-
Ìṣòro Tó Ń Fi Hàn Pé Ìrètí Ń BẹIlé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Ìṣòro Tó Ń Fi Hàn Pé Ìrètí Ń Bẹ
“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.”—2 TÍMÓTÌ 3:1.
ǸJẸ́ o ti gbọ́ nípa èyíkéyìí lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó wà nísàlẹ̀ yìí rí tàbí kí ó ṣojú rẹ?
● Àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí tó pa ọ̀pọ̀ èèyàn.
● Ìyàn tó ṣekú pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn.
● Ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ṣekú pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó sì sọ ọ̀pọ̀ di aláìnílé.
Láwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé èyí, wàá kà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mú kó o ronú jinlẹ̀ nípa ipò tí ayé yìí wà. Wàá tún rí i pé, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,”a ni irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí á máa wáyé.
Àmọ́ ṣá o, a ò kọ àwọn àpilẹ̀kọ́ yìí láti mú kó o gbà pé, à ń gbé nínú ayé tó kún fún ìṣòro. Nítorí ó ṣeé ṣe kí ìwọ́ náà ti fojú ara rẹ rí i. Ìdí tá a fi kọ àwọn àpilẹ̀kọ yìí ni pé, kí wọ́n lè fún ẹ ní ìrètí. Wọ́n máa jẹ́ kó o mọ̀ pé, bí àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́fà yìí ṣe ń ṣẹ fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” kò ní pẹ́ dópin. Nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, a tún máa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àtakò kan táwọn èèyàn ń ṣe sí ẹ̀rí pé a wà lọ́jọ́ ìkẹyìn, àwọn àpilẹ̀kọ yìí tún sọ ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó máa mú ká gbà pé ohun tó dára ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí, ka àpilẹ̀kọ náà, “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?” lójú ìwé 16 àti 17 nínú ìwé ìròyìn yìí.
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 1. Ìsẹ̀lẹ̀Ilé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 1. Ìsẹ̀lẹ̀
“Ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà.”—LÚÙKÙ 21:11.
● Wọ́n yọ Winnie ọmọ ọdún kan àtoṣù mẹ́rin lábẹ́ àwókù ilé ní orílẹ̀-èdè Haiti. Àwùjọ oníròyìn fún ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n ń gbé ìròyìn nípa àjálù náà gbọ́ nígbà tó ń kérora lábẹ́ àwókù ilé náà. Ọmọbìnrin yìí kò kú nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ yìí wáyé, àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ kú.
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ tó lágbára gan-an [ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 7.0] wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti ní January ọdún 2010, èèyàn tó ju ọ̀kẹ́ márùndínlógún [300,000] ló kú. Àwọn èèyàn mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ márùndínlógún [1,300,000] ni wọ́n sì di aláìnílé lójú ẹsẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti lágbára gan-an, síbẹ̀ kì í ṣe ibẹ̀ nìkan ni irú rẹ̀ ti wáyé. Ó kéré tán, ìmìtìtì ilẹ̀ méjìdínlógún tó lágbára ló wáyé kárí ayé láti oṣù April ọdún 2009 sí oṣù April ọdún 2010.
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Kì í ṣe pé ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ ń wáyé, àmọ́ ìtẹ̀síwájú tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló jẹ́ kí àwa èèyàn òde òní máa gbọ́ nípa àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé ju àwọn èèyàn ayé àtijọ́ lọ.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Ṣàgbéyẹ̀wò kókó yìí: Bíbélì kò sọ ní pàtó iye ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó máa wáyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́, ó sọ pé “ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà” máa wáyé “láti ibì kan dé ibòmíràn,” èyí sì mú kí wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó gbàfiyèsí tó máa wáyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Máàkù 13:8; Lúùkù 21:11.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ìsẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ là ń rí lónìí?
Kì í ṣe ìsẹ̀lẹ̀ nìkan ló jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé à ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìkejì.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Àwa [onímọ̀ nípa ìmìtìtì ilẹ̀] ń pè wọ́n ní ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà. Àmọ́, àwọn èèyàn ń pè wọ́n ní àjálù tó burú jáì.”—KEN HUDNUT, U.S. GEOLOGICAL SURVEY.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
© William Daniels/Panos Pictures
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 2. ÌyànIlé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 2. Ìyàn
“Àìtó oúnjẹ yóò wà.”—MÁÀKÙ 13:8.
● Ní orílẹ̀-èdè Niger, ọkùnrin kan kúrò ní abúlé rẹ̀ lọ sí abúlé kan tó ń jẹ́ Quaratadji, kó bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ìyàn. Àwọn àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin lóbìnrin àtàwọn ẹbí rẹ̀ náà ti ṣí kúrò ní abúlé tó jìnnà réré káwọn náà lè bọ́ lọ́wọ́ ìyàn. Síbẹ̀, ọkùnrin náà sùn sórí ẹní lóun nìkan. Kí nìdí tó fi wà níbẹ̀ lóun nìkan? Ọ̀gbẹ́ni Sidi tó jẹ́ baálẹ̀ abúlé náà sọ pé, “Ìdí ni pé, kò lè bọ́ ìdílé rẹ̀, kò sì fẹ́ máa wò wọ́n lójú ló ṣe kúrò lọ́dọ̀ wọn.”
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Kárí ayé, èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹyọ kan nínú méje ni kì í rí oúnjẹ tí ó tó jẹ lójoojúmọ́. Iye yìí tún wá pabanbarì ní gúúsù aṣálẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà, níbi tí wọ́n ti sọ pé èèyàn kan nínú mẹ́ta kò ní oúnjẹ tí wọ́n lè jẹ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Kí ohun tí à ń sọ lè túbọ̀ yé wa, ẹ fojú inú wo ìdílé kan tó ni bàbá, ìyá àti ọmọ kan. Tó bá jẹ́ pé oúnjẹ ẹni méjì ni wọ́n ní, ta ni kò ní jẹun? Ṣé bàbá ni tàbí ìyá àbí ọmọ? Ojoojúmọ́ làwọn ìdílé tó wà nírú ipò yẹn ní láti ṣe irú ìpinnu yìí.
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Oúnjẹ tí ilẹ̀ ayé ń mú jáde pọ̀ ju èyí tí gbogbo èèyàn ayé lè jẹ lọ. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé, kí àwọn tó ń bójú tó ohun tí ilẹ̀ ayé ń mú jáde bójú tó o dáadáa.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Òótọ́ ni pé, àwọn àgbẹ̀ lè pèsè oúnjẹ tó pọ̀ kí wọ́n sì gbé wọn wá sínú ìlú lákòókò yìí ju tí ìgbàkígbà rí lọ. Kò sì sí àní-àní pé, ó yẹ kí ìjọba fi oúnjẹ tí ilẹ̀ ayé ń mú jáde yanjú ìṣòro ebi. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ìsapá tí wọ́n ti ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún láti yanjú ìṣòro náà, pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ohun tó wà nínú ìwé Máàkù 13:8 ló ń ṣẹ? Pẹ̀lú bí ìtẹ̀síwájú ṣe bá ìmọ̀ ẹ̀rọ, ṣé ebi kì í pa àwọn èèyàn kárí ayé?
Àwọn ìṣòro kan máa ń wáyé lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ àti ìyàn, ó sì jẹ́ apá mìíràn lára àwọn àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára àwọn ọmọdé tí òtútù àyà, ìgbẹ́ ọ̀rìn àtàwọn àìsàn míì ń pa ni kò bá máà kú ká ní wọ́n jẹunre kánú.”—ANN M. VENEMAN, TÓ FÌGBÀ KAN RÍ JẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OWÓ TÍ ÀJỌ ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ YÀ SỌ́TỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌMỌDÉ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
© Paul Lowe/Panos Pictures
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 3. ÀrùnIlé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 3. Àrùn
“Àwọn èèyàn yóò . . . ní àwọn àrùn burúkú.”—LÚÙKÙ 21:11, Bíbélì Contemporary English Version.
● Ọ̀gbẹ́ni Bonzali, tó jẹ́ olùtọ́jú àwọn aláìlera ní orílẹ̀-èdè kan tí ogun ti bà jẹ́ nílẹ̀ Áfíríkà ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tọ́jú àwọn òṣìṣẹ́ tó ń wa kùsà tí àrùn Marburg ń pa ní ìlú rẹ̀.a Ó ní kí àwọn aláṣẹ ìjọba tó wà ní ìlú ńlá ran òun lọ́wọ́, àmọ́ wọn kò dá a lóhùn. Lóṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, ìrànlọ́wọ́ dé, àmọ́, ọ̀gbẹ́ni Bonzali ti kú. Ó kó àrùn Marburg yìí lára àwọn awakùsà tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn là.
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Àwọn àìsàn tí kì í jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa (bí òtútù àyà), àrùn ìgbẹ́ ọ̀rìn, kòkòrò HIV àti àrùn éèdì, ikọ́ ẹ̀gbẹ àti ibà wà lára àwọn àrùn tó burú jù lọ tó ń yọ aráyé lẹ́nu. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn àrùn márùn-ún yìí pa èèyàn mílíọ̀nù tó tó mẹ́wàá àti ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [10, 700,000]. Tá a bá ní ká sọ ọ́ lọ́nà míì, àwọn àrùn yìí ń pa nǹkan bí èèyàn kan ní gbogbo ìṣẹ́jú àáyá mẹ́ta, láàárín ọdún kan.
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Iye àwọn èèyàn ayé ń pọ̀ sí i, nítorí náà ó dájú pé ńṣe ni àrùn á máa pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì lè kó àrùn.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Òótọ́ ni pé, iye àwọn èèyàn ayé ti pọ̀ gan-an. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà táwọn èèyàn lè gbà mọ àrùn kí wọ́n sì kápá rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe lè tọ́jú àrùn ti pọ̀ gan-an. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé kí ipa tí àrùn ń ní lórí èèyàn dín kù? Àmọ́, kò dín kù.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ àrùn burúkú ń ṣe àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀?
Ìmìtìtì ilẹ̀, ìyàn àti àrùn jẹ́ nǹkan ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Àmọ́ àwọn èèyàn fúnra wọn ń fìyà jẹ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn tó yẹ kó dáàbò bo àwọn èèyàn ló ń fìyà jẹ wọ́n. Kíyè sí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tó ń fa àrùn Marburg Hemorrhagic Fever jọ ohun tó ń fa àrùn Ebola.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Ohun tó burú ni kí kìnnìún tàbí ohun kan pani jẹ, àmọ́ ohun tó tún burú bí ìyẹn ni kí àrùn burúkú kan jẹ gbogbo ara èèyàn, kéèyàn sì rí i tí ohun kan náà ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó yíni ká.”—Ọ̀GBẸ́NI MICHAEL OSTERHOLM TÓ JẸ́ ONÍMỌ̀ NÍPA ÀRÙN.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]
© William Daniels/Panos Pictures
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 4. Kò Sí Ìfẹ́ Nínú Ìdílé Mọ́Ilé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 4. Kò Sí Ìfẹ́ Nínú Ìdílé Mọ́
‘Àwọn èèyàn kì yóò ní ìfẹ́ tó yẹ fún àwọn ìdílé wọn.’—2 TÍMÓTÌ 3:1-3, God’s Word Bible
● Obìnrin kan tó ń jẹ́ Chris jẹ́ òṣìṣẹ́ àwùjọ tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n hùwà ipá sí nínú ilé ní North Wales. Ọ̀gbẹ́ni Chris sọ pé, “Mo rántí ọmọbìnrin kan tó wọlé wá, wọ́n ti lù ú nílùkulù débi pé, mi ò dá a mọ̀ mọ́. Ẹ̀dùn ọkàn àwọn obìnrin míì pọ̀ débi pé, wọn kò ní lè gbójú sókè wo ìwọ tó ò ń bá wọn sọ̀rọ̀.”
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, nǹkan bí obìnrin kan nínú mẹ́ta ni wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe láti kékeré. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè yìí kan náà, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìdajì àwọn ọkùnrin tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé kò burú láti lu ìyàwó wọn. Àmọ́, kì í ṣe àwọn obìnrin nìkan ni wọ́n ń hùwà ipá sí nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Kánádà nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ta nínú mẹ́wàá ni ìyàwó wọ́n ti lù nílùkulù tàbí hùwà ìkà sí.
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Ó ti pẹ́ tí ìwà ipá ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé. Àmọ́ ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ lóde òní ni pé, wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ nípa rẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ gan-an nípa ìwà ipá inú ilé láti ohun tó lé lógún ọdún sí àkókò yìí. Àmọ́, ṣé bí wọ́n ṣe ń kéde ìṣòro yìí fáyé gbọ́ ti jẹ́ kí ìwà ipá inú ilé dín kù? Rárá o. Ńṣe ni àìsí ìfẹ́ nínú ìdílé túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ohun tó wà nínú ìwé 2 Tímótì 3:1-3 ló ń ṣẹ? Ṣé òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní ìfẹ́ tó yẹ fún àwọn ìdílé wọn?
Àsọtẹ́lẹ̀ karùn-ún tó ń ṣẹ lákòókò yìí kan ayé tó jẹ́ ilé wa. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Wọ́n sọ pé, ìwà ipá inú ilé jẹ́ ìwà ọ̀daràn tí wọn kì í sọ síta láwùjọ wa lónìí. Ìwádìí fi hàn pé ó máa ń tó ìgbà márùndínlógójì [35] ni ọkọ kan máa ń hùwà ìkà sí ìyàwó rẹ̀ kí obìnrin náà tó sọ fún ọlọ́pàá.”—AGBỌ̀RỌ̀SỌ ÀWÙJỌ TÓ Ń ṢÈRÀNWỌ́ FÚN ÀWỌN TÍ WỌ́N HÙWÀ IPÁ SÍ NÍNÚ ILÉ NÍLẸ̀ WALES.
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 5. Pípa Ilẹ̀ Ayé RunIlé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 5. Pípa Ilẹ̀ Ayé Run
“[Ọlọ́run yóò] run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—ÌṢÍPAYÁ 11:18.
● Ẹmu ni ọ̀gbẹ́ni Pirri máa ń dá, abúlé kan tó ń jẹ́ Kpor ló ń gbé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Iṣẹ́ tó ń ṣe bà jẹ́ nígbà tí epo rẹpẹtẹ dà sórí ilẹ̀ ní agbègbè Niger Delta. Ọ̀gbẹ́ni yìí sọ pé, “Ó pa àwọn ẹja wa, ó ba awọ ara wa jẹ́, ó sì ba àwọn odò wa jẹ́. Mi ò ní iṣẹ́ tí mo lè fi gbọ́ bùkátà ara mi mọ́.”
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé, òbítíbitì pàǹtí tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ tọ́ọ̀nù ló ń wọnú àwọn òkun ayé yìí lọ́dọọdún. Wọ́n sọ pé ìdajì àwọn pàǹtí náà ló jẹ́ ike, tí omi á máa gbé kiri fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí wọ́n tó pòórá. Yàtọ̀ sí bíba ayé jẹ́, àwọn èèyàn tún ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ayé ní ìlòkulò lọ́nà tó bani lẹ́rù. Ìwádìí fi hàn pé, ilẹ̀ ayé nílò ọdún kan àtoṣù márùn-ún láti ṣe ìmúbọ̀sípò ohun àmúṣọrọ̀ tí aráyé lò lọ́dún kan ṣoṣo. Ìwé ìròyìn Sydney Morning Herald, láti ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Bí iye èèyàn bá ń pọ̀ sí i bó ṣe ń pọ̀ sí i yìí, tí àwọn èèyàn sì ń lo ohun àmúṣọrọ̀ ayé bí wọ́n ṣe ń lò ó yìí, a máa nílò ayé méjì míì tó bá máa fi di ọdún 2035.”
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Ẹ̀dá tó ní làákàyè ni èèyàn. A lè wá ojútùú sí àwọn ìṣòro yìí, kí á sì gba ayé lọ́wọ́ ewu.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Ọ̀pọ̀ èèyàn, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti ní ẹgbẹẹgbẹ́ ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa tún àyíká ṣe. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ṣì ń ba ayé jẹ́ lọ́nà tó bùáyà.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ ìdí kankan wà tó fi yẹ kí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà, kó sì gba ayé wa lọ́wọ́ àwọn tó ń pa á run, gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí?
Yàtọ̀ sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì márùn-ún tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, Bíbélì tún sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó ń mọ́kàn yọ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò nínú àsọtẹ́lẹ̀ kẹfà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
“Ńṣe ló dà bíi pé mo kúrò nínú Párádísè tí mo sì wá ń gbénú ìdọ̀tí olóró.”—ERIN TAMBER, TÓ Ń GBÉ NÍ ÈTÍKUN GULF, LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ, NÍPA ÀBÁJÁDE EPO TÓ DÀ SÓRÍ ILẸ̀ LỌ́DÚN 2010 NÍ GULF OF MEXICO.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ṣé Ọlọ́run Ló Fà Á?
Nígbà tó jẹ́ pé Bíbélì ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan búburú tí à ń rí lónìí, ṣé ìyẹn wá fi hàn pé Ọlọ́run ló fà á? Ṣé Ọlọ́run ló fà á tí a fi ń jìyà? Wàá rí ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè yìí ní orí 11 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
U.S. Coast Guard photo
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 6. Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Kárí AyéIlé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Àsọtẹ́lẹ̀ 6. Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Kárí Ayé
“A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—MÁTÍÙ 24:14.
● Obìnrin kan tó ń jẹ́ Vaiatea ń gbé ní erékùṣù Pàsífíìkì tó wà ní àdádó ní Tuamotu Archipelago. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, erékùṣù Tuamotu ní nǹkan bí ọgọ́rin [80] erékùṣù káàkiri agbègbè tó fẹ̀ ju ogójì ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbàá àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (802,900) kìlómítà lọ, síbẹ̀ nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [16,000] èèyàn ló ń gbé ibẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí lọ sọ́dọ̀ Vaiatea àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn, ní ibi yòówù kí wọ́n máa gbé.
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń dé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún 2010 nìkan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún mẹ́fà wákàtí láti wàásù ìhìn rere yìí ní ilẹ̀ igba àti mẹ́rìndínlógójì [236]. Ìyẹn sì túmọ̀ sí pé, ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ni Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan lò láti fi wàásù lójúmọ́. Ní ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá báyìí, wọ́n ti ṣe ìtẹ̀jáde tó lé ní ogún bílíọ̀nù, wọ́n sì ti pín wọn fún àwọn èèyàn.
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni wọ́n ti ń wàásù ohun tó wà nínú Bíbélì.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Òótọ́ ni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ti wàásù nípa ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, ìgbà díẹ̀ ni ọ̀pọ̀ fi ṣe é, ibi tí wọ́n sì ṣe é dé kò tó nǹkan. Ṣùgbọ́n ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀, wọ́n ti ń ṣe ìṣẹ́ ìwàásù tó kárí ayé tó sì dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe láìka àtakò tí àwọn alágbára kan tí wọ́n jẹ́ aláìláàánú ṣe sí wọn sí.a (Máàkù 13:13) Síwájú sí i, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba owó nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n yọ̀ǹda àkókò wọn, wọ́n sì ń fún àwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde wọn lọ́fẹ̀ẹ́. Ọrẹ àtinúwá ni wọ́n fi ń ṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wọn.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ìwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” ti kárí ayé? Ṣé bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ fi hàn pé ohun kan tí ó dára jù ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo fídíò mẹ́ta yìí, “Faithful Under Trials,” “Purple Triangles,” àti “Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń pín wọn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“A óò máa bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà nìṣó pẹ̀lú ìtara, a ó sì máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti wàásù fún àwọn èèyàn títí Jèhófà fi máa sọ pé, ó tó.”—2010 YEARBOOK OF JEHOVAH’S WITNESSES.
-
-
Ohun Tó Dára Jù Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú!Ilé Ìṣọ́—2011 | May 1
-
-
Ohun Tó Dára Jù Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú!
“Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—SÁÀMÙ 37:10, 11.
ṢÉ O fẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà lókè yìí ṣẹ? Ó dájú pé wàá fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà pé ó máa tó ṣẹ.
Àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ nípa àwọn kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó fi hàn kedere pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Bíbélì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn kí á bàa lè ní ìrètí. (Róòmù 15:4) Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ fi hàn pé àwọn ìṣòro tí à ń dojú kọ nísinsìnyí yóò dópin láìpẹ́.
Kí ló máa wáyé lẹ́yìn àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso gbogbo aráyé. (Mátíù 6:9) Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ipò ayé ṣe máa rí nígbà yẹn:
● Kò ní sí ebi mọ́. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.
● Kò ní sí àrùn mọ́. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.
● Ilẹ̀ ayé máa di ọ̀tun. “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.”—Aísáyà 35:1.
Èyí jẹ́ díẹ̀ lára àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá tí Bíbélì sọ, tí yóò ṣẹ láìpẹ́. O kò ṣe ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìdí tó fi dá wọn lójú hàn ẹ́ pé ohun tó dára jù ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
-