Sámúẹ́lì Kejì
15 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan yìí, Ábúsálómù ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara rẹ̀, ó kó àwọn ẹṣin jọ pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+ 2 Ábúsálómù máa ń dìde láàárọ̀ kùtù, á sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tó lọ sí ẹnubodè ìlú.+ Nígbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní ẹjọ́ tó ń gbé bọ̀ lọ́dọ̀ ọba,+ Ábúsálómù á pè é, á sì sọ pé: “Ìlú wo lo ti wá?” onítọ̀hún á sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ rẹ ti wá.” 3 Ábúsálómù á wá sọ fún un pé: “Wò ó, ẹjọ́ rẹ dára, ó sì tọ́, àmọ́ kò sí ẹnì kankan láti ọ̀dọ̀ ọba tó máa fetí sí ọ.” 4 Ábúsálómù á tún sọ pé: “Ká ní wọ́n yàn mí ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni! Nígbà náà, gbogbo ẹni tó ní ẹjọ́ tàbí tó ń wá ìdájọ́ á lè wá sọ́dọ̀ mi, màá sì rí i pé mo dá ẹjọ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́.”
5 Nígbà tí ẹnì kan bá sún mọ́ Ábúsálómù kí ó lè tẹrí ba fún un, Ábúsálómù á na ọwọ́ rẹ̀, á gbá a mú, á sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+ 6 Ohun tí Ábúsálómù máa ń ṣe sí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó gbé ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba nìyẹn; torí náà, Ábúsálómù ń dọ́gbọ́n fa ojú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mọ́ra.*+
7 Nígbà tí ọdún mẹ́rin* parí, Ábúsálómù sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí Hébúrónì,+ kí n lè lọ san ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Jèhófà. 8 Nítorí ìránṣẹ́ rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ ńlá kan+ nígbà tí mò ń gbé ní Géṣúrì+ ní Síríà pé: ‘Tí Jèhófà bá mú mi pa dà wá sí Jerúsálẹ́mù, màá rúbọ sí* Jèhófà.’” 9 Torí náà, ọba sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ló bá gbéra, ó sì lọ sí Hébúrónì.
10 Ábúsálómù wá rán àwọn amí sí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé: “Gbàrà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, kí ẹ kéde pé, ‘Ábúsálómù ti di ọba ní Hébúrónì!’”+ 11 Nígbà náà, igba (200) ọkùnrin tẹ̀ lé Ábúsálómù lọ láti Jerúsálẹ́mù; ó pè wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé e láìfura, wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 12 Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí ó rú àwọn ẹbọ náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Áhítófẹ́lì+ ará Gílò, agbani-nímọ̀ràn*+ Dáfídì, láti Gílò+ ìlú rẹ̀. Ọ̀tẹ̀ náà ń gbilẹ̀ sí i, àwọn tó sì wà lẹ́yìn Ábúsálómù ń pọ̀ sí i.+
13 Nígbà tó yá, ẹnì kan wá yọ́ ọ̀rọ̀ sọ fún Dáfídì pé: “Ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti yí sọ́dọ̀ Ábúsálómù.” 14 Ní kíá, Dáfídì sọ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a sá lọ,+ nítorí kò sí ìkankan lára wa tó máa bọ́ lọ́wọ́ Ábúsálómù! Ẹ ṣe kíá, kí ó má bàa yára lé wa bá, kí ó mú àjálù bá wa, kí ó sì fi idà pa ìlú yìí!”+ 15 Àwọn ìránṣẹ́ ọba sọ fún ọba pé: “Ohunkóhun tí olúwa wa ọba bá sọ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ṣe tán láti ṣe.”+ 16 Nítorí náà, ọba jáde, gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀ lé e, àmọ́ ọba ní kí àwọn wáhàrì*+ mẹ́wàá dúró láti máa tọ́jú ilé. 17 Ọba ń bá ìrìn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn èèyàn náà ń tẹ̀ lé e, wọ́n sì dúró ní Bẹti-méhákì.
18 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ kúrò* àti gbogbo àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ àti àwọn ará Gátì,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lé e láti Gátì,+ sì ń kọjá bí ọba ti ń yẹ̀ wọ́n wò.* 19 Nígbà náà, ọba sọ fún Ítáì+ ará Gátì pé: “Kí ló dé tí ìwọ náà fi fẹ́ bá wa lọ? Pa dà, kí o sì lọ máa gbé pẹ̀lú ọba tuntun, nítorí àjèjì ni ọ́, ńṣe ni o sì sá kúrò ní ìlú rẹ. 20 Kò tíì pẹ́ tí o dé, ṣé kí n wá sọ pé kí o máa bá wa rìn káàkiri lónìí, láti lọ síbi tí mo bá ń lọ nígbà tí mo bá ń lọ? Pa dà, ìwọ àti àwọn arákùnrin rẹ, kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́+ hàn sí ọ!” 21 Ṣùgbọ́n Ítáì dá ọba lóhùn pé: “Bí Jèhófà àti olúwa mi ọba ti wà láàyè, ibikíbi tí olúwa mi ọba bá wà, yálà fún ikú tàbí fún ìyè, ibẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ yóò wà!”+ 22 Dáfídì bá sọ fún Ítáì+ pé: “Ó yá sọdá.” Nítorí náà, Ítáì ará Gátì sọdá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin àti àwọn ọmọ tó wà pẹ̀lú rẹ̀.
23 Gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń sunkún kíkankíkan nígbà tí àwọn èèyàn náà ń sọdá, ọba sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ Àfonífojì Kídírónì;+ gbogbo àwọn èèyàn náà sì ń sọdá sójú ọ̀nà tó lọ sí aginjù. 24 Sádókù+ wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n ru àpótí+ májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́; wọ́n sì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́+ kalẹ̀; Ábíátárì+ náà wà níbẹ̀ ní gbogbo àkókò tí àwọn èèyàn náà sọdá láti inú ìlú náà. 25 Ṣùgbọ́n ọba sọ fún Sádókù pé: “Gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sínú ìlú.+ Tí Jèhófà bá ṣojú rere sí mi, á mú mi pa dà, á tún jẹ́ kí n rí i àti ibi tó máa ń wà.+ 26 Àmọ́ tí ó bá sọ pé, ‘Inú mi ò dùn sí ọ,’ nígbà náà, kí ó ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ̀ sí mi.” 27 Ọba wá sọ fún àlùfáà Sádókù pé: “Ṣebí aríran+ ni ọ́? Pa dà sínú ìlú ní àlàáfíà, kí o mú àwọn ọmọ yín méjèèjì dání, Áhímáásì ọmọ rẹ àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì. 28 Wò ó, màá dúró ní ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò aginjù, títí màá fi rí ẹni tí wàá ní kí ó wá jíṣẹ́ fún mi.”+ 29 Torí náà, Sádókù àti Ábíátárì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbẹ̀.
30 Bí Dáfídì ṣe ń gun Òkè* Ólífì,+ ó ń sunkún bí ó ṣe ń gòkè lọ; ó bo orí rẹ̀, ó sì ń rìn lọ láìwọ bàtà. Gbogbo àwọn èèyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà bo orí wọn, wọ́n sì ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ. 31 Dáfídì gbọ́ pé: “Áhítófẹ́lì wà lára àwọn tí ó dìtẹ̀+ pẹ̀lú Ábúsálómù.”+ Ni Dáfídì bá sọ pé: “Jèhófà,+ jọ̀wọ́ sọ ìmọ̀ràn* Áhítófẹ́lì di ti òmùgọ̀!”+
32 Nígbà tí Dáfídì dé orí òkè tí àwọn èèyàn ti máa ń forí balẹ̀ fún Ọlọ́run, Húṣáì+ ará Áríkì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀, ẹ̀wù rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. 33 Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: “Tí o bá bá mi sọdá, wàá di ẹrù sí mi lọ́rùn. 34 Àmọ́ tí o bá pa dà sínú ìlú, tí o sì sọ fún Ábúsálómù pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, Ọba. Ìránṣẹ́ bàbá rẹ ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́,’+ ìgbà náà ni wàá lè bá mi sọ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì di asán.+ 35 Ṣebí àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ? Gbogbo ohun tí o bá gbọ́ ní ilé ọba+ ni kí o sọ fún àlùfáà Sádókù àti Ábíátárì. 36 Wò ó! Àwọn ọmọ wọn méjèèjì wà pẹ̀lú wọn, Áhímáásì+ ọmọ Sádókù àti Jónátánì+ ọmọ Ábíátárì, kí o ní kí wọ́n wá sọ gbogbo ohun tí o bá gbọ́ fún mi.” 37 Nítorí náà, Húṣáì, ọ̀rẹ́* Dáfídì,+ wá sínú ìlú bí Ábúsálómù ṣe ń wọ Jerúsálẹ́mù.