ORÍ KEJÌ
Àwọn Wòlíì Tí Wọ́n Jíṣẹ́ Tó Lè Ṣe Wá Láǹfààní
1. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fẹ́ láti mọ àwọn wòlíì méjìlá tó kọ àwọn ìwé tó gbẹ̀yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?
ṢÉ WÀÁ fẹ́ láti mọ àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run méjìlá tá a ti ń sọ̀rọ̀ wọn bọ̀ yìí? O ò lè rí wọn lójúkojú nítorí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn méjèèjìlá ti gbé ayé, kódà Jésù ò tíì wá sórí ilẹ̀ ayé nígbà náà. Síbẹ̀, o ṣì lè mọ̀ wọ́n, kó o mọ bí wọ́n ṣe fi “ọjọ́ ńlá Jèhófà” sọ́kàn. Ohun tí wàá sì mọ̀ ṣe pàtàkì gidi fún gbogbo Kristẹni tó ń là kàkà láti fi ọjọ́ ńlá Jèhófà sọ́kàn.—Sefanáyà 1:14; 2 Pétérù 3:12.
2, 3. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé àwọn wòlíì méjìlá náà ṣe jọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tiwa yìí?
2 Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ni Ìwé Mímọ́ pè ní wòlíì, kódà, orúkọ àwọn wòlíì la fi ń pe ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé inú Bíbélì. Àwọn ọkùnrin méjìlá tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí jẹ́ olóòótọ́ àti onígboyà bíi tàwọn wòlíì mìíràn. Inú àwọn kan lára wọn dùn gidigidi nítorí pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn mú kí àwọn èèyàn yí ọkàn àti èrò wọn padà, ó sì mú kí wọ́n padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Inú àwọn míì lára wọn bà jẹ́ gidigidi nígbà tí wọ́n rí báwọn oníwàkiwà èèyàn ò ṣe yéé tẹ ìlànà Ọlọ́run lójú tí wọn ò sì yéé ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Bákan náà, ìjákulẹ̀ ló jẹ́ fún àwọn míì nígbà táwọn tí wọ́n ń sọ pé olùjọsìn Jèhófà làwọn kò ka ìkìlọ̀ tí wọ́n ń gbọ́ sí, tí wọ́n sì sọ ara wọn di ẹrú ìwàkiwà.
3 Bí ìgbà tiwa yìí gan-an ni ìgbà ayé àwọn wòlíì méjìlá wọ̀nyẹn rí. Nígbà yẹn, rúkèrúdò wà láwùjọ, rògbòdìyàn ń wáyé láàárín àwọn òṣèlú, ìsìn sì ń jó àjórẹ̀yìn. Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa,” kò sí àní-àní pé àwọn náà ní ìṣòro, àwọn nǹkan kan sì máa wà tó bà wọ́n lẹ́rù. (Jákọ́bù 5:17) Síbẹ̀, wọ́n fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ ká gbé ìwé wọn yẹ̀ wò dáadáa, nítorí pé ìwé wọn jẹ́ ara “àwọn ìwé mímọ́ alásọtẹ́lẹ̀” tí wọ́n kọ fún àǹfààní àwa ‘tí òpin ètò àwọn nǹkan dé bá.’—Róòmù 15:4; 16:26; 1 Kọ́ríńtì 10:11.
BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÁKÒÓKÒ TÁWỌN WÒLÍÌ MÉJÌLÁ NÁÀ GBÉ LÁYÉ
4. Kí lo ti wá mọ̀ nípa ìgbà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wòlíì méjìlá náà gbé ayé, àwọn wo lára wọn sì ni Jèhófà kọ́kọ́ gbé dìde pé kí wọ́n lọ kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀?
4 Ó ṣeé ṣe kó o rò pé bí àwọn ìwé Bíbélì láti Hóséà sí Málákì ṣe tò tẹ̀ léra wọn nínú Bíbélì rẹ ni àwọn wòlíì méjìlá náà ṣe gbé láyé. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn wòlíì tí Ọlọ́run kọ́kọ́ gbé dìde, ìyẹn, Jónà, Jóẹ́lì, Ámósì, Hóséà, àti Míkà, gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹsàn-án àti ìkẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K.).a Lákòókò yẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọba tó jẹ ní ìjọba gúúsù ti Júdà àti ìjọba àríwá Ísírẹ́lì ló jẹ́ aláìṣòótọ́. Ìwàkiwà wọn náà làwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí tẹ̀ lé, ìyẹn sì mú kí wọ́n rí ìbínú Ọlọ́run. Àkókò yẹn ni Ásíríà ń wá bó ṣe máa di agbára ayé. Nígbà tó ṣe, Bábílónì pẹ̀lú làkàkà láti di agbára ayé. Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò mọ̀ pé tó bá yá, Jèhófà yóò lo àwọn agbára ayé wọ̀nyí láti fìyà jẹ àwọn nítorí ìwàkiwà táwọn ń hù! Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń rán àwọn wòlíì rẹ̀ olóòótọ́ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà láti kìlọ̀ fún wọn lákòókò yẹn.
5. Àwọn wòlíì wo ló kéde ìdájọ́ Jèhófà bí ìparun Júdà àti Jerúsálẹ́mù ṣe ń sún mọ́lé?
5 Bí àkókò tí Jèhófà máa mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù ṣe ń sún mọ́lé, Jèhófà tún gbé àwọn agbẹnusọ rẹ̀ mìíràn tí wọ́n jẹ́ onítara dìde. Àwọn wo ni lọ́tẹ̀ yìí? Àwọn ni wòlíì Sefanáyà, wòlíì Náhúmù, wòlíì Hábákúkù àti wòlíì Ọbadáyà. Gbogbo wọn ni wọ́n sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì ní ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ohun ìbànújẹ́ tó burú jù lọ tó ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn ni pípa táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run tí wọ́n sì kó àwọn Júù lọ sígbèkùn lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run fi rán àwọn kan lára àwọn agbẹnusọ rẹ̀ yìí pé kí wọ́n fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gan-an ló nímùúṣẹ yẹn. Àwọn wòlíì náà gbìyànjú láti jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ àwọn ohun tí kò dára tí wọ́n ń ṣe, irú bí wọ́n ṣe máa ń mutí yó bìnàkò tí wọ́n sì máa ń hùwà ipá, àmọ́ àwọn èèyàn náà kò yíwà padà.—Hábákúkù 1:2, 5-7; 2:15-17; Sefanáyà 1:12, 13.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe mú káwọn àṣẹ́kù tó padà láti ìgbèkùn pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn tòótọ́?
6 Nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run padà dé láti ìgbèkùn, wọ́n nílò àwọn aṣáájú tó kúnjú òṣùwọ̀n àti ìtùnú òun ìṣílétí kí wọ́n lè pa ọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn tòótọ́. Àwọn wòlíì tí Ọlọ́run sì rán lákòókò náà ni Hágáì, Sekaráyà àti Málákì. Wọ́n sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì ní ọ̀rúndún kẹfà àti ìkarùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó o bá ṣe ń mọ̀ sí i nípa àwọn wòlíì méjìlá wọ̀nyí tí wọ́n fi àìyẹsẹ̀ gbé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lárugẹ, tó o sì ń mọ̀ sí i nípa iṣẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe máa rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó o lè fi sílò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní àkókò eléwu tá a wà yìí. Ní báyìí, jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn wòlíì wọ̀nyí, ká máa mú wọn lọ́kọ̀ọ̀kan látorí èyí tí Ọlọ́run kọ́kọ́ rán lára wọn dórí èyí tó kẹ́yìn.
BÍ WỌ́N ṢE GBÌYÀNJÚ LÁTI GBA ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ ALÁGÍDÍ LÀ
7, 8. Kí ni ohun tí ìrírí Jónà lè fún wa níṣìírí láti ṣe bó bá ṣẹlẹ̀ pé a kò ní ìgboyà?
7 Ǹjẹ́ ó ti ṣe ọ́ rí bíi pé o kò ní ìgboyà, pé iná ìgbàgbọ́ rẹ ń jó lọọlẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà. Ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jónà gbé ayé. Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé Ọlọ́run sọ fún Jónà pé kó lọ sí Nínéfè, tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ ọba Ásíríà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lákòókò náà. Jèhófà sọ pé kó lọ sọ fáwọn ará Nínéfè pé ìwà ibi tí wọ́n ń hù kì í ṣe ohun tó dára. Àmọ́ kàkà kí Jónà lọ sí Nínéfè, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] kìlómítà sí àríwá ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù, ńṣe ló lọ wọ ọkọ̀ òkun tó ń lọ sí èbúté kan tó ṣeé ṣe kó wà ní Sípéènì. Òdì kejì ibi tí Ọlọ́run sọ pé kó lọ ló forí lé, èyí sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún [3,500] kìlómítà sí Nínéfè! Kí lo ti ro èyí sí? Ṣé ẹ̀rù ló ń ba Jónà ni àbí iná ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti jó lọọlẹ̀, àbí inú ló ń bí i pé ó ṣeé ṣe káwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà kíyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti gbógun ja Ísírẹ́lì nígbà tó bá yá? Bíbélì ò sọ ìdí rẹ̀ fún wa. Àmọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà yìí, a rí ìdí tí kò fi yẹ ká máa ronú lọ́nà tí kò tọ́.
8 Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó o mọ bí Jónà ṣe ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá a wí. Nígbà tí Jónà wà nínú ikùn “ẹja ńlá” tó gbé e mì, ó gbà pé: “Ti Jèhófà ni ìgbàlà.” (Jónà 1:17; 2:1, 2, 9) Nígbà tí Jèhófà yọ Jónà nínú ewu lọ́nà iṣẹ́ ìyanu, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà rán an. Àmọ́ ìjákulẹ̀ ńlá bá a nígbà tí Jèhófà kò pa àwọn ará Nínéfè run nítorí pé wọ́n fetí sí iṣẹ́ tí Jèhófà rán sí wọn tí wọ́n sì ronú pìwà dà. Tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, kò ronú nípa ire àwọn ẹlòmíràn, nítorí náà Jèhófà tún fìfẹ́ tọ́ ọ sọ́nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àléébù Jónà nìkan ló ṣeé ṣe káwọn kan máa rántí nípa Jónà, onígbọràn àti olóòótọ́ ni Ọlọ́run kà á sí.—Lúùkù 11:29.
9. Àwọn àǹfààní wo lo lè rí nínú iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run fi rán Jóẹ́lì?
9 Ǹjẹ́ ìjákulẹ̀ ti bá ọ rí nígbà táwọn èèyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ò ń wàásù pé ńṣe lo kàn ń dẹ́rù ba àwọn èèyàn kiri? Ojú tí àwọn ará orílẹ̀-èdè wòlíì Jóẹ́lì fi wo ohun tí Ọlọ́run rán an pé kó sọ fún wọn nìyẹn. Orúkọ rẹ̀ yìí túmọ̀ sí “Jèhófà ni Ọlọ́run.” Ìgbà ayé Ùsáyà Ọba ló dà bíi pé ó kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní Júdà ní nǹkan bí ọdún 820 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó jọ pé àkókò kan náà ni òun àti Jónà sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Jóẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn eéṣú tó ń fa ìparun tí yóò rọ́ wá láti sọ ilẹ̀ náà dahoro. Dájúdájú, ọjọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ ọjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Àmọ́, wàá rí i pé ègbé nìkan kọ́ ni ohun tí Ọlọ́run fi rán Jóẹ́lì láti kéde. Inú wa yóò dùn láti mọ̀ pé Jóẹ́lì tún fi hàn pé àwọn onígbọràn ‘yóò sá là.’ (Jóẹ́lì 2:32) Ó máa ṣeé ṣe fáwọn tó bá ronú pìwà dà láti rí ìbùkún àti ìdáríjì gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ohun ayọ̀ ló máa jẹ́ fún wa tá a bá ń fi sọ́kàn pé èyí jẹ́ ara iṣẹ́ tí àwa náà ń jẹ́! Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run yóò tú agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, jáde “sára gbogbo onírúurú ẹran ara.” Ǹjẹ́ o rí bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe kàn ọ́? Láfikún, Jóẹ́lì tẹnu mọ́ ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà rí ìgbàlà, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.”—Jóẹ́lì 2:28, 32.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ẹnì kan tó jẹ́ alágbàṣe lásánlàsàn?
10 Tó bá jẹ́ pé nígbà míì, ìrònú iṣẹ́ bàǹtà-banta tá a ní láti jẹ́, pàápàá fún àwọn tí kò fẹ́ gbọ́, máa ń mú ọ láyà pami, ó ṣeé ṣe kí àánú Ámósì ṣe ọ́. Ámósì kì í ṣe ọmọ wòlíì bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ara àwùjọ àwọn wòlíì kan; àgùntàn ló ń dà ó sì tún máa ń ṣàgbàṣe ní àkókò kan nínú ọdún. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nígbà ayé Ùsáyà Ọba Júdà, lápá ìparí ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe inú ìdílé ọlọ́lá ló ti wá, Ámósì, tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Jíjẹ́ Ẹrù; Gbígbé Ẹrù,” jíṣẹ́ tó rinlẹ̀ gan-an, èyí tí Ọlọ́run fi rán an sí Júdà, Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Ǹjẹ́ èyí kò fún ọ níṣìírí, pé Jèhófà lè lo èèyàn rírẹlẹ̀ láti ṣe irú iṣẹ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀?
11. Kí ni Hóséà múra tán láti fara dà kó bàa lè ṣe ìfẹ́ Jèhófà?
11 Ǹjẹ́ o ti béèrè lọ́wọ́ ara rẹ rí pé, ‘Àwọn nǹkan wo ni mo múra tán láti fara dà kí n lè ṣe ìfẹ́ Jèhófà’? Ó dáa, ronú nípa Hóséà, tó gbé ayé ní nǹkan bí àkókò kan náà tí Aísáyà àti Míkà gbé ayé, tó sì fi nǹkan bí ọgọ́ta ọdún ṣe iṣẹ́ wòlíì. Jèhófà sọ fún Hóséà pé kó fẹ́ Gómérì, tó jẹ́ “àgbèrè aya.” (Hóséà 1:2) Nínú ọmọ mẹ́ta tí Gómérì bí lẹ́yìn náà, ó hàn gbangba pé ọ̀kan péré ni ti Hóséà. Kí nìdí tí Jèhófà fi máa sọ pé kẹ́nì kan fara da ìwà àìṣòótọ́ ẹni tí wọ́n jọ ṣègbéyàwó? Ńṣe ni Jèhófà fi èyí kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìdúróṣinṣin àti ìdáríjì. Ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá apá ìhà àríwá ti da Ọlọ́run bí aya tó ṣe panṣágà ṣe dalẹ̀ ọkọ rẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn rẹ̀ ó sì gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà. Ó dájú pé inú wa á dùn láti ṣàyẹ̀wò èyí.
12. Tó o bá gbé àpẹẹrẹ Míkà àti àbájáde àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò, báwo lèyí ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní?
12 Ǹjẹ́ o ò gbà pé àkókò líle koko tá a wà yìí mú kó ṣòro fún ọ láti ní ìgboyà kó o sì gbára lé Jèhófà pátápátá? Àmọ́ tó o bá ní ìgboyà tó o sì gbára lé Jèhófà pátápátá, wàá dà bíi Míkà, tó jẹ́ alájọgbáyé Hóséà àti Aísáyà. Míkà jíṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán an pé kó kéde lòdì sí orílẹ̀-èdè Júdà àti Ísírẹ́lì nígbà ìṣàkóso Áhásì àti Hesekáyà, ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìwàkíwà tó gogò àti ìbọ̀rìṣà ba ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ìhà àríwá Ísírẹ́lì jẹ́, ó sì pa run nígbà táwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun Samáríà lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Orílẹ̀-èdè Júdà ní tiẹ̀ ò mọ èyí tí ì bá ṣe, tó bá gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu díẹ̀, á tún ṣàìgbọràn díẹ̀. Láìka àgbákò tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sí, inú Míkà dùn nígbà tó rí i pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun mú kí Júdà kiwọ́ ìbọ̀rìṣà bọlẹ̀ fúngbà díẹ̀ tíyẹn sì fawọ́ àjálù tí ì bá wáyé sẹ́yìn. Ó dájú pé inú àwa náà máa ń dùn gan-an tá a bá rí i táwọn èèyàn ń ṣe ohun tá à ń sọ bá a ṣe ń kéde ìgbàlà fún wọn!
WỌ́N SỌ ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÀGBÁKÒ TÓ RỌ̀ DẸ̀DẸ̀
13, 14. (a) Báwo ni àpẹẹrẹ Sefanáyà ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìjọsìn rẹ? (b) Àtúnṣe wo ni ìkéde Sefanáyà mú kó wáyé?
13 Bí agbára ayé Íjíbítì àti Ásíríà ṣe ń relẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Bábílónì ń ròkè. Láìpẹ́, ríròkè tí Bábílónì ń ròkè yìí á mú ìyípadà òjijì bá orílẹ̀-èdè Júdà. Lákòókò náà, àwọn wòlíì Ọlọ́run ń kìlọ̀ fáwọn olùjọsìn Jèhófà wọ́n sì ń ṣí wọn létí. Gbé díẹ̀ lára àwọn wòlíì náà yẹ̀ wò. Bó o ṣe ń ṣe àgbéyẹ̀wò yìí, má gbàgbé pé irú ìkìlọ̀ tí wọ́n kéde làwa Kristẹni náà ń kéde lónìí.
14 Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo sapá gidi kó o tó lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn àṣà tó o bá nínú ìdílé rẹ kó o lè ṣe ìfẹ́ Jèhófà, a jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sefanáyà ò lè ṣàjèjì sí ọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ-ọmọ ọmọ Hesekáyà Ọba ló bí Sefanáyà, ó sì tún lè jẹ́ pé mọ̀lẹ́bí Jòsáyà Ọba ni, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọmọ ìdílé tó ń jọba ní ẹ̀yà Júdà. Síbẹ̀, Sefanáyà gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu, ó jíṣẹ́ ìdálẹ́bi tí Ọlọ́run fi rán an sáwọn aṣáájú Júdà oníwà ìbàjẹ́. Orúkọ Sefanáyà túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Pa Á Mọ́.” Sefanáyà tẹnu mọ́ ọn pé àfi àánú Ọlọ́run nìkan ló lè mú ká ‘pa ẹnì kan mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.’ (Sefanáyà 2:3) Ohun ayọ̀ ló jẹ́ pé ìkéde tó fìgboyà ṣe yìí so èso. Jòsáyà Ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣètò bí wọ́n á ṣe ṣàtúnṣe sí ìjọsìn wọn, ó pa àwọn ère run, ó tún tẹ́ńpìlì ṣe, ó sì dá ìjọsìn mímọ́ padà. (2 Àwọn Ọba orí 22 àti 23) Ó dájú pé Sefanáyà àtàwọn wòlíì bíi tiẹ̀ (Náhúmù àti Jeremáyà) gan-an ni wọ́n ran Jòsáyà Ọba lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n gbà á nímọ̀ràn. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ojú ayé lásán ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù tí wọ́n sọ pé àwọn ronú pìwà dà ṣe, wọn ò ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Wọ́n padà sínú ìbọ̀rìṣà wọn lẹ́yìn tí Jòsáyà ku lójú ogun. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn ará Bábílónì kó wọn lọ sígbèkùn.
15. (a) Kí nìdí tí ègbé tí Náhúmù kéde fi tọ́ sí Nínéfè? (b) Kí lo lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nínéfè?
15 Bí o kò bá gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta, ó ṣeé ṣe kó o máa rò pé o kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan. Ká sòótọ́, àǹfààní bàǹtà-banta làwa Kristẹni ní bá a ṣe jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú Ọlọ́run, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ wa ni kì í ṣe ẹni tó gbajúmọ̀ lọ títí. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí fún wòlíì Náhúmù. Gbogbo nǹkan tá a mọ̀ nípa rẹ̀ kò ju pé ó wá láti ìlú kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Élíkóṣì, tó ṣeé ṣe kó wà ní Júdà. Àmọ́, iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni Ọlọ́run fi rán an. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Bó ṣe rí bẹ́ẹ̀ ni pé, Nínéfè tí í ṣe olú ìlú agbára ayé Ásíríà ni Náhúmù sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí. Àwọn tó ń gbé Nínéfè ṣàtúnṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìkéde Jónà, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tún padà gbé ẹ̀wù ìwàkiwà tí wọ́n ti bọ́ sílẹ̀ wọ̀. Àwọn àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára òkúta táwọn kan rí ní ibi tí ìlú Nínéfè ayé ọjọ́un wà fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Náhúmù sọ, pé Nínéfè jẹ́ “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Náhúmù 3:1) Àwọn àwòrán náà fi báwọn ará Nínéfè ṣe máa ń hùwà ìkà tó burú jáì sáwọn tí wọ́n bá mú lẹ́rú nígbà ogun hàn. Náhúmù sàsọtẹ́lẹ̀ pé Nínéfè yóò pa run, èdè àpèjúwe tó sì ṣe kedere ló lò, kò figbá kan bọ̀kan nínú. Iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi ran an yìí nímùúṣẹ, bí iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán àwa náà lónìí yóò ṣe nímùúṣẹ.
16, 17. Bó bá ń ṣe wá bíi pé òpin ò tètè dé, kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Hábákúkù?
16 Ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá sẹ́yìn, àwọn kan lára àwọn tó ń ka Bíbélì retí pé kí ọjọ́ Jèhófà dé, àmọ́ kò dé lákòókò tí wọ́n retí rẹ̀. Gbogbo nǹkan lè tojú sú àwọn míì nítorí ó dà bíi pé ìdájọ́ Jèhófà ń pẹ́. Ìwọ ńkọ́, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ? Hábákúkù sọ àwọn nǹkan tó ń bà á lọ́kàn jẹ́, ó béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? . . . Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi?”—Hábákúkù 1:2, 3.
17 Hábákúkù sọ tẹ́lẹ̀ lákòókò tí gbogbo nǹkan dojú rú ní Júdà, lẹ́yìn ìṣàkóso Jòsáyà ọba rere, kí Jerúsálẹ́mù tó pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Lákòókò náà, ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá gbòde kan. Hábákúkù kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé bíbá Íjíbítì lẹ̀dí àpò pọ̀ kò lè gba Júdà sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ. Ọ̀nà tó gbà kọ̀wé ṣe kedere, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì rinlẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tuni nínú pé “ní ti olódodo, òun yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.” (Hábákúkù 2:4) Dájúdájú, ọ̀rọ̀ yẹn ṣe pàtàkì gan-an sí wa, nítorí pé ibi mẹ́ta ni Pọ́ọ̀lù ti tún un sọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. (Róòmù 1:17; Gálátíà 3:11; Hébérù 10:38) Ìyẹn nìkan kọ́, Jèhófà tún gbẹnu Hábákúkù mú un dá wa lójú pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀. . . . Kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
18. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kí Ọbadáyà sàsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Édómù?
18 Wòlíì Ọbadáyà ló kọ ìwé tó kéré jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ẹsẹ mọ́kànlélógún péré ni ìwé rẹ̀ ní. Gbogbo ohun tá a sì mọ̀ nípa wòlíì yìí kò ju pé ó sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí Édómù. Ọ̀dọ̀ ọmọ ìyá Jékọ́bù làwọn ọmọ Édómù ti ṣẹ̀ wá, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ “arákùnrin” tàbí ẹbí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Diutarónómì 23:7) Àmọ́, ńṣe làwọn ọmọ Édómù hùwà sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi pé wọn ò tiẹ̀ mọ̀ wọ́n rí. Lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àkókò kan náà tí Ọbadáyà kọ ìwé rẹ̀, àwọn ọmọ Édómù dínà mọ́ àwọn Júù kí wọ́n má bàa ríbi sá mọ́ àwọn ará Bábílónì ọ̀tá wọn lọ́wọ́, wọ́n sì tún fi àwọn tó ń sá lọ lára wọn lé àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń sá fún lọ́wọ́. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé Édómù yóò dahoro, àsọtẹ́lẹ̀ náà sì nímùúṣẹ. Ká sòótọ́, bíi ti Náhúmù, nǹkan díẹ̀ la mọ̀ nípa Ọbadáyà, àmọ́, ǹjẹ́ ẹ ò rí i pé ó ń fúnni níṣìírí gan-an láti mọ̀ pé Ọlọ́run lè lo àwọn tó dà bíi pé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ Rẹ̀!—1 Kọ́ríńtì 1:26-29.
WỌ́N JÍṢẸ́ TÓ Ń FÚNNI NÍṢÌÍRÍ, TÓ Ń TUNI NÍNÚ, TÓ SÌ Ń KINI NÍLỌ̀
19. Báwo ni Hágáì ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run níṣìírí?
19 Hágáì ni àkọ́kọ́ lára àwọn mẹ́ta tó sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì lẹ́yìn tí àṣẹ́kù àwọn Júù tó jẹ́ onígbọràn padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Hágáì wà lára àwọn tó kọ́kọ́ padà dé láti ìgbèkùn. Pa pọ̀ pẹ̀lú Gómìnà Serubábélì, Àlùfáà Àgbà Jóṣúà, àti wòlíì Sekaráyà, Hágáì gbìyànjú láti fún àwọn Júù níṣìírí kí wọ́n lè borí àtakò tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn àti ìwà àgunlá tiwọn fúnra wọn, èyí tí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì fà. Wọ́n ní láti parí ohun tí wọ́n tìtorí rẹ̀ padà wá láti ìgbèkùn, ìyẹn, títún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. Iṣẹ́ mẹ́rin tí Hágáì jẹ́ láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ ní ọdún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni tẹnu mọ́ orúkọ Jèhófà àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Bó o bá ṣe ń ka ìwé Hágáì, wàá rí i pé ìgbà mẹ́rìnlá ni awẹ́ gbólóhùn náà, “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,” fara hàn nínú rẹ̀. Iṣẹ́ tó rinlẹ̀ tí Hágáì jẹ́ yìí fún àwọn èèyàn náà níṣìírí láti padà sẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́. Ìwọ náà ńkọ́? Nígbà tó o mọ̀ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, pé agbára rẹ̀ ò láàlà, àti pé ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló wà lábẹ́ rẹ̀, ǹjẹ́ èyí kò fún ọ níṣìírí?—Aísáyà 1:24; Jeremáyà 32:17, 18.
20. Ìwà tó gbilẹ̀ wo ni Sekaráyà gbógun tì?
20 Nígbà míì, ó ṣeé ṣe kí bí àwọn kan tí wọ́n ti fìgbà kan sin Ọlọ́run ṣe wá dẹni tí kò ní ìtara mọ́ bà ọ́ lọ́kàn jẹ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé wàá mọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára Sekaráyà. Ó ṣe iṣẹ́ kan tó le bíi ti Hágáì tí wọ́n jọ gbé ayé lákòókò kan náà. Ó fún àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí pé kí wọ́n má ṣe kúrò nídìí iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́ títí tí wọn á fi parí rẹ̀. Sekaráyà ṣiṣẹ́ kára láti fún àwọn èèyàn náà lókun kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ bàǹtà-banta yẹn. Láìka ti pé àwọn èèyàn náà fi ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì kẹ́ra bà jẹ́ sí, Sekaráyà sapá gidigidi láti fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà kí wọ́n sì ṣe ohun tó máa fi hàn pé wọ́n ní irú ìgbàgbọ́ yẹn. Ohun tí Sekaráyà fún àwọn èèyàn náà níṣìírí pé kí wọ́n ṣe ni wọ́n ṣe. Sekaráyà ṣàkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Kristi. Iṣẹ́ tí Sekaráyà jẹ́, pé “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” kò ní gbàgbé àwọn tó bá wá ojú rere rẹ̀, yóò fún àwa náà lókun.—Sekaráyà 1:3.
Ó SỌ TẸ́LẸ̀ PÉ MÈSÁYÀ Ń BỌ̀
21. (a) Kí nìdí táwọn Júù fi nílò iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán Málákì? (b) Ìdánilójú wo ni ìwé Málákì fi kádìí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?
21 Orúkọ ro Málákì, tí í ṣe ẹni tó kẹ́yìn lára àwọn wòlíì méjìlá náà. Ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “Ońṣẹ́ Mi.” Àárín ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló gbé ayé, ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ la sì mọ̀ nípa rẹ̀. Àmọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, a mọ̀ pé ó jẹ́ onígboyà wòlíì, tó bá àwọn èèyàn Ọlọ́run wí lọ́nà mímúná nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àti àgàbàgebè wọn. Àwọn nǹkan tí Málákì sọ pé ó ń ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn jọ àwọn ohun tí Nehemáyà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà kan náà ni wọ́n gbé láyé, ṣàpèjúwe. Kí nìdí táwọn Júù fi nílò iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán Málákì? Ìdí ni pé ìtara tí wòlíì Sekaráyà àti Hágáì jẹ́ kí wọ́n ní lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn ti pòórá. Wọ́n ti tutù pátápátá nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Málákì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sáwọn agbéraga àti alágàbàgebè àlùfáà, ó sì bẹnu àtẹ́ lu àwọn èèyàn náà nítorí ìjọsìn tí kò tọkàn wọn wá tí wọ́n ń ṣe àti ẹbọ tí kò dára tí wọ́n ń rú. Síbẹ̀, bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe mú un dá wa lójú pé ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni Málákì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹni tí Ọlọ́run máa rán ṣáájú Mèsáyà, ìyẹn Jòhánù oníbatisí, ń bọ̀ àti pé lẹ́yìn náà Kristi fúnra rẹ̀ yóò dé. Ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí ni Málákì fi kádìí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó ṣèlérí fún wa pé “oòrùn òdodo yóò sì ràn dájúdájú” fáwọn tó bẹ̀rù orúkọ Jèhófà.—Málákì 4:2, 5, 6.
22. Kí ni nǹkan tó o ti rí báyìí nípa àwọn wòlíì méjìlá náà àti iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́?
22 Wàá ti rí i báyìí pé àwọn ọkùnrin tó kọ ìwé méjìlá tó gbẹ̀yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ní ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú. (Hébérù 11:32; 12:1) A lè rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú àpẹẹrẹ wọn àti iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ bá a ṣe ń fi gbogbo ọkàn retí “ọjọ́ Jèhófà.” (2 Pétérù 3:10) Wàyí o, wo bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú àwọn ìwé wọ̀nyí ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní ayérayé.
a Tó o bá fi èyí wéra pẹ̀lú àwòrán tó wà lójú ewé 20 àti 21, wàá rí i pé Míkà àti Hóséà pẹ̀lú ń sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì lákòókò tí Aísáyà ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù.