọ igba ti a la silẹ fun mi ni emi yoo duro de, titi amudọtun mi yoo fi dé. Iwọ iba pè, emi iba sì dá ọ lohun; iwọ o si ni ifẹ si iṣẹ ọwọ rẹ.” (Joobu 14:13-15) Ibanujẹ ńláǹlà ni a kii saba ni nigba ti ọrẹ ọ̀wọ́n kan ba lọ si irin ajo, nitori a nireti lati ri i lẹẹkan sii. Irobinujẹ jijinlẹ tí ipadanu ololufẹ kan lè dásílẹ̀ ni a le dinku lọna kan ṣaa bi a ba foju wo iku Kristẹni olododo kan ni ọna kan naa. Bi oun ba ni ireti ilẹ-aye, oun ni a o ji lati oju orun iku sihin in lori ilẹ-aye nigba Iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun Kristi. (Johanu 5:28, 29; Iṣipaya 20:11-13) Bi a ba nireti lati gbe lori ilẹ-aye titilae, awa le wa nihin in lati ki ololufẹ wa ti a ji dide kaabọ.
14. Bawo ni awọn Kristẹni opó meji ṣe koju iku ọkọ wọn?
14 Lẹhin iku ọkọ rẹ̀, arabinrin kan mọ pe oun nilati maa baa lọ pẹlu awọn igbokegbodo rẹ̀ ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. Yatọ si mimu ki ‘ọpọlọpọ lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa’ mu ọwọ rẹ dí, o ṣe aṣọ ibusun kan ti o ni fọ́nrán ti o tó 800. (1 Kọrinti 15:58) O wi pe, “eyi jẹ idawọle didara kan nitori pe gbogbo igba ti mo ba nṣiṣẹ mo le fetisilẹ si awọn ohùn orin Ijọba ati teepu Bibeli, eyi ti o gba ọkan mi.” O fi tifẹtifẹ ranti ibẹwo kan ti alagba oniriiri kan ati aya rẹ ṣe. Lati inu Bibeli, alagba naa tọka jade pe Ọlọrun bikita fun awọn opó. (Jakobu 1:27) Kristẹni obinrin miiran ko juwọsilẹ fun ikaanu ara-ẹni nigba ti ọkọ rẹ ku. O mọriri itilẹhin awọn ọrẹ o si bẹrẹ sii ni ifẹ ọkan pupọ sii ninu awọn ẹlomiran. O sọ pe, “mo ngbadura lemọlemọ sii mo si mu ipo ibatan timọtimọ dagba pẹlu Jehofa.” Ẹ si wo ibukun ti o jẹ lati ni itilẹhin awọn apa Ọlọrun wiwa titilae!
Iranlọwọ Nigba ti A Ba Ṣàṣìṣe
15. Ki ni koko ti o wa ninu awọn ọrọ Dafidi ni Saamu 19:7-13?
15 Bi o tilẹ jẹ pe a nifẹẹ ofin Jehofa, a maa nṣaṣiṣe nigba miiran. Eyi laiṣiyemeji nba wa ninu jẹ, gẹgẹ bi o ti rí fun Dafidi, ẹni ti awọn ofin, irannileti, aṣẹ, ati ipinnu idajọ Ọlọrun jẹ eyi ti o fa lọkan mọra ju wura lọ. O wi pe: “A ti kilọ fun iranṣẹ rẹ funraarẹ nipasẹ wọn; ninu pipa wọn mọ ni èrè jaburata wà. Awọn aṣiṣe—ta ni o le wòye rẹ̀? Lati inu ẹṣẹ ti o farasin kà mi si alaimọwọmẹsẹ. Lati inu iṣe ìkùgbùù pẹlu fa iranṣẹ rẹ sẹhin; maṣe jẹ ki wọn jẹgàba le mi lori. Ni ọna yẹn emi yoo jẹ pipe, emi yoo si ti wà laimọwọmẹsẹ kuro ninu ọpọjulọ ìrélànà kọja.” (Saamu 19:7-13, NW) Ẹ jẹ ki a ṣàrúnkúnná awọn ọrọ wọnyi.
16. Eeṣe ti a fi gbọdọ yẹra fun ìkùgbùù?
16 Awọn iṣe ìkùgbùù jẹ awọn ẹṣẹ wiwuwo ti o fi pupọ ju awọn aṣiṣe lọ. Sọọlu ni a kọ̀ gẹgẹ bi ọba fun rirubọ lọna ìkùgbùù ati fun dídá Agagi ọba Amaleki ati ikogun didara julọ sí, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ti paṣẹ pe ki a ya awọn ara Amaleki sọtọ patapata fun iparun. (1 Samuẹli 13:8-14; 15:8-19) Ọba Usaya ni a fi ẹ̀tẹ̀ kọlu fun fifipa já iṣẹ alufaa gbà lọna ìkùgbùù. (2 Kironika 26:16-21) Nigba ti wọn ngbe aaki Majẹmu lọ si Jerusalẹmu, tí maluu ti nfa kẹ̀kẹ́ naa si fẹrẹẹ fa idojude, Ọlọrun pa Usahi fun gbígbá Aaki naa mu lati mu un duro lọna àìlọ́wọ̀. (2 Samuẹli 6:6, 7) Nitori naa, bi awa ko ba mọ ohun ti a o ṣe, tabi boya a fun wa laṣẹ lati ṣe ohun kan, a gbọdọ fi imọwọn ara ẹni hàn ki a sì fọranlọ awọn wọnni ti wọn ni oye. (Owe 11:2; 13:10) Nitootọ, bi a ba ti kùgbùù nigba kankan rí, a gbọdọ gbadura fun idariji ki a si sọ fun Ọlọrun lati ran wa lọwọ lati pa wa mọ kuro ninu ìkùgbùù ni ọjọ iwaju.
17. Bawo ni awọn ẹṣẹ ti a fipamọ ṣe le nipa lori ẹnikan, sibẹ bawo ni a ṣe le ri idariji ati itura gba?
17 Awọn ẹṣẹ ti wọn farasin le fa idaamu ọkan. Gẹgẹ bi Saamu 32:1-5 (NW) ti wi, Dafidi gbiyanju lati fi ẹṣẹ rẹ pamọ, ṣugbọn o wi pe: “Nigba ti mo dakẹ o rẹ egungun mi lati inu ikerora mi ni gbogbo ọjọ. Nitori ni ọsan ati oru ni ọwọ rẹ wuwo lara mi. Ọ̀rinrin igbesi-aye mi ti yipada gẹgẹ bi o ti ri ni igba ooru gbigbẹ igba ẹẹrun.” Gbigbiyanju lati tẹ ẹ̀rí-ọkàn ẹlẹ́bi rì mú kí o rẹ Dafidi, àròkàn si mu okun rẹ̀ dinku gẹgẹ bi igi kan ti npadanu ọ̀rinrin ti nfunni ni iye nigba ọ̀gbẹlẹ̀ tabi nigba ooru gbigbẹ igba ẹrun. O han gbangba pe oun jiya inipalori buburu niti ero ori ati ti ara o si padanu ayọ nitori ikuna lati jẹwọ. Kiki jijẹwọ fun Ọlọrun ni o le mu iforiji ati itura wa. Dafidi wi pe: “Alayọ ni ẹni naa ti a fori iditẹ rẹ̀ jì, ti a bo ẹṣẹ rẹ̀. . . . Ẹṣẹ mi ni mo jẹwọ rẹ̀ fun ọ nigbẹhin-gbẹhin, aṣiṣe mi ni emi ko si fi bò. Mo wi pe: ‘emi yoo ṣe ijẹwọ lori awọn irelanakọja mi fun Jehofa.’ Iwọ funraarẹ sì fori aṣiṣe awọn ẹṣẹ mi ji mi.” Iranlọwọ onifẹẹ lati ọdọ awọn Kristẹni alagba le ṣe iranlọwọ lati mu ìkọ́fẹ tẹmi dagba.—Owe 28:13; Jakobu 5:13-20.
18. Ẹ̀rí wo ni o wà nibẹ pe ẹṣẹ le ni ipa ti o wà pẹtiti, ṣugbọn ki ni o le jẹ orisun itunu ninu iru ọran bẹẹ?
18 Ẹṣẹ le ni awọn ipa pipẹ titi. O ṣe bẹẹ fun Dafidi, ẹni ti o da ẹṣẹ panṣaga pẹlu Biaṣeba, ti o fọgbọn dari iku ọkọ rẹ̀, ti o si gbe opó ti o loyun naa ni iyawo. (2 Samuẹli 11:1-27) Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun fi aanu han nitori majẹmu Ijọba naa, ironupiwada Dafidi ati ọna ihuwa alaaanu rẹ̀ si awọn ẹlomiran, Dafidi niriiri ‘ajalu ibi lati inu ile oun funraarẹ.’ (2 Samuẹli 12:1-12) Ọmọ ti a fi panṣaga bí naa ku. Aminọni ọmọkunrin Dafidi fipa ba Tamari arabinrin ọmọ baba rẹ̀ dapọ a sì pa a labẹ aṣẹ Abusalomu arakunrin rẹ̀. (2 Samuẹli 12:15-23; 13:1-33) Abusalomu ko itiju ba Dafidi nipa nini ibalopọ pẹlu awọn ale rẹ̀. O gbiyanju lati fipa gba ìtẹ́ naa ṣugbọn o pade iku rẹ. (2 Samuẹli 15:1-18:33) Ẹṣẹ ṣì ni abajade ikẹhin sibẹ. Fun apẹẹrẹ, oniwa aitọ kan ti a yọ lẹgbẹ le ronupiwada ki a si gba a sipo pada ninu ijọ, ṣugbọn o le gba ọpọlọpọ ọdun lati bori orukọ rere ti o ti bajẹ ati àjálù niti ìmí ẹdun ti njẹ jade lati inu ẹṣẹ. Nisinsinyi ná, bawo ni o ti tuni ninu to lati ni idariji Jehofa ati itilẹhin awọn apa rẹ̀ wiwa titilae!
A Gbà Wa Kuro Lọwọ Pakanleke Ti a Wà Labẹ Rẹ̀
19. Bawo ni ẹmi Ọlọrun ṣe le ṣeranlọwọ nigba ti a ba ndan wa wo lọna mimuna?
19 Nigba ti a ba dan wa wo lọna mimuna, a lè ṣalaini ọgbọn ati okun ti o tó lati ṣe ipinnu ki a sì mu un ṣẹ. Ninu iru ọran bẹẹ, ẹmi Ọlọrun “nran ailera wa lọwọ: nitori a ko mọ bi a tii gbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmi tikaraarẹ nfi irora ti a ko le fi ẹnu sọ bẹbẹ fun wa.” (Roomu 8:26) Bi Jehofa ba mu iyipada awọn ipo wa, a gbọdọ kun fun imoore. Sibẹ, apa rẹ̀ le gba wa la ni ọna miiran. Bi a ba gbadura fun ọgbọn, Jehofa nipasẹ ẹmi rẹ̀ le tọka ohun ti a gbọdọ ṣe ki o si pese okun ti a nilo lati ṣe e. (Jakobu 1:5-8) Pẹlu iranlọwọ rẹ̀, a le farada a nigba ti ‘a ba ko ẹdun ọkan ba wa nipa oniruuru adanwo’ ti a si la wọn kọja pẹlu igbagbọ ti a ti danwo ti a si ti fun lokun.—1 Peteru 1:6-8.
20. Ki ni awa yoo gbadun bi a ba fi awọn apa Jehofa wiwa titilae ṣe itilẹhin wa nitootọ?
20 Ẹ maṣe jẹ ki a ṣaarẹ lae ni yiyiju si Ọlọrun ninu adura. “Oju mi gbe soke si Oluwa [“Jehofa,” NW] lae; nitori ti yoo fa ẹsẹ mi yọ kuro ninu àwọ̀n naa,” ni Dafidi wi. “Yi pada si mi, ki o si ṣaanu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju. Ìṣẹ́ àyà mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi. Wo ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹṣẹ mi ji mi.” (Saamu 25:15-18) Bii Dafidi, awa yoo gbadun idande, ojurere, ati idariji atọrunwa bi a ba fi apa Jehofa wiwa titilae ṣe itilẹhin wa nitootọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọrọ-ẹkọ lori irẹwẹsi ọpọlọ ninu Ji! ti April 22, 1988, oju-iwe 2 si 16, ati May 8, 1988, oju-iwe 12 si 16.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun Pada?
◻ Bawo ni Jehofa ṣe nran awọn iranṣẹ rẹ̀ ti wọn nṣaisan lọwọ?
◻ Ki ni o le ṣeranlọwọ nigba ti a ba ndan wa wo lati koju isorikọ ti ero ori?
◻ Ki ni o le ṣeranlọwọ lati mu irobinujẹ ọkan dinku lori iku ololufẹ kan?
◻ Bawo ni awọn wọnni ti wọn nfi ẹṣẹ wọn pamọ ṣe le ri itura gba?
◻ Iranlọwọ wo ni o wà nibẹ nigba ti a ba ndan awọn eniyan Jehofa wo lọna mimuna?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Awa le ri itunu lati inu ireti ajinde, gẹgẹ bi Joobu oniwa-bi-Ọlọrun ti ṣe